O ṣẹlẹ: Awọn ole fọ banki l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn adigunjale ti fọ banki Wema to wa niluu Iyin-Ekiti, nijọba ibilẹ Irẹpọdun/Ifẹlodun, nipinlẹ Ekiti.

Ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan yii ni wọn sọ pe awọn eeyan naa ya bo ilu ọhun, ti wọn si da ibọn bolẹ, bẹẹ ni wọn fi awọn nnkan abugbamu fọ ilẹkun ileefowopamọ naa.

Ẹnikan tọrọ naa ṣoju ẹ sọ pe bi awọn eeyan ṣe n gbọ iro ibọn ni wọn sa lọ, fun bii ọgbọn iṣẹju lawọn eeyan naa si fi ṣọṣẹ, bẹẹ lawọn ọlọpaa ko yọju.

Ẹni naa waa sọ pe nnkan ayọ kan ṣoṣo to ṣẹlẹ ni pe iṣẹlẹ naa ko mu ẹmi lọ, ṣugbọn awọn ole naa ri owo gbe.

Alukoro ọlọpaa, Sunday Abutu, sọ pe awọn ọlọpaa n wa awọn ole naa ninu igbo ti wọn sa wọ lọwọlọwọ.

About admin

Check Also

Lanlọọdu ati getimaanu pa ọmọọdun mẹrin, wọn yọ ẹya ara ẹ lati fi ṣoogun owo

Faith Adebọla Diẹ lo ku kawọn araalu tinu n bi dana sun baba getimaanu kan …

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: