O ṣẹlẹ: Buhari ju bọmbu ọrọ pada s’Ọbasanjọ

Nigba ti aarẹ tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti kọkọ sọ oko ọrọ ranṣẹ si olori ijọba ilẹ wa, Muhammadu Buhari, lọsẹ to kọja yii lawọn eeyan ti mọ pe ko si ki ọrọ naa ma di ija awọn aloku ṣọja meji, wọn mọ pe Buhari yoo fesi pada ṣaa ni. Ni irọlẹ Ọjọ Aiku, Sannde yii, ni esi ọrọ naa jade. Ṣugbọn ki i ṣe esi lasan, bombu ọrọ ni. Ileeṣẹ aarẹ ni bi awọn kan ba wa ti wọn fẹẹ pin Naijiria si wẹwẹ, tabi ti wọn fẹẹ sọ awọn ọmọ Naijiria di ọta ara wọn, iru awọn eeyan bẹẹ ko le ni olori tabi alaga meji ju Oluṣẹgun Ọbasanjọ lọ.

Bi ẹ ko ba ti i gbagbe, Ọjọbọ to kọja yii, iyẹn ọjọ Alamisi, ni Ọbasanjọ ju oko ọrọ ranṣe si Buhari, nibi ipade kan ti awọn agbaagba ẹya gbogbo ni Naijiria ṣe ni ilu Abuja. Nibẹ ni Ọbasanjọ ti sọ pe Buhari ati ijọba rẹ lo n sọ awọn ọmọ Naijiria di ọta ara wọn, awọn ni wọn n ṣe ijọba ẹlẹyamẹya, oun ko si ri iru rẹ ri lati ọjọ ti oun ti daye. Ṣugbọn Buhari sọrọ, lati ẹnu agbẹnusọ rẹ, Garba Shehu, o ni nigba ti oun Buhari n wa gbogbo ọna lati mu iṣọkan ba Naijiria, Ọbasanjọ pẹlu awọn kan wa nibi kan ti wọn n fi ọrọ ẹsin ati ẹlẹyamẹya pin Naijiria wẹlẹwẹlẹ.

Shehu ni Buhari ti ṣe bẹbẹ, ẹgan ni hẹẹ, ati pe gudugudu meje pẹlu yaayaa mẹfa ti baba naa n ṣe lo jẹ ki awọn eeyan bii Ọbasanjọ maa ṣe ilara ẹ, o ni ko si ohun meji to n da Ọbasanjọ laamu ju owu jijẹ lọ. O ni, “Buhari ti sọ Naijiria di ọrẹ awọn ilu odikeji, o ti mu idagbasoke ba eto ọrọ aje, bẹẹ lo ti ṣe agbekalẹ awọn ohun amayedẹrun gbogbo to ti bajẹ, o si tun ku oriṣiriṣi ti yoo ṣe. Ki waa ni awọn bii Ọbasanjọ ko ni i jowu rẹ si, nigba to jẹ ohun ti awọn ko le ṣe ni Buhari n ṣe!”

Buhari gba ẹnu Shehu sọro pe ori oke giga ni Ọbasanjọ wa ti gbogbo eeyan to o si, ṣugbọn o ti ko itiju ba awọn ti wọn fẹran rẹ pẹlu awọn ọrọ to n sọ, nitori wọn ro pe yoo maa pari ija nibi ti nnkan ba ti fẹẹ daru ni, ṣugbọn awọn naa ti ri i pe oun gan-an lo n da rugudu silẹ. Omọ Buhari yii waa ni Ọbasanjọ fẹran lati maa fi ara rẹ han gẹgẹ bi Mesaya ti aye n wi, oun naa si maa n ri ara rẹ bẹẹ pe Mesaya kan loun, eleyii lo si maa n jẹ ko ṣiwa hu, tabi ko ṣi ọrọ sọ, ti yoo si maa ro pe ko sẹni to le ṣe ilu daadaa bii toun. O ni nitori ẹ lo ṣe fẹẹ yi ofin pada nijọsi, ko le lo ju saa meji lọ lori aga ijọba, ko too di pe iyẹn ko ṣee ṣe fun un. O ni ki Ọbasanjọ lọọ jokoo jẹẹ, ko sinmi owu jijẹ ati ilara, ko si yee ro pe mesaya nla kan loun.

4 thoughts on “O ṣẹlẹ: Buhari ju bọmbu ọrọ pada s’Ọbasanjọ

 1. Ero ti temi ni wipe, Obasanjo ni
  lati pee si akiyesi to ba ri wipe nkan fe
  daru sugbon kiise wipe komaa ko awon eeyan kan jopo lati maa ru won nidi Sijoba ki wahala wa maa sele, opolopo nkan ti Obasanjo n so yii ni ohun naa ti kunna nigbati o wa nipo ijoba orileede yii.
  Lasiko yii , ao nilo oro to yio tun wa maa da rugudu sile, laikojepe saa odun mejo re pe kosi nkan taale se sii
  ayaafi ti abakan fe ba iluje ni, Olohun ko lawa ooo. Orileede yii maa di ilu ifokanbale lagbara Olohun. Amin

 2. Otito ti sonu lenu koowa wa,
  Ojo ni si n pawa ku lo, ki Olorun gbawa.
  Gbogbo olori ologun ile, ofurufu, omi,
  To fi mo oga asobode ati iwolewode abbl, ti di eya kan naa.
  E dakun kin ni erongba won?

Leave a Reply