O ṣẹlẹ, wọn lẹni to fẹẹ jẹrii ta ko Fayoṣe nile-ẹjọ ti ko Korona

Faith Adebọla, Eko

Ẹjọ ti gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ọgbẹni Peter Ayọdele Fayoṣe, n jẹ lọwọ lori ẹsun ikowojẹ ko le tẹsiwaju lọjọ Ẹti, Furaidee, latari bi ajọ EFCC ti i ṣe olupẹjọ ṣe sọ nile-ẹjọ pe ẹlẹrii pataki tawọn fẹẹ mu wa ti ko arun Korona bayii.

Agbẹjọro fun ajọ to n gbogun tiwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku (Economic and Financial Crimes Commission), Amofin agba Rotimi Jacobs, lo sọ eyi nigba ti ẹjọ naa waye nile-ẹjọ giga tijọba apapọ to wa niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko.

O ni loootọ loun ṣeleri lati mu ẹlẹrii to ṣe pataki ju ninu ẹjọ naa wa lonii, ilu oyinbo lẹni naa ti fẹẹ wa, ṣugbọn alẹ ana, Ọjọbọ, Tọsidee yii, loun ṣẹṣẹ gbọ nipa ipo ti ilera onitọhun wa, wọn lo ti lugbadi arun Korona lorileede rẹ, ibudo itọju lo si wa bayii, ko le wọ baluu, debi ti yoo le waa ṣẹlẹrii.

Rotimi ni: “Oluwaa mi, ẹlẹrii mẹrin ni mo ṣeto lati fi gbe awijare mi lẹsẹ ninu ẹjọ yii, alẹ ana ni mo gbọ pe arun Korona ti mu ọkan to fẹẹ wa latilu oyinbo, ko si lokun ninu lasiko yii rara, tori o n gba itọju lọwọ. Ko ṣee ṣe fun mi lati ri awọn meji mi-in wa, ẹlẹrii kan ṣoṣo lo wa pẹlu mi nibi lonii.”

“Ni ti ẹlẹrii akọkọ ti mọ sọ yẹn, mi o mọ igba ti ara rẹ maa ya, itọju arun COVID-19 yii ko ṣee da pato rẹ, Oluwaa mi.”

Agbejọro fun olujẹjọ, Amofin agba Ọla Ọlanipẹkun, fesi si ọrọ yii, o ni yatọ si ti pe awọn ẹlẹrii olupẹjọ ko si ni kootu, akọsilẹ awọn ọrọ tawọn ẹlẹrii naa ti sọ, ti wọn ti kọ, ko ti i tẹ awọn lọwọ latọjọ yii. O ni igba toun n sọkalẹ ni papakọ ofurufu n’Ikẹja, laaarọ ọjọ Ẹti lati wa si kootu ni wọn ṣẹṣẹ mu ọkan ninu awọn akọsilẹ ọhun foun, bawo waa loun ṣe fẹẹ mọ ibeere to yẹ lati beere lọwọ awọn ẹlẹrii nigba ti ẹri wọn ko tẹ oun lọwọ lasiko.

Bakan naa ni agbẹjọro fun ileeṣẹ Spotless Investments Limited to jẹjọ ẹsun kan naa pẹlu Fayoṣe, Amofin agba Ọlalekan Ojo, sọ pe oun fara mọ awijare agbẹjọro Fayoṣe, tori nnkan bii aago mẹrin irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ni olupẹjọ ṣẹṣẹ fi awọn akọsilẹ kan ṣọwọ soun lori atẹ Wasaapu (Whatsapp) oun, bẹẹ o yẹ ki wọn ti fi i ranṣẹ ṣaaju.

O tun loun ko faramọ ki olupẹjọ pe ẹlẹrii tuntun lori ẹjọ yii, awọn ti wọn fẹẹ lo tẹlẹ yẹn ni ki wọn lo.

Nigba ti Adajọ Chukwujekwu Aneke to n gbọ ẹjọ naa beere lọwọ olupẹjọ pe igba wo waa ni ara ẹlẹrii pataki ẹ maa ya, Jacobs fesi pe lagbara Ọlọrun, o yẹ kara ẹ ti ya loṣu keji, ta a fẹẹ mu yii.

Latari eyi, Adajọ Aneke ni oun sun awọn igbẹjọ to n bọ si ọjọ kejidinlọgbọn, ati ikọkandinlọgbọn, oṣu ki-in-ni, ọjọ kejidinlogun, ati ikọkandinlogun, oṣu keji, ati ọjọ kẹrindinlọgbọn si ikejidinlọgbọn, oṣu kẹrin, o si paṣẹ pe ki wọn ṣeto lọtun-un losi fawọn ẹlẹrii wọn lati yọju lawọn ọjọ ti wọn da wọnyi.

Tẹ o ba gbagbe, lati ọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2018, ni Ayọdele Fayoṣe ati ileeṣẹ Spotless Investiments Limited ti n jẹjọ ẹsun ṣiṣẹ owo ilu ti iye rẹ to biliọnu meji naira (#2.2 billion) baṣubasu.

Leave a Reply