O ṣẹlẹ, ija nla bẹ silẹ laarin Mr Latin ati Pariolodo

Adewale Adeoye

‘’Ni gbogbo ọna, mi o ki i ṣegbe rẹ, loootọ, o le lowo lọwọ ju mi lọ bayii, ṣugbọn iyẹn ko sọ pe ko o ri mi fin rara, ki i ṣe bi emi naa ṣe maa ba ku ree, bẹẹ, ori lo duro fun agbọn mu omi, mo wa lara awọn oṣere tiata to kọkọ lana fun iru yin tẹ ẹ ṣẹṣẹ de lojiji.

‘‘Ọbẹ dun tan, adamu yin waa n bu u la bayii. Bi ko baa-se kin ni baa-la fẹẹ la. Mo wa lara awọn to fori laku nidii iṣẹ tiata, to waa dohun ti gbogbo yin waa n jẹ ninu rẹ bo ṣe wu yin. ‘‘Lọdun 1976 ti mo bẹrẹ iṣẹ tiata, o daju daadaa pe ileewe girama lo ṣi wa lakooko naa, mi o ki i ṣẹgbẹ rẹ rara nidii iṣẹ yii, igiimu si jinna gan-an sori’’.

Eyi lọrọ to n jade lẹnu agba osere tiata nni, Ṣola Ọlanipẹkun, ẹni tawọn eeyan mọ si Pariolodo, ninu awọn fiimu agbelewo gbogbo to n jade lorileede wa Naijiria.

ALAROYE gbọ pe, ọrọ mọto bọginni kan bayii ti awọn araalu dawo jọ ra fun Pariolodo lo n bi Mr Latin ninu, to si fi sọrọ odi si gbogbo awọn oṣere tiata kọọkan ti wọn n tọrọ mọto lọwọ awon araalu bayii. Ni pataki ju lọ, ọrọ ti Latin  sọ si Pariolodo ni pe ki i ṣohun to daa rara bawọn to pe ara wọn ni agba ọjẹ nidii iṣẹ tiata naa ṣe n tọrọ mọto gẹgẹ bi Pariolodo naa ṣe se lẹyin taọn kan ti kọkọ ṣe bẹẹ. Mr Latin ni lara idi pataki toun gẹgẹ bii aarẹ ẹgbẹ oṣere ‘TAMPAN’ ko ṣe dide iranlọwọ kankan fawọn oṣere tiata mi-in ni pe ọpọ lara wọn ni wọn ki i da sọrọ ẹgbẹ nigba ti wọn ṣi n ṣe daadaa laaarọ ọjọ wọn.

Ohun ta a tiẹ gbọ ni pe ṣe ni Latin fajuro gidi si bi Pariolodo ti ṣe gbe fidio oniṣẹju diẹ kan bayii sita, nibi to ti n bẹ awọn araalu pe kawọn ẹlẹyinju aanu ọmọ orilẹ-ede yii ṣaanu oun, ki wọn fun oun naa ni mọto lati maa fi ṣẹsẹ rin kaakiri ilu Eko, to ni iya airi mọto toun n dojukọ ti to gẹẹ.

Wọn lọrọ ti Latin sọ si Pariolodo pe ki wọn yee tabuku ẹgbẹ atawọn oloye ẹgbẹ gbogbo lo bi Pariolodo ninu to fi juko ọrọ ranṣẹ si aaerẹ ẹgbẹ onitiata yii.

Pariolodo ni lara pe Latin daju gidi ni, o ni ki lo de ti ko da sọrọ, tabi gbe igbesẹ gidi kan nigba ti agba oṣere nni, Baba Ijẹsha, n jẹjọ lọwọ, ko too di pe wọn ju u ṣewọn.

Ninu fidio kan ti baba naa ṣe sori ayelujara lo ti kilọ fun Latin pe oun ki i ṣẹgbẹ rẹ ni gbogbo ọna, ati pe ko yee ṣe ilara oun lori ohun kekere ti Ọlọrun ṣe foun yii.

Bakan naa ni Pariolodo tun dupẹ  lọwọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ gbogbo bii: Ọlaiya Igwe, Adekọla Tijani, Sanyeri ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn ti ba a dupẹ lori ohun ti Ọlọrun Ọba ṣe fun un yii.

O ni gbogbo awọn oṣere toun darukọ wọn pata yii ni wọn ti pe oun lori foonu, ti wọn si ti b’oun yọ ayọ idunu fohun ti Ọlọrun ṣe foun yii, ṣugbọn eyi ti Latin iba fi ba oloore yọ ayọ ohun to daa, niṣe lo n binu oun.

Leave a Reply