O ṣẹlẹ, ẹgbẹ APC da awọn ọmọ ẹyin Lai Muhammed mọkanla duro ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ẹgbẹ oṣelu APC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti da ọmọ ẹgbẹ mọkanla to jẹ ọmọ ẹyin Minisita fun eto ibanisọrọ ati aṣa nilẹ yii, Lai Muhammed, duro fẹsun pe wọn n ṣe oju meji ninu ẹgbẹ.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe igbimọ alaga afun-un-sọ nilẹ yii, James Akpanudoedeche, buwọ lu to fi ṣọwọ si alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni Kwara, Abdullahi Samari Abubakar, ni ọrọ naa ti jade.

Awọn tọrọ naa kan ti wọn da duro ni: Joseph Tsado, Bamidele Ogunbayọ, Issa Fulani, Bọla Ajani, Imam Abdulkadir, Morufu Ọlaniyi Yusuf, Salaudeen Lukman, Kerebu Fatai, Nurudeen Fasasi, Salman Shehu Babatunde ati Abdullateef Ahmed Kọlawọle.

Wọn ni ẹgbẹ naa fiya jẹ wọn latari pe wọn wọ alaga ẹgbẹ wọn, Abdullahi Samari Abubakar, lọ sile-ẹjọ, wọn ni awọn ko fọwọ si iyansipo rẹ.

Awọn igun ti minisita naa ni wọn ta ko iyọnipo alaga tẹlẹ ọhun, Bashir Bọlarinwa. Eyi lo da gbọn-mi-si-i, omi-o to-o silẹ ninu ẹgbẹ, ti ẹgbẹ ọhun si pin si meji, eyi to mu ki minisita ati gomina maa jija ẹni to ni ẹgbẹ nipinlẹ naa. Eyi lo fa a tawọn mọkanla yii fi gba ile-ẹjọ lọ, ti wọn si n pe fun ki kootu yọ Samari kuro nipo gẹgẹ bii alaga.

Leave a Reply