O ṣoju mi koro (Apa kin-in-ni)

Ẹni ba moju baba yii, ẹ jẹ yaa ba a sọrọ

Ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2014, Muhammadu Buhari (Ko ti i di aarẹ nigba naa) ṣaaju, alaga ẹgbẹ APC igba naa, John Oyegun, tẹle e, bẹẹ si ni gomina ipinlẹ Rivers asiko ọhun, Rotimi Amaechi, ati awọn agbaagba pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ APC, wọn ṣe iwọde nla kan niluu Abuja, iwọde naa milẹ titi. Laye ijọba Goodluck Jonathan ni. Buhari lo ṣaaju, nibi ikede naa lo si ti sọ fun gbogbo aye pe ki Jonathan fijọba to n ṣe naa silẹ, ko kuro lori ipo nitori apa rẹ ko ka awọn ọmọ ogun afẹmiṣofo ti wọn n daamu araalu kiri. O ni yatọ si iyẹn, Jonathan ti ba eto ọrọ aje ilẹ wa jẹ, ko si si ohun meji to tọ si ọkunrin ara Ijaw naa ju ko ko ẹru rẹ kuro nile ijọba lọ, bi ko ba fẹ ki awọn araalu le oun ni tipatipa. Gbogbo awọn eeyan lo n kan saara si Buhari ati awọn ti wọn jọ ṣewọde lọjọ naa, ti wọn ni ohun to dara ju lọ ni wọn ṣe. Loootọ si ni, bo ṣe yẹ ko ri gan-an niyẹn. Ninu ijọba tiwa-n-tiwa ti wọn n pe ni dẹmokresi, bi ijọba kan ba wa ti ko ṣe daadaa to loju awọn araalu, awọn eeyan ni ẹtọ lati fi ẹhonu han, ki wọn jẹ ki ijọba naa mọ pe inu n bi awọn, ki wọn ṣe iwọde, ki wọn si sọrọ si ijọba ọhun daadaa. Ki i ṣe tuntun rara, ni gbogbo orilẹ-ede to laju lagbaaye ni wọn ti n ṣe bẹẹ. Iru nnkan bẹẹ ki i ba ohunkohun jẹ, yoo kan jẹ ki awọn ti ọrọ kan sun ṣokoto wọn giri, ki wọn si tubọ ṣe daadaa fawọn araalu ni. Ko ju bẹẹ lọ. Nitori ẹ lo ṣe jẹ ko si ohun ti eeyan le pe ohun tawọn agbofinro ijọba Buhari yii kan naa ṣe fawọn ọmọ Naijiria ti wọn n fi ẹhonu wọn han lọsẹ to koja ju iwa were lọ. Iwa ẹni ti nnkan ti daru mọ lọwọ ti ko mọ ọna ti yoo gba mọ, iwa ọba to n jo nihoohoo ti ko rẹni sọ fun un pe ihooho lo wa, iwa aṣaaju ilu to ko awọn olori-ma-ṣanfaani yi ara ẹ ka, awọn ti wọn ko jẹ sọ ododo fun un, to jẹ irọ ni wọn yoo maa pa fun un. Bi Buhari ti jade ni ọdun 2014, awọn kan naa jade ni ọsẹ to kọja yii, wọn pe ara wọn ni Revolution Now (Ayipada Lẹsẹkẹsẹ!), ohun ti wọn si n sọ ni pe bi nnkan ṣe n lọ yii, yoo bajẹ pata bi ayipada ko ba tete waye. Ootọ si ni, ṣe ọrọ awọn Boko Haram ti Buhari tori ẹ jade nijọsi ni ko ti buru ju ti ọdun naa lọ ni, abi ti eto ọrọ aje, abi ti iṣejọba funra rẹ, nibi ti ko sẹni to le tọka pato bayii pe ẹni to n dari ijọba yii ree. Ṣebi gbogbo rẹ lo ti bajẹ, to si jẹ awọn eeyan ti wọn n ṣejọba yii ko ni ootọ kan ṣoṣo bayii lẹnu ju irọ ti wọn n fi ojoojumọ pa faraalu lọ. Ki lawọn eeyan ko waa ni i jade ki wọn fi ibinu wọn han si! Ṣugbọn kaka kijọba Buhari gbọ ọrọ wọn bi awọn Jonathan ti ṣe nijọsi, niṣe ni wọn ko ọlọpaa ati ṣọja jade, wọn ni ki wọn maa na wọn, wọn ni ki wọn sa wọn soorun, wọn ni ki wọn ti wọn mọle, nitori wọn sọ pe ohun tijọba yii n ṣe ko dara. Ijọba to ba n ṣe bayii, bii ọmọde ti wọn n ba wi to n warun ki ni, yoo parun gbẹyin ni! Ẹni to ba fẹran Buhari ko ba a sọrọ, ẹni to ba fẹ iṣọkan ati iduroṣinṣin orilẹ-ede yii ko ba ijọba yii sọrọ, bi nnkan ṣe n lọ yii ko daa, ọrọ ti yoo di wahala ni. Wọn ko le fi gbogbo ọjọ aye pa araalu lẹnu mọ, ọjọ kan n bọ tawọn ṣọja ati ọlọpaa ti wọn n lo yii yoo doju ibọn kọ awọn funra wọn. Ẹni to ba leti ko gbọ. Ẹ ba Buhari sọrọ. Bo ba ṣẹlẹ tan, ko ni i ribi kankan sa lọ.

 

Awọn yii gangan ni baba awọn ole

Ẹsịn iwaju ni tẹyin yoo wo sare, ohun ti aṣaaju kan ba n ṣe ni awọn ti wọn ba tẹle e yoo maa ṣe. Ninu ohun kan to n ba awọn eeyan ninu jẹ ju lọ ninu ijọba Buhari yii ni iwa ‘ka-sọro-ka-ma-ba-a-bẹẹ’ to mọ wọn lara. Koko ohun ti ijọba yii fi wọle ni pe awọn yoo gbogun ti iwa ibajẹ, awọn yoo si ri i pe ko si ẹni kan to huwa ibajẹ to fara rere lọ. Ko sẹni ti ko mọ pe ojulowo ohun to n fa orilẹ-ede yii sẹyin ree, iwa ibajẹ, ikowojẹ, ati ojuṣaaju. Kaluku lo mọ pe bi eleyii ba ti le kuro ni Naijiria loootọ, nnkan wa yoo yatọ si bo ṣe ri. Ohun to jẹ ki ọpọ eeyan tẹle Buhari ree, ti wọn si gbe ijọba rẹ wọle. Ṣugbọn ijọba Buhari funra ẹ, tabi Buhari gan-an paapaa, ohun ti wọn ni ko daa yii gan-an lawọn naa tẹpẹlẹ mọ. Ẹni ti wọn ko ba fẹran, tabi alatako wọn, nikan ni ole, bi awọn ti wọn ba jọ n ṣe ba fọle lọsan-an gangan tabi wọn paayan ni gbangba ode, wọn yoo gboju wọn si ẹgbẹ kan ni. Tabi ẹ ko ri ti Ize-Iyamu, ọkunrin to fẹẹ du ipo gomina ipinlẹ Edo lorukọ APC ni. Ọkunrin naa lọ si ọdọ Buhari lọsẹ to kọja, Buhari wọ ọ mọra, o fẹnu ko o lẹnu, o si gbe asia ẹgbẹ APC fun un lati sọ fun gbogbo aye pe eeyan oun ni. Bẹẹ Buhari yii kan naa yii lo ni EFCC to n mu awọn onibajẹ eeyan. EFCC yii ti mu Ize-Iyamu, wọn n ba a ṣẹjọ pe o ko owo bii ẹẹdẹgbẹrin miliọnu jẹ. Ṣe ẹni ti EFCC fẹsun kan waa yẹ ko sun mọ Buhari, debii pe wọn yoo jọ maa dọwẹkẹ, ti wọn yoo fi maa gbe asia ẹgbẹ fun un. Ẹni to ba n ṣọrẹ ole, ole loun naa, nitori agbepo-laja nikan kọ ni ole, ẹni to gba epo lọwọ ẹ lati ori aja to ba a gbe e silẹẹlẹ, ole kan naa ni gbogbo wọn. Ba a ba wo awọn eeyan Buhari yii daadaa naa, awọn gan-an ni baba awọn ole!

 

Ṣe ọrọ niyẹn lẹnu olori

Ni 2015, nigba ti gbogbo ọmọ Naijiria yoo dibo fun Buhari, ko sẹni ti ko gba pe onibajẹ ni awọn ti wọn n ṣe ẹgbẹ PDP, ati pe iwa ibajẹ ẹgbẹ naa pọ debii pe wọn ko ṣee mu yangan lawujọ. Awọn adari APC igba naa si mọ, eyi ni wọn ṣe n pariwo pe ayipada lawọn n mu bọ, “ṣenji” lawọn n mu bọ, ohun gbogbo yoo yipada bi awọn ba gbajọba. Eyi lo ṣe maa n baayan ninu jẹ nigba ti ọrọ kan ba ṣẹlẹ tai ṣẹlẹ, to jẹ ti ileeṣẹ aarẹ Naijiria yoo ba fesi ọrọ, paapaa ọrọ to jẹ toṣelu ti ko yẹ ko kan wọn rara, wọn yoo sọ pe ṣebi bẹẹ naa ni PDP n ṣe. Ṣe ọrọ niyẹn  lẹnu eeyan gidi! Wọn ni o huwa ibajẹ, o bayawo ọmọ rẹ sun, iwọ ni ṣebi bẹẹ naa ni baba lagbaja ṣe. Bi baba lagbaja ba ya were, ṣe dandan ni ki iwọ naa ya were ni! Wọn ni ko dara bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe gba Ize-Iyamu to fẹẹ ṣe gomina Edo lalejo, nitori tọhun n jẹjọ niwaju awọn EFCC, eleyii yoo si di idajọ lọwọ, yoo di iṣẹ awọn EFCC funra wọn lọwọ, nitori wọn yoo maa fi oju pe ọmọ Aarẹ ni wo Ize-Iyamu, wọn ko si ni i mura si ẹjọ rẹ bo ṣe yẹ. Kaka ki awọn eeyan yii waa gba pe awọn ṣe aṣiṣe, kia ni ileeṣẹ Aarẹ ti gbe ọrọ jade pe ki PDP dakẹ ẹnu wọn jare, bi wọn ba mọ pe ohun ti Buhari ṣe ko dara, ki awọn naa lọọ le awọn gomina wọn ati sẹnetọ ti wọn lẹjọ ni kootu kuro nipo wọn, nitori onibajẹ pọ ninu awọn PDP yii naa ju bi wọn ṣe n sọ faye lọ. Akọkọ ni pe awọn eeyan yii gba pe iwa ibajẹ wa lọwọ Ize-Iyamu ti Buhari fa ọwọ ẹ soke, to si gbe asia le lọwọ. Ẹẹkeji ni pe wọn gba pe ohun tawọn n ṣe ko dara. Ṣugbọn wọn n dunnu nitori pe PDP naa ti ṣe iru rẹ ri nigba kan. Pẹlu iru erokero, iwakiwa to wa lọkan awọn a-yinni-loju-ẹni to yi Buhari ka yii, bawo ni ijọba yii yoo ṣe lu aluyọ. Ohun to n jẹ ki ọrọ wọn daru ree, nitori wọn ko ṣee bo ti yẹ ki wọn ṣe e, ko si le ri bo ṣe yẹ ko ri fun wọn.

 

Bi aja ba ni ẹni lẹyin, yoo pa ọbọ

Nigba ti Buhari ti le ṣe eyi to ṣe fun ẹni to fẹẹ dupo gomina lorukọ APC ni Edo, Ize-Iyamu, boya ni baba arugbo yii mọ pe oun ti fun awọn eeyan naa laṣẹ lati huwa ibajẹ loriṣiiriṣii ni. Nitori ẹ ni ko ṣe ya awọn ọlọgbọn lẹnu nigba ti awọn kan n lọọ ti ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ naa pa, ti awọn mi-in si n lọọ yọ orule ile naa, ti awọn kan si n ji ọpa-aṣe gbe, ti awọn mi-in n tun ọpa-aṣẹ rọ, ti ohun gbogbo si di rudurudu l’Edo. Itiju nla lo yẹ ki eleyii jẹ fun gbogbo ẹni to ba ni laakaye, to si fẹran orilẹ-ede wa. Nigba ti ipilẹ ohunkohun ba ti wọ, to ti bajẹ, lati ilẹ, iru nnkan bẹẹ ko ni i pada yọri si rere, ipari rẹ ko le daa. Itumọ ni pe ko si ọna ti wọn yoo gba, ibo ti wọn yoo di ni Edo yii ko ni i mu eeso rere kan jade. Ko si ẹgbẹ oṣelu ti yoo wọle nibẹ ti ko ni i mu itajẹsilẹ tabi ojooro buruku dani, nitori pe awọn ti wọn n ṣejọba funra wọn ti faaye gba ohun buruku gbogbo. Ṣe ijọba Buhari yoo sọ pe oun ko ri ohun to n ṣẹlẹ ni Edo yii ni. Ọtọ ni ijọba, ọtọ ni oṣelu, ijọba wa fun gbogbo ilu, nigba ti ẹgbẹ oṣelu wa fun tara wọn. Awọn ti wọn n ṣejọba Naijiria yii ko mọ iyatọ laarin ohun ti ẹgbẹ oṣelu le ṣe, ati eyi ti ijọba le ṣe. Ijọba ko gbọdọ laju silẹ ki ẹgbẹ oṣelu kan maa huwa ọdaran, ki wọn si maa ba ilu jẹ, koda, ko jẹ awọn ni ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba. Bi PDP ba ṣejọba to dalu ru, ti APC ni awọn n bọ pẹlu ayipada, ti awọn naa tun de, to jẹ iwa tiwọn buru ju tawọn ti wọn lawọn fẹẹ yipada lọ. Nigba wo ni Naijiria yoo waa roju raaye. Ohun ti awọn eeyan Buhari ti wọn n ṣejọba yii n ṣe ko dara o, aburu ti awọn eeyan yii yoo si da sọrun awọn ọmọ Naijiria, apa wọn ko ni i pada ka a.

 

Ohun to sọ iyawo Buhari dero Dubai niyẹn

Ṣugbọn iṣoro wa fun Naijiria. Iṣoro gidi. Iṣoro naa si ni pe awọn ti wọn n ṣejọba wa ko lojuti. Wọn ko lojuti kan bayii bii ti i kere mọ. Bi wọn ba lojuti, yoo yaayan lẹnu pe Aarẹ Muahammdu Buhari pẹlu ẹnikẹni ninu idile rẹ yoo lọ si oke-okun lati gba itọju. Buhari funra ẹ lo kuku sọ bẹẹ nigba to fẹẹ du ipo aarẹ. Awọn oyinbo lo beere ọrọ lọwọ rẹ, o si da wọn lohun pe ko sohun ti oun yoo wa lọ siluu oyinbo lati gba itọju, o ni ko si bi aisan naa ti le le to. O ni bawo loun yoo ṣe ṣe ijọba fun ọdun meji mẹta ti oun ko ni i ni ileewosan ti yoo le wo gbogbo arun, to waa jẹ ilu oyinbo loun yoo maa lọ. Ṣugbọn Buhari ti n lo ọdun kẹfa lọ bayii, Ọlọrun lo mọ iye igba to ti lọ siluu oyinbo fun itọju, ati iye igba ti wọn ti lọọ fi owo wa ko awọn oyinbo dokita wa lati waa tọju ẹ mọ inu Aso Rock nibẹ. Ọmọ ẹ yọ ayọpọrọ, o ja bọ lori ọkada, ilẹ Jamani ni wọn gbe e lọ fun itọju. Iyawo ẹ lara ẹ ko tun ya yii, o wa ni Dubai to n gba itọju. Lẹyin ọdun mẹfa ti wọn ti n ṣejọba niyi o. Ṣebi ko ṣee maa sọ ni, Ọlọrun lo fi ajakalẹ-arun Korona yii tu aṣiri ọpọ awọn oloṣelu ati olori ijọba Naijiria, kinni naa ka wọn mọle, wọn ko rọna jade, iyẹn ni wọn ṣe n ku pii pii bii adiẹ. Bẹẹ nigba ti ẹ ba gbọ iye owo ti wọn ti ko jẹ labẹ ijọba to wa lode yii, ẹru Ọlọrun yoo baayan, nitori owo ti wọn fi kọ awọn ọsibitu ti wọn n ru awọn eeyan wọn lọ niluu oyinbo yii ko to owo ti wọn n ko jẹ laarin ara wọn. Naijiria le dara, ko si ohun to ṣe wa. Ṣugbọn afi ka ni ijọba ti ko ni i ṣe ojuṣaaju, ijọba ti yoo sọrọ, ti a oo ba a bẹẹ, ijọba ti awọn ti wọn n dari ẹ yoo maa funra wọn ṣe ohun ti wọn ba sọ pe kawọn araalu to ku ṣe. Ki i ṣe ijọba ti yoo ni kawọn eeyan ma gba owo ẹyin, to jẹ ohun tawọn yoo maa fojoojumọ ṣe niyẹn, tabi ti wọn yoo ni kawọn eeyan ma kowo jẹ, ti yoo jẹ ojulowo iṣẹ tiwọn niyẹn. Ijọba Buhari ni kawọn eeyan ma lọ siluu oyinbo lọọ gba itọju, ṣugbọn nibẹ ni oun ati iyawo ati awọn ọmọ tirẹ n lọ lati gba itọju tiwọn. Ọlọrun yoo da a o, Ọlọrun yoo da a ṣaa ni!

Leave a Reply