O ṣẹlẹ, Portable jade tan fun Bobrisky, eyi nimọran to fun un

Jọkẹ Amọri

Ọkunrin olorin tẹnu ki i sin lara rẹ nni, Okikiọla Ọmọ Ọlalọmi, ti gbogbo eeyan mọ si Portable, ti gba ọmọkunrin to maa n mura bii obinrin nni, Idris Okunnẹyẹ, ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky nimọran o. Orin lo kọ to fi gba a nimọran pe ko afi ko ronupiwada. Portable ni Ọlọrun ko fẹ iku ẹlẹṣẹ, afi ko ronupiwada. O ni egbe ni fun ẹnikẹni, iyẹn ẹlẹṣẹ ti ko ronupiwada.

Portable ni ki Bobridky ma lọọ pokunso o, nitori to ba tun ku, inu ina lo maa wọ. O ni Ọlọrun ko fẹ iku ẹlẹṣẹ o. Ki Bobriaky ronupiwada lo daa. O ni gbogbo nnkan to n feesi yẹn, to ba tonupiwada, o maa jere aye. Ṣugbọn ti ko ba ronupiwada, aparo ko ronupiwada lo fi paro.

Imọran Portable ko sẹyin ọrọ kan ti ọmọkunrin to maa n ṣe bii obinrin yii kọ sori ikanni rẹ laipẹ yii pe, ‘’Mi o ronu nipa pe ki eeyan binu para rẹ ri laye mi, ṣugbọn ni bayii, ọrọ naa n wa sori mi nigba ti mo ri ohun ti eeyan n ṣe fun ẹlẹran ara ẹgbẹ rẹ lati fa wọn wa silẹ ni tipatipa nitori wọn ko fẹran onitọhun. Mi o nilo idaro lati ọdọ ẹnikẹni. Awọn eeyan ti mo le ni idaro wọn ni awọn obi mi. Ṣugbọn ta lo feẹ ja fun ọ? Ṣe ọrẹ ni? Ẹyin abinu ẹni, ẹ ṣaṣeyọri lori eleyii.

O jọ pe ọrọ yii ni Portable ri to fi n gba Bobrisaky nimọran pe ki o ronupiwada. O ni ironupiwada lo nilo, ki i ṣe iru igbesẹ to fẹẹ gbe yii.

Tẹ o ba gbagbe, Portable ti figba kan wọ studio nitori Bobrisky, to si ṣe awo orin fun un lasiko ti wahala kan waye laarin awọn mejeeji. Ṣugbọn ko ti i ṣe awo orin fun un lọwọ yii, imọran lo kan gba a.

Leave a Reply