O ṣẹlẹ, DPO Iyaganku gbe telọ rẹ lọ si kootu, o ni ko ranṣọ oun daadaa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pupọ ninu awọn to gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni wọn n bu ẹnu atẹ lu ọga ọlọpaa kan, CSP Alex Sanni Gwazah, to jẹ DPO agọ ọlọpaa Iyaganku, n’Ibadan, pẹlu bo ṣe fiya jẹ telọ rẹ, bẹẹ lo tun gbe e lọ si kootu, to si fẹsun ọdaran kan an, o lọkunrin naa ko ran aṣọ oun daadaa foun.

Ìkẹ́ tabi ibukun ni telọ ọhun, Lukman Adeniyi ka a si nigba ti ọkan ninu awọn onibaara rẹ mu un mọ ọga ọlọpaa teṣan Iyaganku, paapaa nigba ti iyẹn gbe oriṣii aṣọ mejila fun un lati ran lẹẹkan naa, to si jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira (N60,000) lowo ti wọn jọ ṣadehun lati fi ranṣọ naa lai mọ pe iya ati ifasẹyin nla niṣẹ naa yoo mu ba oun.

Tidunnu tidunnu l’Ọgbẹni Adeniyi fi lọọ gbe aṣọ naa fun CSP Gwazah lọfiisi ẹ ni Iyaganku nigba to ran an tan, ṣugbọn ibanujẹ lo ba kuro nibẹ, ko faraare pada sile lọjọ naa pẹlu. Idi ni pe awọn aṣọ to ran fun onibaara rẹ yii ko tẹ ẹ lọrun rara.

DPO

Bo tilẹ jẹ pe o gba awọn aṣọ naa ti ko si sanwo iṣẹ ti ẹni ẹlẹni ṣe fun un, igbaju olooyi lo kọkọ fi da sẹria fun telọ yii ti baba onibaba si ba ibanujẹ nla pada sile pẹlu ọwọ ofo.

Ṣugbọn lẹyin ti ọkunrin telọ yii ti lọ tan, ibinu ọga ọlọpaa tun ru soke, o gba pe baba aranṣọ naa ni lati jiya ju bẹẹ lọ, nigba naa lo ranṣẹ pe e pada wa a ba a lọfiisi rẹ, to si ti i mọle gẹgẹ bii ọdaran ni teṣan naa. Ọjọ kẹta, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lo too gba beeli rẹ, ko si deede fi i silẹ bẹẹ, o gbe e lọ si kootu ni, ẹsun ọdaran lo si fi kan an.

Yara igbẹjọ kẹjọ ile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Iyaganku, n’Ibadan, nigbẹjọ ọhun ti waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Nigba to n ṣalaye idi to fi pe baba aranṣọ rẹ yii lẹjọ, DPO teṣan Iyaganku sọ pe oriṣii aṣọ mejila ọtọọtọ ti oun ra pẹlu owo nla lọkunrin naa ran ni irankuran-an wọnyẹn, ẹgbẹrun mọkanlelọgọsan-an Naira (181) loun si fi ra wọn.

O ni nitori ti telọ ran awọn aṣọ naa lọna ti ko tẹ oun lọrun, to si ṣe bẹẹ bààná owo nla ti oun fi ra wọn, o jẹbi ẹsun ọdaran, nitori naa, dandan ni kile-ẹjọ ba oun fiya jẹ ẹ.

Ṣugbọn olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ọdaran, olujẹjọ kan n lo agbara rẹ nilokulo le oun lori ni nitori ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira (N60,000) loun fi ra awọn nnkan eelo ti oun fi ran awọn aṣọ naa, ṣugbọn niṣe lọga ọlọpaa yii kan gba awọn aṣọ naa lọwọ oun lai san kọbọ foun.

Ṣaaju igbẹjọ lolujẹjọ ti ṣalaye pe “Mi o ranti ọjọ ti mo ti sunkun gbẹyin laye mi, afi lọjọ ti mo lọọ gbe aṣọ fun ọkunrin DPO yii. Niṣe lo fọ mi leti bii ẹni pe mo ja a lole, bẹẹ ko fun mi lowo iṣẹ ti mo ṣe.

“Ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira (60,000) lowo ta a jọ ṣadehun, ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (N50,000) ni mo fi ra màtíríàsì, ṣugbọn o kan gba awọn aṣọ yẹn lọwọ mi ni, ko san kọbọ fun mi ninu owo yẹn.

“Lọjọ keji lo pe mi pe ki n waa gbowo mi lai mọ pe o fẹẹ ti mi mọle ni. Ifọti mi-in lo kọkọ fun mi ko too paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ pe ki wọn ti mi mọle.”

Gẹgẹ bi iwadii ALAROYE ṣe fidi ẹ mulẹ, eyi kọ nigba akọkọ ti CSP Gwazah yoo fija jẹ ẹni to ba ba a ṣiṣẹ. Wọn lo ti ṣe bẹẹ fọ telọ kan leti nigba kan ri. Ṣugbọn iya to fi jẹ onitọhun ko to bayii nitori o fun iyẹn lẹgbẹrun lọna ogun Naira (N20,000) ninu ẹgbẹrun lọna ogoji Naira (N40,000) to yẹ ko san. Ẹsun to fi kan onitọhun naa ni pe ko ba oun ran awọn aṣọ ti oun gbe fun un daadaa to.

Ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin la gbọ pe DPO yii fọ ọlọpaa ẹgbẹ ẹ leti lori ọrọ ti ko to nnkan, ọlọpaa to si fọ leti yii naa ki i ṣe ọmọ kekere lẹnu iṣẹ, o ti gboye DSP lẹnu ṣẹ agbofinro.

Ṣaaju asiko yii lo binu sọ ọkunrin kan naa satimọle, lẹta ni iyẹn lọọ fi jiṣẹ fun un lọfiisi to fi ba ibinu ọga ọlọpaa yii pade, o ni ko tete mu lẹta ọhun wa, ohun to si tori ẹ sọ ọ satimọle ko ju iyẹn naa lọ.

Nigba to n sọrọ lori ọrọ to wa ni kootu yii, agbẹjọro telọ ti onibaara rẹ pe lẹjọ yii, Amofin Jubril Muhammed, ṣapejuwe iwa ọga ọlọpaa naa gẹgẹ bii aṣilo agbara.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Bawo leeyan yoo ṣe sọ ara ẹ di adajọ lori ẹjọ to kan oun funra rẹ. Oun gẹgẹ bii DPO lo ti olujẹjọ mọle lẹyin to ti fipa mu un lati kọ sítétímẹ́ǹtì lọfiisi ẹ ni teṣan Iyaganku, oun yii lo fọwọ si iwe ipẹjọ. Idajọ ododo maa waye nigba to ba ya ṣaa.”

Adajọ kootu naa, Onidaajọ-binrin Ọlajumọkẹ Akande, gba beeli olujẹjọ pẹlu oniduuro meji ati ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (N50,000), o waa sun igbẹjọ naa si ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun (17) oṣu kọkanla ọdun 2020 yii.

 

Leave a Reply