Owo dọla ti ko din ni miliọnu mẹrin aabọ ni ọkunrin kan, Murambiwa Murangariri, ọmọ orilẹ-ede Zimbabwe, n beere bayii lọwọ ọkunrin mi-in torukọ tiẹ n jẹ Tineyi Lavite. Alajọgbe lawọn mejeeji, ṣugbọn Tineyi n ba iyawo ọkunrin akọkọ yii ṣerekere, ere ọhun si di ọmọ ọkunrin lantilanti.
Ile-ẹjọ ni Maurambiwa gba lọ lẹyin ti ayẹwo DNA fi han pe ọmọ tiyawo rẹ bi gbẹyin ki i ṣe tiẹ, nibẹ naa lo si ti ni oun yoo gba miliọnu mẹta owo dọla fun itọju ọmọ naa toun ti n ṣe tipẹ,(ọmọ ti dagba bayii).
O loun yoo gba miliọnu kan naira owo iyalẹnu ati ṣọọki ti iwa iyawo oun ko ba oun, bẹẹ lo ni idaji miliọnu dọla yoo wa fun idojuti tiyawo naa ko oun si laduugbo, gbogbo rẹ yoo si jẹ miliọnu mẹrin aabọ owo dọla.
Gẹgẹ bi Maurambiwa to gbe iyawo rẹ torukọ ẹ n jẹ Chipo Musonza lọ si kootu ṣe ṣalaye, o ni ọdun kẹtadinlọgbọn ree tawọn ti ṣegbeyawo, obinrin naa si bimọ mẹrin foun.
Awọn mẹta akọkọ lo jẹ tiẹ ṣa, abigbẹyin wọn to jẹ ọkunrin ki i ṣe ti Maurambiwa gẹgẹ bi DNA ṣe sọ.
Ọkunrin yii naa ṣalaye fun kootu pe oun ko deede lọọ ṣayẹwo ẹjẹ fun ọmọ abigbẹyin naa, o ni oun ti ka iyawo oun ati ọkunrin tawọn jọ n gbele naa ri ti wọn n ṣe aṣemaṣe.
O fi kun alaye ẹ pe kootu ibilẹ niluu awọn ti figba kan paṣẹ fun Tineyi to n ba iyawo oun sun pe ko pese ẹranko meji gẹgẹ bii itanran iwa agbere to n hu naa, ṣugbọn bo ṣe san an tan lo tun tẹsiwaju ninu biba iyawo oun sun lọ.
Ibaṣepọ naa ko tilẹ bo rara gẹgẹ bi ọkọ iyawo yii ṣe wi, o ni niṣe ni Tineyi maa n fi oun ṣe yẹyẹ loju awọn eeyan pe oun ko to ọkunrin, nitori ẹ loun ṣe fọ Chipo, iyawo Maurambiwa, lẹnu.
Igbeyawo naa ti foriṣanpọn bayii o, owo itanran lo ku ti Maurambiwa n beere lọwọ Tineyi, miliọnu mẹrin aabọ dọla si ni.