O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Naijiria ki i ṣe ti Fulani, wọn n tan ara wọn jẹ lasan ni

NIgbakigba ti wọn ba n kọ itan orile-ede yii lakọtun, itan Naijiria ko le sọ daadaa nipa Aarẹ Muhammadu Buhari. Ohun ti eleyii ko ṣe ni i ri bẹẹ ni pe oun naa ko ṣe daadaa fun Naijiria, aburu to n ṣe fun wa ju oore yoowu ti awọn abọbaku rẹ ba ro pe o n ṣe lọwọlọwọ bayii lọ. Bi ẹnikan ba wa nibi kan, to ba n tan Aarẹ yii, to n sọrọ didun si i leti, ti wọn n sọ pe ijọba rẹ lo dara ju laye ati lọrun, ki Buhari funra rẹ fi iye si i o, awọn eeyan yii gan-an ni yoo kọkọ bẹrẹ si i ṣepe fun un ni gẹrẹ to ba fi ipo silẹ, nitori yoo ka loju gbogbo wọn pe awọn ti ba aye ara awọn jẹ, awọn ti fi ohun ti awọn n jẹ lọwọ gba gbogbo ohun ti awọn fẹẹ jẹ lọjọ iwaju ati igbẹyin aye awọn jẹ. Buhari ko ṣe daadaa fun Naijiria, bo ba ṣe daadaa ni, gbogbo aburu to n fojoojumọ ṣẹlẹ yii ko ni i maa ṣẹlẹ, bo tilẹ jẹ awọn ti wọn n ri jẹ nidii ibajẹ yii n sọ fun gbogbo aye pe ko si nnkan kan. Awọn eeyan ti wọn n da ilu ru, ti wọn fẹẹ dogun silẹ gan-an, ijọba Buhari ki i ṣe bii ẹni to ri wọn, wọn maa n gbe oju sẹgbẹẹ kan bi wọn ba n sọ isọkusọ, ti wọn n sọ ọrọ adogun-silẹ, ti wọn si n huwa ti yoo tu gbogbo Naijiria ka ni. Loju awọn kan, paapaa awọn oloṣelu APC, awọn ti laakaye wọn dorikodo ninu wọn ni o, bi o ba beere ọrọ nipa Buhari, wọn yoo ni oun lo n ṣe daadaa ju lọ ni. Ṣugbọn oore wo lo wa ninu ki Naijiria fọ si wẹwẹ, tabi ko ti daru pata lai ni atunṣe mọ ki Buhari too lọ. Ọkunrin akọwe ẹgbẹ onimaaluu, Miyetti Allah, Alhassan Saleh, sọrọ kan lọsẹ to kọja yii, bo ba ṣe nibi ti nnkan ti daa ni, tabi nibi ti Buhari ti n ṣejọba fun gbogbo Naijiria, ti ko jẹ ijọba tawọn Fulani nikan ni, iru ọkunrin bẹẹ ko ni i sun oorun ọjọ naa ni ile rẹ, ijọba gbọdọ mu un, ki wọn mu un nikan kọ ni o, ki wọn ba a ṣẹjọ, ki wọn si ri i pe wọn gbe e kuro ninu igboro, laarin ilu pata, ko wa lẹwọn fun igba pipẹ. Bi iru oun ba wa lẹwọn, yoo di iṣoro fun ọpọlọpọ lati maa waa sọ ọrọ ti yoo pin gbogbo ọmọ Naijiria si wẹwẹ. Ọkunrin naa n ba awọn oniroyin sọrọ ni, o si fẹ ki gbogbo aye gbọ. Ohun to wi ni pe ko si ẹnikẹni, bi Naijiria ti to yii, ti yoo le awọn Fulani kuro ni ilẹ Yoruba. O ni iwa ati igbe-aye lile ti mọ awọn Fulani lara, ko si si ẹni to le le wọn nibi ti wọn ba fẹẹ gbe. Bi eeyan ba si pa Fulani tabi to fiya jẹ Fulani, ki tọhun ma sun, nitori awọn Fulani n pada bọ waa gbẹsan. Ọkunrin buruku yii ko sọrọ lori bi awọn Fulani ti n fi maaluu jẹ oko oloko ni tipatipa, ko sọrọ lori bi awọn Fulani yii ti n fipa ba awọn obinrin olobinrin ati ọmọ ọlọmọ lo pọ, ko sọrọ lori bi awọn Fulani yii ti n paayan to ba ni ki wọn ma fi maaluu jẹ oko awọn. Bi ẹnikẹni ba fẹẹ gbẹsan, ṣebi awọn ti Fulani n ṣe nika yii lo yẹ ki wọn gbẹsan. Ṣugbọn ọkunrin yii n fọkan awọn Fulani balẹ pe ki wọn gbẹsan nibi yoowu ti wọn ba wa, ki wọn si maa ṣe gbogbo aburu ti wọn n ṣe lọ. Idi pataki ti wọn si fi gbọdọ maa ṣe bẹẹ ni pe ko si ẹni to le le wọn ni Naijiria, nitori awọn lawọn ni Naijiria yii, ibi to ba si wu awọn lawọn le gbe, ohun to ba si wu awọn lawọn le ṣe. Ijọba to ba fẹ alaafia ni orilẹ-ede rẹ ko ni i jẹ ki iru ẹni bayii maa rin kiri, o ṣaa yẹ ko mọ pe iru awọn ọrọ bayii yoo da ogun ati ijangbọn silẹ ni. Ṣugbọn ijọba ti a ni yii ki i sọrọ si ohun ti awọn Fulani yii ba wi, tabi ti wọn ba ṣe. Iru ọkunrin to n sọrọ yii, Abuja ni oun n gbe, gbogbo awọn ti wọn n ṣejọba ni wọn mọ ọn, aarin wọn lo n lọ to n bọ, eyi si ja si pe awọn ti wọn n ba Buhari ṣiṣẹ mọ nipa awọn ọrọ to n sọ lẹnu. Oni kọ o, bẹẹ ni ki i ṣe ana, to ti n sọ iru ọrọ bayii, Ọrọ ti yoo pa ọmọ Naijiria, ati Naijiria funra rẹ lara. Ki waa ni ijọba Buhari n wo ti ko mu iru ẹni bayii, ati pe anfaani wo lo wa fun Buhari bi Naijiria ba tori ẹ fọ. Bi Naijiria ba fọ lojiji bayii, oore ni Buhari ṣe fun wa ni tabi aburu! Nitori ẹ lẹ ṣe gbọdọ sọ ootọ ọrọ fun un, ẹyin ti ẹ n ba Buhari rin, ẹ sọ fun un pe itan orileede yii ko ni i sọ daadaa nipa ẹ, ko yee fi aaye igbakugba gba awọn Fulani yii, nitori ki i ṣe tiwọn ni Naijiria, wọn n purọ tan ara wọn jẹ lasan ni.

Iyẹn lo ṣe yẹ ki wọn yẹ ọpọlọ gomina yii wo

Gomina ipinlẹ Bauchi ni, Bala Muhammed, o yẹ ki wọn yẹ ọpọlọ ẹ wo nitori isọkusọ ati ọrọkọrọ to n sọ lẹnu. Lọsẹ to kọja, ọkunrin naa ni ko si ohun ti awọn Fulani to n da maaluu kiri le ṣe ju ki wọn maa gbe ibọn kaakiri pẹlu maaluu wọn lọ, nitori ijọba ko ṣeto aabo kankan fun wọn, bẹẹ ni awọn ara agbegbe ti wọn ti n da maaluu wọn naa ko ṣeto aabo fun wọn. Ki waa ni wọn ko ni i gbe ibọn si lati fi daabo bo ara wọn o. Bala lo n beere lọwọ awọn ọmọ Naijiria bẹẹ, eyi si ni pe loju tirẹ, ko sohun to buru rara ki awọn Fulani maa ko maaluu kiri inu igbo pẹlu ibọn. Bala ko ronu rara pe ibọn yi lawọn eeyan naa fi n ji awọn ẹni ẹlẹni gbe o; ibọn yii ni awọn Fulani onimaaluu yii n na si awọn obinrin olobinrin ti wọn fi n ba wọn sun, ibọn yii ni wọn fi n paayan to ba fẹẹ ta ko wọn pe wọn fi maaluu jẹ oko oun. Bi Fulani onimaaluu ba lẹtọọ lati fibọn daabo bo ara rẹ nitori pe o fẹẹ fi maaluu jẹ oko oloko, awọn oloko naa lẹtọọ lati wa ibọn to lagbara ju tirẹ lọ ki wọn fi daabo bo ara wọn ati oko wọn lọwọ Fulani onijaadi to fẹẹ maa jẹ oko oloko lai da oko tirẹ. Gẹgẹ bii gomina, o yẹ ki ọpọlọ iru ọkunrin yii ṣiṣẹ debii pe ko si ilu tabi orilẹ-ede kan to laju ti awọn Fulani ti n ko maaluu kiri ninu igbo mọ, gbangba, nibi aaye ti wọn ti n sin maaluu ni kaluku n wa, nibi ti wọn yoo ti dako, ti wọn yoo si ti ni anfaani lati ṣe gbogbo ohun to ba wu wọn. Bẹẹ ni ki i ṣe ijọba lo n fun awọn eeyan yii nilẹ, nigba to ṣe pe okoowo wọn ni wọn n ṣe. Aye ko da maaluu kiri igbo mọ, onikaluku to ba n sin maaluu n ṣe agbo fun ẹran wọn ni. Nigba ti odidi gomina ba wa ti ironu rẹ gbodi bayii, to jẹ gbogbo ironu to wa lori ẹ ni bi awọn Fulani yoo ṣe maa gbe ibọn kiri inu igbo lati sin maaluu, bawo ni ipinlẹ ti iru ẹni bẹẹ wa yoo ṣe nilaari, tabi ni ilọsiwaju kan. Ko sohun to buru nibẹ, bo ba ti jẹ ki awọn Fulani onimaaluu maa gbebọn kiri ni, ti ofin si gba wọn laaye bẹẹ, o daa ki awọn agbẹ naa maa ni ibọn, ki kaluku maa gbe ibọn tirẹ naa kiri, ka waa wo ẹni ti ọwọ rẹ yoo dun ẹni keji lara. Awọn elewọnyi ko ni laakaye iṣejọba rara, odi patapata lọpọlọ wọn n ṣiṣẹ si.

 

Ṣebi Ọlọrun lo yọ Wọle Ṣoyinka

Pabambari ohun to maa n ṣẹlẹ si wa nilẹ yii ni pe iṣoro gidi ni fun araalu lati gboju le awọn ọlọpaa, nitori ni ọpọ igba, ọrọ to ba jade lẹnu wọn, ododo ibẹ ki i pe rara. Ọsẹ to kọja ni ariwo deede gba gbogbo ilu pe awọn Fulani onimaaluu kọ lu Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ninu ile rẹ to n gbe ni Abẹokuta. Ile ti ọjọgbọn yii n gbe ki i ṣe inu ile kan lasan, ile to wa ninu igbo ni, laarin igbo lo kọle naa si, igbo si yi ile naa ka ni. O ti pẹ gan-an ti ọkunrin onkọwe yii ti ra gbogbo agbegbe naa, to si ti n gbebẹ lati igba to ti wa ninu igbo kijikiji. Eyi ti a n wi yii yoo ti sun mọ bii ọgbọn ọdun daadaa. Ohun to fa eyi ko ju pe Ṣoyinka n lo ibẹ fun iṣẹ onkọwe rẹ, nitori aaye naa daa, o si tutu fun iṣẹ ọpọlọ ni ṣiṣe. Lọna keji, Ṣoyinka fẹran igbẹ-didẹ, ọdẹ to n pa ẹran keekeeke ninu igbo ni. Awọn ọrẹ rẹ mọ ile ọhun, nibẹ naa ni wọn si maa n wa a lọ l’Abẹokuta nibẹ, o jinna si ilu gan-an. Awọn Fulani onimaaluu yii a maa ko maaluu wọn wọ apa ibẹ, Ṣoyinka a si maa le wọn jade, pẹlu ikilọ pe ki wọn ma ko maaluu wọn wa si agbegbe naa mọ. Lọsẹ to kọja, Ṣoyinka sọrọ pe ki ijọba Buhari mọ bi yoo ti yanju ọrọ awọn Fulani onimaaluu, nitori awọn gan-an ni wọn n mura lati da ogun silẹ nilẹ wa. Nijọ kẹta to sọrọ, awọn Fulani da maaluu wọn dewaju ile Ṣoyinka gan-an, wọn da a kuro ninu igbo, wọn kuku do si iwaju ile ẹ. Ni Soyinka ba le wọn, ṣugbọn ko le da le wọn, kia lo tete ranṣẹ sawọn ọlọpaa pe ki wọn gba oun ki ọrọ too di ariwo. Awọn ọlọpaa ko tete de, ni Soyinka ba fi ọgbọn gbe mọto ẹ, o n wa awọn ọlọpaa lọ. Nigbẹyin, o ṣaa ri awọn ọlọpaa ko de, awọn ni wọn si ba a le awọn Fulani onimaaluu yii lọ. Ṣugbọn nigba ti awọn ọlọpaa yoo rojọ, wọn ni ẹnikan lo n gbe maaluu ẹ kiri, maaluu ẹ lo ṣi ile wọ, o kan rin gberegbere de ile Ṣoyinka ni. Ọrọ naa bi ọkunrin ọjọgbọn yii ninu to fi kọwe jade pe oun ko fẹran irọ buruku ti awọn ọlọpaa naa n pa mọ oun. Ni wọn ba yaa sinmi. Bo ba jẹ araalu mi-in ni, bi wọn yoo ṣe purọ mọ ọn ti tọhun ko ni i le wi kinni kan niyẹn. Bẹẹ ohun to n faja naa niyi, bi awọn Fulani yii ṣe n ṣe ree, bi wọn ba n fi maaluu jẹ ibi kan ti ẹni to ni ibẹ ba ni ki wọn ma fi maaluu jẹ oko oun mọ, ibi ti wọn ti n pa wọn niyẹn. O ṣee ṣe ki awọn Fulani to wa sile Ṣoyinka ma mọ ọn, to ba si ṣe pe o ba wọn ṣe agidi ju bẹẹ lọ, ti ko tete wa ọlọpaa kan, eyi ti a n wi yii kọ ni a ba maa wi. Bi wọn ba si pa a tan, ẹgbẹ Fulani onimaaluu yoo ni ko sibi ti wọn ko ti le fi maaluu jẹ oko, iru gomina balubalu to wa ni Bauchi yii naa yoo ni o yẹ ki wọn maa gbebọn kiri nitori aabo wọn. Kin ni iyatọ laarin adigunjale ati Fulani to fẹẹ fi maaluu jẹ oko oloko to gbe ibọn atamatase dani! Nnkan n fojoojumọ daru, ọrọ ọlọpaa ni ko si ṣee tẹle yii, ta la waa fẹẹ gbojule. Tabi  ẹyin ko ri i pe loootọ, Ọlọrun lo yọ Wọle Ṣoyinka!

 

Ṣebi ẹ gbọ ti wọn ni ko sẹni to fara pa ni Lẹkki!

Obinrin ẹlẹnuuyọ kan wa ninu awọn ti wọn n ba Buhari ṣejọba rẹ yii, boya obinrin naa wa nile ọkọ bi ko si, ẹni kan ko mọ, boya obinrin naa si ṣe abiyamọ tabi ko ṣe abiyamọ, ko sẹni to le sọ. Lauretta Onochie lorukọ rẹ, ṣugbọn agbalagba obinrin ni. Ni ọpọlọpọ igba, awọn ọrọ to maa n ti ẹnu obinrin naa jade nipa ijọba yii ko daa. Bi Buhari yagbẹ sara, yoo sọ fun gbogbo aye pe oyin ni, bi ijọba yii si dorikodo to fẹẹ ṣubu, obinrin yoo ni niṣe ni ijọba naa duro deede, ati pe nnkan ko gbọdọ tun dara ju bayii naa lọ. Lasiko ti awọn ọdọ mura lati ṣe iwọde lọjọ Satide to kọja, ti ọrọ naa fi di ariwo nla, ohun ti obinrin yii kọ jade ni pe awọn dupẹ lọwọ awọn ọlọpaa Naijiria gidigidi, nitori ko ṣeni kan to fara pa, bẹẹ ni ẹni kan ko ṣeṣe nibi iwọde naa, nitori ọgbọn ati laakaye ti awọn ọlọpaa lo ti wọn fi jẹ ki kinni naa lọ wọọrọ. Bo ba jẹ ko si fidio awọn Misita Macaroni ti wọn gbe jade to fi ibi ti wọn ti n lu wọn bii ẹran, ti wọn ti ko wọn jọ bii ẹran ti wọn n lọọ pa, bi obinrin yii yoo ṣe maa din irọ gbẹrẹfu fawọn eeyan ree, nitori ki wọn le ni o n ṣiṣẹ tootọ fun Buhari. Ifiyajẹni ti awọn ọlọpaa ṣe fun awọn ti wọn mu ni Too-geeti Lẹkki yii le debii pe ọga ọlopaa ipinlẹ Eko funra rẹ ti gbe igbimọ dide lati wadii ohun to fa a ti awọn ọlọpaa fi le huwa bẹẹ yẹn, bẹẹ lo sọ ni gbangba pe ko si ẹni to ran awọn ọlọpaa naa ni iṣẹ ti wọn n jẹ yii. Ṣugbọn pẹlu gbogbo eyi, Lauretta jade, nitori to n ṣiṣẹ fun Buhari, o ni ko sẹni kan to fara pa, koda, ko sẹni to ṣeṣe nibi iṣẹlẹ naa, nitori awọn ọlọpaa jẹ ki ohun gbogbo lọ wọọrọ. Bo ba jẹ wọn pa wọn ni, bi yoo ti jade ti yoo ni ko sẹni to ku ree; bi ko si si fidio to wa nita ni, bi yoo ti ni ko sẹni to fara pa ree, pe awọn ọlọpaa ko fọwọ kan ẹni kan. Ki lo de ti awọn eeyan yii n ṣe bayii? Ko si idi kan ti wọn fi n ṣe bẹẹ ju pe wọn ko nifẹẹ Naijiria lọ, wọn koriira awọn ọmọ orile-ede yii, ọna ti wọn yoo gba lati mu inu Buhari dun pẹlu irọ pipa fun un nikan ni wọn n wa, nitori nibi eyi nikan ni wọn fi le maa ri ohun ti wọn n jẹ lẹnu bayii jẹ, ti Buhari yoo si tun wo wọn sunsun, ti yoo gbe wọn si ipo mi-in to ga ju bẹẹ lọ. Gbogbo ẹ naa, lori irọ ni!

Leave a Reply