O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Kin ni wahala Lai Muhammed yii gan-an?

Ko si ki eeyan ma beere pe kin ni wahala Bọọda Lai Muhammed. Bi eeyan ba ri idaamu ti ọkunrin naa ko ara rẹ si, ko si ki eeyan ma beere pe ki lo kuku de bayii nitori Ọlọrun. Okun n ho yee, ọsa n ho yee, ọmo buruku tori bọ ọ, iru ẹ gan-an ni iṣẹ ti Bọọda Lai yii gbe fun ara rẹ ṣe. Lọsẹ to kọja yii, ọkunrin kan sọrọ lori redio, Mailafia lorukọ ẹ, ara ilẹ Hausa lọhun-un naa ni. Ohun to sọ ni pe gomina ilẹ Hausa kan ni olori awọn Boko Haram, o ni awọn ti ijọba dariji ninu awọn ọmọ ogun afẹmiṣofo naa ni wọn sọ bẹẹ foun. Nitori pe eeyan nla lati ilẹ Hausa ni, ti oun naa si ti figba kan jade poun naa fẹẹ du ipo aarẹ orilẹ-ede yii ri, ni awọn ti wọn beere ọrọ lọwọ ẹ fi bi i pe ki lohun to ri si ọrọ awọn Boko Haram ti wọn n daamu ilu yii. Idahun rẹ ko si ruju, o sọ ẹni to sọrọ foun, oun naa si lorukọ. Nigba ti ọrọ ti foju han bayii, ki waa ni wahala ijọba. Awọn DSS mu Mailafia, ọjọ ti wọn mu un naa ni wọn fi i silẹ, o tun jade kuro lọdọ wọn, o ni ododo ọrọ loun n sọ, ko ṣeni to le pa ohun mọ oun lẹnu. Awọn gomina ilẹ Hausa funra wọn jade, wọn ni ki ijọba apapọ gbe iwadii gidi dide lati mọ hulẹhulẹ ohun ti ọkunrin yii sọ. Ṣugbọn Lai Muhammed ko duro de iwadii ijọba, bẹẹ ni ko lọ si ọdọ awọn DSS ko lọọ beere lọwọ wọn idi ti wọn fi fi ọkunrin to sọ iru ọrọ bẹẹ silẹ, kaka bẹẹ, ileeṣẹ redio to n ṣe iṣẹ tiwọn jẹẹjẹ lo gba lọ, o ni wọn gbọdọ san miliọnu marun-un lẹsẹkẹsẹ, nitori wọn jẹ ki ọkunrin naa sọ ọrọ ẹnu rẹ jade. O daju pe ko le jẹ Buhari lo ran ọkunrin Lai yii ni iṣẹ to n ṣe yii, o si daju pe ko le jẹ pe ijọba yii fẹẹ pa gbogbo oniroyin ati akọroyin lẹnu mọ pe wọn ko gbọdọ wi kinni kan mọ, koda, ki awọn yagbẹ sara ni. Tabi nibo ni wọn ti n ṣe eyi ti Lai ṣe yii! Wọn fi ẹtẹ silẹ, wọn n pa lapalapa; wọn fi onija silẹ, wọn gba alapẹpẹ mu. Ẹni to sọrọ ko ku, ko si sa lọ, ko si sọ pe oun ko sọrọ ti redio gbe jade, o tun sọ ni gbangba pe ohun ti oun sọ ni redio gbe jade. Ṣe araalu ko lẹtọọ lati sọ ọrọ ẹnu rẹ mọ ni, abi redio ni ko lẹtọọ lati ṣiṣẹ! Kaka ki ijọba yii wa ọna ti wọn yoo fi yanju ọrọ ogun awọn afẹmiṣofo, iranu ni wọn n le kiri. Bi wọn ti n ṣe niyi o. Nigba ti wọn ba ra pala wọ ile ijọba, ti ijọba ba wa lọwọ wọn, wọn yoo maa huwa bii ẹni pe ibẹ ni wọn fẹẹ ku si. O digba ti iṣẹ ijọba ba tan ki oju wọn too walẹ, ti wọn yoo waa maa rin kiri bii igbona laarin ilu, ti wọn ko waa ni i ja mọ kinni kan mọ, ti wọn ko si ni i niyi lọdọ ẹni kan. Tabi nibo ni iru awọn eeyan bii Lai Muhammed yii yoo gba nigba ti ijọba yii ba bọ kuro lọwọ wọn! Oju wa yii naa ni yoo ṣe, ẹ sọ fun un ko mura si i daadaa.    

 

Wọn n ba ara wọn ja, ẹ tete la wọn o

Bi eeyan ba jokoo, to ni ọrọ Minisita Lai Muhammed yii loun yoo maa sọ, oluwarẹ ko ni i ri iṣẹ mi-in ṣe. Bẹẹ ni ọkunrin yii ro pe oun n fi awọn irọ ati ọrọ ẹtan to n jade lẹnu oun si araalu tun ijọba yii ṣe ni o, ṣugbọn o n fi awọn ọrọ naa ba ijọba yii jẹ loju gbogbo ọmọ Naijiria ni. Lati ọdun 2015 ni Lai Muhammed ti n pariwo pe awọn ti ṣẹgun Boko Haram, o ni awọn ṣẹgun wọn pata. Ko sigba ti wọn bi i, bi yoo ti wi nu-un, koda, ko jẹ awọn Boko Haram yii ṣẹṣẹ pa odidi ilu kan run ni. Ọkunrin Lai Muhammed yii yoo sọ fun yin pe awọn ti ṣẹgun Boko Haram, awọn ti wọn n kiri igboro Maiduguri, ti wọn n paayan kiri yẹn ki i ṣe Boko Haram, ralẹralẹ lasan ni wọn. Ṣugbọn fun igba akọkọ lọsẹ to kọja yii, Lai Muhammed sọ ododo. Ohun to sọ ni pe ijọba Buhari iba ti ṣẹgun awọn Boko Haram, ṣugbọn awọn orilẹ-ede agbaye ko ta irinṣẹ ijagun fawọn ni. Awọn ko ri awọn ibọn nla nla ati ọta, pẹlu awọn maṣingan-annu ti awọn fi le rẹyin Boko Haram ra lọwọ awọn oyinbo wọnyi ni, nitori wọn ko jẹ ta awọn irinṣẹ ogun yii fawọn. Lọrọ kan, ohun ti Lai n sọ ni pe awọn ko ti i ṣẹgun Boko Haram, ohun ti ko si jẹ ki awọn ṣẹgun naa ni pe ko si eelo irinṣẹ ogun to to. Ṣugbọn lọjọ yii kan naa ni Fẹmi Adeṣina toun jẹ agbẹnusọ fun Buhari ni eelo ijagun to to wa lọwọ awọn ologun Naijiria, nitori ko si ọga ologun kan to kun si awọn leti pe awọn ko ni eelo ijagun to. O ni eelo ijagun to pọ jaburata wa lọdọ awọn ṣọja ti wọn n jagun. Afi bii igba ti oludamọran Aarẹ yii ni ki Lai gbẹnu sọhun-un, ko mọ ohun to n sọ ni. Ṣugbọn ta ni eeyan yoo gbagbọ ninu awọn mejeeji yii, ṣe Lai ni abi Fẹmi, ṣe irinṣẹ ijagun wa loootọ abi ko si! Ta ni n parọ, ta ni n sọ ododo. Ninu ijọba kan naa ni wọn jọ wa o, ẹni kan naa ni wọn n ba ṣiṣẹ o, sibẹ, ọrọ wọn ko ye ara wọn. Ta ni yoo waa la wọn bayii, nibi ti wọn ba aye Naijiria jẹ de lẹ ri yẹn.

 

Abi ko jẹ loootọ lọmọbinrin yii n tan wa jẹ ni

O ti n lọ si bii ọsẹ meji bayii ti iroyin jade pe wọn ti gbe Aishat Buhari lọ si Dubai, nitori aiyaara. Ọrun ni wọn sọ pe o n dun un, wọn si ni kinni naa le gan-an. Bi ko ba tilẹ le, ṣe wọn yoo waa gbe e gba ọna Dubai bi! Awọn eeyan kan ko tilẹ gba pe ọrun lo n dun un, wọn ni o le jẹ Korona lo kọ lu u, nigba to jẹ arun awọn olowo ni. Ṣugbọn ko tun ju ọjọ mẹta lọ ti iroyin mi-in bẹrẹ si i jade, iroyin to si n jade naa ni pe ki i ṣe pe ara obinrin naa ko ya, wọn fi ọrun ati aiyaara yẹn tan awọn ọmọ Naijiria jẹ ni. Iroyin ti Sahara gbe jade naa sọ pe ọmọ obinrin yii lo fẹẹ ṣegbeyawo, ọmọ rẹ kan to n jẹ Hanan, wọn loun lo fẹẹ ṣeyawo, nitori lati ra awọn ohun ti yoo lo fun igbeyawo rẹ ni Aishat ṣe lọ, ti wọn gbe ẹronpileeni ọkunrin olowo ilẹ Hausa kan, Muhammed Indimi, lọ. Ko jẹ jẹ bẹẹ lawọn eeyan n wi, ti kaluku si n pe iroyin naa ni iroyin ẹlẹjẹ, ti wọn ni ko si bi Aishat yoo ṣe daju to bẹẹ, ti yoo huwa bẹẹ fun awọn ọmọ Naijiria ti wọn n ṣadura fun un nigba ti wọn gbọ pe o fẹ si i. Ṣugbọn o ṣe gate, ko ṣe gate, kinni naa jọ pe o n fi ẹsẹ mejeeji duro bayii o. Iroyin mi-in ti jade pe loootọ ni ọmọ Buhari yii yoo ṣegbeyawo ni ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan-an to n bọ yii, iyẹn bii ọsẹ mẹta si asiko ti a wa yii, ọkan ninu awọn ọmọkunrin Hausa kan to ti ba Babatunde Faṣọla ṣiṣe ri, Muhammad Turad, lo fẹẹ fi ṣe ọkọ. Wọn ti ni ninu Aso Rock ni wọn yoo ti ṣegbeyawo naa, ki i ṣe ti alariwo ti wọn yoo pe opọlọpọ ero sibẹ, kidaa awọn alagbara aye nikan ni. Ohun to jẹ ki ọrọ yii jọ ootọ ni pe bi ọmọ Buhari yoo ba ṣeyawo, o waa le ṣe e nigba ti iya rẹ n gba itọju ni Dubai bi! Itumọ eyi ni pe ki i ṣe pe ara Aishat ko ya, o lọọ ra nnkan iyawo ni. Tabi ta lo tun gbọ iroyin kankan nipa irin-ajo yii mọ lati bii ọsẹ meji sẹyin naa. Ṣugbọn bi Aishat ba tun n fi aiyaara tan gbogbo ọmọ Naijiria jẹ, ta lo waa ku ta a fẹẹ gbagbọ ninu ijọba yii gan-an! Eeyan gidi wo lo waa wa laarin awọn arufin ti wọn n ṣe olori wa yii! Bẹẹ, Ọlọrun yoo si ṣedajọ awọn naa nijọ kan o. Oju lo n kan wa. Ki wọn maa ṣe e niṣo, Ọlọrun n bọ ti yoo beere iwa wọn lọwọ wọn. Tabi awọn ti wọn ṣe e lanaa da!

 

Nibo ni ẹjọ Magu de duro bayii

Ohun to ba ijọba yii jẹ ree, ohun ti ko si ṣe si ẹnikan to ka wọn si ijọba to nikan i ṣe niyẹn. Awọn naa ko yee huwa bii alainikan-an-se, nitori otubantẹ ni gbogbo ileri wọn. Gbogbo igba, gbogbo ọjọ, ni wọn yoo fi sọ pe awọn n gbogun ti iwa ibajẹ, ṣugbọn to ba di ibi ti wọn yoo ti fi kinni naa han gbogbo aye, wọn yoo kuna patapata. Ẹyin lẹ pariwo pe Ibrahim Magu huwa ibajẹ, o kowo jẹ, owo sọnu mọ ọn lọwọ, o ṣe awọn owo to gba baṣubaṣu, o ra ile, o ra ilẹ, ati awọn iwa oriṣiiriṣii bẹẹ, ohun ti gbogbo araalu n gbọ niyẹn. Ṣugbọn lati bii oṣu kan aabọ ti wọn ti mu Magu ni gbangba ode, ti wọn ti i mọle, ti wọn si ti gba beeli ẹ, ko tun sẹni to gbọ kinni kan mọ o. Ọrọ Naijiria ko le, awọn ti wọn n dari wa ti mọ pe ariwo lasan la le pa, pe bi ọrọ kan ba ti di ariwo bẹẹ, ti a pa a lọ, ti a pa a bọ, kaluku yoo dakẹ, wọn yoo si sinmi. Tabi nibo ni wọn ti n ṣe eyi ti awọn eeyan yii n ṣe wọnyi. Ṣe pe awọn igbimọ ti wọn jokoo, ti wọn n wadii ọrọ Magu ko ni ẹri to dara lọwọ ni wọn ni ki ọlọpaa lọọ mu un ni, abi nigba ti wọn mu un tan, ẹri to ko silẹ kan araale, o kan ara oko, wọn si mọ pe aṣiri awọn ọrọ kan ko gbọdọ tu sita. Tabi iru ilu wo ree paapaa. Ẹ mu eeyan, ẹ ko ọkan gbogbo ilu soke, eeyan nla bẹẹ yẹn, ẹ ko si jẹ ki araalu tun gbọ kinni kan mọ. Koda, igbimọ to n wadii ọrọ ko sọrọ mọ, ohun gbogbo pa kese. Ẹjọ naa ti daru ree o, o ti daru pata. Bi ọrọ ba ti pẹ nilẹ, o maa n gbọn si i ni, ọrọ Magu yii ti gbọn mọ awọn ti wọn mu un lọwọ, o si daju pe wọn yoo bo kinni naa mọlẹ gbẹyin ni. Eleyii ko daa, ko daa rara. Ko le gbe wa debi kan ni, bo ba si gbe wa debi kan rara, ibi ifasẹyin ni. Awọn nnkan ti ko jẹ ki Naijiria nilọsiwaju lẹ n ri yii, nitori bo ba n lọ bayii, ko si ibi kankan ti a fẹẹ lọ ju ka wa lẹyin lọ. Ọlọrun o, waa gba wa lọwọ awọn ẹni ibi wọnyi o. Ma jẹ ko pẹ, ma jẹ ko jinna o jare.

 

Awọn adajọ aye ti wọn n gbeja Ọlọrun

Ọrọ ẹsin ilẹ Yoruba ati ti ilẹ Hausa ko ni i dọgba laye, nitori awọn aṣaaju ilẹ Hausa ko ni i ṣe ohun ti Ọlọrun ni ki wọn ṣe, awọn mẹkunnu ni wọn yoo maa da laamu, bẹẹ aaye iru rẹ ko si ni ilẹ Yoruba, ọhun naa ni gbogbo raurau bẹẹ yoo ti mọ. Ki i ṣe tuntun mọ bayii pe wọn ti dajọ iku fun ọmọkunrin akọrin kan ni Kano. Yahaya Shariff Aminu lorukọ ẹ, ọmọ Hausa bii tiwọn naa ni. Wọn lo kọrin kan to fi bu Anọbi ni, n lawọn adajọ wọn ba jokoo, ni wọn dajọ iku fun un. Awọn eeyan yii ni wọn n jẹ ki ẹsin Islam da bii ẹsin lile tabi ẹsin buruku loju awọn ti ki i ṣe Musulumi, ati loju awọn Musulumi mi-in paapaa. Ta ni le gbeja Ọlọrun bi ko ṣe Ọlọrun funra rẹ! Agbara wo ni ẹda kan ni ti yoo ni oun n gbeja Ọlọrun. Ṣugbọn nitori abosi ati agabagebe, awọn eeyan yii yoo maa fi ofin Sharia dẹruba awọn eeyan wọn, wọn yoo si maa fi ofin to yẹ ko jẹ idunnu awọn eeyan ni wọn lara. Nigba ti wọn bẹrẹ Sharia nijọsi, ọkunrin to bẹrẹ ẹ ni Zamfara, Yerima, ni ki wọn ge ọwọ ẹni to ji maaluu kan gbe, ṣugbọn nigba ti oun kuro ni ijọba ti aṣiri owo to ko jẹ tu, owo buruku to pọ nipọkupọ, ariwo to n pa ni pe ki wọn ma fi Sharia ṣedajọ oun, oun ko fẹ ẹjọ Sharia. Bẹẹ oun lo bẹrẹ ẹ o, oun lo si ti lo ofin naa lati fi ge ọmọ talaka lọwọ. Iru ẹ naa leleyii, iru orin wo ni tọhun ibaa kọ ti yoo jẹ iku ni adajọ yoo da fun un, ti ko tilẹ si ki wọn kilọ fun un rara. Laakaye tabi ifẹ Ọlọrun wo lo wa ninu iru idajọ bẹẹ. Wọn yoo kan maa le awọn eeyan kuro nidii ẹsin naa ni, bẹẹ awọn ti wọn n ṣe bayii, onibajẹ ati alagabagebe kan ni wọn. Ṣugbọn gomina Kano ko gbọdọ faaye gba eleyii o, bi bẹẹ kọ, bi oun naa ba kuro, awọn eeyan yoo hu ọrọ owo dọla ti oun naa ji ko nijọsi jade, ofin Sharia ni wọn yoo si lo, bo jẹ wọn ni ki wọn ge e lọwọ mejeeji ni, bo si jẹ wọn ni ki wọn juko pa a ni, ọkan yoo ṣe ninu mejeeji. Ṣugbọn ẹ ma pa ọmọ kekere akọrin yii o, ẹmi eeyan kan ko gbọdọ ti ọwọ ẹni to ba bẹru Ọlọrun loootọ bọ.

Leave a Reply