O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Isiaka Akintọla, ori ọkẹrẹ koko lawo, ba a wi fọmọ ẹni a gbọ

Nigba ti bata kan ba n ro larooju, bata naa ṣetan ti yoo ya ni. O pẹ ti O-ṣoju-mi-koro pẹlu awọn agba ilẹ Yoruba mi-in ti n kilọ fun Purofẹsọ Ishaq Akintọla ti Yunifasiti LASU pe ko ṣọra rẹ gidi nidii awọn ọrọ to maa n sọ, ati bo ṣe n mu gbogbo nnkan le koko lọna ti ki i ṣe aṣa ti Yoruba, to si tun jinna si bi awọn agbaagba ti a ba nidii ẹsin Islam yii ṣe n ṣe e. Gbogbo ero ati iṣe Akintọla, bii igba to fẹẹ da ogun ẹsin silẹ, tabi bii igba to n fẹ ki wahala kan ṣẹlẹ laarin awọn Musulumi ati awọn Kristẹni ni Naijiria yii ni. Bi wọn gbe kinni kan dide ti yoo ṣe ilu lanfaani, bi Akintọla ko ba ni yoo ba ẹsin oun jẹ, o le ni wọn ko fi awọn Musulumi sinu ẹ. Nigba ti wọn da Amọtẹkun silẹ nilẹ Yoruba nibi, ọtọ ni oriṣiiriṣii ọrọ ti ko nitumọ to n ti ẹnu ọkunrin naa jade. Bi awọn Hausa ba gbe wahala tiwọn de, ti wọn n ja ija ti ko mu ọpọlọ dani, ti wọn n fi ẹsin boju lati ṣebajẹ, Akintọla ni yoo jade ti yoo ni bi wọn ti n ṣe e gan-an lawọn onibajẹ naa n ṣe e yii. Bi Amẹrika ba gbogun ti awọn afẹmiṣofo nibi kan, Akintọla le ni ọna ti wọn gbe kinni naa gba ko daa, yoo di Islaam lọwọ, o si ti ba ọrọ naa debii pe o ti di ẹlẹtẹẹ loju ọpọ eeyan. Ṣugbọn gbogbo eyi ti a ti n ba bọ lati ẹyin,  o daa, o dun titi. Ṣugbọn eyi to fi ọwọ ara rẹ fa yii, boun naa ba bọ nibẹ, yoo mọ pe iwọnba leeyan n tori ati lorukọ, tabi pe ki aye mọọyan, ko maa sọ ọrọ ti ko nitumọ kiri. Wọn ni Akintọla ati ẹgbẹ rẹ gbowo lọwọ awọn ọmọ ogun afẹmiṣofo, nigba ti ọrọ yoo si fọ loju, awọn ti wọn sọ bẹẹ ki i ṣe Naijiria, awọn ara ilẹ Afrika mi-in ni. Eyi tumọ si pe ki i ṣe awọn ara Naijiria nikan ni Akintọla yoo ṣe alaye fun, yoo ṣe alaye naa kari Afrika, yoo ṣe niluu oyinbo, koda, yoo ṣe e lọdọ awọn Larubawa ti ẹsin ti wa, bi wọn ba si gba a mu nibi kan, afaimọ ko ma pẹ nibẹ kanrin. Ko sẹni to gbadura eleyii fun Ishaq Akintọla, ṣugbọn ki oun naa fi ọwọ sibi ti ọwọ n gbe, ko ma ro pe awọn ọrọ ti oun n sọ yii yoo fun oun ni orukọ rere nibi kan, tabi yoo sọ oun di olori Musulumi ilẹ Yoruba, yoo kan fẹnu ko ba ara rẹ ni. Ọrọ yii ti n kọja ibi to yẹ o, ẹyin famili, ẹ pepade, kẹ ẹ ba Ishaq Akintọla sọrọ, ọna to n gba yii ko daa, o lewu pupọ fun oun alara.

 

Ki lo wa n ṣelẹ si wọn ni Yunifasiti Eko yii o

Nigba ti nnkan ṣi dara nilẹ yii, ko sibi ti nnkan daadaa ti n waye ju inu ọgba yunifasiti lọ, nitori nibẹ ni wọn ti n kọ awọn aṣaaju ọla, ibẹ ni ile imọ, ibẹ si ni awọn ọjọgbọn aye ati onimimọ pin si. Ṣugbọn loni-in yii, nnkan ko ri bii ti atijọ mọ, iwa ibajẹ ti n jade lati awọn yunifasiti wa, ko si yaayan lẹnu pe iwa ibajẹ kun ibi gbogbo to ku, boya nile ijọba ni o, tabi nidii iṣẹ ijọba. Wahala ṣẹlẹ ni Yunifasiti Eko lọsẹ to kọja, wọn si le Olori yunifasiti naa, Purofẹsọ Oluwatoyin Ogundipẹ, kuro nipo, wọn ni ko maa lọ sile. Ni wọn ba fi ẹlomiiran rọpo rẹ. Ọpọ eeyan ni wọn dide ti wọn bẹrẹ ija, awọn mi-in n sọ pe ko yẹ ki wọn le ọga agba naa lọ. Awọn kan sare pade, wọn ni awọn igbimọ adari yunifasiti yii, ọga agba ti wọn si le lọ yii naa ni olori wọn, wọn lawọn ko ni i gba. Kin ni wọn waa fẹẹ sọ, nigba to jẹ ara wọn ni ẹni ti wọn le lọ, oun si ni olori wọn. Ẹgbẹ awọn olukọ agba ni awọn yunifasiti to ku naa binu, wọn sare kọwe, wọn ni awọn ko ni i gba. Koda, awọn tiṣa kan naa jade, wọn tẹle Ogundipẹ, wọn jọ n wọ inu ọgba kiri, wọn ni ko sẹni to le yọ ọ. Ṣugbọn nigba tawọn ti wọn gba Ogundipẹ sẹnu iṣẹ jade, ti wọn ni nitori pe o n kowo jẹ lawọn ṣe le e lọ, pe o n ko owo yunifaisti jẹ ni, a ko ti i gbọ kinni kan lẹnu awọn olugbeja ojiji yii mọ. Dokita Wale Babalakin ti i ṣe olori igbimọ apaṣẹ fun yunifasiti yii, awọn ti wọn gba Ogundipẹ siṣẹ, ti wọn si le e lọ ni ko si bojuboju kan ninu ọrọ yii, pe Ogundipẹ n kowo jẹ lawọn ṣe le e lọ. O ni Ogundipẹ fi miliọnu mọkandinlaaadọta (N49 million) tun ile to ni oun n gbe ṣe, ki i ṣe pe o kọ ile tuntun o. Nigba ti akapo ileewe naa fẹẹ maa jampata, o fun oun naa ni miliọnu mọkanlelogoji ki oun naa fi tun ile tirẹ naa ṣe, ni akapo ba yaa sinmi. Lọọya nla ni Babalakin, eeyan to si lorukọ niluu ni, ko jẹ jade si gbangba lati waa sọ iru ọrọ nla bayii bi ki baa ṣe ododo. Wọn waa ni wọn pe Ogundipẹ ko waa ṣalaye awọn nnkan wọnyi, kaka bẹẹ, o bẹrẹ si i ni ko sẹni to le paṣẹ le oun lori, ohun to ba wu oun loun yoo ṣe. Nigba ti ọrọ waa ja si bo ti ja si yii, awọn ti wọn ko mọdi ọrọ n jade, wọn n ja ija ti wọn ko mọ, wọn n da si ohun ti ko ṣoju wọn. Ki lo de ti wọn ko pe Ogundipẹ funra ẹ ko ṣalaye boya oun kowo jẹ tabi oun ko kowo jẹ, ko ṣalaye bọya loootọ loun fi miliọnu rẹpẹtẹ bẹẹ tun ile ti oun n gbe ṣe lai jẹ pe oun kọle tuntun. Ohun to n ṣẹlẹ ni Yunifasiti Eko yii fi ohun to n ṣẹlẹ kaakiri Naijiria han ni, nnkan wa ti bajẹ jinna, ki Ọlọrun ma jẹ ko bajẹ kọja atunṣe ni.

 

Iṣẹ ti wọn fun Sanwo-Olu l’Ondo yii

Alaga igbimọ apaṣẹ fidi-hẹ-ẹ ti ẹgbẹ APC, Mai Mala Buni, ti sọ fun Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, pe ko ri i daju pe ipinlẹ Ondo ko bọ lọwọ ẹgbẹ awọn o, iyẹn APC. Ki waa ni ti Sanwoolu ninu iyẹn. Oun ni alaga igbimọ ti yoo dari ipolongo ibo naa fun Akeredolu ni, oun ni yoo ṣaaju gbogbo APC to ku lati ri i pe Akeredolu wọle pada, yoo nawo, yoo nara, yoo si na ọmọluabi to ba ni. Eleyii ki i ṣe tuntun rara, bi awọn ẹgbẹ oṣelu ti n ṣe naa niyi, to jẹ nibikibi ti ibo ba ti jẹ ibo adadi bii ti Ondo yii, wọn yoo yan ọkan ninu awọn eeyan nla inu ẹgbẹ naa ti wọn ko ba dibo lọdọ tiwọn pe ki wọn lọọ ṣaaju ipolongo, ki ẹgbẹ wọn le wọle. Ohun to dara ni. Eyi to kan le nibẹ ni aṣẹ ti adari ẹgbẹ wọn yii pa, pe ki Sanwoolu ri i pe ẹgbẹ awọn lo wọle. Aṣẹ onikumọ ree o. Ko si ohun ti Sanwoolu le ṣe bi Akeredolu to wa nibẹ ko ba ti ṣe daadaa fawọn eeyan wọn tẹlẹ, tabi kin ni yoo ṣe si i ti aṣọ ko ba ba Ọmọyẹ mọ, to ba jẹ Ọmọyẹ ti fẹẹ rin ihooho wọja. Ohun ti wọn n sọ fun awọn oloṣelu ree, to jẹ ti wọn ba ti wọle, wọn yoo ro pe ọdun mẹrin mi-in ko ni i pe mọ, to jẹ kaka ki wọn ṣiṣẹ, ija ati ẹjọ kọtadọti ni wọn yoo maa fi gbogbo asiko wọn ro, o digba ti ibo ba tun n bọ bayii ki wọn too mọ pe awọn eeyan awọn lagbara. Ọrọ to wa nilẹ yii ko le rara, irẹjẹ ko si ninu fọto, beeyan ba ti jokoo ni yoo ba ara rẹ, asiko ti esi idanwo ti Arakunrin ti n ṣe lati ọjọ yii yoo jade ree, bo ba paasi, yoo ri i, bo ba si feeli, yoo ri i. Ko si ohun ti Sanwoolu yoo ṣe sọrọ yii, bo ba si ko owo Eko lọ sibẹ lati na an ni ọna ti ko tọ, yoo gbọ winrinwinrin lẹnu awọn ara Eko gbogbo. Ohun yoowu ko ṣẹlẹ si Akeredolu, ọwọ ara rẹ lo fi fa a o.

 

Ni bayii ti Agboọla ti di ọmọ Lebọ, ko jijo ọwo ẹ han wa ka ri i

Nigba ti ẹni kan ba n ṣe inawo, boya iya rẹ lo ku tabi baba rẹ, to ṣaa jẹ oun lọmọ oninaawo, nigba to ba di asiko ti ijo kan an lẹyin to ti ṣe wahala titi lati tẹ awọn alejo rẹ lọrun, to ba bọ si oju agbo, awọn onilu yoo yi ilu pada, wọn yoo maa ni, ‘Lagbaja ọmo lagbaja, jijo ọwọ ẹ han wa ka ri i.’ Wọn yoo ni ko jijo to ba mọ ọn jo, nigba to jẹ oun lo pe ilu, oun naa lo yẹ ko jo eyi to pọ ju lọ ninu ijo oju agbo. Bi ọrọ Agboọla Ajayi ti ri ree o, Ajayi to kuro lẹyin ọga rẹ, igbakeji gomina to binu kuro lẹyin gomina rẹ, o tun kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC, to gba PDP lọ. O tun de PDP, eku ko ke bii eku, ẹyẹ naa ko ke bii ẹyẹ, ni inu ba tun bi Ajayi, lo ba tun gba inu ẹgbẹ mi-in lọ. Ko si ohun to n wa ju ẹgbẹ ti wọn yoo fa a kalẹ ti yoo ti du ipo gomina pẹlu ọga rẹ lọ. Agboọla da ara rẹ loju, o nigbagbọ pe oun yoo wọle ibo bi oun ba ti ri ẹgbẹ oṣelu kan fa oun kalẹ, nitori gbogbo Ondo lo mọ oun, ti wọn si ni igbẹkẹle ninu oun. Ko ni i daa bi Agboọla ko ba ri ẹgbẹ oṣelu kan fa a kalẹ loootọ, yoo da bii igba ti wọn ge iyẹ apa rẹ ni. Ati paapaa, ere ti eeyan ko ba jẹ ki ọmọde ṣe, ere naa yoo maa niyi loju ọmọde naa ni. O da bii Agboọla ti wa ninu awọn ti wọn fẹẹ du ipo gomina yii, gbogbo araalu yoo foju ara wọn ri bi gbajumọ ọkunrin yii ti to, ati bo ṣe lagbara nidii oṣelu ipinlẹ Ondo yii to. Abi ta lo le sọ, aja to ku naa le jẹkọ, Agboọla ma le gba inu ZLP di gomina, koda, ko jẹ oju ferese lo gba debẹ. Ni bayii, ẹsẹ awọn mẹta ti pe, ko si pe ara ipinlẹ Ondo ko ri ẹni ti wọn yoo yan, ninu awọn mẹta yii, o yẹ ki wọn le mu ẹni kan ti yoo ṣe wọn loore. Ṣugbọn ki awọn naa ma tori owo dibo, tabi nitori ounjẹ ọjọ kan ti awọn oloṣelu fẹẹ fun wa. Ẹ dibo nitori awọn ọmọ yin, nitori ọjọ ọla wọn, ati bi ipinlẹ Ondo yoo ṣe dara.

 

Ọọni ti sọrọ, bẹẹ lo gbọdọ ri o

Ọọni Ileefẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ti gba awọn DSTV ati awọn to ku ti wọn n ṣe eto kan ti wọn n pe ni BBNaija (Big Brother Naija) nimọran pe ki wọn pa eto naa rẹ, ki wọn si fi nnkan mi-in rọpo ẹ. Eto ti wọn maa n ṣe lori tẹlifiṣan naa jẹ eyi ti wọn maa n ko awọn ọdọ sinu ibugbe kan naa, wọn le to ogun tabi ju bẹẹ lọ, tọkunrin tobinrin wọn, wọn yoo mura wọn bii tọkọ-taya, wọn yoo maa ṣi ara silẹ, wọn yoo maa rin ni ihooho, koda, wọn a maa ba ara wọn sun ni gbangba loju aye nibẹ. Ko si ohun to n mu awọn ọdọ wa sare lọ sidii eto naa ju owo buruku to wa nibẹ lọ. Bẹẹ ni toootọ, owo buruku lo wa nibẹ, owo to to bii ọgota miliọnu naira lẹni to ba ṣe aṣeyege ninu wọn le gba. Nitori bẹẹ, ko si ohun ti wọn ṣe fun iru ọmọ bẹẹ, paapaa ọmọbinrin, ti ko ni i fara mọ, koda ki wọn maa ba a lo pọ nibi ti wọn gbe tẹlifiṣan si, ti gbogbo aye si ti n ri i. Paripari rẹ ni pe ko si ẹkọ gidi ti kinni naa fi n kọ awọn ọmọ wa bi ko ṣe ere egele lasan. O si ti di nnkan aṣa bayi pe gbogbo awọn ọdọ ni wọn fẹẹ wa nidii ẹ, awọn ileeṣẹ mi-in paapaa fẹẹ maa ṣe iru ẹ, nitori wọn mọ pe awọn ọdọ yoo wa sibẹ lati kopa. Eleyii ko dara fun ilẹ wa, ni inu wa si ṣe dun pe Ọọni funra rẹ ri eleyii, to si sọ pe ki awọn ti wọn n ṣe eto yii wa nnkan mi-in ṣe. Ko si ohun to buru bi iru eto yii ba wa, bẹẹ ni ko si ohun to bajẹ bi awọn ọmọ yii ba jọ gbe, ṣugbọn niṣe lo yẹ ki wọn lo o fun ẹkọ gidi, ẹkọ ti yoo wulo fun wọn titi aye, ki i ṣe fun iṣekuṣe ati iwa aṣa ti yoo ba aye wọn jẹ, ti yoo si ba aye awọn ẹlẹgbẹ wọn to ba n wo wọn jẹ. Ọọni ti sọrọ o, bo si ti ṣe gbọdọ jẹ niyẹn. Ẹ wa nnkan mi-in fi rọpo BB Naija yii, kẹ ẹ ma tubọ ba aye awọn ọdo orile-ede yii jẹ si i.

Leave a Reply