O ṣẹlẹ, wọn ti mu Bobrisky ni bọda Sẹmẹ

Jọkẹ Amọri

Asiko yii ki i ṣe eyi to dara rara fun ọmọkunrin jayejaye Eko to maa n mura bii obinrin, to si tun maa n sọrọ bii obinrin nni, Idris Okunẹyẹ, ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky. O ti to ọjọ mẹta ti ẹnu ti n ku ọmọkunrin naa, ṣugbọn iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn aṣọbode ilẹ wa ti mu un lasiko to fẹẹ kọja si orileede Bẹnnẹ, nibi ti ọmọkunrin naa fẹẹ lọọ fara pamọ si nitori ọkan-o-jọkan ẹjọ to wa lọrun rẹ.

Gẹgẹ bi Very Dark Man, ọmọkunrin to tu aṣiri Bobrisiky, ti wọn tun maa n pe ni Mummy of Lagos, pe ko sun oorun ọjọ kan lọgba ẹwọn lasiko ti ile-ẹjọ ran an lẹwọn, to si tun fun ileeṣẹ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ wa lowo ki wọn le pa ọkan ninu awọn ẹṣẹ to ṣẹ rẹ ṣe sọ, o ni ọdọ awọn aṣọbode nilẹ wa ni ọmọkunrin naa wa bayii ti wọn ti n fọrọ po o nifun pọ. Wọn ti gba iwe irinna rẹ, o si wa lọdọ wọn. VDM ni niṣe ni Bobrisky fẹẹ sa lọ si orileede Benne, nitori bi igbimọ ti awọn aṣofin gbe kalẹ ti ṣe bẹrẹ iwadii lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an lori fọran kan to gba ori ayelujara laipẹ yii.

Ọkunrin yii ni nigba ti Bobrisky de ẹnuubode Benne, eyi ti iba fi bọ silẹ ko lọọ lu pasipọọtu rẹ lọdọ awọn aṣobode, ẹnikan lo ran pe ko lọọ ba oun lu u, ti oun funra ẹ si farapamọ sinu mọto.

Lasiko naa ni akara tu sepo, wọn fa gburu, ni gburu ba fa igbo. Eyi ni wọn fi mu ọmọkunrin to maa n ṣe bii obinrin naa, to si ti wa ni akata wọn.

Bẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni awọn aṣofin gbe igbimọ kam kalẹ pe ki wọn wadii fọnran kan to gba ori ayelujara, nibi ti Bobrisky ti sọ pe oun fẹẹ fun awọn alakooso ọgba ẹwọn ni owo ki oun maa baa sun ninu ẹwọn. Bẹẹ lo tun sọ ninu itakurọsọ ọhun pe oun feẹ fun ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ nilẹ wa lowo, ki wọn le yọ ẹsun ṣiṣe arọndarọnda owo kuro lọrun oun.

Lasiko yii kan naa ni ogbontarigi agbẹjọro ilẹ wa nni, Fẹmi Falana tun fẹsun kan an pe afi ko ko ohun to sọ ninu fọnran naa pe oun fun ọmọ oun lowo ki ọkunrin agbẹjọro naa le ran oun lọwọ lati gba idariji lọdọ ijọba jẹ. O ni ti ko ba ko ọrọ naa jẹ, ko si tọrọ aforiji, oun yoo pe e lẹjọ.

Bo tilẹ jẹ pe Bobrisky ko sọ pe bẹẹ ni tabi bẹẹ kọ lori ohun ti ọkunrin agbẹjọro yii ni ko ṣe, ohun ti Mummy of Lagos gegẹ bi wọn ṣe maa n pe e sọ nigba to n fesi si ọrọ naa ni pe oun ko ba ẹnikẹni sọrọ, oun kọ loun n sọrọ ninu fọnran naa, ati pe ẹni to gbe e jade ni ki wọn lọọ ba, ki wọn beere ibi to ti ri i.

 

Leave a Reply