O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Ta lawọn agbalagba yii n ṣiṣẹ fun, Yoruba ni tabi ara wọn?

Nigba ti awọn agbaagba Yoruba kan ba ti ba aye jẹ pẹlu iwakiwa, ti wọn tẹ lọwọ araale, ti wọn si tẹ lọwọ ara oko, sibẹ naa, wọn o ni i fi ara wọn sipo ọwọ, wọn yoo tubọ maa da nnkan ru si i naa ni. Ẹgbẹ Igbimọ Agba Yoruba, Yoruba Council of Elders (YCE), ko ti i ṣiṣẹ kankan fun Yoruba lati ọjọ yii wa, yatọ si ija ti wọn n ja laarin ara wọn, lori ọrọ pe wọn ko owo jẹ, wọn ko ko owo jẹ. Ija pe awọn yọ akọwe ẹgbẹ wọn, tabi wọn ko yọ akọwe ẹgbẹ wọn, ija pe awọn kan gbowo lọwọ ijọba, ija pe awọn kan ko gbowo lọwọ ijọba. Yatọ si eyi, lati bii ọdun mẹwaa sẹyin, koda, ju bẹẹ lọ, ko si ẹnikan ti yoo sọ pe ẹgbẹ igbimọ agba yii ni oore ẹyọ kan bayii ti wọn n ṣe fun ilẹ Yoruba wa. Bi nnkan ba fẹẹ bajẹ, awọn agba ni i to o, o si ni ọna ti wọn yoo fi to o fun wa. Ṣugbọn eyi to n ṣẹlẹ yii, awọn Ẹgbẹ Igbimọ Agba yii ko ni nnkan gidi kan fun Yoruba, nitori awọn funra wọn, ẹnu wọn ko ko, ọtọ ni eyi ti lagbaja yoo sọ, ọtọ ni eyi ti Tamẹdo yoo sọ. Kunle Ọlajide ni oun ni akọwe ẹgbẹ wọn, ọrọ to si ri sọ si gbogbo ohun to wa nilẹ yii ni pe ko si ọmọ Yoruba to gbọdọ beere fun Ijọba ilẹ Yoruba, ko fẹ ki Yoruba da duro, ko ma di pe wọn yoo pa wọn tan. Ọrọ naa le dara daadaa, ṣugbọn nnkan meji ni ko jẹ ko dara rara. Akọkọ ni pe nigba ti awọn eeyan kan ti dide lati maa ja fun pe awọn fẹ ominira Yoruba lo yẹ ki iru awọn Ọlajide ti dide, ki wọn si pe awọn eeyan yii lati ba wọn sọrọ, ki wọn si sọ pe awọn yoo de ọdọ awọn ti wọn n ṣejọba lati yanju ohun to n bi wọn ninu. Ẹẹkeji ni pe awọn eeyan yii ko sọ ohun ti wọn fẹ ki Yoruba ṣe. Ṣe Ọlajide ati awọn eeyan ẹ fẹ ki iya jẹ Yoruba gbe ni, tabi ka kawọ gbera bayii titi ti awọn ti wọn fẹẹ sọ wa dẹru wọnyi yoo fi ṣe aburu ti wọn fẹẹ ṣe fun wa ni. Kin ni Ẹgbẹ Igbimọ Agba ṣe, kin ni Kunle Ọlajide ṣe, ipo wo lawọn wa ninu ọrọ to wa nilẹ yii, tabi wọn kan n wa ipo ati jijẹ mimu funra wọn ni. Ẹni ti ko ba le ran Yoruba lọwọ, ko ma da kun iṣoro Yoruba, ẹ fi wa silẹ ki ẹ jẹ ki Ọlọrun wa gba wa o.  

 

Inu bi Sunday Igboho, tiẹ to bẹẹ, o ju bẹẹ lọ

Nigba ti wọn pe awọn ọmọ Yoruba ki wọn jade, ki wọn waa fi ẹhonu han nitori ijọba Buhari ati ohun ti awọn Fulani kan ṣe fun wa, lọjọ ipade, wọn ko rẹnikan. Ni inu ba bi Sunday Igboho to ṣeto ipade, lo bẹrẹ si i sọrọ si awọn agba Yoruba, to si n ṣepe, to n fara ya rẹkẹrẹkẹ. Ko le ṣe ko ma ri bẹẹ, ko sẹni ti yoo ṣe bẹẹ ti ko ni i bara jẹ, nigba ti awọn ti wọn ba n tori wọn ja ko ba jade sita, tabi ti wọn tun kọju ija si awọn to fẹẹ gbeja wọn. Bi Yoruba ti ri ree. Ṣugbọn ẹni ti yoo ba maa ko awọn eeyan jọ bayii, yoo ko awọn eeyan to ku dani, yoo ti rin in bo ṣe yẹ ko rin in, yoo si ni idaniloju awọn ti wọn fẹẹ jọ jade. Bi bẹẹ kọ, tọhun yoo kan fara lugi lasan, iyẹn bi ko ba ku sidii ohun to n ṣe. Iṣoro Yoruba ni pe o loju awọn agba ti yoo sọrọ, ti yoo mu ohun ti wọn ba wi ṣẹ o, oṣelu ti ko si awọn ọmọ Yoruba lori debii pe awọn ti Fulani n fiya jẹ ninu wọn naa ni yoo kọkọ pariwo pe Sai Buhari lawọn n ba lọ, oun lo le ṣe e. Oun ni baba awọn. Awọn agbaagba ilẹ Yoruba to le gba wa, pupọ ninu wọn ti jẹ ijẹkujẹ, ijẹkujẹ ko si le jẹ ki ẹnu wọn to ọrọ mọ, koda ti wọn ba de kọrọ ti wọn ba n bu Buhari, ti wọn ba ti jade, awọn ni wọn yoo kọkọ sọ pe eeyan daadaa ni. Ẹni to ba ni oun fẹẹ ja fun Yoruba, yoo ṣe suuru, yoo si fi ọrọ lọ awọn agba kọọkan ti wọn ba ṣi nifẹẹ ilẹ wa. Ki Sunday Igboho ma binu, ija naa ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, ibẹrẹ si kọ ni oniṣẹ, wọn ni ẹni ba fori ti i dopin la oo gbala, ko si ẹni kan ti i yin ẹni to ṣiṣẹ ẹ laabọ, ẹni to ba ṣiṣẹ pari naa ni yoo gba oriyin, ki i ṣe ẹni to ba sa lẹnu iṣẹ nitori ibinu tabi ẹgbin. Ọna Yoruba jin ninu ija ominira, bi a ba si fẹẹ ni ominira fun Yoruba loootọ, afi ka na suuru si i.

 

Fani Kayọde pẹlu iyawo ẹ

Ọrọ ọkọ ati iyawo ṣoroo da si, ṣugbọn ti eeyan ba ti le sọrọ ju, oriṣiiriṣii nnkan ni yoo maa ba a. Ko sẹni ti ko mọ Fẹmi Fani-Kayode, oloṣelu alariwo kan bayii ni. Gbogbo igba ni yoo maa pariwo laulau, ti yoo si maa sọ awọn ọrọ kan ti ko ni i fi ẹsẹ ẹ mulẹ, tabi nigbẹyin, ti yoo ni oun ko sọ bẹẹ mọ. Bẹẹ,  ‘bii ṣee ṣe niyẹn’ ki i jẹ ki eeyan mọ ọjọ ti abiku fẹẹ ku loootọ, nigba ti ọrọ ba ti pọ ju, ko seeyan gidi kan ti yoo ka ohun ti tọhun ba n sọ si. Nigba ti wọn ni iyawo Fẹmi Fani-Kayọde kọ ọ silẹ, ohun ti gbogbo eeyan n wi ni pe iwa ẹ ni, eeyan lile, eeyan buruku ni, gbogbo awọn iyawo to ba fẹ lo n na bẹẹ, iya lo fi jẹ iyawo naa ti iyẹn fi sa lọ. Ṣugbọn igba ti ọrọ de oju ẹ, Fani Kayọde funra ẹ jade, ohun to si sọ ya aye lẹnu. O ni oun ka iyawo oun mọ inu yara pẹlu ọkunrin mi-in ti wọn n ba ara wọn lo ni, bẹẹ ni ki i ṣe pe ẹni kan lo waa sọ foun, funra oun loun mu un. Ohun ti yoo mu obinrin to ti jẹ iyawo gbajumọ, to si bimọ mẹrin fun ọkọ hu iru iwa bẹẹ, nnkan nla ni. Ṣugbọn bi ọrọ naa ko ba jade, tabi ko ti ẹnu Fani-Kayọde wa bo ṣe wa yii, ohun ti kaluku yoo maa sọ naa ni pe eeyan lile ni Fani-Kayọde, alatẹnujẹ, ati ẹni to jẹ ibi to ba ti n jẹ lo ti n sọ ni. Ṣebi aipẹ yii loun naa ki oniroyin kan mọlẹ ni gbangba to n bu u nitori tiyẹn bi i leere pe ta lo n sanwo awọn irinajo to n rin kaakiri yii, ti ko si sẹni to gba a gẹgẹ bii oluṣọ-agutan. Ju gbogbo ẹ lọ, ẹkọ to wa ninu ọrọ yii fun Fani-Kayọde funra ẹ, ati gbogbo eeyan paapaa, ni pe ka ṣọra lati maa sọrọ tan, ka jẹ ki bẹẹ ni wa jẹ bẹẹ ni, ki bẹẹ kọ wa jẹ bẹẹ kọ, ka ma si tori ohun ta a ba n jẹ lẹnu di ẹnu-n-ja-waya, ka maa rojọ ohun to ṣẹlẹ ati eyi ti ko ṣẹlẹ kaakiri. Bi eeyan ba ti le rojọ ju, awọn ohun ti yoo maa ba a naa ree o. Fẹmi, ẹjọ rẹ pọ ju!

 

Akeredolu ati igbakeji ẹ ti wọn jọ n tu aṣiri ara wọn

Ẹni ti yoo ba fọrọ ẹnu ba ti ẹnikeji jẹ, ko ṣaa maa ranti pe ki i ṣe oun nikan ni oun ni ọrọ lẹnu. Bi ẹni kan ba ni aṣiri lọwọ to fẹẹ tu nipa igbakeji ẹ, ko mọ pe ki i ṣe oun nikan ni oun ni aṣiri lọwọ, awọn mi-in naa le ni aṣiri oun paapaa lọwọ to ju eyi ti oun n gbe kiri lọ. Arakunrin Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo yoo ro pe inu yoo bi awọn eeyan si Igbakeji oun, Agboọla Ajayi, ti wọn yoo si maa pe e ni alaimoore bi oun ba ti le tu aṣiri to wa lọwọ oun. Ni Akeredolu ba tu aṣri naa, ṣugbọn nigba ti Agboọla tu eyi to wa lọwọ tirẹ naa, Akeredolu lo ku ti gbogbo aye n bu. Gbogbo sọrọsọrọ, ki wọn ranti ẹni to ba mọ ọn gbọ. Akeredolu jade sita, o ni alaimoore pata gbaa ni igbakeji oun, iyẹn Agboọla, o ni bo ṣe wa yẹn, miliọnu mẹtala naira loun n fun un loṣu kan lati fi ṣe akoso ọọfiisi rẹ, ki iṣẹ rẹ le maa lọ geerege. O ni pẹlu owo nla ti oun n fun yii, sibẹ, ọkunrin naa ko ni itẹlọrun, o tun fẹẹ gba aga nidii oun ni. Bi eeyan ba gbọ iru ọrọ bẹẹ loootọ, yoo kọ haa ni, yoo si ni alaimoore ni igbakeji rẹ yii loootọ. Ṣugbọn igba ti Agboọla paapaa sọrọ, kaluku sinmi ni o. Agboọla ni loootọ ni oun n gba miliọnu mẹtala fun owo iṣakoso ọọfiisi oun, ṣugbọn aadọjọ miliọnu naira (N150m) ni Akeredolu n gba, bẹẹ lo si lowo kan ti wọn ya sọtọ fun eto aabo, ti ko si ẹni ti yoo bere lọwọ rẹ bo ba ti na an, oṣooṣu naa lo si n gba a, miliọnu lọna aadọtadinlẹẹẹgbẹrin naira (N750m), eyi ni pe owo ti Akeredolu n gba loṣu kan ti ko sẹni ti yoo bi i bo ṣe na an, owo to din diẹ ni biliọnu kan ni. Oun nikan lo lowo naa, oun nikan lo n na an. Ninu owo yii lo ti n fun Agboọla ni miliọnu mẹtala fun ọọfiisi rẹ, to n fun iyawo tiẹ ni miliọnu mẹjiọ fun ọọfiisi tirẹ, to si n fun ọmọ rẹ ni miliọnu marun-un loṣooṣu fun ọọfiisi rẹ. Ko sẹni to dibo fun iyawo Akeredolu, ko si sẹni to dibo fun ọmọ rẹ, owo ti wọn n na lati apo ijọba yii, owo ti ko bofin mu ni. Ati pe nigba ti Akeredolu n fi owo bii biliọnu kan ṣe akoso ọọfisi rẹ loṣu, to wa n fun igbakeji ẹ ni miliọnu mẹtala, bawo ni iyẹn ko ṣe ni i fẹẹ gba ipo to wa loootọ. Bẹẹ ni oun Akeredolu naa ko ṣe aaye daadaa fun igbakeji rẹ ko ma binu, nigba to jẹ wọn jọ yan wọn si ipo yii naa ni, iṣẹ yoowu ti Akerdolu ba n ṣe to fi n na iru owo bayii, ko si ohun to buru to ba da iru iṣẹ bẹẹ si ọna mẹrin, to si ko apa kan rẹ fun igbakeji rẹ, ki iyẹn naa maa ṣe e lọ. Bi igbakeji rẹ ba wa awọn iṣẹ yii maya, ti oun naa n gba bii miliọnu lọna aadọtalerugba (250million) loṣooṣu, bo ba huwa kan, eeyan yoo ni alaimoore ni. Ṣugbon ọga to n jẹun ti ko fẹ ki ẹlomiiran jẹ, ọmọọṣẹ yoo gbẹ koto iku silẹ fun un ni o. Arakunrin wa ko lẹnu ọrọ rara, o kan n fi ara rẹ ṣe yẹyẹ ni gbangba ni.

 

Ṣugbọn, ẹyin ara Ondo, ẹ waa gbọ o

Ibo gomina ti wọn n pariwo ni ipinlẹ Ondo naa lo ti de yii o, ọjọ Abamẹta, Satide, yii ni. Gbogbo yin lẹ ti gbọ ọrọ lẹnu oloṣelu ọtun, ẹ si ti gbọ lẹnu oloṣelu osi, ẹ ti ri ti ọmọọṣẹ to dalẹ ọga ẹ, ẹ si ti ri ti ọga to n jẹ ti ko fẹ ki ọmọọṣẹ rẹ jẹ. Ohun to ṣẹlẹ ni pe ki i ṣe gbogbo awọn ti ẹ n ri yii ni wọn fẹran yin, tabi ti wọn n mu idagbasoke kankan bọ fun yin, ọpọ ninu awọn oloṣelu yii, jijẹ-mimu tiwọn ati ti ẹbi wọn, ati bi wọn yoo ṣe lowo ju gbogbo ẹda aye lọ ni wọn n wa kiri. Wọn yoo tan yin, wọn yoo sọrọ didun, wọn yoo ni bi awọn ba wọle tan, igba lẹ oo maa fi wọn owo kiri, ti ẹ oo si maa jẹgbadun bi ẹ ṣe fẹ. Ṣugbọn ti wọn ba ti wọle tan, wọn yoo da yin da iṣoro yin ni. Nitori bẹẹ lo ṣe yẹ ki ẹ laju daadaa, ki ẹ too dibo yin, ki ẹ si ṣe laakaye rẹpẹtẹ. Akọkọ ni pe ẹ ko gbọdọ ba ara yin ja, tabi ki ẹ jẹ ki wọn lo awọn ọmọ yin bii tọọgi lati pa ẹni kan tabi lati ṣe awọn eeyan lọṣẹ. Ẹni ti wọn ba pa nidii idibo lọjọ naa, apa gbe ni o, ko si kinni kan ti yoo gba nibẹ mọ. Yoo kan da ara rẹ ati awọn ẹbi rẹ loro lasan ni. Ẹni ti wọn ba si mu pe o paayan lọjọ idibo, ọjọ aye oun naa, bi wọn o ba ba pa a, ẹwọn ni yoo ti lo o. Nitori bẹẹ, ẹ ko gbọdọ ba wọn lọwọ si i. Ọna mi-in ni pe ẹ ma gbowo lọwọ ẹnikẹni lati dibo. Bi wọn ba kowo wa fun yin, bi ẹ ko ba le kọ ọ, ẹ gba a, ṣugbọn iyẹn ko ni ki ẹ dibo fun ẹni to ko owo waa fun yin, nitori ẹni to n ko owo kiri yii, ole ni, o fẹẹ lo yin lasan ni. Ẹ ma si ṣe jẹ ki ẹru ba yin, owo to n na ki i ṣe owo rẹ, owo yin ni, nitori bẹẹ, bi ẹ ba gba owo lọwọ oloṣelu kan, owo yin lẹ gba pada, ẹ ma tori iyẹn dibo fun un. Bi a ba le mu awọn nnkan wọnyi lo, gbogbo wa la oo jẹ anfaani ẹ, nitori ohun gbogbo ni yoo dara ni ipinlẹ wa. Ẹ jẹ ka ṣi awọn oloṣelu yii lọwọ ki wọn yee ṣe aye wa baṣubaṣu, ẹni to  ba le ṣe ipinlẹ Ọndo daadaa ni ka dibo fun o.

Leave a Reply