O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Kin ni Tinubu tun n sọ fun wọn l’Ondo

Laarin ọdun kan, o pọ ju, a ko ri iru rẹ ri, ẹẹmeji ni Aṣiwaju Bọla Tinubu yoo de ipinlẹ Ondo, afi ti nnkan kan pataki kan ba ṣẹlẹ lojiji to di dandan pe ko lọlo ku. Yatọ siyẹn, ẹẹmeji ni yoo debẹ ri wọn. Igba akọkọ ni nigba ti wọn ba fẹẹ dibo, ti ẹgbẹ wọn ba faayan kalẹ, ti wọn ba waa sọ fawọn eeyan pe ki wọn dibo fun ẹni ti wọn fa kalẹ. Igba ẹẹkeji ni bi ẹgbẹ wọn ba wọle, ti wọn ba waa ba ẹni to wọle naa ṣe ajọyọ, ti wọn si ṣe ibura fun un. Lẹyin awọn ọjọ meji yii, ohun yoowu to ba n ṣẹlẹ ni ipinlẹ Ondo, Tinubu ko mọ mọ o. Bẹẹ ni ki i ṣe oun nikan, bi yoo ti ri fun Baba Bisi Akande naa ree, ati awọn gomina mi-in, ati ọpọlọpọ awọn eeyan ti wọn pe jọ siluu Akurẹ lọsẹ to kọja yii, ti wọn waa ṣe kampeeni ibo fun Arakunrin Rotimi Akeredolu. Ohun kan naa ti wọn sọ ni ọdun kẹrin sẹyin naa ni wọn tun n sọ, ohun kan naa ti wọn sọ ni ọdun kẹjọ sẹyin ni wọn tun n sọ, bi wọn yoo si ti ṣe maa sọ ohun kan naa titi aye ree, bawọn oloṣelu Naijiria ti ri niyẹn. Awọn ki i ri aaye lati lọọ wo ohun ti ẹni ti wọn fa kalẹ lati du ipo kan ba n ṣe nipo ti wọn gbe wọn si, nitori rẹ ni wọn ki i ṣee mọ ohun ti wọn yoo sọ ju pe ‘ẹ dibo fun wa, ẹ ma dibo fawọn ole, ẹni ti a fa kalẹ yii yoo ṣe daadaa.’ Awọn ti wọn n ṣe kampeeni oṣelu gbọdọ ni ọrọ to dara, to si ni itumọ, ju gbogbo iyẹn lọ. Wọn yoo mọ iye eeyan to wa ni ipinlẹ naa, wọn yoo mọ bi eto ọrọ aje ibẹ ti ṣe ri ni pato, wọn yoo mọ iye gbese ti wọn jẹ, wọn yoo si sọ fawọn araalu, ọna pataki ti wọn yoo gba lati fi tan iṣoro yoowu to ba n koju ipinlẹ wọn. Ṣugbọn awọn oloṣelu tiwa ki i ṣe bẹẹ, bo ba tun di ọdun mẹrin oni, ohun ti wọn sọ yii naa ni wọn yoo tun sọ, orin kan naa ni wọn yoo maa kọ lenu bii aditi. Iyẹn lo ṣe jẹ pe ọrọ ibo to n bọ yii, awọn ọmọ ipinlẹ Ondo funra wọn ni wọn yoo ṣejọba ara wọn, awọn ni ọrọ ara wọn wa lọwọ wọn, awọn ni wọn si le fọwọ ara wọn tun nnkan ara wọn ṣe. Ọlọrun ba wọn ṣe e, wọn ti ri ijọba ti Akeredolu fi ọdun mẹrin ṣe, ti ijọba rẹ ba tẹ wọn lọrun, wọn yoo tun dibo fun un ko maa ba iṣẹ rẹ lọ; bi ijọba rẹ ko ba si tẹ wọn lọrun, wọn yoo paarọ rẹ nipa didibo fẹlomi-in ti wọn ba lero pe yoo tun ipinlẹ wọn ṣe. Ṣugbọn ni ti ariwo ti awọn oloṣelu atijọ yii waa pa ni Akurẹ, ti wọn n da ilẹ laamu, ẹ gboju nbẹ, iṣẹ owo tiwọn lawọn waa ṣe. Ko si eyi to kan yin kan wọn, awọn eeyan yin to fẹẹ dibo ni kẹ ẹ gbaju mọ, ki ẹ si mu eyi to dara ninu wọn. Ẹ ma da awọn oloṣelu to wa lati ọna jinjin wọnyi lohun, afoṣelu-jẹun lawọn ni tiwọn.

 

Iyẹn ni pe wọn ṣẹṣẹ mọ pe Agboọla Ajayi ko ni sabukeeti ni

Bi wọn ba fi le wadii, ti wọn si ri i pe ododo ni pe Agboọla Ajayi, igbakeji gomina Ondo to ti ba ọga rẹ ja, to si fẹẹ du ipo naa lorukọ egbẹ Z-Labour, ko ni sabukeeti, bi wọn ba ti n mu un, bẹẹ naa ni ki wọn maa mu ọga rẹ, titi dori Arakunrin Akeredolu to ba ṣiṣẹ. Bi awọn oloṣelu ṣe ri niyẹn, ole, ọdalẹ, aferugbabukun ni gbogbo wọn. Ọta araalu ni wọn, ọpọlọpọ wọn ki i ṣeeyan gidi. Ni bayii, ariwo n lọ, ẹjọ si ti fẹẹ bẹrẹ paapaa lori pe Agboọla ko ni sabukeeti gidi, wọn n sọ pe ayederu sabukeeti lo ni. Bi wọn ba ṣewadii ọrọ naa tan, ti wọn si fidi ẹ mulẹ, niṣe lo yẹ ki wọn mu Agboọla fi pamọ, nitori ọta araalu ni. Ko si ẹnikẹni ti yoo fẹẹ gba iṣẹ ijọba ti ko ni i ni sabukeeti, ohun ti ofin wi niyi. Awọn oṣiṣẹ ijọba to si n ba ijọba ipinlẹ tabi ijọba apapọ ṣiṣẹ, pupọ ninu wọn lo ti fi ọdun gbọgbọrọ kawe, ti wọn si ni sabukeeti loriṣiiriṣii. Iru irẹjẹ wo waa niyẹn, ko waa jẹ ẹni ti ko kawe, tabi to sa nileewe, tabi to gba ayederu iwe ni yoo waa maa ṣejọba le awọn ti wọn fi akoko silẹ lati kawe wọn lori. Ohun ti wọn ṣe gbọdọ mu Agboọla ree, koda ki wọn dibo tan, ki wọn ni oun lo wọle. Ṣugbọn bi wọn ba ti ṣe n mu Agboọla, wọn gbọdọ mu awọn eeyan bii Akeredolu naa mọ ọn o. Akeredolu lo fa Agboọla kalẹ nijọsi, oun lo fi i han awọn ara Ondo pe igbakeji oun ni, ko si le sọ pe oun ko mọ pe ọkunrin naa ni ayederu iwe ẹri, ẹgbẹ wọn, APC, paapaa ko le sọ bẹẹ, nitori lara ojuṣe wọn ni lati wadii pe ọkunrin naa ni iwe to tọ ati eyi to yẹ. Awọn eeyan naa yoo ti wadii, wọn yoo si ti ri idi okodoro, ṣugbọn wọn yoo bo ootọ naa mọlẹ, nitori ọmọ ẹgbẹ wọn lọrọ kan. Nitori rẹ lo ṣe jẹ iya yoowu to ba tọ si Agboọla, to tọ sawọn naa daadaa. Awọn oloṣelu yii lo n ba aye jẹ, ti wọn ba sọ pe adegun loni-in, wọn yoo sọ pe adeogun lọla. Abi wọn ṣẹṣẹ mọ pe Agboọla ko ni sabukeeti ni, awọn enranu gbogbo!

 

Bi ọlopaa pe ogun, bi wọn pe ọgbọn, iyẹn kọ ni koko o…

Ọga ọlọpaa pata ti kede pe ọgbọn ẹgbẹrun awọn ọlọpaa lawọn n ko lọ si ipinlẹ Ondo fun ti ibo to n bo yii, pe awọn ni wọn yoo mojuto ibo naa daadaa. Ọga ọlọpaa pata funra ẹ, Muhammadu Adamu, lo kede bẹẹ, o ni awọn ko fẹ ki kinni kan yingin, tabi ki idarudapọ kan wa nibi kan lawọn ṣe ṣe bẹẹ. Bi eeyan ba gbọ iru iyẹn, ọkan yoo balẹ daadaa pe ko si wahala loootọ, ọkan yoo balẹ daadaa pe ko si idaamu kan, ibo naa yoo lọ wọọrọ. Ṣugbọn ki i ṣe ki awọn ọlọpaa yii pọ rẹpẹtẹ ni yoo mu nnkan lọ bo ṣe yẹ ko lọ. Ohu ti yoo mu nnkan dara ni ki awọn ọlọpaa to n lọ si Ondo yii ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ, ko ma jẹ awọn gan-an ni wọn yoo maa jiṣẹ ti wọn ko ran wọn, tabi ti wọn yoo maa jiṣẹ awọn oloṣelu ọbayejẹ. Ni gbogbo igba ti ibo ba n bọ yii, ẹru to maa n ba awọn araalu ju ni ti awọn agbofinro funra wọn. Awọn oloṣelu mi-in wa to jẹ awọn agbofinro yii ni wọn gboju-le lati ṣe aburu yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe ni asiko ibo, awọn ni wọn yoo maa lo bi wọn ba ti fun wọn ni owo taṣẹrẹ. Iyẹn lo ṣe jẹ pe ki i ṣe iye ọlọpaa ti ọga ko lọ si Ondo lo ṣe pataki, bi ko ṣe ki wọn ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ, ki wọn ṣe iṣẹ naa ko dara, ohun ti ọga yii gbọdọ sọ fun awọn ọmọ rẹ niyẹn. Iru awọn ibo bayii lo yẹ ki araalu fi ni ifọkanbalẹ ninu ọlọpaa ati ijọba, pẹlu awọn ti wọn ba fa eto idibo naa le lọwọ, ohun to si le tete jẹ ki eleyii ṣee ṣe ni bi awọn ọlọpaa naa ba ṣe ṣiṣẹ wọn si o. Ọrọ yii dọwọ ọga ọlọpaa pata. Ẹ ba awọn ọmọ yin sọrọ, ki wọn jinna si awọn oloṣelu Ondo, ki wọn ma joye agbẹyinbẹbọjẹ, kawọn ọmọ Naijiria le maa ṣadura fun wọn.

 

Wọn sọ fun wọn to, wọn ko gbọ ni

Ijọba ipinlẹ Ọṣun, labẹ Gomina Gboyega Oyetọla, ti kede pe awọn yoo da ileewe gbogbo nibẹ pada si aaye wọn, wọn yoo da wọn pada si bi wọn ti ṣe wa tẹlẹ, nibi ti ileewe gbogbo yoo ti maa wọ aṣọ ti wọn fi da wọn silẹ, ti wọn yoo si maa tẹle eto ati ofin ti wọn fi da ileewe naa silẹ lati ọjọ to pẹ wa. Eleyii lo jẹ ko di eto meji ti ijọba tuntun yii ti fagi le ninu eto ti gomina atijọ, Raufu Arẹgbẹṣọla ṣe nibẹ. Akọko ni yiyi orukọ ipinlẹ naa pada si Ọṣun State to wa ninu iwe ijọba Naijiria, yatọ si State of Ọṣun ti gomina tẹlẹ naa sọ ọ. Ohun to ṣẹlẹ ni pe ni gbogbo igba ti Arẹgbẹ n ṣe awọn eto yii, awọn eeyan ti ọrọ kan kilọ fun un to. Awọn ti ọrọ ko kan paapaa kilọ fun un, nitori wọn mọ pe to ba delẹ tan, gbogbo wọn naa ni yoo kan. Oun naa lo delẹ yii o. Owo ni wọn yoo na lati yi iwe ati awọn ohun gbogbo ti wọn ti tẹ jade si orukọ ti Arẹgbẹ sọ ipinlẹ rẹ pada, bẹẹ ni lati ṣe atunṣe si ọrọ awọn ileewe yii naa ko ni i jẹ inawo kekere. Ohun ti wọn ni ki okobo bọ, ko bo ọ, ohun ti wọn ni ki gomina ṣe kọ lo n ṣe. Tabi orukọ yiyipada ni yoo jẹ ki awọn ọmọọleewe mọwe ni abi ti eto ikọni tuntun ti ijọba ba ṣe. Yiyi orukọ ipinlẹ Ọṣun pada ni yoo jẹ ko di ipinlẹ gidi ti orukọ rẹ yoo kari aye ni abi eto idagbasoke ti ijọba ibẹ ba dawọ le. Loootọ ni wọn yi orukọ ipinlẹ naa pada, ṣugbọn kin ni wọn mu bọ nibẹ ju gbese ti arọmọdọmọ yoo maa san lọ. Ijọba Arẹgbẹṣọla ko awọn eeyan Ọṣun si gbese ti awọn naa ko mọdi, idagbasoke ti wọn si pariwo titi pe awọn n ṣe siluu nigba naa, o daju pe ọpọ ara Ọṣun ko ti i foju ri i. Ṣugbọn awọn eeyan wa naa fẹran ẹtan, bi Arẹgbẹṣọla ti n ṣe gbogbo eleyii ni wọn n patẹwọ fun un, ti wọn si n lọgun rẹ, bo tilẹ jẹ pe o n ko wọn sinu gbese ni. Ẹran ti ku bayii, o fi iṣẹ silẹ fun awọ: Arẹgbẹ ti ba tirẹ lọ, wahala ijọba lo ku lọrun Oyetọla. Ṣugbọn ti Arẹgbẹ naa yoo maa ba a lọ, bo ba ṣe e daadaa, awọn ara Ọṣun yoo maa san an fun un nigbakigba toun naa ba yọju si wọn; bi ko si ṣe e daadaa naa, ẹsan to ba tọ si i naa, wọn yoo maa san an fun un. Ile ijọba ki i ṣe ile-titi-aye, ẹni kan yoo lo ibẹ fungba diẹ ni. Iyẹn ni ki i ye ọpọ oloṣelu, bi wọn ba ti debẹ, wọn yoo ro pe awọn ti di igbakeji Ọlọrun ni. Yẹyẹ lasan.

 

Sanwoolu pẹlu Abiọdun, o si daa bẹẹ o

Ikede to wa lati ọdọ awọn ijọba ipinlẹ Ogun ati ijọba Eko pe awọn mejeeji yoo jọ pawọ-pọ tun titi Eko si Abẹokuta ṣe, ti awọn yoo si maa gba owo lori ẹ nigba ti awọn ba ṣe e tan jẹ eyi to dara pupọ gan-an. Ni gbogbo aye, bi awọn ijọba orilẹ-ede ti n ṣe niyi. Wọn yoo ṣe titi to dara gan-an, wọn si le gbe e fun awọn agbaṣẹṣe kan pe ki wọn ṣe e, bi wọn ba si ti ṣe e tan, wọn yoo ni ki wọn maa gba owo irinna ti wọn n pe ni too-geeti lọwọ awọn  to n lo o. Owo yii naa ni wọn yoo gba titi ti wọn yoo fi ri owo ti wọn fi ṣe ọna naa pe, ti wọn yoo si tun maa lo o lati fi tun ọna naa ṣe. Ọna Eko si Abẹokuta ti fẹẹ di ẹti, koda, ohun itiju ni fun ijọba Naijiria, to ba jẹ awọn eeyan naa lojuti rara, nitori ọna to so Naijiria pọ pẹlu awọn orilẹ-ede mi-in ni. Iye ọdun ti wọn ti n fi ṣe ọna naa ko ṣee ka mọ bayii: bo ba fi ọdun kan dara, yoo fi ọdun marun-un di ẹgẹrẹmiti ni. Afi bii ẹni pe ko si orilẹ-ede ti wọn ti tun n lo titi mọ ni gbogbo aye, to jẹ ti ọna Abẹokuta si Eko yii nikan ni. Inira ti ọna naa n fun awọn ti wọn n tọ ọ ko kere ra, nibi ti wọn yoo ti lo bii wakati marun-un lati fi rin irin ti ko ju wakati kan lọ. Mọto yoo bajẹ nibi gbagagbaga to ba n ṣe, awọn ti wọn wa ninu mọto ko ni i gbadun ni fifi ara lu irin, akoko iṣowo ati ọrọ aje yoo daru mọ awọn oniṣowo gidi lọwọ nigba ti wọn ba jade laaarọ kutu ti wọn ko si tete de ibi ti wọn n lọ. Ohun to ṣe jẹ iroyin ayọ lọrọ naa pe ijọba mejejeji fẹẹ ṣe titi yii niyi. Ki Ọlọrun fun wọn ṣe, ki awọn eeyan paapaa si ṣe atilẹyin, ki gbogbo awọn ti wọn n tọ ọna yii, ati awọn ti wọn n gbe apa adugbo yii, le bọ ninu hilahilo ojoojumọ.

About admin

Check Also

Ẹ sọ fun Buhari ko sọrọ soke

Ẹ sọ fun Buhari ko sọrọ soke Eyi to buru ju ninu ohun to n …

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: