Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Kijokijo lawọn tiṣa ati olukọ ileewe Iṣanbi Comprehensive High School, Iliṣan Rẹmọ, nipinlẹ Ogun, n sa kiri l’Ọjọbọ, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹta yii, nigba ti wọn de ileewe naa, ti wọn ba mariwo ọpẹ tawọn kan so mọ ẹnu ọna abawọle ọfiisi ọga agba, ti ẹnu ọna naa si waa da bii abawọle ile oriṣa.
Ko sẹni to mọ bi mariwo yii ṣe de ẹnu ọna, nitori ko si nibẹ nigba ti wọn n lọ sile l’Ọjọruu, afi bi wọn ṣe deleewe lọjọ keji ti wọn ba mariwo lẹnu ọna. Koda, iyalẹnu gbaa lo jẹ fun ọga ileewe naa, Abilekọ Olu James, mama naa ko le wi nnkan kan, niṣe lọkan rẹ poruru.
ALAROYE gbọ pe ọkan ninu awọn olukọ ileewe yii na akẹkọọ kan to wa nipele aṣekagba lọjọ Iṣẹgun ọsẹ naa. Wọn ni akẹkọọ yii fibinu pada sile, o lọọ pe ẹgbọn rẹ kan wa lati gbeja rẹ, n lẹgbọn naa ba bẹre si i dalẹru, lo n pariwo pe ki ni wọn n lu aburo oun nileewe fun.
Afi bo ṣe di l’Ọjọbọ ti wọn ba mariwo lẹnu ọna ọfiisi ọga agba, ti ko si sẹni to mọgba ti wọn so o mọbẹ, tabi ẹni to so o gan-an.
Oluwo Iliṣan Rẹmọ, Oloye Fagorala, lo pada waa yọ mariwo ọpẹ naa kuro lẹnu ọna ọhun, lẹyin to pe awọn ede to nilo si i ko too ja a kuro.
Ẹsẹkẹsẹ ni ileewe naa pe ipade pajawiri fun awọn obi ati olukọ (PTA meeting), bẹẹ lawọn ọlọpaa wa lati Iliṣan ati Ṣagamu, ti wọn jọ jiroro lori ohun to fa iṣẹlẹ yii, ati bi iru rẹ ko ṣe ni i waye mọ.