O ṣẹlẹ: Awọn ọtẹlẹmuyẹ mu Magu, ọga EFCC

Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ yii (DSS) ti mu ọga ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu (EFCC),  Ibrahim Magu.

ALAROYE gbọ pe wọn mu Magu lori dukia mẹrin to ni lọna aitọ, ati pe o n ko owo pamọ soke-okun.

Olu-ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Aso Drive niluu Abuja la gbọ pe wọn gbe e lọ, iyẹn lẹyin to ti kọkọ wa ni ọfiisi ileeṣẹ naa ni Wuse II, niluu kan naa.

Gẹgẹ bi iroyin to n lọ, iṣẹlẹ naa ko ṣẹyin iwadii awọn DSS lọdun 2016, eyi to sọ pe Magu n gbe ile nla kan towo ẹ to miliọnu lọna ogoji naira ti Ọgagun-fẹyinyi Umar Mohammed to jẹ adari nileeṣẹ ọmọ-ogun ori omi tẹlẹ ra fun un.

Bakan naa la gbọ pe ẹka to n ṣakoso ileeṣẹ ọlọpaa, Police Service Commission, sọ pe o jẹbi ẹsun aṣemaṣe kan an lọdun 2010.

Ajọ DSS ko ti i sọrọ lori iṣẹlẹ yii, bẹẹ ni gbogbo awọn to ti gbọ nipa ọrọ naa n reti abajade rẹ.

Ọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ọdun 2015, ni Magu di adele ọga-agba EFCC, ipo adele lo si wa di akoko yii.

About admin

Check Also

Awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori tiṣa to na ọmọleewe to fi ku l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko Afaimọ ni tiṣa ti wọn porukọ rẹ ni Ọgbẹni Stephen yii ko …

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: