O ṣẹlẹ! Wọn ji Nwosu, ọkọ ọmọ gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ

Faith Adebọla

Awọn afurasi ajinigbe ti tun gba ọna mi-in yọ nipinlẹ Imo, ondije-dupo gomina ipinlẹ naa, Ọgbẹni Uche Nwosu, to jẹ ọkọ ọmọ gomina ana nipinlẹ ọhun, Ọgbẹni Rochas Owelle Okorocha, ni wọn ji gbe lọjọ Aiku, Sannde yii.

ALAROYE gbọ pe niṣe ni eto isin ti wọn n ṣe lọwọ ni ṣọọṣi Saint Peter’s Anglican Church, Eziama-Obire, nijọba ibilẹ Nkwere, ipinlẹ Imo, daru, ti ọrọ si di bo-o-lọ-o-yago nigba tawọn agbebọn ṣadeede ya bo ileejọsin ọhun, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ.

Nwosu, to jẹ oludije funpo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, wa ninu ṣọọṣi naa fun eto isin idupẹ to n lọ lọwọ lọjọ Sannde ọhun, fun ti ayẹyẹ isinku iya rẹ, Oloogbe Jemaimah Nwosu, eyi ti wọn sinku rẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja.

Lati ọjọ Aiku, Mọnde, to kọja, lọkunrin naa atawọn mọlẹbi rẹ ti wa lagbegbe ọhun fun ti ayẹyẹ isinku ọhun.

Ẹnikan to lọrọ naa ṣoju oun sọ pe ojiji ni iro ibọn bẹrẹ si i dun layiika ṣọọṣi naa. Awọn agbebọn naa wọle, wọn ni ki kaluku doju bolẹ, wọn si gan Nwosu lapa, ni wọn ba mu un lọ sinu ọkọ ayọkẹlẹ kan ti wọn gbe siwaju ọgba ṣọọṣi ọhun, o ni inu buutu ẹyin ọkọ ọhun ni wọn sọ ọ si, lẹsẹkẹsẹ si ni wọn wa a lọ.

Ko ti i sẹni to gburoo ibi ti wọn dori ọkọ naa kọ lasiko yii, bẹẹ lawọn ajinigbe naa ko ti i kan sawọn mọlẹbi lati beere ohun ti wọn maa gba ki wọn too tu Nwosu silẹ.

Uche Nwosu ni kọmiṣanna fun ọrọ ilẹ nipinlẹ Imo lati ọdun 2013 si 2015, ki wọn too yan an sipo olori awọn oṣiṣẹ ọba ipinlẹ ọhun lọdun 2015 si 2019.

Iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ yii.

Leave a Reply