O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Ẹ ma ko wọn wa silẹ Yoruba yii rara o

Yatọ si awọn ti wọn gba sinu iṣẹ ologun, awọn ṣọja ilẹ wa ti tun ko awọn ọmọ Boko Haram mọkanlelẹgbẹta (601) pada saarin awujọ. Wọn ni awọn ti kọ wọn ni iṣẹ ọwọ ti wọn yoo maa ṣe, wọn si ti le maa gbe laarin ilu bayii, ko si wahala kankan mọ. Iṣẹ ọwọ to pọ ju ti wọn kọ awọn ọmọ Boko Haram atijọ yii ni iṣẹ baaba, gẹrigẹri. Nigba ti wọn si fẹẹ tu wọn silẹ, wọn ra kilipaasi ati awọn eelo igẹrun-un mi-in fun wọn, wọn waa fun wọn ni ẹgbẹrun lọna ogun naira ẹni kọọkan, wọn ni Ọlọrun yoo sin wọn o. Eto naa ki i ṣe eto daradara kan. Ẹni to ti ṣe Boko Haram ri, ti wọn mọ bi wọn ti n paayan lati gba ohun-ini rẹ, ti wọn n lọ si abule ati ilu lati gba owo to pọ gan-an lọwọ awọn eeyan, ti ẹ waa ni ẹ kọ ọ niṣẹ baaba, ẹ fun un ni ogun ẹgbẹrun. Lọjọ wo ni yoo fi na ogun ẹgbẹrun tan, ẹni meloo ni yoo fi kilipa gẹrun fun lai ni ṣọọbu. Ṣebi bii igba ti wọn tun da awọn ẹgbẹta ọmọ Boko Haramu si aarin ilu ni. Aburu ti awọn yii yoo si ṣe yoo ju ti awọn ti wọn wa ninu igbo wọn jẹẹjẹ tẹlẹ lọ. Ṣe bi wọn ti n ṣe awọn ọdaran ti wọn ba fẹẹ fi silẹ saarin awujọ lagbaaye ree. Ṣe iṣẹ baaba ni wọn n kọ wọn, ogun ẹgbẹrun ni wọn yoo si fun wọn lati maa fi ṣe aye wọn. Ko buru o. Amọ bi wọn ti fẹẹ tu wọn saarin ilu yii, adugbo wọn ni Borno naa ni ki wọn jẹ ki wọn duro o, ẹ ma ko aloku Boko Haram de ilẹ Yoruba, ohun ti yoo fa wahala gidi niyẹn, ki gbogbo ẹyin ọmọ Yoruba naa si maa ṣọra o, bi ẹ ba ti ri irin kọsẹkọsẹ kan laduugbo yin, tabi ti wọn ba ni ẹnikan ti ṣe Boko Haram, ko ṣe e mọ, o ti yiwa pada, ẹ tete yaa pariwo sita. Ki i tan lara wọn bẹẹ yẹn, wọn yoo kan tun da gbogbo ilu si adanwo ni. Ohun buruku digbo rere, a o fẹ aloku Boko Haram lọdọ tiwa o.

 

Nigba ti Akeredolu wọle yii

Iṣẹ oṣelu ati awọn ti wọn n ṣe e, eyi-jẹ, eyi-o-jẹ, bii ẹni ta tẹtẹ ni. Wọn yoo ti ro pe bi awọn ba ti gba ọna kan bayii, o daju pe ibi ti awọn yoo yọri si ree, ko si ni i si wahala kan. Awọn ti wọn sọ pe ki Agboọla Ajayi kuro ninu ẹgbẹ APC, ko pada lẹyin gomina rẹ, ko si maa bọ ninu PDP yoo ti ṣe gbogbo alaye fun un pe oun ni ẹgbẹ awọn fẹẹ fa kalẹ, oun ni wọn yoo mu lati du ipo gomina pẹlu ọga rẹ, awọn yoo si ri i pe awọn gbe e wọle. Ṣugbọn ọrọ oṣelu ko ri bẹẹ. Akọwe ijọba to kuro ninu ijọba ati ẹgbẹ oṣelu wọn naa, ko si ohun meji ti wọn tori ẹ kuro ju pe Agboọla ni yoo gba tikẹẹti PDP lọ, awọn yoo si lo anfaani naa lati di gomina laaye ara wọn. Ṣugbọn wọn ti dibo tan, ọna ko si gba ibi ti wọn foju si rara. Awọn kan ninu PDP n sọ pe ki Jẹgẹdẹ to wọle lati ta asia PDP fi Agboọla ṣe igbakeji rẹ, ṣugbọn o daju pe ọkunrin to n ṣe igbakeji gomina lọwọ bayii ko ni i lọ sinu ẹgbẹ oṣelu mi-in nitori ki wọn le fi oun ṣe igbakeji gomina ninu ẹgbẹ oṣelu mi-in, itiju ko ni i jẹ ko ṣe iru iyẹn. Bẹẹ ni ko si agbara kan to le sa ti yoo fi gbe PDP wọle, afi ti awọn araalu ba kuku ti sọ pe awọn pada lẹyin ẹgbẹ naa ni. Bi nnkan si ti ṣe ri yii, kinni naa yoo le ko too bọ sọwọ ẹgbẹ wọn. Yoo ṣoro fun Agboọla lati pada lọọ ba Akeredolu pe oun ti pada de, nitori ọrọ naa ti yiwọ, bii ẹni to leku meji to pofo ni. Rotimi Akeredolu ni yoo waa ṣe iṣe agba, ti yoo fa igbakeji rẹ mọra, ti yoo gbe iṣẹ daadaa fun un ṣe niwọnba igba tijọba wọn ku yii, ti yoo si tibẹ da a pada sinu ẹgbẹ wọn bi iyẹn ba ṣee ṣe. Dajudaju, Agboọla ko ṣiwere, awọn iwa kan ti Akeredolu funra ẹ hu ni yoo ti bi i ninu, ko too di pe o binu fi ẹgbẹ silẹ fun wọn. Ki Akeredolu pe e mọra bayii, ko tun apa ibẹ ṣe, ko le ni atilẹyin awọn to yẹ. Bi bẹẹ kọ, aja ti ko ti i ku le jẹkọ o, oro adagbẹyin a si maa buru ju oro akọkọda lọ.

 

Jẹgẹdẹ, ẹnu dun i rofọ o

Ko si ohun ti eeyan ko le fi ẹnu ṣe, afẹnu-wa-mọto ki i jaamu. O le ni ‘fuumu’ ti oun ba ṣe bayii, oun ti de Sokoto niyẹn. Bẹẹ ni ẹnu dun i rofọ, agada ọwọ ṣee bẹ gẹdu. Eyitayọ Jẹgẹdẹ ti gba tikẹẹti ẹgbẹ PDP bayii, oun ni yoo du ipo gomina lorukọ ẹgbẹ wọn. Ṣugbọn o, bo ti gba tikẹẹti naa tan lo bọ sita, ọrọ ti yoo si kọkọ sọ ni pe ki Arakunrin Rotimi Akeredolu maa ko ẹru ẹ kuro nile ijọba, nitori oun n bọ waa gba ijọba oun, oun yoo si tun ipinlẹ Ondo ti awọn Akeredolu n ba jẹ yii ṣe. Bẹẹ ni gbogbo awọn oloṣelu yii maa n wi, wọn yoo bẹrẹ si i fọnnu nigba ti wọn ba wa loju ọna, nigba ti wọn ba wọle tan ni wọn yoo di nnkan mi-in pata, bo o ba si beere lọwọ wọn pe ọrọ ti wọn sọ tẹlẹ nkọ, wọn yoo ni awọn ko mọ pe bẹẹ ni nnkan bajẹ to ni. Ohun to ṣe n ri bẹẹ fun wọn ni pe igba to yẹ ki wọn lo lati fi wadii ohun to wa nilẹ, ohun to n lọ, iye ti ijọba n pa wọle, eto ti wọn le ṣe ti yoo mu nnkan daa, ati bẹẹ bẹẹ lọ, oṣelu ni wọn yoo fi gbogbo akoko naa ṣe, nigba ti ijọba ba si bọ si wọn lọwọ, wọn ko ni i ni kinni kan nilẹ ti wọn yoo lo fun eto idagbasoke kankan, ẹjọ ati aroye nikan naa ni wọn yoo maa ṣe. Ki Jẹgẹdẹ ma jẹ ki toun ri bẹẹ, asiko to wa yii ki i ṣe asiko ti yoo maa dannu kiri, tabi ti yoo maa sọ ohun ti ko le ṣe tabi ti ko mọdi. Asiko ti yoo fi ṣe ironu ati iwadii ijinlẹ nipa idagbasoke ipinlẹ Ondo ree, to fi jẹ pe nigba ti ijọba ba de ọwọ rẹ, iyẹn bo ba jẹ ẹgbẹ oṣelu tirẹ lo wọle, iṣẹ ijọba naa ko ni i ṣoro fun un. Ohun to ba Naijiria jẹ ni pe awọn oloṣelu naa ki i ronu eto iṣakoso ilu, ori eto oṣelu nikan ni ironu wọn maa n lọ. Ki Jẹgẹdẹ ma ronu bayii, ko mu nnkan tuntun jade waa fawọn ara Ondo gbogbo ni.

 

Ẹ ma bu Adelabu nitori iyẹn o

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ti tun n ṣeto ẹyawo kan, ọgọrun-un biliọnu naira lo fẹẹ ya fun idagbasoke ipinlẹ rẹ. Gomina naa ṣalaye pe iṣe idagbasoke ilu loun fẹẹ fi i ṣe, awọn iṣẹ pataki kan loun si fẹẹ fi owo naa de mọlẹ, ko le jẹ anfaani fun gbogbo ara Ọyọ. Ko si ohun to dara to bẹẹ, koda, ko jẹ eeyan kan lo fẹẹ yawo, to ba ti jẹ ohun to le pa owo wọle ni yoo fi owo naa ṣe, ko buru raa. Ṣugbọn bi ijọba kan ba fẹẹ ya owo bayii, paapaa awọn ijọba Naijiria, awọn ti wọn ba mọ nipa eto ọrọ aje lẹtọọ lati sọ si i, koda, ki wọn ma jẹ oloṣelu, bi wọn si jẹ oloṣelu naa, ko ṣe nnkan kan. Akọkọ ni pe ipinlẹ wọn ni kinni naa wa, lara awọn ti wọn yoo si san gbese naa ni iru ẹni bẹẹ. Nitori bẹẹ, bi Makinde ba fẹẹ yawo, ti Bayọ Adelabu to ba a du ipo gomina lorukọ APC ba ni ko daa, oju oṣelu nikan kọ leeyan yoo fi wo ọrọ naa, gbogbo ọlọgbọn lo gbọdọ yẹ ọrọ naa wo finnifinni, ki wọn si wo eyi to ba jẹ ọrọ pataki ninu ohun tiru ẹni bẹẹ ba sọ. Ki i ṣe nitori pe Adelabu jẹ agba nidii imọ eto inawo kọ, ṣugbọn nitori pe ọkan lara awọn **alaa ipinlẹ Ọyọ ni. Meloo meloo lawọn gomina ti wọn ti yawo titi, to jẹ aburu ni wọn ko ba ipinlẹ wọn. Ipinlẹ Ọṣun lo wa nibẹ yẹn, gbese ti Arẹgbẹ jẹ silẹ de wọn, awọn ọmọọmọ wọn ko le san an tan, bẹẹ loun si ti ba tirẹ lọ. Ọpọ awọn gomina ti wọn jẹ gbese bayii ti wọn ni awọn fẹẹ fi tun ipinlẹ wọn ṣe, wọn gba owo naa, araalu ko ri nnkan kan nidii ẹ. Eyi ko sọ pe bi Makinde ba gba owo tirẹ, bi awọn to ku ti ṣe yii loun naa yoo ṣe, ṣugbọn ẹni to ba waa sọ pe ko ma yawo, tabi pe ko ṣọra gbese jijẹ, ẹni kan ki waa dide ko bu iru ẹni bẹẹ, alaye to mu ọpọlọ dani, ti tọhun yoo fi mọ pe ijọba to fẹẹ yawo mọ ohun to n ṣe leeyan yoo ṣe ni gbangba. Kẹnikan ma bu Adelabu nitori iyẹn o, alaye ni kẹ ẹ ṣe fun un, ati fun gbogbo ilu lapapọ.

 

O daa bẹẹ o jare, alaṣeju baba aṣetẹ

Orukọ awọn agbofinro ti wọn n pe ni SARS ko daa niluu rara. Lojoojumọ lorukọ wọn n bajẹ laarin awọn araalu, ọpọ igba ni wọn si ti sọ pe ki ijọba pa wọn rẹ, nitori iṣẹ ibi, iwa ọdaju, iwa ika, ka fi ẹtẹ silẹ, ka maa pa lapalapa ti awọn ọlọpaa SARS yii maa n ṣe. Ko si awọn ti wọn fi eleyii han ju awọn meji ti wọn ṣe fidio jade lọsẹ to kọja yii lọ. Tijani Ọlatunji ati Gboyega Oyeniyi, awọn ọlọpaa SARS ti wọn ṣe daadaa, ṣugbọn ti wọn fi aṣeju ati aṣetẹ ba iṣẹ ti wọn ṣe jẹ. Ọkunrin ajinigbe kan to tun maa n digunjale ni wọn n wa, wọn si ṣọ ọ titi ti wọn fi de Ibadan, nibẹ ni wọn ti mu un. Ṣugbọn wọn ba ọmọbinrin kan nile ẹ, Tọwọbọla. Lẹyin ti wọn ti mu ọdaran yii tan, wọn sọ ankọọbu si Tọwọbọla lọ, wọn si bẹrẹ si i fi i ṣe ẹsin, wọn ni aṣẹwo ati ọdọkọ to n sun kiri pẹlu oriṣiiriṣii ọkunrin ni. gbogbo alaye ti iyẹn ṣe pe ọrọ naa ko ri bẹẹ, oun ko ti i lọkọ, oun ṣẹṣẹ kuro nidii iṣẹ agunbanirọ ni, oun si n ta bata, ọkunrin naa si ri oun, o ni oun fẹẹ ra bata lọwọ oun, ati pe oṣiṣẹ ijọba loun, nibi ti awọn ti dọrẹ niyẹn. Fun obinrin ti ko lọkọ tabi ọkunrin ti ko ti i niyawo, ti wọn si ti balaga to ẹni to too lẹnikeji, ibi kan naa leeyan yoo ṣaa ti pade ara ẹni. Obinrin ti wọn mu ko jọ ole, ọmọde lasan to ṣi n wa ẹni ti yoo fẹ ni. Ṣugbọn awọn ọlọpaa yii ri iyẹn bii anfaani lati ba aye ẹ jẹ, ati lati fi i ṣe yẹyẹ loju araye gbogbo. Iyẹn ni wọn ṣe fidio ẹ, ti wọn fi i ṣẹsin, ti wọn waa sọ fidio naa sita fun araye ri. Aṣeju leleyii, iwa ika ti ko si dara ni. Bi ọmọ naa ba jẹ ole, ko sẹni ti yoo kaaanu rẹ, ṣugbọn lati fi i ṣẹsin nitori pe wọn ba a lọdọ ọkunrin, ti ko si lọkọ sile, ti ko si jẹ aṣewo, eleyii ti yatọ si iṣẹ ti wọn ran wọn. O daa bi ọga ọlọpaa ṣe ni ki wọn mu wọn ti mọle, o daa ki wọn fi iya diẹ jẹ wọn, ki wọn too tu wọn silẹ, ki wọn le mọ pe ile aye yii ko ri bẹẹ rara.

Leave a Reply