O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Ẹ jẹ ka ṣọra fun Koro o

Arun Korona ti wọn pariwo ẹ nibẹrẹ ọdun yii ti tun bẹrẹ lakọtun o. Kaakiri ipinlẹ ni ijọba ti n ṣe ofin oriṣiiriṣii, ohun ti wọn si n ṣe ni bi arun naa ko ṣe ni i maa gbilẹ si i. Ṣugbọn ọpọlọpọ eeyan ni ko gba pe arun kan wa to n jẹ Korona, wọn ni awọn ti wọn n ṣejọba n fi kinni naa ko owo jẹ laaye ara wọn ni. Awọn mi-in ni arun oyinbo ni, awọn mi-in ni ko sohun ti Koro fẹẹ fi awọn ṣe; awọn mi-in ni ibinu Ọlọrun lori awọn oloṣelu jẹgudujẹra ni, nigba ti awọn ko si ti n ṣe oloṣelu, tabi oṣiṣọ ijọba, ti awọn ko si ko owo jẹ, ko si Koro ninu ọrọ tawọn. Gbogbo ọrọ yii le jẹ ootọ, ṣugbọn ohun kan to daju ni pe arun kan wa nita, abilu buruku ni, boya Koro ni o boya Koro kọ o, iyẹn lawa naa ko le sọ. Arun yii n paayan, bẹẹ ni ki i sọ fawọn to ba fẹẹ mu tẹlẹ ko too mu wọn. Nigba ti ko si si arun mi-in nita lẹnu lọọlọ yii to tun n paayan bẹẹ, afi ki awa naa gba pe koro yii naa ni. Boya oloṣelu lo ko o wa ni o, boya awọn oyinbo ni, boya iya ẹṣẹ ni tabi nnkan mi-in, Koro wa nigboro o, ko si si alaye fun ẹni to ba kọ lu, tọhun yoo mọ pe nnkan ba oun. Boya koro muuyan ki i ṣe pe ọjọ iku ẹ pe, ṣugbọn bi wọn ko ba tete mura si i lo maa n ja siku. Ọpọ eeyan la ti tun gbọ iku wọn bayii ti wọn n sọ pe Koro lo pa wọn, bẹẹ ni awọn naa ko le sọ pe awọn mọ igba ti kinnni naa wọ wọn lara. Nitori ẹ lo ṣe jẹ ẹni ti ara rẹ ko ba ti ya, ko fi ile awọn ọlọsibitu wẹlọ, ko tete lọọ ṣe ohun to ba yẹ. bo ba si jẹ awọn oogun tiwa kan wa ti tọhun mọ pe o n gbọ akọ iba ati awọn arun ti ko nidii bayii, ki tọhun gbe e lura ko ṣe nnkan kan. Ṣugbọn pataki ju lọ ni ka sọra, ka ma jẹ ki Koro yii mu wa, nitori bo ba ti mu eeyan, a maa pẹ ko too lọ. Ka ṣọra nibi ti ero ba ti pọ ju, boya ni pati ni o, tabi ni awọn ibi ariya mi-in, bo ba si di dandan ka lọ, ki awa naa bo imu wa bi awọn to ku ti n ṣe. Ko si ohun to buru bi a ba ṣe eleyii niwọn igba ti Koro yii ba ṣi wa, nitori fun alaafia ara wa ni. Bi a ko ba fẹ ki Koro na wa lowo, ti a ko si fẹ ko da wa jokoo, ki awa naa tọju ara wa o. Ogun awitẹlẹ ki i pa arọ, arọ to ba gbọn nikan ni o.

 

 

 

Ki Ṣeyi Makinde fura, ifura loogun agba

Ariwo to wa niluu bayii ni pe aarin Gomina Ṣeyi Makinde ati igbakeji rẹ, Rafiu Ọlaniyan ko fi bẹẹ gun mọ, wọn ni ija gidi wa laarin wọn, bo tilẹ jẹ kinni naa ko ti i jade sita. Eleyii ki i ṣe akọkọ ti iru eyi yoo ṣẹlẹ, eyi to si ṣe wọn ninu APC ni Ondo buru debii pe niṣe ni wọn fi ẹgbẹ naa silẹ funra wọn. Ni ọpọ igba, awọn alaṣẹ pẹlu igbakeji wọn ki i ṣọrẹ pẹ titi, kinni kan yoo ṣaa ṣẹlẹ ni. Ohun to si maa n jade sita naa ni pe gomina ko faaye gba igbakeji ẹ, ki i fi nnkan han an, o ti sọ ọ di ẹru, tabi pe o n da nikan ṣe ijọba rẹ ni. Ọrọ to maa n jade lẹnu ọpọ igbakeji awọn gomina yii niyẹn. Ni tootọ, bi a ba fẹẹ da a silẹ ti a si fẹẹ tun un ṣa, ko si awo kan ninu awo ẹwa, ko si ohun to yẹ ki gomina maa ṣe ki igbakeji rẹ ma mọ, nibi ti nnkan ba ti dara, ti olori ijọba si n ṣejọba bo ti yẹ ko ṣe e. Idi ni pe igbakeji gomina yii naa, bii gomina funra ẹ ni, nitori yatọ si pe wọn jọ dibo yan wọn sipo naa, bi ko ba ti si gomina yii nile, igbakeji rẹ yii ni yoo maa ṣejọba titi ti yoo fi de, bi gomina ko ba waa fi ohun to n lọ han igbakeji rẹ, bawo ni yoo ṣe le ṣe iru iṣẹ bẹẹ. Ṣugbọn nitori bi ọrọ oṣelu ilẹ wa ṣe ri, adiẹ ko fi ibi akitan han ọmọ rẹ ni, awọn gomina ki i fẹ ki igbakeji awọn ri ibi ti awọn ti n jẹ. Eyi ko sọ pe awọn igbakeji mi-in naa ko buru o, awọn naa le, nitori ni gbara ti wọn ba ti debẹ ni wọn yoo ti maa ṣe ọna bi awọn yoo ṣe gbajọba lọwọ ọga wọn lasiko ti ibo mi-in tun n bọ. Nidii eyi, aidaa, ati aburu gomina naa ni wọn yoo maa ṣare, wọn yoo si maa rojọ rẹ fun gbogbo awọn olori ẹgbẹ oṣelu wọn laidaa. Eyi a maa jẹ ki gomina mi-in foju ọdalẹ wo igbakeji rẹ, wọn ko si ni i ṣejọba jinna ti wọn yoo fi di ọta ara wọn. Bẹẹ bi aarin gomina ati igbakeji rẹ ko ba dan mọran, ipalara ni yoo jẹ fun ipinlẹ, nitori ilọsiwaju to ba yẹ ko wa ko ni i wa rara. Ohun ti Makinde ko ṣe gbọdọ faaye gba awuyewuye to n lọ nigboro bayii niyi. Bi kinni kan ba wa laarin oun ati igbakeji rẹ, ko yanju rẹ kia, bo ba si jẹ awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu rẹ lo n binu, ko mọ bi yoo ti ṣe e. Ibi ti eeyan ba ti ba gun igi ni yoo wo, eeyan kan ki i gbagbe ibi to ba doke. Loootọ awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu mi-in, ole paraku ni wọn, bii ko ko gbogbo owo ile ijọba fun wọn ni yoo ri loju wọn, Makinde ni yoo mọ bi yoo ti ṣe e ti gbogbo aye yoo fi ri i pe alaṣeju niru awọn ẹni bẹẹ. Asiko ti Makinde gbọdọ fura ree, nitori ifura loogun agba, ti kinni naa ba kọja asiko yii, afaimo ki nnkan ma yi biri fun un.

 

Fayemi ati APC l’Ekiti

Nigba ti awọn ẹgbẹ oṣelu to n ṣẹjọba ni ipinlẹ kan ba ni awọn sọrọ, to ba ti jẹ ni Naijiria wa yii ni, keeyan ti mọ pe olori ijọba ibẹ lo sọrọ, nitori ko si ẹgbẹ oṣelu kan to n da duro ni ipinlẹ kan, gomina ibẹ ni yoo maa paṣẹ le gbogbo ẹni to ba wa nibẹ lori. Oun ni yoo yan alaga ati awọn ijoye ẹgbẹ, oun ni yoo si mọ bi ẹgbẹ yoo ṣe maa ṣe, nitori oun ni yoo maa fun wọn lowo lati fi ṣe akoso ẹgbẹ naa. Lọrọ kan, gomina ipinlẹ kan lolori ẹgbẹ oṣelu rẹ nibẹ, ko sẹni ti i ba a du u rara. Eyi lo ṣe jẹ ọrọ ti awọn APC ipinlẹ Ekiti sọ lọsẹ to kọja yii pe  dandan ni ki Kayọde Fayẹmi ti i ṣe gomina ibẹ du ipo aarẹ ni 2023 lorukọ ẹgbẹ wọn, ki i ṣe lati ẹnu ẹlomi-in lo ti wa, lati ẹnu Fayẹmi funra ẹ ni. Ko si ọrọ awo kan ninu ọrọ yii mọ, gbogbo ilu lo ti mọ pe Fayẹmi yoo du ipo aarẹ, eyi ti ko ni i tọna nibẹ ni ọgbọn alumọkọrọyi tabi etekete. Bi yoo ba dupo aarẹ, ko si ohun to buru nibẹ, bo ba ti mọ pe oun ni aya ẹ, oun si lọgbọn lati ṣe’lu, oun si ni eto rere fun ọmọ Naijiria gbogbo. Nibi ti nnkan ti daa, ko si ohun to buru rara pe ki Fayẹmi du ipo, nitori o ti kọ ẹkọ gẹgẹ bii gomina, ati gẹgẹ bii minisita, o ti mọ eto iṣejọba daadaa debii pe o yẹ ko le mu ayipada rere ba ilu. Ṣugbọn ọna to wa n gba yii kọ ni yoo gba, oun ati awọn aṣaaju rẹ gbọdọ jọ jokoo, ki wọn sọrọ naa ko gun rege. Fayẹmi ko le sare kuro lẹyin Tinubu ko lọọ sọ ara rẹ di ọrẹ awọn Fulani nitori yoo ṣejọba. Awọn Fulani ko le mọ ọn, bẹẹ ni wọn kiba ti ri i bi ko jẹ Tinubu wa lẹyin rẹ lati di gomina. Oun paapaa yoo ṣaa si maa ranti awọn ọjọ to jẹ ile Tinubu loun n gbe tọsan-toru, nigba ti ko jẹ kinni kan, ti ko si sẹni to ka a si gẹgẹ bii oloṣelu gidi. Bo ba waa di gomina loni-in yii, to ba di minisita, to si n lakaka lati dupo aarẹ, o gbọdọ maa fi oju ẹgbẹ kan wo Tinubu, ko si maa ranti atẹyinwa, wọn gbọdọ jọ jokoo sọrọ yii kunna laarin ara wọn ni. Ko ṣaa le sọ pe oun ko mọ pe Tinubu fẹẹ du ipo arẹ, ṣe o waa fẹẹ daju ọga rẹ ni gbangba bẹẹ ni. Ki Fayẹmi tete ṣe ohun to yẹ ko ṣe o, ko lọọ ba ọga rẹ sọrọ, ko ṣalaye fun awọn agbaagba APC ilẹ Yoruba, nigba naa ni yoo ṣẹṣẹ waa kede ohun ti oun fẹẹ ṣe. Ṣugbọn eyi ti oun ati awọn Fulani ọrẹ rẹ n ṣe yii, ṣakara lasan ma ni, bii ẹni to n fi akoko ṣofo ni!

 

Ẹ jẹ ki Tinubu jade ko fi ẹnu ara ẹ sọrọ

Dayọ Adeyẹye, ọkan ninu awọn aṣaaju PDP to pada wọ inu APC, ko ero lẹyin lọsẹ to kọja, o dile awọn ọba ilẹ Yoruba. Wọn gba ile Ọọni kọja, wọn ko ya ibẹ (Ọlọrun nikan lo mọ ohun to ṣẹlẹ), ọdọ Olubadan ati Alaafin ni wọn lọ taara. Nigba to n lọ, o mu Musiliu Ọbanikoro dani, aṣaaju PDP loun naa, o ti ṣe minisita nibẹ daadaa ko too waa pada wa si APC, bẹẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ APC mi-in tun tẹle wọn. Njẹ kin ni wọn n wa kiri! Wọn ni awọn waa ri awọn ọba mejeeji, ki awọn le sọ fun wọn pe ni 2023, Tinubu ni yoo ṣe aarẹ ilẹ Naijiria, awọn si ti bẹrẹ iṣẹ fun un. Bi Tinubu ba dide, to loun yoo di aarẹ ilẹ wa, nigba to jẹ oloṣelu ni, ọga wọn ni paapaa, gbogbo aye lo si mọ iṣẹ to ti ṣe sẹyin ki ẹni to wa nibẹ yii too di aarẹ. Bakan naa ni ko si ohun to buru bi Tinubu ba ranṣẹ si awọn ọba ati ijoye ilu, ohun to buru ni ki awọn eeyan kan ko ara wọn jọ, ki wọn waa maa tan ara wọn jẹ, ki wọn ni ki i ṣe Tinubu lo ran awọn niṣẹ, awọn kan dide lati ọdọ awọn, awọn si n wa ẹni ti yoo ṣe aarẹ, awọn si ri i pe Tinubu lo yẹ lẹni naa. Ọrọ naa ko daa, bii igba ti awọn eeyan yii n pe araalu lọbọ ni. bẹẹ wọn ko pe ara ilu lọbọ o, ara wọn ni wọn n pe ni akinyẹyẹ, nitori oju oniranu lawọn eeyan yoo maa fi wo wọn. Bẹẹ bo ba jẹ nigba ti wọn de ile awọn ọba wọnyi ti wọn ba sọ fun awọn ọba naa pe Tinubu lo ran awọn wa o, Tinubu fẹẹ di aarẹ, oun naa n bọ o, ọmọ yin ni, a fẹ kẹ ẹ ṣe atilẹyin fun un. Ọrọ naa yoo daa leti awọn araalu, awọn yoo si le mọ ohun ti wọn yo ṣe. Ṣugbọn nigba to ti jẹ omi-irọ ni wọn fi da awọn oloṣelu Naijiria, aye wọn ki i daa bi wọn ko ba ti i purọ, irọ ti wọn yoo fi bẹrẹ ipolongo yii naa ree, irọ naa ni wọn yoo si fi pari rẹ. Ọpọ igba ni wọn ti beere lọwọ Tinubu funra ẹ to ni oun ko sọ fẹnikẹni pe oun fẹẹ du ipo aarẹ. Titi di bi a ti n wi yii, ko ti i jade nibi kan pe oun fẹẹ du ipo aarẹ, iru iṣẹ dindinrin wo waa lawọn yii n ko ara wọn lẹyin ti wọn n jẹ kiri. Wọn ni awọn n ṣiṣẹ fun Tinubu! Wọn si ni ki i ṣe Tinubu lo ran awọn! Ṣe ko le di lọla kan ki Tinubu ni awọn eeyan kan lo waa bẹ oun ni! Tabi ta lawọn eeyan yii n ṣiṣẹ fun. Dajudaju, wọn n ṣiṣẹ fun ara wọn ati fun apo ara wọn ni, nitori ko si araalu kan to gbe iru iṣẹ bayii le wọn lọwọ. Bi Tinubu ba fẹẹ du ipo aarẹ, ẹ jẹ ko jade, ko kọkọ sọ bẹẹ, eyi lawọn araalu yoo fi mọ eyi ti wọn yoo ṣe. Gbogbo eyi ti ẹ n ba kiri yii, iranu ni o; ẹ jẹ ki Tinubu jade ko fẹnu ara ẹ sọrọ.

 

Ki awọn ọba wa paapaa ṣọra wọn gidigidi

Awọn oloṣelu ti bẹrẹ si i pooyi kiri bayii, wọn dele  Alaafin, wọn si de ọdọ Olubadan, ariwo ti wọn n pa bayii ni pe ki ọmọ Yoruba waa di aarẹ. Ṣugbọn awọn ọba wa gbọdọ ṣọ ara wọn gidigidi, nitori bi wahala kan ba ṣẹlẹ nidii ọrọ oṣelu lasiko yii, awọn ọba ti wọn ba lọwọ si abosi, iru awọn ọba bẹẹ yoo fi ara gba ohun ti ko dara o, ko ma di pe wọn jo aafin, ti wọn yoo si le ọba funra ẹ jade, ti ọba yoo si fi arugbo ara maa sa kabakaba kaakiri. Bi ọba kan ba fi ara rẹ si ipo ọwọ to yẹ ki ọba wa, iru iyẹn ko ni i ṣẹlẹ si i. Awọn ti wọn n kiri yii, ọba kọọkan gbọdọ ba wọn sọ ootọ ọrọ, ki wọn si jẹ ki araalu mọ ohun ti awọn ba wọn sọ. Akọkọ ni pe kin ni awọn oloṣelu ti wọn kiri lọjọsi, ti wọn ni Buhari yoo mu ire ba ilẹ Yoruba nitori pe o mu Ọṣinbajo ni igbakeji, ri ṣe si gbogbo iṣoro to n koju awa Yoruba bayii, paapaa iṣoro aile-sun aile-wo tawọn Fulani wọnyi ko ba wa. Kin ni awọn oloṣelu ilẹ Yoruba ti wọn gbe Buhari wa ri ṣe si ọrọ pe wọn Fulani n gba ilẹ wa? Kin ni wọn ri ṣe si pe Buhari n yọ awọn Yoruba nidii iṣẹ gidi ni Naijiria, o si n fi awọn Fulani si i. Kin ni wọn ri ṣe si pe ko si ifọkanbalẹ, ati isinmi kan ni ọpọ ilẹ Yoruba laye ijọba to wa lode yii! Ọna wo gan-an ni awọn naa si fẹẹ gba ti ijọba tiwọn yoo fi yatọ. Ki lo de ti wọn ko si fun ijọba to wa lode yii ni iru amọran bẹẹ, lati le mọ ohun ti wọn yoo ṣe. Gbogbo ohun ti awọn ọba yii gbọdọ beere ree ki wọn too wa lẹyin oloṣelu kan. Ọba to ba n gbe oloṣelu kan gẹgẹ lasiko yii, to n fipa mu awọn eeyan rẹ pe oun ni ki wọn tẹle, toun naa n jade, to n ko agbada wọ kiri lori ohun ti ko mọ, tabi nitori owo buruku ti wọn ko wa fun un, ọba bẹẹ yoo jẹka gbẹyin, yoo kabaamọ, nitori bi wahala ba bẹrẹ, ile rẹ ni awọn ọdọ ati aralau yoo kọkọ rọ lọ, iru alejo bẹẹ ko si ni i jẹ alejo alaafia, alejo lile ni. Ọba to ba fẹẹ fi igbadun lo igbẹyin aye rẹ, afi ko ṣọra fun awọn oloṣelu lasiko yii, ọba to ba jẹ ki wọn ko ba oun, ko ti mọ pe ohun ti oju oun ba ri, oun loun fi ọwọ ara oun fa a o. Ẹyin ijoye ilu, ẹyin ayaba gbogbo, ẹ ba awọn kabiyesi sọrọ, nitori ọba to ba fọwọ ẹ fa jọgọdi, yoo fori ara rẹ ru u o. Ni asiko ta a wa yii, ẹ sọ fawọn ọba wa ki wọn sọra wọn gidigidi!

Asiko ti awọn ọba wa gbọdọ sọ ara wọn gidigidi ree o.

Leave a Reply