O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Ki lawọn ṣọja Naijiria n ṣe bayii si

Nigba ti gbogbo agbaye gbe fidio awọn ṣọja Naijiria ti wọn n yinbọn pa awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde lori ọrọ SARS jade, kia lawọn olori ologun ilẹ wa ti jade, ti wọn ni awọn kọ lawọn ṣe iṣẹ naa, pe ki i ṣe ṣọja tawọn ni wọn jade o, awọn ko si mọ kinni kan nipa ẹ. Ṣugbọn ko tọjọ, ko to ọsẹ, awọn ṣọja wa yii kan naa jade, wọn ni awọn lawọn lọ sibẹ, ṣugbọn awọn ko yinbọn pa ẹnikan kan. Bawo ni ṣọja yoo ṣe lọ si oju ogun ti ko ni i paayan, nitori ibi tawọn lọ yii, oju ogun ni wọn ka a si. Aṣiri tiẹ tu laipẹ rara, nitori wọn ba awọn ọta ibọn ni ilẹẹlẹ ibi ti wọn ti yinbọn fun awọn ọmọ naa. Njẹ ki wọn lọọ wo mọṣuari awọn ṣọja, nigba ti wọn ti wa oku awọn to ku titi ti wọn ko ri wọn, awọn ṣọja yari, wọn ni awọn ti n tun mọṣuari awọn ṣọja naa ṣe lati bii ọdun kan sẹyin. Bawo ni eeyan yoo ṣe fi ọdun kan tun mọṣuari ṣe? Awọn ti wọn n ku lati ọdun kan sẹyin, nibo lawọn ṣọja wọnyi n gbe wọn si. Ati pe nigba ti oju awọn ti wọn lọ sibẹ lati ṣe iwadii ko fọ, ṣebi ti wọn ba wọle, wọn yoo ri ibi ti awọn ṣọja yii ti n tun mọṣuari to wa lọdọ wọn ṣe. Itumọ eyi ni pe gbogbo ohun ti wọn n wi yii, awawi lasan, irọ buruku ni. Ẹni ti yoo ba purọ ni yoo ni ẹlẹrii oun wa lọrun, ati pe bi eeyan yoo ba parọ, ko ni i pa irọ ti ko ni i bo o lẹyin ẹsẹ, gbogbo irọ ti awọn ologun ilẹ wa n pa yii lo han saye, koda, awọn omugọ paapaa mọ pe irọ ni wọn n pa. Ka tilẹ ni ohun ti wọn ṣe nipa yinyinbọn pa awọn alaiṣẹ buru, eyi ti wọn n ṣe yii, iyẹn irọ ti wọn n pa yii, buru ni ilọpo meji ju ti akọkọ lọ. Wọn n ba orukọ Naijiria jẹ kaakiri agbaye ni, wọn n sọ  pe ṣọja yẹpẹrẹ lawọn niwaju aye gbogbo, ati pe Naijiria ko ni ṣoja, awọn obinrin, awọn ojo, awọn ti oṣelu ti ba aye wọn jẹ nikan ni wọn ko jọ. Ni orilẹ-ede ti awọn ṣọja ba ti n ba wọn da si ọrọ oṣẹlu, ohun ti ẹ oo maa ri naa la n ri yii, bẹẹ ni iru awọn orilẹ-ede bẹẹ ko ni i ga laye. Awọn ti wọn n ba Naijiria yii jẹ pọ ju bi a ṣe n ro o lọ, ọkan ninu wọn si ni awọn ṣọja ilẹ yii, ko jọ pe wọn wa fun iṣọkan ati iduro ṣinṣin Naijiria, bẹẹ ni wọn ko si fun aabo ọmọ Naijiria, nitori to ba jẹ aabo awọn ọmọ Naijiria ni wọn wa fun, wọn ko jẹ doju ibọn kọ awọn ọmọ Naijiria yii kan naa ti wọn n ṣe iwọde wọọrọ lai mu ibọn tabi ohun ija kankan lọwọ. Ọrọ Naijiria ti di egbinrin ọtẹ, to jẹ bi a ti n pa ọkan ni omi-in tun n ru, nibo la fẹẹ gbe iru eleyii gba Ọlọrun. Gba wa lọwọ awọn aninilara wọnyi, ki o gbe olori ti yoo ṣe ododo dide laarin wa.

 

Sanwo-Olu, puro ki n niyi, ẹtẹ ni i kangun ẹ  

Nigba ti eeyan ba kọkọ purọ, iyi gidi ni yoo gba nibẹ, awọn eeyan ti ko ba mọdi ọrọ yoo si maa kan saara si i. Ṣugbọn tọhun ko ni i ti i rin jinna ti irọ naa yoo fi ja, bi irọ naa ba si ja, itiju ti yoo tibẹ yọ, yoo ju iyi ti tọhun ti kọkọ gba ni akọkọ lọ. Eyi ni Yoruba ṣe n sọ pe ‘purọ ki n niyi, ẹtẹ ni i kangun ẹ’. Irọ ti Babajide Sanwoolu ti i ṣe gomina Eko pa lọjọsi to niyi kaakiri agbaye, irọ naa ti pada ja, bo si ti niyi kaakiri aye to, bẹẹ naa lo tẹ to, ẹtẹ naa si ju iyi rẹ lọ, nitori ẹtẹ yii yoo wa titi aye ni. Nigba ti ina ọrọ n jo pe wọn yinbọn pa awọn ọmọọlọmọ ni Lẹkki, Sanwoolu sare jade, o ni oun ko mọ awọn ti wọn yinbọn yii o, oun ko mọ ẹni to ran wọn, awọn alagbara kan to ju toun lọ ni. Ṣugbọn lọjọ ti awọn ṣọja jẹwọ pe awọn lawọn lọọ yinbọn nibẹ yii, wọn ni awọn o deede lọ, pe Sanwoolu lo ranṣẹ pe awọn pe ki awọn waa ba oun le awọn to n ṣewọde naa lọ. Eyi ni pe Sanwoolu lo dẹ awọn ṣọja si awọn ara Eko, oun lo dẹ awọn ṣọja si awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde wọn jẹẹjẹ, gbogbo aburu to si ba awọn eeyan naa, oun lo ko o ba wọn. Awọn eeyan ti wọn n ṣejọba wa ki i mọ pe ohun to maa n mu araalu fẹran ijọba, to si maa n jẹ ki araalu ṣe daadaa pẹlu ijọba wọn, ni ododo. Ijọba to ba n ṣe ootọ pẹlu araalu, ijoba naa yoo ri idunnu awọn eeyan, gbogbo ọna ni iru awọn eeyan bẹẹ yoo si maa gba lati ran ijọba wọn lọwọ, ti wọn yoo maa wa ọna gbogbo lati daabo bo ijọba naa lọwọ ewu, ti wọn ko si ni i jẹ ki nnkan ijọba yii bajẹ nibikibi. Ṣugbọn ijọba opurọ ki i niyi loju araalu, araalu ki i fẹran wọn, bẹẹ ni wọn ki i kọ bi nnkan ijọba bẹẹ bajẹ, nitori wọn yoo ti mọ pe awọn nnkan ti ijọba opurọ yii ni ki i ṣe ti awọn. Lara ohun to si n fa wahala nibi gbogbo nilẹ wa ree, nitori opurọ lawọn ijọba wa. Ṣugbọn ọpọ awọn ara Eko yii ni wọn n fi oju rere wo Sanwoolu, ti wọn si ro pe ko jẹ ṣe ohun ti ko dara kan sawọn, afi nigba ti eleyii ṣẹlẹ, to ki irin gbigbona bọ wọn ninu oju. Eleyii ko dara o, ko daa rara. Sanwoolu ati awọn eeyan ẹ ti leri pe awọn n bọ waa ṣalaye bi ọrọ ti jẹ, ṣugbọn lati ọjọ naa, ko sẹni to jade lati ṣalaye ọrọ yii, ohun ti ko si jẹ ki eyi ṣee ṣe ni pe ko si alaye kan ti wọn fẹẹ ṣe, nigba to jẹ irọ ni wọn pa fawọn eeyan ilu tẹlẹ. Afi ki Sanwoolu jade, ko si tuuba. Ko bẹ ara Eko gidigidi, ko si ṣeleri pe iru ohun to ṣẹlẹ naa ko ni i waye mọ. Bo ba ṣe eleyii, o ṣee ṣe ki awọn eeyan fori ji i, ki wọn si tun fẹran ijọba rẹ pada, ki ohun gbogbo si lọ deede fun un. Ṣugbọn to ba jokoo sibi kan to ro pe ko si ohun ti ẹnikan yoo fi oun ṣe, eyi ti oun ṣe yii ti di aṣegbe, ọrọ naa yo lẹyin, ipadabọ ọrọ naa ko si ni i dara. Ki Sanwoolu ṣe eyi to dara, ko ma di pe oju rẹ yoo ri eyi ti ko dara.

 

Ko yẹ ko jẹ Faṣọla

Ohun ti ọpọlọpọ awọn ololufẹ rẹ n wi niyi, pe ko yẹ ko jẹ Faṣọla. Ko yẹ ko jẹ Babatunde Raji Faṣọla, gomina Eko ti gbogbo eeyan fẹran, ni yoo maa pẹlu ọbọ jẹko, ti yoo gbiyanju lati fi juuju bo gbogbo araalu loju, ti yoo fẹẹ pe gbogbo ilu lomugọ, nitori ati bo aṣiri ijọba Buhari ti wọn n ba ṣiṣẹ. Lẹyin ti iṣẹlẹ Lẹkki yii ṣẹlẹ, ijọba ipinlẹ Eko ko duro ki awọn akoṣẹmọṣẹ to le wadii ohun to ṣẹlẹ nibẹ gan-an de ti wọn fi ko awọn oṣiṣẹ kolẹ-ko-dọti jade, ti awọn si gba gbogbo ibẹ to mọ fefe, ti ko si apẹẹrẹ pe ohunkohun ṣẹlẹ nibẹ. Ṣugbọn lẹyin ọjọ meloo, lẹyin to ti han pe ko si ohunkohun nibẹ mọ, ti awọn ọlọpaa paapaa ti lọ, atawọn ọtẹlẹmuyẹ mi-in, ti kaluku ni awọn ko ri kinni kan, Faṣọla ati awọn eeyan rẹ lọ sibi ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹ, nibẹ ni Faṣọla ti ni oun ri kamẹra ti wọn fi n ya fọto kan ati pe kamẹra naa le ni ohun ti wọn n wa ninu, iyẹn ni pe kamẹra aramanda yii le sọ ohun to ṣẹlẹ ni Lẹkki gan-an. Kamẹra atijọ ti ko sẹni to n lo iru ẹ mọ ni kamẹra naa, gbangba, nibi ti gbogbo eeyan ti ba kọja, ti wọn si ti gba mọ fefe ni Faṣọla loun ti ri i. Eyi ni ọrọ naa ṣe jinna si ootọ loju awọn eeyan, ti gbogbo wọn si n bu Fasọla pe o waa tan wọn jẹ ni, o waa purọ fun wọn lorukọ ijọba Buhari ni. Ṣugbọn ko yẹ ko jẹ Faṣọla loootọ, nitori Faṣọla mọ bi nnkan ṣe ri fun awọn eeyan orilẹ-ede yii ati bi ara ti n kan wọn to nipa irẹjẹ ati iwa ika to kun ọwọ awọn ọlọpaa ati ijọba. Ki waa ni Faṣọla n gbeja ijọba ika bii iru eyi si, koda, bo ba n ba ijọba yii ṣiṣẹ, o yẹ ko mọ ohun ti yoo ṣe lọdọ awọn eeyan Eko, bi ọrọ ba ri bo ti ri yii. Ṣugbọn ohun gbogbo ti dorikodo nilẹ yii, ko si ẹni kan ti araalu le gboju le mọ, gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba, gbogbo awọn alagbara nidii iṣẹ ilu, minisita, gomina, gbogbo wọn lo n purọ fun wọn. Ṣugbọn ko yẹ ko jẹ Faṣọla, ohun to n ka gbogbo ara Eko lara niyẹn. Afi ki Faṣọla tun ọmọluabi ẹ ṣe.

 

Inu awọn eeyan bii Lai Muhammed yoo dun bayii

Loju awọ eeyan bii Lai Muhammed, ohun to ṣẹlẹ yii yoo dun mọ wọn ninu. Bi awọn ṣọja ti jade, ti wọn yinbọn pa wọn ni Lẹkki, bi awọn ọlọpaa ṣe bẹrẹ si i ṣa awọn ti ọrọ ko kan kiri, awọn ti wọn ko mọwọ, ti wọn ko mẹsẹ, bi wọn ṣe n tu awọn ọmọ Mọla silẹ; ti wọn n ko awọn ọmọ Yoruba ati Ibo sitimọle. Dajudaju, iru eyi yoo dun mọ awọn eyan bii Lai Muhammed. Ṣugbọn nijọ wo ni a oo ṣe iru eleyii da, ni ọjọ wo si ni awọn minisita yii fẹẹ duro ni ileejọba mọ. O pẹ o ya, wọn yoo pada kuro nibẹ, awọn iwa ika ti wọn si n hu yii ko ni i tan, wọn yoo pada waa hu iwa naa si awọn naa, ati si awọn ọmọ wọn. Ko si ohun to dara bii ki olori tabi ẹni yoowu to ba wa ni ipo aṣẹ ṣe ododo lọ. Ṣugbọn awọn eeyan yii ko ni ododo. Minisita Lai Muhammed lo ti n pariwo pe ijọba gbọdọ fi ọwọ lile mu awọn ọdọ ti wọn n ṣẹwọde yii, ijọba si ti fi ọwọ lile mu wọn bayii, ọrọ naa si gbọdọ dun mọ minisita eto iroyin orileede yii ninu. Minisita yii n mura lọwọ bi ijọba yoo ṣe gbegi le e fun ọmọ Naijiria ti wọn ko fi ni i le lọ si ori Facebook, ti wọn ko ni i le lo Wasaapu (WhatsApp) mọ, ti wọn ko ni i le sọrọ lati ori ẹrọ ayelujara mọ, gẹgẹ bi wọn ti n ṣe bayii. Njẹ ki lo de, minisita yii ni isọkusọ ati irọ ti awọn ọdọ Naijiria n gbe sori awọn ẹrọ ayelujara yii ti pọ ju. Sugbọn Alaaji Lai Muhammed ko sọ fun wọn pe awọn gan-an lawọn da kinni yii silẹ, awọn lawọn gbe irọ ati eke bayii kalẹ, awọn lawọn gba ọdọ lati maa ṣe iru iṣẹ buruku yii, laye ijọba Jonathan, ki awọn le lo irọ ati ẹtan bayii fi gbajọba lọwọ wọn. Ati pe nigba ti wọn lo awọn ọdọ naa tan ni wọn sọ wọn silẹ, ti wọn ko si jẹ ki wọn ri awọn mọ nigba ti wọn ti gbajọba, ti awọn ọdọ naa si waa dọgbọn lati lọ sori ẹrọ ayelujara, lati lọọ maa ṣe ohun ti awọn minisita yii kọ wọn. Ki waa ni Lai Muhammed n tori ẹ binu si. Ṣebi ohun ti wọn fi kọ awọn ọmọ naa ni wọn n ṣe. Iwa ika ti wọn hu tẹlẹ naa lo n da le wọn lori. Ṣugbọn eyi ti yoo ba wọn lẹyin ti wọn ba gbejọba ti wọn n ṣe yii silẹ yoo buru pupọ, ko si ṣẹni to le sọ bi igbẹyin oun naa yoo ṣe ri ninu wọn. Alagba Lai Muhammed, ṣe rere. Alaaji Lai Muhammed, ṣe rere o. Bi bẹẹ kọ, gudugbẹ kan n bọ ti yoo ja, ori awọn aṣẹbajẹ ni yoo ja le o. Ẹyin ọrẹ Lai Muhammed, ẹ tete kilọ fun un.

 

Nibo lawọn ṣọja tiwa wa

Awọn Boko Haram atawọn Fulani ajinigbe ji ọmọ orilẹ-ede Amẹrika kan gbe ni ọjọ Mọnde to kọja yii, ni orilẹ-ede Nijee (Niger), ni wọn ti gbe e, nibi aala wọn pẹlu Naijiria. Kia ni wọn si gbe e wọ Naijiria, wọn gbe e sinu igbo ilẹ Hausa wa nibi. Awọn Amẹrika gbọ pe wọn ji ọmọ orile-ede wọn gbe, wọn si ya wọ Naijiria lai sọ fẹnikan. Ki oloju too ṣẹ ẹ, kia ni wọn ti gba ọmọ orile-ede wọn yii lọwọ awọn ajinigbe naa, ti wọn si pa mẹfa danu ninu awọn meje ti wọn ji i. Ẹni ti wọn ji yii ko fara pa pẹẹ! Awọn ti wọn n pe ni ṣọja niyẹn! Ẹni kan ṣoṣo ni wọn ji gbe ni wọn tori ẹ waa paayan mẹfa, ti wọn si tori ẹ ko ogun jade. Nibo lawọn ṣọja ti Naijiria wa. Awọn ti wọn ji gbe lori-ilẹ wọn, awọn ọmọleewe, awọn araalu, ati awọn mi-in bẹẹ, ewo ni awọn ṣọja Buratai yii ri gba jade ninu wọn. Bo ba jẹ ni Naijiria wa nibi ni, Buratai yoo ko awọn oniroyin jọ, wọn yoo ni awọn yoo gba ẹni ti wọn ji gbe naa jade laarin ọsẹ kan, nigba ti ọṣẹ kan ba kọja, wọn yoo ni awọn wa lẹnu ẹ, to ba pẹ, wọn yoo ni awọn to gbe e ti gbe e sa lọ pata. Bẹẹ ni wọn yoo gba owo gọbọi lati fi ṣe iṣẹ naa. Iyatọ ninu awọn ṣọja ti wọn fẹran orilẹ-ede wọn ati tawọn ṣọja ti wọn fẹran owo ati agbara lasan lẹ ri yii o.  Awọn ṣọja Amẹrika fẹran orilẹ-ede wọn ati awọn eeyan ibẹ. Awọn ṣọja tiwa n yinbọn pa awọn ọdọ, wọn n sa fun Boko Haram, nitori pe owo ati agbara nikan lawọn fẹran. Ọlọrun yoo gba Naijiria ooo!

Leave a Reply