O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Fayẹmi l’Ekiti pẹlu awọn ọrẹ rẹ

Nigba miiran, awọn oloṣelu fẹran ẹtan, wọn yoo si maa tan ara wọn jẹ. Ibi ti wọn ba fẹẹ lọ, wọn yoo ni laelae, awọn ko ni i debẹ, wọn yoo si maa fi ori awọn araalu gba ara wọn. O yaayan lẹnu gan-an pe awọn aṣofin ipinlẹ Ekiti yoo sare ni awọn yọ alaga ijọba ibilẹ Ikẹrẹ, Fẹmi Ayọdele, kuro nipo rẹ, nitori wọn lo fi owo ara rẹ ṣe posita, nibi to ti n kede pe Gomina Ekiti, Olukayọde Fayẹmi, loun fẹẹ dupo aarẹ lọdun 2023. Boya ni awọn aṣofin yii wa niluu, nitori bi wọn ba wa niluu ni, wọn yoo mọ pe ki i ṣe ọkunrin alaga yii lẹni ti yoo kọkọ sọ pe Fayẹmi fẹẹ du ipo aarẹ. Lati ibẹrẹ ọdun to kọja ni alaga Egbẹ Apapọ awọn Yoruba ti ni Fayẹmi daa pupọ lẹni ti yoo ṣe aarẹ, nitori gbogbo ohun to yẹ ko ni lo ti ni. Fayẹmi ko ko ọrọ naa danu, ko si sọ pe oun ko ṣe, o n rẹrin-in bi wọn ti n sọ fun un ni. Awọn irin kan ti oun funra ẹ si n rin lati ọjọ yii wa, awọn ti wọn mọ nipa oṣelu ko ko ọrọ naa danu pe o le du ipo aarẹ bo ba ya. Nigba ti Ayọdele si lẹ posita mọta yii, Fayẹmi ko sọrọ, ọmọọṣẹ rẹ to si sọrọ ko sọ pe yoo ṣe tabi ko ni ko ṣe, o ni ẹni to sọrọ yẹn, ero ọkan rẹ lo n sọ jade. Iru ọrọ ti Babangida sọ titi to fi ba ibo ‘June 12’ jẹ niyi, ti wọn n sọ pe yoo du ipo aarẹ, to ni ero to wa lọkan awọn ti wọn n sọ bẹẹ niyẹn. Bi alara ba ni ara ko ro oun, ki waa ni awọn aṣofin Ekiti n sọ pe tọhun ku aisun, o ku aiwo si. Ta ni awọn eeyan naa n ṣiṣẹ fun, Ṣe Bọla Tinubu ni wọn n ṣiṣẹ fun ni abi Kayọde Fayẹmi. Ọrọ ti ko kan wọn ni wọn n da si, awọn naa si ti fi han pe ẹyin ẹni kan lawọn wa ninu ọrọ idibo aarẹ ọdun 2023. Iṣẹ gidi wa nilẹ to yẹ ki wọn ṣe fun ilu, anfaani gidi wa ti wọn le fi ipo wọn ṣe fun araalu, sibẹ, gbogbo iyẹn ko ka wọn lara, ẹni to jade to fowo ẹ tẹ posita to ni ẹnikan fẹẹ ṣe aarẹ ni 2023, ti ẹni to ni o fẹẹ ṣe aarẹ ko si tori ẹ ba a ja, ni wọn jokoo ti wọn n fi akoko ṣofo le lori. Ki lo de ti wọn ko beere lọwọ Fayẹmi eyi toun naa fẹẹ ṣe gan-an! Abi ewo ni lala-koko-fẹfẹ ti wọn ko ara wọn si. Ẹ wabi kan jokoo si jare.

 

Buruji Kaṣamu ati Adebutu Baba Ijẹbu

Ọrọ kan to n ja ran-in ran-in gidi nilẹ ni ti fidio kan to jade lori Oloogbe Buruji Kaṣamu ati Oloye Adebutu Kessington. Ninu fidio naa to ti kari aye bayii, Kaṣamu da bii ẹni to wa lori akete aisan rẹ, to si n bẹ Baba Ijẹbu pe ko dariji oun pẹlu gbogbo aṣiṣe ti oun ṣe. Ṣe ko too di ọjọ yii, ija buruku lo wa laarin Adebutu ati Kasamu, ti ọrọ naa si ti dele-ẹjọ loriṣiiriṣii. Ohun ti o si fa ija wọn ko ju ileeṣẹ tẹtẹ ti awọn mejeeji jọ n ṣe lọ. Baba Ijẹbu ni ileeṣẹ tẹtẹ tirẹ, Buruji naa si ni ileeṣẹ tẹtẹ tirẹ. Nigba ti ọrọ yoo tubọ tilẹ daru, ọmọ Adebutu ti wọn n pe ni Ladi loun yoo ṣe gomina ipinlẹ Ogun labẹ PDP, Kaṣamu ni oun naa yoo ṣe gomina labẹ PDP yii kan naa. Ija de, wọn pin ẹgbẹ si meji, Kaṣamu ni kinni ọhun si bọ si lọwọ.  Nibi yii ni ija naa ti le, Kaṣamu doju kọ ọmọ nidii oṣelu, o si doju kọ baba nibi iṣẹ okoowo ti wọn jọ n ṣe. Ṣugbọn nigba ti iku n kanlẹkun ile Kaṣamu, o pe Baba Ijẹbu, o ni ko foriji oun, koda, bo ba fẹẹ gba ileeṣẹ tẹtẹ oun, oun yoo ni ki wọn ko gbogbo ẹ fun un, ati pe ti oun ba le gbadun, gbogbo ohun yoowu ti Ladi ba fẹ nidii oṣelu ipinlẹ Ogun loun yoo ṣe atilẹyin rẹ fun un. Ṣugbọn pẹlu gbogbo ileri yii, Kaṣamu pada ku naa ni. Ko pẹ ni fidio isọnu yii jade. Isọnu ni fidio naa nitori awọn eeyan mọ pe ọdọ awọn Adebutu lo ti jade, ohun ti wọn si n beere ni idi ti Adebutu yoo fi gbe iru fidio yii jade, nitori bii igba ti eeyan n fi oku ọrun ṣe yẹyẹ ni. Awọn ti wọn mọ Adebutu ni ki i ṣe bẹẹ, Ijẹbu ni Kaṣamu, Ijẹbu ni Adebutu, bo si tilẹ jẹ pe gbogbo aye lo gbọ pe Korona lo pa Kaṣamu, sibẹ, awọn kan ko yee gbe e kiri ni gbogbo ilẹ Ijẹbu pe Adebutu lo pa Kasamu, ija ti wọn jọ n ja lori ileeṣẹ tẹtẹ ati ohun to ṣe fun ọmọ rẹ lo jẹ ko sa si i. Ohun to fa a ti Adebutu fi ni ki wọn gbe fidio jade ree, ki gbogbo aye le mọ pe ko si ija laarin oun ati Kaṣamu titi to fi ku, nitori o ti bẹ oun, koda, o ti gbe gbogbo ẹjọ to pe oun kuro ni kootu ko too ku. Ẹkọ to wa ninu eleyii fun gbogbo eeyan ni bi ile aye ṣe jẹ ile asan to. A ko mu kinni kan wa aye yii, o si daju pe ko si ohun ti a oo mu lọ sọrun. Ki iku too mu Kaṣamu lọ, gbogbo ohun to ko dani, gbogbo ohun to wawọ mọ, gbogbo ẹ lo fẹẹ ju silẹ, o fẹẹ ju u silẹ boya iyẹn iba jẹ ra ẹmi oun. Bẹẹ bi iku ba ti de, ko gbọ arọwa mọ, ẹni to ba ti kan lo n mu lọ, aaye ko si si fun tọhun lati mu ohunkohun lọ. Gbogbo wa naa ni yoo kan, titi dori Adebutu ati awọn eeyan rẹ ti wọn gbe fidio jade lati fi wẹ ara wọn mọ, gbogbo wa naa ni iku yoo kan, nitori rẹ la ṣe gbọdọ gbe ile aye ka ṣe rere.

 

Ẹ ma ṣe bii awọn oloṣelu Ondo ti wọn n wa ile aye mọya

Awọn oloṣelu ipinlẹ Ondo n wa ile aye mọya ni, wọn ti ro pe nibi ibo ti wọn yoo di yii ni aye parẹ si, ṣe ẹlomi-in ninu wọn ko kuku ni iṣẹ gidi lọwọ mọ, oṣelu nikan ni wọn sọ di ounjẹ wọn. Eyi lo n fa ija, to n fa ka maa yọ ada yọ ọbẹ sira ẹni, gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ ninu ibo ijọba ibilẹ ti wọn di kọja lọ yii. Nigba ti wọn ba dibo ijọba ibilẹ to le to bayii, ti wọn n yọ ada, ti wọn n yọ ọbẹ, ti APC ni tọọgi, ti PDP ni, ti ZLP ni, ti awọn ADP lawọn tiwọn, nigba wo ni nnkan ko ni i daru kọja atunṣe. Ohun to si n biiyan ninu lọrọ awọn ole ajẹgudujẹra oloṣelu yii ni pe pẹlu gbogbo oṣi ti wọn n ṣe yii, ariwo kan naa lo wa lẹnu wọn, ariwo pe awọn fẹẹ ṣiṣẹ sin ilu ni wọn n pa kiri. Ilu wo ni wọn fẹẹ ṣiṣẹ sin, bawo ni wọn ṣe fẹẹ ṣiṣẹ sin in, ta lo si gbe iṣẹ naa fun wọn ṣe. Bi eeyan ba fẹẹ ṣiṣẹ sin ilu, ṣe iyẹn ni yoo ṣe maa haayaa tọọgi lati fi ṣe alatako rẹ leṣe, ti yoo maa sin awọn ọmọọta bii ẹni n sin aja, ti yoo si maa da wahala silẹ kaakiri laarin awọn araalu to ni awọn loun waa ṣiṣẹ sin. Gẹgẹ bi a ti n wi, koko ibẹ ni pe awọn oloṣelu Naijiria ko waa sin ẹnikan, awọn waa sin ara wọn, wọn n wa ọna ti wọn yoo fi ji owo awọn araalu ti wọn n sọ pe awọn fẹẹ waa sin yii ko ni. Tabi ẹ ko ri i pe bi adigunjale ṣe n ṣe lawọn naa n ṣe ni. Adigunjale ni yoo ko ada, ko ibọn lọ sile onile, ti wọn yoo halẹ mọ onile tabi ki wọn pa a, ki ohun ti wọn fẹẹ ji ko nibẹ le to wọn lọwọ. Ariwo ti a ti n pa naa ni pe ki gbogbo ọmọ ipinlẹ Ondo mọ pe ọgọọrọ awọn oloṣelu ti wọn jade ti wọn fẹẹ du ipo lọdọ wọn yii, ohun ti wọn yoo jẹ ni wọn n wa o, ati bi owo ti wọn ti ko jẹ yoo ṣe tubọ pọ si i. Nitori bẹẹ, ẹ fara yin balẹ, ki ẹ si fi oju inu wo gbogbo ọrọ, ẹ ma jẹ ki ẹnikẹni lu yin ni jibiti, ẹ ma jẹ ki wọn fi owo taṣẹrẹ gba ohun ti ẹ maa jẹ titi ọjọ aye yin lọwọ yin o. Ole lo pọ ninu wọn, Ọlọrun Ọba si n gbọ!

 

Ẹyin Ọlọpaa Ibadan, ori lo ko yin yọ o

Lati igba ti iroyin ti jade pe Sunday Shodipẹ, apaayan to n pa awọn eeyan bii ẹran, ti sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ ni teṣan ti wọn fi si, lati igba naa ni gbogbo araalu ti n sọ oriṣiiriṣii oko ọrọ ranṣẹ si awọn ọlọpaa Ibadan, lati ori ọga wọn ni ipinlẹ Ọyọ titi de ori awọn ọmọọṣẹ to kere ju lọ. Igbagbọ onikaluku ni pe ko si bi ọkunrin apaayan naa yoo ṣe sa jade ni teṣan ti ko ba ni ọwọ awọn ọlọpaa kan funra wọn ninu. Wọn ni wọn gba owo lọwọ ẹ ni, awọn mi-in si ni awọn alagbara to n ṣiṣẹ fun lo waa yọ ọ lọdọ wọn, ti wọn wa n purọ fun araalu pe o sa lọ. Orukọ awọn ọlọpaa ko daa rara laarin ilu, iru ohun to si ṣẹlẹ yii tubọ ba orukọ wọn jẹ si i ni, awọn araalu ko si fẹẹ gbọ pe aṣiṣe wa lati ibi kan ni. Nitori rẹ lo ṣe jẹ iroyin ayọ, nigba ti ariwo jade lẹẹkan naa pe wọn ti ri ọkunrin apaayan naa mu. Ṣugbọn pe wọn mu ọkunrin yii ko ti i tẹ araalu lọrun to, wọn fẹẹ gbọ bo ṣe sa lọ mọ awọn ọlọpaa lọwọ, ona to gba to fi sa jade. Ṣe fifọwọ dẹngẹrẹ mu iṣẹ ẹni lati ọdọ awọn ọlọpaa lo jẹ ko ribi sa lọ ni, abi awọn kan lo gbabọde, ti wọn deede ṣilẹkun fun un to fi ribi sa lọ. Awọn ọlọpaa funra wọn gbọdọ wadii eyi, ki wọn mọ okodoro ọrọ ibẹ, ki wọn le mọ awọn agbẹyin-bẹbọ-jẹ to ba wa laarin wọn. Bo ba si jẹ aika-iṣẹ-ẹni si lo fa a, ki wọn ti mọ pe ọlọpaa ti wọn ba ka iru ẹ mọ lọwọ gbọdọ lọọ wa iṣẹ mi-in ṣe. Awọn ọlọpaa gbọdọ ri i pe iru eleyii ko ṣẹlẹ mọ, nitori yatọ si pe ibanilorukọ jẹ lo jẹ fawọn naa, ohun to ko ọkan gbogbo ilu soke, to si din igbọkanle awọn eeyan ilu ninu ọlọpaa ku gan-an ni. O daa ti ọwo ti tẹ Sunday bayii, ko tun gbọdọ ribi kan sa lọ.

 

Ọrọ ti Sunday Igboho sọ nipa Amọtẹkun

Ọkan ninu awọn ajijagbara nipinlẹ Ọyọ, ọkunrin ti wọn n pe ni Sunday Igboho, sọ pe oun ko fara mọ ọna ti wọn gba ti wọn fi n gba awọn ọmọ sinu ikọ Amọtẹkun ti wọn ni yoo ba wọn gbogun ti iwa ọdaran nilẹ Yoruba kaakiri. O ni epe ti pọ ju ohun to sọnu lọ, ariwo ti pọ ju nidii kinni yii, o si ṣee ṣe ko ma mu eeso rere ti gbogbo ọmọ Yoruba n reti wa. O ni ki i ṣe iru awọn ọmọleewe to jade ni yunifasiti tabi ni poli ti wọn ko riṣẹ tawọn gomina n ṣa jọ pe ki wọn waa fi orukọ silẹ lori kọmputa ni yoo ba wọn jagun yii, bo ba si jẹ ọna ti ijọba n gba yii ni, wọn ko ni i ri awọn ọmọ ogun Amọtẹkun gidi kan bayii, awọn ọmọ ọlọmọ ti wọn jade ileewe ti wọn ko niṣẹ ni wọn yoo kan ri ko jọ sibẹ, wọn yoo si maa ṣere ni tiwọn ni, wọn ko ni i ba ijọba mu ọdaran kankan. Bi eeyan ba fi oju inu wo ọrọ yii, yoo ri ododo ibẹ di mu. Bi Amọtẹku ti dara to, ti awọn ijọba wa ko ba fi ọgbọn ṣe e, yoo kan parẹ mọlẹ lasan ni. Ijọba apapọ ti gbe awọn ọlọpaa ibilẹ dide bayii, ti wọn yoo wa ni ilu kọọkan, biliọnu mẹtala owo ni Buhari ni ki wọn gbe kalẹ lọsẹ to kọja yii ki wọn fi bẹrẹ eto naa ni gbogbo ipinlẹ kaakiri. Itumọ eyi ni pe awọn ọlọpaa ibilẹ yoo wa, awọn ti wọn si ti gba sinu iṣẹ Amọtẹkun yii naa ni yoo sare lọọ ba wọn, nitori wọn yoo mọ pe iṣẹ tijọba apapọ yii yoo pe wọn ju ti ijọba ipinlẹ lọ. Nitori rẹ lo ṣe jẹ ọwọ ile, ọna ile, ọna awọn baba wa lo yẹ ki ijọba lo ju ninu gbigba awọn eeyan wa si Amọtẹkun, iṣẹ ti wọn yoo si maa ṣe naa ki i ṣe ti alariwo, iṣẹ abẹle, iṣẹ inu igbo, iṣẹ ọdẹ ilu lalẹ ati loru bi Sunday Igboho ti wi ni. Gbogbo eyi ti a n ṣe yii, bi ẹni kan n pariwo lasan ni, bi awọn ọlọpaa ibilẹ wọnyi ba si de, ijọba apapọ yoo da kinni naa ru mọ wa lọwọ. Ki gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba jokoo ipade, ki wọn tun kinni naa ṣe lọna ti yoo fi jẹ ti Yoruba gan-an. Amọtẹkun ki i ṣe tijọba, ti Yoruba ni, bẹẹ naa si ni kẹ ẹ jẹ ka ṣe e.

Leave a Reply