O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Asiko inira leleyii, ki i ṣe ọdun ominira

Ko si ẹni ti ko mọ pe inira wa lorile-ede yii bayii, ohun to si n baayan lẹru ni pe ojoojumọ ni inira naa n pọ si i. Ẹni ti ko ba gbadun ri, ti ko jẹ anfaani ina ojoojumọ, omi ẹrọ, titi to dara gan-an, ni Naijiria yii naa ni, ki i ṣe ni orilẹ-ede mi-in o, tọhun ko ni i mọ pe inira gidi wa nilẹ yii, yoo ro pe ninu ominira la wa nitootọ. Ṣugbọn inira gidi wa, o wa fun wa nibi gbogbo ni ilẹ wa. Awọn ijọba to ti lọ sẹyin ṣe oriṣiiriṣii aidaa lati mu inira yii wa, ohun ti gbogbo eeyan si ro ni pe pẹlu ijọba tuntun ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣeleri pe oun n mu bọ, gbogbo ohun to daru ni wọn yoo tun ṣe, nitori ẹ ni wọn si ṣe dibo fun un. Ki Buhari too wọle, funra ẹ lo fẹnu ara rẹ sọ pe oun mọ gbogbo iya to n jẹ Naijiria. O ni oun mọ ohun to fa a ti eto aabo Naijiria ko fi dara, tawọn afẹmiṣofo fi n dun mahurumahuru mọ gbogbo ọmọ Naijiria, o ni ijọba to wa nibẹ nigba naa ni ko ṣeto igbaradi ati itọju to yẹ fun awọn jagunjagun wa, ati pe ti oun ba de, gbogbo rẹ ni yoo yanju. Buhari ti de, nnkan kan ko yanju, kaka ki ewe agbọn dẹ ni, koko lo n le. Awọn ti wọn n ba a ṣejọba ti purọ titi, amọ lọjọ ti wọn ba sọ pe awọn rẹyin Boko Haram, ọjọ keji lawọn tọhun yoo tun paayan lọ rẹpẹtẹ, ti wọn yoo si leri pe ko sẹni to le kapa awọn. Tabi ti eto pe ko si olori tabi ọga nidii iṣẹ ijọba to gbọdọ lọ si orilẹ-ede mi-in lọọ gbatọju la oo sọ ni! Buhari funra rẹ lo sọ pe iwa ti ko daa ni, ati pe bi oun ba de, ko sẹni ti yoo dan iru rẹ wo ninu ijọba oun. Ṣugbọn titi di bi a ti n wi yii, Ọga Buhari funra rẹ ko ni ibi to ti n gba itọju ju ilu oyinbo lọ. Bi ẹnikẹni ba si sọ pe iwa naa ko dara to, to si gbiyanju lati ran awọn eeyan leti ohun ti Buhari funra ẹ sọ nipa gbigbe alaisan lọ siluu oyinbo fun itọju, awọn eeyan ti wọn n ṣejọba yoo bẹrẹ si i bu u, tabi ki wọn tilẹ maa fi awọn agbofinro halẹ mọ ọn. Buhari lo sọ fun wa ko too gbajọba pe ẹronpileeni to wa nile Aarẹ Naijiria ti pọ ju, ko si ohun to yẹ ki aarẹ kan maa fi iru awọn eronpileeni to pọ to bẹẹ ṣe nile ijọba. Ṣugbọn ni bayii, ẹronpileeni to wa nile Aarẹ pọ ju ti ki Buhari too de lọ, ti awọn ọmọ rẹ ati awọn ọrẹ ọmọ rẹ si n lo  ẹronpileeni ijọba yii lati fi ṣe ohun ti ki ṣe iṣẹ ijọba Naijiria rara. Eto ọrọ aje bajẹ, eto idagbasoke wa si duro si oju kan, ko si sẹni to le sọrọ, afi ẹni ti wọn yoo pe ni ọta ijọba. Ni asiko ti ara n ni gbogbo agbaye, ijọba tiwa gbe owo lori owo-epo, wọn gbe owo lori owo ina, wọn si da mẹkunnu si iya ti ko ṣee ka tan, wọn si ni ẹnikẹni ko gbọdọ wi kinni kan. Iwa ibajẹ ti Buhari sọ pe oun yoo gbogun ti ko dinku, kaka bẹẹ, o n le si i ni. Ojoojumọ la n gbọ iro owo nla nla ti wọn n gbe jade nile ijọba, ibi ti awọn owo naa n wọlẹ si ko si ye ẹnikan. Ṣugbọn tẹ ẹ ba ti wi kinni kan, wọn yoo ni awọn alatako ijọba ni, awọn oloṣelu ni, awọn ti ko ṣe ẹsin Buhari ni, ati awọn ọrọ ẹtan bẹẹ bẹẹ. Awọn ti wọn yi Buhari ka n tan an, wọn si ro pe ọmọ Naijiria lawọn n tan, wọn n purọ fun un, wọn ro pe awọn ọmọ Naijiria lawọn n purọ fun. Wọn ba ohun gbogbo jẹ, wọn si da gbogbo nnkan ru lasiko ijọba yii, ohun kan ti a si ranti bayii ni inira. O ba ni o, ọrọ yii ko ti i bajẹ, Buhari ṣi ni ọdun mẹta din diẹ lati fi ṣe atunṣe, ati lati fi orukọ rẹ sinu iwe awọn eeyan rere ni Naijiria titi aye. Ki Buhari yiwa pada, ki awọn ti wọn ba a ṣejọba yii naa yiwa pada, ki wọn tun eto ọrọ aje wa ṣe, ki wọn yọwọ iwa ẹlẹyamẹya ninu ijọba wọn, ki wọn si mu iyapa to wa laarin awọn ọmọ Naijiria kuro pata. Asiko ọdun ominira yii lo yẹ ki wọn lo lati fi ṣe eyi, ka le bọ ninu inira to n yọ wa lẹnu.

 

Ibo ti wọn di ni Edo nijsi, bo ti y ki nnkan ri niyn

Bi nnkan kan ba wa ti eeyan gbọdọ bẹ Ọlọrun fun ni Naijiria wa yii, iru ibo ti wọn di ni ipinlẹ Edo lọsẹ to kọja lọhun-un ni. Ki i ṣe nitori pe Gomina Godwin Ọbaseki lo wọle ni o, ṣugbọn nitori bi eto idibo naa ti lọ ni. O fẹrẹ jẹ pe ibo akọkọ ti a oo di ti ijọba apapọ ko ni i lo agbara wọn le lori niyi, ti wọn yoo jẹ ki ẹni ti awọn araalu dibo fun gan-an wọle, ti wọn yoo si lo agbara wọn lati ri i pe ko si oloṣelu to ri tọọgi lo, tabi to lo awọn ọlọpaa tabi ṣọja lati halẹ mọ awọn to ku, tabi dẹru ba awọn araalu, ti ibo naa ko fi ni i ṣee ṣe. Ibo ti wọn di ni Ekiti lọjọsi, kaluku lo mọ bi ọrọ ibo naa ti ri, eyi ti wọn si di gbẹyin ni Ọṣun, o lohun tawọn araalu sọ, bo tilẹ jẹ pe awọn oloṣelu yoo maa purọ funra wọn, wọn yoo maa tan araalu, wọn yoo ni bo ti yẹ ki kinni naa lọ lo lọ. Ohun yoowu to ba jẹ ki ijọba Buhari sọ pe bi ibo Edo yoo ṣe lọ niyẹn, ohun daadaa ni o, nitori o jẹ ki ifẹ awọn araalu han, ko si si ẹni to yi esi ibo, tabi to ji apoti ibo gbe, nitori oloṣelu kan. Bi ijọba ba ṣe eleyii nidii eto idibo gbogbo, kia lawọn oloṣelu wa yoo kọ ọgbọn tuntun, wọn yoo mọ pe agbara gbogbo, ọwọ awọn araalu lo wa, ẹni ti wọn ba si fẹ ni wọn yoo yan sipo olori wọn. Oloṣelu to ba mọ pe oun n pada bọ waa ba awọn eeyan fun ipo giga tabi fun saa keji, yoo ṣe daadaa nigba to ba n ṣejọba, tabi to ba n ṣe aṣoju wọn. Iyẹn ni ibo naa ṣe daa gan-an loju wa, ti a si bẹ ijọba ati awọn olori eto idibo lati fi ibo ti wọn di ni Edo yii ṣe awokọṣe, ki wọn maa lo o fun gbogbo ibo to ba ku, o si daju pe igbesẹ ti yoo mu Naijiria daa gidigidi ni.

 

Ọrọ naa ki i ṣe bi Buhari ti wi ṣaa o

Nigba ti Gomina Godwin Obaseki wọle tan ni Edo, ẹni akọkọ to lọọ ki naa ni Aarẹ Muhammadu Buhari. Ohun to daa ni. Akọkọ ni pe o fi han bi olori orilẹ-ede kan ṣe gbọdọ jẹ, pe gbogbo eeyan ilu rẹ lo gbọdọ ko mọra, lai fi ti ẹsin, tabi ẹya, tabi ẹgbẹ oṣelu kan ṣe. Bi gomina ba jẹ APC, tabi PDP, iyẹn ko le sọ pe ko gbọdọ ri Buhari, nitori pe ọkunrin naa ki i ṣe ti ẹgbẹ oṣelu wọn, ipo to jẹ ti gbogbo ọmọ Naijiria ni. Pe Buhari gba Ọbaseki laaye ko waa ri oun yii, nnkan daadaa ni, apẹẹrẹ to si yẹ ki ẹni yoowu to ba pe ara rẹ ni olori ilẹ yii ni, nitori ọmọ APC ni Buhari, ọmọ ẹgbẹ PDP si ni gomina Edo. Ohun to yẹ ko maa ṣẹlẹ nilẹ wa niyi. Ṣugbọn kinni kan wa ti Buhari sọ nigba to ri Gomina Obasẹki, boya nitori inu rẹ to dun ni o, abi nitori nnkan mi-in. Buhari ni ko si ohun to buru bi oloṣelu ba nawo rẹpẹtẹ fawọn araalu lasiko ti wọn ba fẹẹ dibo, nitori owo ti awọn oloṣelu ba na yii yoo ṣe awọn eeyan naa lanfaani lasiko ọhun, yoo si ran wọn lọwọ lati ri jijẹ-mimu. Haa, Buhari! Bawo ni olori ijọba wa yoo ṣe sọ bẹẹ. Owo ti oloṣelu fẹẹ na faraalu yii, nibo ni yoo ti ri i. Bo ba jẹ o ya a ni, bo ba si jẹ o ji i ni, ṣe ko ṣaa ti na an fawọn araalu naa ni! Tabi Aarẹ wa ko mọ pe bi oloṣelu ba na owo bayii nitori pe o fẹẹ ṣeto idibo, yoo gba owo naa pada nile ijọba bo ba debẹ ṣaa ni. Ṣebi oniṣowo ni! Ati pe njẹ o waa dara ki araalu maa beere owo lọwọ oloṣelu ki wọn too dibo fun un. Ki lo de ti ijọba ko wa ọna lati ṣeto igbe-aye rere ti ko ni i jẹ ki araalu gbowo lọwọ oloṣelu kankan, ki ijọba si tun ṣalaye fawọn eeyan yii pe owo ti wọn n gba lọwọ oloṣelu ko daa, nitori bii ẹni to n ta ọjọ iwaju ara wọn ati tawọn ọmọ wọn nitori owo taṣẹrẹ ni. Ko yẹ ko jẹ olori ilẹ wa ni yoo maa dunnu pe awọn oloṣelu n fi owo abẹtẹlẹ fawọn araalu, ti yoo si tun sọ pe inu oun n dun si i. Idunnu wo lo wa ninu iwa ka fi owo abu ṣe abu lalejo, ki oloṣelu maa ji owo araalu ko, ko si maa fi ra ibo lọdọ wọn. Ọrọ ti Aarẹ sọ ku diẹ kaato, ko tete mọ bi yoo ti yi ọrọ yi pada, ti yoo si sọ fawọn oloṣelu pe ki wọn yee hawo faraalu nitori ibo, ẹni to ba ṣe bẹẹ yoo ri pipọn oju ijọba. Ko si araalu to fẹ owo oloṣelu, nitori owo ole, owo araalu ti wọn ji ko, ni ọpọlọpọ wọn n ko kiri.

 

 

Ṣe wọn o ni i pa gomina yii bayii

Ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keje, ọdun yii, ni bii oṣu meji ṣẹyin, ti Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum, n lọ si Baga, nitosi Maiduguri, o ku dẹdẹ ki wọn yọ si ilu naa ni awọn ọmọ ogun Boko Haram jade lojiji, ni wọn ba da ina ibọn bolẹ, wọn si yinbọn naa titi ti Gomina yii fi fẹsẹ fẹ ẹ. Oun nikan kọ lo fẹse fẹ ẹ, gbogbo awọn ti wọn tẹle e ni, nitori niṣe ni awọn mọto n sare yi pada, ti awọn agbofinro si rọ gomina naa wọ mọto, ti onikaluku sa asala fun ẹmi rẹ lọwọ kan. Inu bi gomina yii, ẹru si ba a, ibinu naa lo si ba lọ si ọgba awọn ṣọja to wa nitosi ibi ti wọn ti kọlu wọn, to da ọrọ buruku silẹ fun wọn. O ni kin ni wọn n ba kiri ti wọn ni awọn n ṣọ ilu ati agbegbe naa, nigba to jẹ nibi ti wọn ti kọ lu awọn yii ko jinna si ibi ti awọn ṣọja naa kọ ibudo wọn si, ti ọmọ ogun si kunbẹ rẹkẹrẹkẹ. Ṣugbọn kia ni ọga ṣọja to wa nibẹ jade, to ni ko si Boko Haram ni gbogbo agbegbe naa mọ, awọn janduku keekeeke to ku nibẹ nikan lo n daaamu awọn araadugbo, ko si Boko Haram nibi kankan ni adugbo naa mọ. Ṣugbọn o ti han bayii pe ọrọ ti ọga awọn ṣọja naa sọ ki i ṣe ootọ o. Lọjọ Jimọ to lọ yii, Gomina Zalum yii kan naa tun ni awọn n lọ si Baga yii kan naa ki oun tun lọọ wo awọn ti awọn Boko Haram yii kan naa le nile wọn, ṣugbọn eyi to ṣẹlẹ lọjọ naa buru ju takọkọ lọ. Eeyan mẹẹẹdogun ni iroyin kọkọ sọ pe o ku, nigba ti yoo si fi di ọjọ keji, oku ti di ọgbọn geerege, bẹẹ lawọn mi-in si farapa gidi, ti wọn ṣi n gba itọju. Ninu awọn ọgbọn to ku yii, ọlọpaa wa ninu wọn, ṣọja wa ninu wọn, bẹẹ lawọn agbofinro mi-in to wa ninu ijọba rẹ. Nibi tọgbọn eeyan ba ti ku, to jẹ iku ibọn ni wọn ku, eeyan ti mọ pe awọn ti wọn gbe ogun naa jade ki i ṣe kekere. Ṣebi awọn ṣọja ati awọn ọlọpaa yẹn naa ni ibọn tiwọn, ṣugbọn apa ibọn wọn ko ka awọn Boko Haram, awọn yẹn ni nnkan ijagun ju awọn ṣọja ati ọlọpaa tiwa lọ. Akọkọ ohun to han ninu iṣẹlẹ yii ni pe Boko Haram ti gba ilu yii mọ awọn ologun tiwa lọwọ. Abi nigba ti odidi gomina ko ba le de apa kan ninu awọn ilu to wa labẹ rẹ, to jẹ iku ni iru irin-ajo bẹẹ yoo ja si fun ọpọlọpọ eeyan.  Ẹẹkeji ti eleyii fi han ni pe awọn ologun wa ko sọ ootọ fun wa. Bi wọn ba sọ ootọ fun wa ni, ifẹmiṣofo yii ko ni i to eleyii rara. Bẹẹ ọrọ to wa nilẹ yii ki i ṣe ohun ti ẹnikan n purọ fun ẹni kan mọ. Bo ba ṣe n lọ ni ki araalu mọ, wọn yoo si mọ ibi ti awọn naa ti le ran ijọba lọwọ. Ṣugbọn bi nnkan buruku ba n ṣẹlẹ ni ipinlẹ Borno, ti awọn olori ṣọja ati awọn ijọba ba n sọ pe ko si kinni kan to n ṣẹlẹ nibẹ, ohun ti yoo maa ṣẹlẹ naa la n ri yii o. Gomina  Zululm ko ni ẹbi kankan bayii ju pe o ni ifẹ awọn eeyan rẹ lọ, bi ko ba si ṣe pe awọn ṣọja gbe ẹronpileeni kekere fun un pe ko maa gun un lọ si apa ibẹ lẹyin igba ti wọn fẹẹ pa a lọjọsi, ko si bi wọn ko ṣe ni i pa a danu lọjọ ti wọn kọlu wọn yii. Oun gan-an ni wọn tiẹ fẹẹ pa, afaimọ ni wọn ko si ni i wa ọna mi-in lati fi pa a, bi ko ba yee lọ si agbegbe ti awọn Boko Haram ti n ṣejọba wọn ni Naijiria yii. Titi di bi a ṣe n wi yii, ko si ẹbi ọrọ awọn Boko Haram yii lọrun ẹni meji ju ijọba apapọ ilẹ wa lọ. Ṣe ti irọ ti wọn n pa fun eeyan nitori ọrọ oṣelu ni eeyan yoo sọ ni tabi ti ojuṣaaju ti wọn n fi ọrọ yii ṣe. Gbogbo eeyan lo pariwo pe ki wọn yọ awọn olori ologun Naijiria gbogbo kuro ki wọn fi awọn mi-in si i, boya awọn yii yoo ni ẹjẹ tuntun ati eto tuntun lati fi koju awọn afẹmiṣofo yii, Buhari ko dahun lati ọjọ yii wa, ohun to si de to fi n lo awọn olori ologun ti wọn ko kapa ogun to doju kọ Naijiria yii ni ko yeeyan. Gbogbo awọn nnkan wọnyi ni ki ijọba Buhari ṣe kia, ko paarọ awọn olori ologun yii, ko ko awọn mi-in si i, ki wọn ṣeto ijagun tuntun, ki wọn ṣe koriya fawọn ologun, ka tiẹ bọ ninu walaha awọn Boko Haram nilẹ yii, nitori bi wọn ṣe n pa awọn ọmọ  Naijiria yii ko daa o, ko daa rara ni!

Leave a Reply