O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Fani-Kayọde paapaa ni alaye lati ṣe

Bo ba ṣe pe Oloye Fani-Kayọde, ọkan ninu awọn oloṣelu ilẹ Yoruba to ti ṣe minisita nigba kan, ni oogun ti yoo lo to n jẹ bii idan ni, iba lo kinni naa ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja yii, lori ibo ti wọn di ni Amẹrika. Ṣugbọn pẹlu pe ko loogun naa, ọna kan naa to mọ, o tọ ọ. Adura nla nla lo ki mọlẹ bii ti wolii to ṣẹṣẹ n ti ori-oke bọ, bẹẹ lo n fi ẹsẹ Bibeli gba a lẹgbẹẹ, o n sọ pe bi Donald Trump, Aarẹ ilẹ Amẹrika, ti n jade lọ yii o, ire ni yoo ko wọle pada, oun ni yoo bori gbogbo ọta ẹ nile, ati nibi gbogbo, oun ni yoo wọle, ti yoo si pada di aarẹ ilẹ Amẹrika lẹẹkan si i. Adura naa pọ o! Ẹni ba ri kinni naa lori ẹrọ ayelujara lo le sọ. Awọn ọlọmọ ni ọmọ awọn ko daa, Fani-Kayọde ni awẹlẹwa lọmọ wọn. Awọn ara Amẹrika funra wọn koriira Trump, ibo ti wọn si di yii yoo fi han, iru ikoriira ti wọn ni si i. Gbogbo awọn ileeṣẹ iroyin nla nla kọyin si i debii pe wọn ko gbe ọrọ ati irọ nla nla to n pa jade, sibẹ ẹni ti Fani-Kayọde ri mu lọrẹẹ niyẹn. Nijọ ti wọn ti n ṣejọba Amẹrika yii, ko kuku si olori orilẹ-ede naa kan to fi awọn ọmọ Naijiria ati ijọba wọn wọlẹ to ti Trump yii ri, tabi orukọ buruku kan wa nibi kan ti Trump ko pe awọn Naijiria ni. Ṣe ole ni ko pe wa ni abi onijibiti. Tabi nibo ni Trump ti pọn Naijiria le laarin ọdun mẹrin to fi ṣejọba. Ewo waa ni Fani-Kayọde bọ ẹwu silẹ to gbe apẹrẹ wọ si, ki lo de to n fi apa janu lori ọrọ ọlọrọ, ọrọ ti ko kan an rara. Bi Fani-Kayọde ba fẹran Trump to bẹẹ, ki lo de ti ko kuku ko lọ si Amẹrika lọhun-ko maa gbe. Bo ba jẹ Ọlọrun Ọba jẹ alabosi ni, niṣe ni iba gba adura ti awọn eeyan bii ọkunrin oloṣelu PDP yii n ṣe, Trump ni iba tun wọle, ti iba si maa ko wahala rẹ ba gbogbo aye. Tabi ẹsin Kristiẹni ni Fani-Kayode fi fẹran Trump, ṣe Trump sọ fun un pe Kristiẹni loun, ṣe bi iwe mimọ ti fi kọ awọn Kristiẹni ni Trump n ṣe nile ijọba yii. Ẹyin ti ẹ n beere ijọba rere ni Naijiria, ṣugbọn ti ẹ ri ohun to buru nibomi-in, ti ẹ n gba a mọra. Ohun ti ẹ n sọ ni pe iru yin ko ni ko ni i mu ilọsiwaju ati ominira ti a n fẹ ba Naijiria, nitori bi ẹyin naa ba wa nile agbara, aburu tiyin yoo fẹrẹ ju ti Buhari yii lọ. Ani wọn tun dibo tan, Fani-Kayọde n sọ pe ile-ẹjọ giga ni yoo yanju ọrọ naa. O sọ kinni naa di arọnda-rọnda ojoro ati oṣelu mari-majẹ ti wọn n ṣe ni Naijiria. Fani-Kayọde lọrọ lati sọ o. Ohun to ba pa oun ati Trump pọ, o yẹ kaye mọdi ẹ, bi ko ba si wọ mọ, ko fi Naijiria silẹ, ko wa iṣẹ lọ sọdọ Trump, ko kuku si nnkan gidi kan to n ṣe lọwọ bayii. Bo ba si jẹ Ishaaq Akntọla lo ko agidi bori lori ọrọ awọn ẹlẹsin Islam ni Iraq tabi ni Afghanistan, oun Fani-Kayọde yii ni yoo kọkọ gbẹnu soke ti yoo maa bu u. Iyatọ wo lo waa wa laarin awọn mejeeji. Ẹyin ko jẹ ran aṣọ yin nibi to ti gbe faya, ẹwu ẹlẹwu lẹ n ran. Ẹ wabi jokoo si jare!

 

Awọn eeyan ti wọn n ku soju ọna Ibadan yii n pọ ju

Ti eeyan ba n ranti ohun ti jọba yii n ṣe, omi yoo si fẹrẹ maa ja bọ loju onitọhun. Bẹẹ ki i ṣe ijọba lo buru, awọn ti wọn n ṣejọba yii leeyan raurau. Awọn ni ọbayejẹ, opurọ ati oniwakiwa ẹda gbogbo. Ni bii ọdun meji sẹyin, nigba ti ibo aarẹ Naijiria ti a fẹẹ di ninu oṣu keji, 2019, n sun mọle, ọkunrin kan ti wọn n pe ni Rotimi Amaechi, minisita fun eto igbokegbodo ọkọ, ko awọn eeyan kan lẹyin, ọba wa ninu wọn, minisita wa ninu wọn, o ni ki wọn waa ba oun ṣi ọna reluwee to lọ lati Eko si Ibadan. Minisita ko gbogbo wọn gba ọna Abẹkuta lọ, pẹlu awọn ọkọ reluwee aloku kan ti wọn ra, ti wọn kun ni ọda tuntun. O ni ki wọn waa tẹẹsi ọna naa ni, o ni o ti pari, ki wọn kan ko awọn eruku oju ẹ kuro lo ku, awọn eeyan yoo si maa lọ, wọn yoo maa bọ lori ọna reluwee naa lati inu oṣu karun-un, ọdun naa lọ. Bawo ni eeyan ko ṣe waa ni i fẹẹ sunkun nigba ti ẹ ba gbọ ọrọ lẹnu ọkunrin yii kan naa lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii. Amaechi yii tun sọ pe ki ọna reluwee yii too le pari o, awọn tun nilo miliọnu ọtalelẹgbẹta o din mẹrin owo dọla ($656m), biliọnu rẹpẹtẹ niyẹn jẹ ninu owo naira tiwa. Iru ijọba wo lo n ṣe bayii fawọn eeyan ẹ. Ki lo de ti irọ rọ awọn eeyan yii lọrun bayii, ki lo de ti wọn n fi aye gbogbo awa ọmọ Naijiria ṣe oṣelu bayii, ki la kuku ṣe fun wọn. Nigba ti Amaechi n sọrọ nipari 2018 pe ọna naa ti pari, to n ko awọn eeyan rin ibẹ, o n tan gbogbo wa ni, o si n lo awọn ọba, awọn oniroyin atawọn mi-in lati fi juuju bo wa loju. Nitori kin ni? Nitori oṣelu yii naa ni! Awọn ọbayejẹ ti wọn n pe ara wọn loloṣelu lẹ ri yẹn. Ni Satide to lọ yii ni oku tun sun lọna Ibadan, ti mọto bii ogoji si jona. Bo ti n ri lojoojumọ aye yii niyẹn, ti tirela elepo ati awọn mi-in n fojoojumọ paayan lọ. Wọn fi ogun ọdun ṣe titi Eko s’Ibadan, iyẹn o pari, wọn ṣe reluwee, iyẹn o yanju, bẹẹ awọn eeyan ti wọn n ku loju ọna yii ti pọ ju, eto ọrọ aje wa to si n ti idi aidaa ọna yii bajẹ ko ṣee maa fẹnu sọ. Nibo la fẹẹ gbeyii gba! Ta ni yoo gba wa lọwọ awọn eeyan yii! Ẹyin araabi yii, ẹ o si ṣayee re!

 

Sanwo-Olu ati awọn ṣọja ọrẹ ẹ

Ọga ṣọja kan jade niwaju igbimọ to n rojọ lori ọrọ awọn ti wọn yinbọn fun ni Lẹkki, ọkunrin naa ni Sanwo-Olu lo pe oun pe Ọgagun kan ti wọn n pe ni Bello n yinbọn ni too-geeti Lẹkki. Ọga ṣọja yii ni n loun ba pe Bello, ni Bello ba sọ foun pe oun ko yinbọn o, awọn n yin ẹtu soke lasan ni. Fidio fi awọn oku to ku han, o fi bi awọn ṣọja ti n daamu awọn ọdọ ti wọn ṣẹwọde han, sibẹ, awọn ṣọja yii lawọn ko yinbọn lu ẹni kan. Nigba ti wọn lọ tan, lọjọ keji, ọta ibọn kun ilẹ ibẹ giran giran ni o, sibẹ, awọn ologun naa lawọn ko yinbọn lu ẹnikan. Bi ẹ ba si ro gbogbo irọ ti wọn ti pa latẹyin, ti wọn kọkọ lawọn ko wa, ti wọn tun ni awọn yoo wa, ti wọn tun ni ki wọn pe awọn si i, ko si ẹni ti yoo gba eyi ti wọn n sọ yii naa gbọ. Ṣugbọn ti ẹni ti ko daa to ninu gbogbọ ọrọ yii ni Babajide Sawoolu ti ṣe gomina Eko yii. Ki loun gan-an mọ ninu ọrọ to wa nilẹ yii, irọ meloo lo pa fawọn ara Eko gan-an. Ko jọ pe ohun gidi kan le ti ara iwadii ti ijọba n ṣe yii jade. Tabi ki lo fẹẹ ti idi ẹ jade! Ijọba to huwa ọdaran naa lo gbe igbimọ dide! Ijọba to huwa ọdaran yii naa lo n ko ẹlẹrii sita! Ijọba to huwa ọdaran yii naa lo gbe adajọ kalẹ! Bawo ni araalu yoo ṣe waa mọ ododo. Ṣugbọn kaluku naa lo mọ ododo o. Wọn mọ ododo daadaa, wọn si mọ ohun ti wọn ṣe. Ṣugbọn bi eeyan ba ṣe aidaa kan, tabi to ba ṣẹ ẹṣẹ kan to n tọrọ idariji, tabi to fẹ ki Ọlọrun ati awọn eeyan dariji oun, ohun ti yoo kọkọ ṣe ni lati sọ ododo. Ẹlẹṣẹ ti ko ba sọ ododo ko ti i ṣetan ti yoo ri idariji, gbogbo ohun to ba n sọ, irọ lasan ni. Ki lododo to wa nidii ọrọ yii! Ta ni Sanwoolu ranṣẹ pe! Ta ni gba Sanwoolu nimọran pe ko pe ṣọja! Aṣiṣe wo lawọn ṣọja ti wọn ran niṣẹ si ṣe nigba ti wọn debi ti wọn ran wọn! Ohun ti araalu fẹẹ mọ ree, gbogbo eyi to ku, iregbe lasan ni. Ọrọ n bẹ lẹnu Sanwoolu ati awọn ṣọja ọrẹ rẹ, ki wọn tete fẹnu wọn ṣalaye bi ọrọ ti jẹ ni ko tun ni i mu wahala kanka ba wọn. Tabi ki lẹyin naa ko jawọ ninu irọ pipa yii si, nigba to jẹ bẹ ẹ ti n parọ naa lo n ja. Wọn firọ ṣe yin ni! Ṣiọ! O ma ṣe o!

 

Awọn Amọtẹkun Ondo yii da paapaa!

Ko si ẹni kan nilẹ Yoruba ti yoo sọ pe oun ko mọ pe iṣoro wa fun awọn ọlọpaa wa lati koju awọn ọdaran, awọn ajinigbe, paapaa awọn Fulani onimaaluu nilẹ Yoruba nibi. Awọn ọlọpaa ki i fẹẹ mu Hausa tabi Fulani onimaaluu, wọn yoo ni wọn ko gbede, wọn ko mọ ofin, bẹẹ wọn mọọyan ji gbe, wọn mọọyan pa. Bi ọlọpaa si mu wọn naa, ko sẹni ti yoo mọ bi ẹjọ naa ṣe pari, mọkumọku ni yoo gbẹyin ẹ. Ohun ti gbogbo eeyan ṣe dunnu nigba ti awọn gomina wa gbe Amọtẹkun jade ree, ti wọn ni wọn yoo ba wa kapa awọn ọdaran to yi wa ka. Ti ipinlẹ Ondo tilẹ tun kamama, nigba ti wọn ko wọn jade, ti ati gomina, ati awọn oloye ilu, mura bii ologun gan-an. Eleyii fi ọkan gbogbo eeyan balẹ. Ṣugbọn ohun to waa n ṣẹlẹ ni agbegbe Ondo bayii ko fi ni lọkan balẹ mọ o, o da bii pe adugbo naa ni awọn ajinigbe wọnyi ṣiju si bayii, ti wọn si n fi gbogbo igba ṣe iṣẹ ibi wọn. Awọn mẹrindinlogun mi-in ni wọn tun ji gbe lọsẹ to kọja yii, awọn Iyalọja ati Babalọja, ti wọn ni ki awọn eeyan wọn lọọ wa miliọnu mọkanla wa ki wọn too le fi wọn silẹ. Ni ilu to lọba, to nijoye, ti awọn ajinigbe si waa fẹẹ sọ ara wọn di ikooko si gbogbo ilu lọrun. Ibi ti awọn Amọtẹkun ti gbọdọ sun ṣokoto giri ree, nitori kinni kan n ṣẹlẹ to gbọdọ yeeyan, iyẹn naa ni pe ọrọ awọn ajinigbe wọn ti n fẹẹ ni ọwọ awọn araalu ninu. Awọn ọmọ tiwa naa ti n ba awọn Fulani yii ṣiṣẹ, iwa ọdaran naa si ti fẹẹ kari. Bi ina ko ba lawo, ina ki i jo sọda si odikeji odo, bi iku ile ko si pa ni, tode ko le pa ni, awọn ọdaran Fulani onimaaluu yii ti n ri awọn ọmọ wa mu lagbegbe wa, nibi ti iṣẹ si ti dọwọ awọn Amọtẹkun ree. Gbogbo ohun to ba yẹ ki ijọba ṣe lati ran wọn lọwọ ni ki wọn tete ṣe, araalu fẹẹ ri ipa awọn Amọtẹkun yii laarin wọn. Ko dara ki a ni awọn Amọtẹkun, ki awọn kan tun maa waa ji wa gbe, ki wọn si maa fi wa pawo laarin ara wa. O ya o, Amọtẹkun ẹyin da, ẹ tete ṣe ojuṣe yin karaalu ri yin o!

 

Adajọ Dọlapo Akinsanya, awọn adajọ kan niyẹn

Gbogbo ohun yoowu ti eeyan ba ṣe loni-in, ọrọ itan ni yoo da bo ba dọla. Awọn eeyan kan wa ti wọn yoo gbe igbesẹ nitori ọjọ ọla wọn, bẹẹ ni awọn kan wa to jẹ oni nikan ni wọn n ro, wọn ki i ro ọla. Awọn yii ni igbẹyin aye wọn maa n buru ju ibẹrẹ aye wọn lọ. Ọsẹ to kọja yii ni aye gbọ iku Adajọ Dọlapọ Akinsanya, ọkan ninu awọn adajọ ti orukọ rẹ ko ni i parun ninu itan Naijiria laye ni. Ṣe ẹsẹ kan naa leeyan yoo gbe ti yoo yi itan aye rẹ pada, ẹsẹ kan naa ni Adajo Akinsanya gbe to sọ ọ dẹni torukọ rẹ wọ inu iwe itan aye wa. Lasiko ijọba awọn ologun, lasiko ti oju ogun le gan-an, ti awọn Babangida n ranṣẹ iku kiri, ti awọn Abacha n sọ pe ẹni to ba sọrọ, awọn yoo pa a, ohun ti awọn ba ti fẹ ni kaluku gbọdọ ṣe, Adajọ Akinsanya yii lo ṣẹ ohun ti gbogbo wọn ko fẹ, to ni ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe foun ki wọn tete ṣe e. Oun lo dajọ, to sọ pe ijọba fidi-hẹ-ẹ ti Oloye Ernest Sonẹkan jẹ olori ẹ nigba naa ki i ṣe ijọba to bofin mu, o ni ijọba wayo ni. O ni ki ijọba naa kogba wọle kia. Bo si ti dajọ naa lo ri, lawọn ologun ba gbajọba ayederu naa. Bo ba jẹ awọn ti wọn gbajọba yii ṣe daadaa, ti wọn mu adehun ṣẹ, ti wọn ṣe ẹtọ bii Akinsanya ni, Naijiria iba ti ri ojutuu si iṣoro rẹ lọjọ to ti pẹ. Ṣugbọn awọn ti wọn ba Naijiria jẹ ni orukọ tiwọn ninu iwe itan, bẹẹ ni Akiinsaya si ni orukọ tirẹ ninu iwe itan awọn ti wọn tun Naijiria ṣe. Dọlapọ Akinsanya dagbere faye lọsẹ to kọja yii, ṣugbọn iwa rere ati idajọ rere rẹ ko ni i kuro ni Naijiria ati ni Afrika titi lae, nitori ni tootọ, awọn adajọ rere kan niyẹn.

Leave a Reply