O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Wahala awọn Fulani l’Ondo

Nigba ti a ba wo ohun to ṣẹlẹ  ni ipinlẹ Ọndo lọsẹ to kọja yii, ibẹru gidi ni yoo mu dani o. Wọn pa odidi ọba alaye, wọn si ji iyawo olori oṣiṣẹ Gomina Rotimi Akeredolu gbe lọ. Nigba ti wọn ba pa ọba, ti wọn si gbe odidi iyawo olori oṣiṣẹ gomina ipinle naa, ki lo waa ku ti araalu yoo ṣe o, nibo ni araalu yoo gba, ọna wo ni wọn yoo fi bọ lọwọ awọn ti wọn n ni wọn lara yii o. Ko si tabi ṣugbọn ninu pe awọn Fulani onimaaluu yii ti di nnkan mi-in si awọn ara Ondo lọrun, ọna Ondo si Ekiti tabi si agbegbe naa ko si ṣee tọ mọ bi ilẹ ba ti n ṣu. Itumọ eyi ni pe gbogbo ohun yoowu ti ijọba yii ba le ṣe ni ki wọn ṣe lati ri i pe eto aabo ipinlẹ naa kuro lọwọ awọn alainikan-an-ṣe lati ọdọ ijọba apapọ, ki wọn mojuto kinni naa funra wọn. Iroyin ayọ lo jẹ pe awọn Amọtẹkun ni wọn ṣe atọna bi wọn ṣe ri awọn ọdaran Fulani wọnyi mu, ti wọn si gba iyawo olori oṣiṣẹ gomina naa lọwọ wọn. Eyi fi han pe ko si ẹni to le mọ eto aabo adugbo kan bii awọn ti wọn n gbe adugbo naa, bi ọdaran ba si n gbilẹ nibi kan, awọn ti wọn jẹ ọmọ adugbo naa ba wọn lọwọ si i ni. Ohun to yẹ ki ijọba apapọ ti ṣe ni lati faaye gba gbogbo ipinlẹ ki wọn ni ọlọpaa tiwọn nibi ti wọn yoo ti gba awọn ọmọ ibilẹ sinu ẹ, awọn ọmọ ibilẹ ti wọn yoo mọ ibi ti awọn ọdaran n sapamọ si, ati awọn ẹlẹgbẹ wọn to jẹ ọmọ ilu wọn. Ṣugbọn oṣelu ko jẹ ki ijọba apapo ṣe eyi, wọn n foni doni-in, fọla dọla, titi ti ohun gbogbo fi bajẹ. Wọn ni ọlọpaa ni ka gboju-le, bẹẹ wọn mọ pe apa ọlọpaa ko ka awọn eeyan ti wọn n ṣe aburu yii, nitori bi wọn mu wọn paapaa, wọn ko ni i ba wọn ṣẹjọ kan. Ipinlẹ ti awọn janduku ba ti n pa ọba, ti wọn n ji eeyan ijọba gbe, ipinlẹ naa ti n wọ wahala nla lọ niyi, idi ti Akeredolu ṣe gbọdọ tun sokoto rẹ san niyẹn. Ko si si ohun kan ti yoo ṣe ju ko fun awọn Amọ Amọtẹkun ni agbara kun agbara lọ. Bi awọn Amọtẹkun yi ba lagbara, wọn yoo ṣe bẹbẹ ju eyi ti wọn n ṣe yii lọ. Ijọba gbọdọ ṣe ọna bi wọn yoo ṣe lagbara, wọn gbọdọ ba awọn ijọba apapọ sọrọ ki wọn fi aaye gba wọn lati maa gbe ibọn, nitori ẹni to fẹẹ mu ọdaran to gbebọn dani, oun naa gbọdọ gbebọn, bi bẹẹ kọ, wọn yoo kan maa fi ẹmi ara wọn ṣofo lasan ni. Awọn ọlọpaa wa ko le gba wa, nitori awọn funra wọn n sa fun Fulani onimaaluu, ijọba apapọ ko si ko ṣọja wa, nitori o da bii pe wọn fẹran ohun to n lọ, ko si si ọna meji to ṣi silẹ fun wa bayii ju ki a daabo bo ara wa funra wa lọ.  Nitori bẹẹ, ki Akeredolu ma jokoo tẹtẹrẹ o, ọrọ awọn Fulani ajinigbe Ondo yii n fẹ amojuto kiakia, ka tete le wọn sọna jinjin nikan ni gbogbo ilẹ Yoruba fi le nisinmi.

 

Afi ki Arẹgbẹ jokoo jẹẹ o

Wahala ti iba ṣẹlẹ ni ipinlẹ Ọṣun lọsẹ to kọja yii, Ọlọrun lo ba awọn eeyan ipinlẹ naa koore abilii. Ọrọ naa iba di wahala, iba si ba alaafia to wa ni ipinlẹ naa jẹ fun igba pipẹ. Awọn eeyan kan ti wọn jẹ ọmọlẹyin Arẹgbẹṣọla ni ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ni wọn ni awọn fẹẹ ṣe ayẹyẹ kan, ayẹyẹ ọdun mẹwaa ti ijọba awọn APC ti wa ni ipinlẹ naa. Arẹgbẹṣọla si ni alejo pataki awọn, oun ni yoo ba wọn sọrọ. Lọrọ kan, Arẹgbẹ ni wọn fi ayẹyẹ naa sọri. Ko si sohun to ṣẹlẹ ju pe Arẹgbẹ fẹẹ wa siluu Ọṣun pẹlu ariwo lọ. Awọn Buhari ti paṣẹ lati Abuja pe ki kaluku pada si ipinlẹ rẹ, ko lọọ tun ibẹ ṣe nitori rogbodiyan awọn SARS, ati lati fi ẹgbẹ oṣelu APC mulẹ daadaa si i. Bo ba jẹ nigba kan ni, Eko ni Arẹgbẹ iba wa, ṣugbọn awọn ara Eko ti fọgbọn ti i lọdọ wọn. Ohun to sọ ọ di ero Ọṣun ree, niwọn igba to si jẹ ọpọ awọn ti wọn wa ni ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ naa bayii, oun lo fi wọn sibẹ, o ti mọ pe bii ẹni fi akara jẹkọ ni yoo jẹ fun oun lati wọ ipinlẹ naa, bo tilẹ jẹ Gomina Gboyega Oyetọla funra ẹ ko fi taratara fẹ Arẹgbẹ nitosi oun. Arẹgbẹ ko fi bo rara pe oun naa fẹẹ di Jagaban fun gbogbo oloṣelu Ọṣun, ki oun naa jẹ alagbara nibẹ bi Tinubu ti jẹ alagbara l’Ekoo, ṣugbọn awọn Oyetọla ko fẹ eyi, bẹẹ si ni ọpọ awọn oloṣelu Ọṣun, ohun to si fa a ti awọn kan fi jẹ ọmọ Arẹgbẹ ree, ti awọn kan si jẹ ọmọ Oyetọla. Awọn mejeeji yii ni wọn iba koju ara wọn bo ba ṣe pe Arẹgbẹ raaye wọ ipinlẹ naa bo ti ṣe mura ni. Ọpẹlọpẹ awọn agbaagba ilu, ti wọn ni a ki i ri ọba meji laafin, ti wọn si kilọ fun Arẹgbẹ ko sun irinajo ẹ si ọjọ mi-in, ati pe ọdun yoowu to ba fẹẹ ṣe l’Ọṣun, Oyetọla to jẹ gomina lo gbọdọ ṣaaju. Ohun yoowu ti Arẹgbẹ ba n wa l’Ọṣun, afi ko fi suuru ṣe e o nitori gẹgẹ bi Oyinlọla ti wi nigba ti ọrọ yii n gbona, awọn ti wọn ṣe gomina ṣaaju oun naa ko yọ ọ lẹnu, oun naa ko si lẹtọọ lati maa yọ Oyetọla lẹnu, tabi ko maa halẹ mọ ọn. Bi Arẹgbẹ yoo ba jẹ oloṣelu Ọṣun ati baba iṣalẹ wọn, Ọṣun ni yoo jokoo si, ti yoo si tibẹ maa paṣe, ki i ṣe ko jokoo si Abuja, tabi ko ni ile ati ilẹ kaakiri Eko, ko tun maa waa yọ awọn ara Ọṣun lẹnu. Ṣe Alimoṣọ l’Ekoo ni Arẹgbẹṣọla ti fẹẹ maa paṣẹ oṣelu ẹ ni abi ipinlẹ Ọṣun. Afi ko mu ọkan, ko si jẹ ki gbogbo aye mọ. Nitori oju kan ladaa ni, bo ba ti di oju meji, o di ida niyẹn, bẹẹ ni ogun ni ida n ja o. Aja kan ki i roro ko ṣọ ojule meji: ẹ sọ fun Arẹgbẹ ko kaamu-dan-un (Calm down), ko jokoo jẹẹ lo n jẹ bẹẹ.

 

 

Bẹẹ ni, o yẹ ki Faṣọla waa sọ tẹnu ẹ

Lọsẹ to kọja, niwaju igbimọ to n gbọ ẹjọ awọn ti wọn ṣe iwọde SARS l’Ekoo, nijọsi, lọọya awọn to ṣe iwọde naa, Adeṣina Ogunlana, sọ pe ko si igba ti oun ko ni i bẹ igbimọ naa ki wọn pe minisita fun eto iṣẹ-ode ati ọrọ ile gbigbe, Ọgbẹni Babatunde Raji Faṣọla, lati waa sọ ohun to mọ nipa ọrọ to ṣẹlẹ lọjọ ti awọn ṣọja yinbọn pa awọn ti wọn n ṣewọde ni too-geeti Lẹkki. Ki lo de ti wọn yoo pe Faṣọla, nigba ti ko si l’Ekoo lasiko ti wahala yii ṣẹlẹ! Bẹẹ naa ni! Ṣugbọn lẹyin ti awọn agbofinro gbogbo ti wa, ti awọn kolẹ-kodọti ti lọ sibẹ,  ti awọn onileeṣẹ too-geeti yii ti palẹmọ, ti wọn gba ibi gbogbo, ti wọn si fọ ilẹ ati ayika, Faṣọla lọ si too-geeti yii ni ọjọ karun-un iṣẹlẹ naa, oun ati awọn minisita ẹgbẹ rẹ ni wọn lọ. Ṣugbọn ninu gbogbo wọn, ati awọn ti wọn wa nibẹ tẹlẹ ati awọn ti wọn jọ lọ, Faṣọla nikan lo ri kamẹra kan nilẹẹlẹ ni gbangba nibẹ, o ni kamẹra to ya fọto ohun to ṣẹlẹ niyẹn. Họwu! Iru oju wo ni Faṣọla ni to ju oju awọn ti wọn ti gba ilẹ agbegbe naa, ati awọn ti wọn ko ni iṣẹ meji ju iṣẹ kolẹ-kodọti lọ. Bawo ni kamẹra ṣe jẹ! O ṣe jẹ Faṣọla lo ri kamẹra lẹyin ọjọ karun-un iṣẹlẹ. Dajudaju, kamẹra yii ki i ṣe lasan, awọn kan ni wọn fi kamẹra naa sibẹ fun Faṣọla lati mu un, nitori wọn mọ pe orukọ rẹ ṣe pataki, awọn eeyan yoo si gba ohun to ba jẹ oun lo mu silẹ gbọ ju ko jẹ ẹlomiiran lo mu un silẹ lọ. Ohun ti wọn ṣe lo orukọ ọkunrin naa ree. Ohun to si fihan ni pe awọn eeyan kan wa nibi kan ti wọn n ṣe aboosi ojulowo, ti wọn fẹẹ da oju ọrọ yii ru pata, ki wọn le sọ pe ijọba ati awọn ṣọja lo jare, awọn ọdọ ti wọn si ṣe iwọde naa ni wọn jẹbi. Awọn wo lo  ṣe iru eyi! Ṣe ijọba ni abi awọn oloṣelu agbegbe yii! Kin ni wọn fẹẹ gba nidii ohun ti wọn n ṣe naa! Ati pe ṣe Faṣọla mọ pe wọn dẹ kamẹra silẹ foun ni, abi oun paapaa mọ nipa bi kamẹra ṣe de Lẹkki lẹyin ọjọ marun-un! Ki lo mọ ninu ọrọ yii gan-an, ki lo si wa ninu kamẹra alugbagba naa! Idi niyi ti Faṣọla fi gbọdọ wa siwaju igbimọ ni ojutaye, ko waa sọ gbogbo ohun to ba mọ, ko waa ṣalaye ọrọ kamẹra fun gbogbo ọmọ Naijiria, ki wọn le mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an. Asiko yii ki i ṣe asiko irọ pipa mọ, nitori gbogbo irọ ti ijọba apapọ n pa lo n ja butẹ, gbogbo irọ ti awọn ijọba Eko pa ni ko tẹwọn, aṣiri ọrọ si n tu si awọn araalu lọwọ ohun ti ijọba Naijiria fọkan si lọ. Wọn n binu, wọn n fẹsẹ halẹ, wọn ni wọn fẹẹ ba CNN ja, ati awọn ileeṣẹ iroyin to n gbe iṣẹlẹ naa jade pe ẹnikankan ku tabi pe ibọn ba ẹnikankan ni Lẹkki. Lai Muhammed ati awọn ọga ṣọja ni ko si ṣọja to yinbọn ni Lẹkki. Ṣugbọn ọmọkunrin kan ṣẹṣẹ jade bayii to waa ṣalaye bi awọn ṣọja ṣe yinbọn lu oun ni Lẹkki, ati bi wọn ṣe gbe oun lọ si ọsibitu, ti wọn si pada waa ge ẹṣẹ oun lọsibitu. Wọn ya fọto ọmọkunrin naa, gbogbo iwe ọsibitu ọwọ ẹ lo si fi han pe Lẹkki ni wọn ti yinbọn fun un. Ṣe anjannu lo waa yinbọn fawọn eeyan ni Lẹkki ni, to ba jẹ anjannu, ki lo de ti awọn anjannu naa ko ti yinbọn tẹlẹ ko too di ọjọ ti awọn ṣọja ilẹ wa lọ. Gbogbo irọ ti ijọba yii n pa ko ran wọn lọwọ, o tubọ n mu ọrọ wọn buru si i ni. Nitori bẹẹ, ki Faṣọla ma ronu irọ kankan o, ko wa sita gbangba, niwaju igbimọ, ko waa sọ bi ọrọ yii ti ri gan-an. Bi bẹẹ kọ, orukọ rẹ to ti niyi laarin awọn eeyan tẹlẹ, orukọ naa yoo bajẹ ni o.

 

Bi wọn ba n peeyan lole…

Bi wọn ba n pe eeyan lole, njẹ o yẹ ki tọhun tun maa gbe ọmọ ẹran jo ni! Ki lo tun de ti Gomina Babajide Sanwoolu kọ ile agbegbe idagbasoke ijọba ibilẹ Apapa-Iganmu, ti ko si ri orukọ ẹlomi-in fi ile naa sọri ju Aṣiwaju Bọla Ahmed Tiknubu lọ. Nigba mi-in, awọn eeyan yii funra wọn ni wọn maa n sọ Tinubu lẹnu, ki i ṣe Tinubu funra ẹ lo kuku n wa gbogbo nnkan mọya bayii. Awọn gomina yii paapaa a maa fẹẹ fi han Tinubu pe tirẹ lawọn n ṣe, ati pe bi o ba si oun, awọn ko le gbe ile aye. Tabi ninu gbogbo wahala to ba ọkunrin gomina yii, tawọn eeyan si n pariwo pe Tinubu lo ko ba a, kin ni idi lati fi tun kọ ile ijọba, ko si pe e lorukọ Tinubu. Ṣe Tinubu nikan lo wa l’Ekoo ni, tabi ṣe oun lo ko owo kalẹ lati kọ ile naa ni, ṣebi owo awọn ara Eko ni! Nnkan Eko meloo lawọn to n ṣejọba yii yoo sọ lorukọ Tinubu, o jọ pe bo ba ṣee ṣe fun wọn, wọn yoo yi orukọ Eko paapaa pada, wọn yoo si maa pe e ni Tinubu. Ki i ṣe pe eeyan ki i fi nnkan ranti ọga ẹni tabi ẹni to ba ṣe daadaa kan fun ilu, ṣugbọn nigba ti kinni naa ba ti pọ ju, aṣeju ni yoo da, ẹtẹ ni yoo si kangun rẹ. Ẹnu n kun Tinubu ju lori ọrọ Eko, awọn eeyan ko si sọrọ rẹ daadaa, nitori pe wọn ro pe gbogbo idaamu Eko yii, Tunubu lo ko o ba wọn. Bo ba waa ri bẹẹ, bi wọn ba n peeyan ni ole, ko yẹ ko tun de ọja ko maa gbe ọmọ ẹran jo. Ẹ sọ fun Sanwoolu ko wa oruko mi-in sọ ile to kọ, eyi ti wọn n pariwo orukọ Tinubu kiri si buburu yii naa to gẹẹ! Kawọn gomina yii yee sọ ọga wọn lẹnu jare!

 

Wọn n wabi ti wọn yoo fi asinwi si …

Awọn oloṣelu lo yẹ ki wọn maa pe ni asinwin, nitori bi wọn ba n wa ibi ti wọn yoo fi asinwi si, yoo si maa pariwo pe ti wọn ba ti de oke-odo, ki wọn duro de oun. Gomina Kogi, Yahaya Bello, ti gbogbo eeyan ipinlẹ naa n bẹ Ọlọrun ki asiko rẹ tete pe ko si maa ko ẹru rẹ lọ, jade si gbangba lọsẹ to kọja, o ni awọn kan ti n waa bẹ oun ki oun du ipo aarẹ Naijiria ni 2023. Awọn wo lo n bẹ Yahaya Bello o, ta lo fẹ ko ṣe aarẹ le wọn lori, nibo ni yoo si ti ṣe e. Ko si ohun meji to fẹẹ ṣẹlẹ, ọkunrin naa fẹẹ bẹrẹ eto lati fi owo awọn ara Kogi ṣofo ni. Ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe ni yoo da duro, nitori gbogbo owo to ba n gba ni yoo maa na lori irin-ajo asan to fẹẹ bẹrẹ yii. Ẹyin ara Kogi o, ẹ ma gba Yahaya Bello laaye ko bẹrẹ si i nawo yin o, yoo kan na owo yin danu, yoo sọ  pe oun n du ipo aarẹ ni. Paripari rẹ ni pe yoo sọ pe ẹyin le waa bẹ oun. Ẹyin nikan lẹ le gba ara yin lọwọ ẹ o. Bo ba pepade oṣelu, ẹ ma lọ o,  ẹ ma jo pade ẹ nibi kan, bi bẹẹ kọ, yoo ni ẹ waa bẹ oun ni o, yoo si bẹrẹ si i na gbogbo owo to yẹ ko fi ṣeto idagbasoke fun yin. Abani-wọran-ba-o-ri-da ni Yahaya Bello, ẹyin ara Kogi, ẹ tete jinna si i.

Leave a Reply