O ṣoju mi koro (Apa kin-in-ni)

Ọrọ ti Ọbasanjọ sọ ranṣẹ si Buhari

Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, tun sọrọ kan jade lọsẹ to kọja, ọrọ naa si baayan lẹru gidigidi, paapaa awọn ti wọn ba mọ ohun to n lọ nilẹ yii. Baba naa ni lati ọjọ ti oun ti wa ni Naijiria yii, ko si igba kan ti awọn ọmọ orile-ede yii koriira ara wọn to bayii ri, ati pe ijọba Buhari yii lo n sọ wọn di ọta ara wọn. Ọrọ yii baayan lẹru nitori pe ohun ti baba naa sọ, ootọ ọrọ pọnnbele ni. A ti di ọta ara wa ni orilẹ-ede yii, Yoruba ko fẹẹ ri Hausa, Hausa ko fẹẹ ri Ibo, ati Yoruba ati Ibo, ko si fẹẹ ri awọn Fulani rara. Koda, ko si ọmọ Naijiria to fẹẹ ri awọn Fulani lọdọ wọn. Bawo ni wọn yoo ṣe fẹẹ ri wọn, nigba to jẹ nibi gbogbo bayii, awọn Fulani lo ku ti wọn n ji awọn eeyan gbe. Bi wọn ṣe  n mu wọn ni ilẹ Yoruba ni wọn n mu wọn nilẹ Ibo, awọn Fulani n ji awọn eeyan wa gbe, wọn si n gba owo nla nla lọwọ wọn, owo ti wọn si n gba lọwọ wọn yii, ohun eelo ija oloro ni wọn fi n ra. Kaka ki gbogbo ọmọ Naijiria pawọ pọ, ka ba awọn Fulani yii wi, ijọba to wa lode yii ko gba fun wọn, nitori bii igba to jẹ pe wọn n gbe leyin awọn eeyan naa ni iwa ti wọn n hu. Ohun ti wọn n sọ kiri ni pe awọn Fulani onimaaluu ni wọn, nitori pe awọn ọmọ oniluu ko fun wọn ni ilẹ ni wọn ṣe ya ipanle, ti ijọba Buhari yii si n wa gbogbo ọna lati gba ilẹ awọn ẹlomi-in fun wọn. Ofin oriṣiiriṣii ni wọn n gbe dide. Ọtọ ni wọn ṣe ofin RUGA, nigba ti iyẹn ko wọle, wọn tun gbe ofin bebe omi gbogbo dide, ki wọn le gba gbogbo eti omi Naijiria si ọwọ ijọba apapọ, ṣugbọn gbogbo eeyan lo mọ pe bi wọn ba ri bebe omi wọnyi gba, ọwọ awọn Fulani ni yoo pada bọ si. Iru idajọ wo leleyii! Ijọba Naijiria ko gbọdọ ri ibọn lọwọ ẹlomi-in, bẹẹ ojoojumọ lawọn Fulani yii n gbe ibọn kiri. Lojoojumọ lawọn Fulani yii n paayan, ti wọn n jiiyan gbe, a ko mọ iye awọn Fulani yii ti ijọba tiwa ti dajọ iku fun ri. Awọn ẹgbẹ onimaaluu ti wọn n pe ara wọn ni Miyetti Allah ko yee fi ojoojumọ sọ isọkusọ, ti wọn yoo ni awọn lawọn ni Naijria, ohun to ba wu ẹnikẹni ko ṣe. Ẹgbẹ Miyetti Allah ni awọn yoo da ọmọ ogun fijilante tiwọn silẹ, wọn lawọn yoo ko maaluu awọn jẹ oko nibi to ba ti wu awọn, wọn ni ko si ibi ti awọn ko le wọ ni Naijiria, ko si sẹni to le da awọn duro. Gbogbo ọrọ tuulu tuulu ti awọn eeyan yii n sọ, awọn eeyan ijọba apapọ ni Naijiria ko gbọ. Ṣugbọn to ba jẹ Yoruba tabi Ibo kan lo sọ eleyii ni, awọn DSS yoo bẹrẹ si i wa a kiri, awọn minisita ijọba apapọ yoo sọ pe ọrọ ti tọhun sọ, ọrọ ikoriira ni, wọn si le tori ẹ ti gbogbo ileeṣẹ redio kan pa. Ijọba apapọ n yọ awọn akọṣẹmọṣẹ ti wọn ti wa lẹnu iṣẹ fun ọpọlọpọ ọdun tabi awọn ti wọn ti wa nipo giga lẹnu iṣẹ wọn kuro lẹnu iṣẹ yii, wọn yoo si fi ọmọ Fulani tabi Hausa kan si i, koda, ki tọhun ma mọ kinni kan. Nibi ti awọn eeyan kan ba ti n gba ilẹ onilẹ, ti wọn n gba oko oloko, ti wọn n ṣe bo ti wu wọn ni llu oniluu, ti wọn n paayan ni apagbe, ti wọn n fipa ba iyawo oniyawo sun, ti gbogbo awọn ti wọn n ṣe ni jamba yii si mọ pe Fulani lawọn ti wọn gbe ogun ti awọn, bawo ni wọn yoo ṣe fẹran iru ẹya bẹẹ. Bawo ni Yoruba yoo ṣe fẹran Hausa tabi Fulani! Bawo lawọn Ibo yoo ṣe fẹran wọn nigba ti wọn mọ pe aburu ni wọn jẹ fawọn. Ohun ti awọn ti wọn ti ṣejọba sẹyin tẹlẹ n ṣe ni pe wọn ki i fi ẹlẹyamẹya ṣe ijọba apapọ, nitori ijọba to wa fun gbogbo ọmọ Naijiria ni. Ṣugbọn ijọba yii fi pupọ si ẹyin awọn Fulani, bii igba pe wọn fẹran aburu ti wọn n ṣe fawọn ọmọ Naijiria ni. Ohun to fa idi ikoriira ree, ohun to sọ wa di ọta ara wa ree, ohun  t’Ọbasanjọ naa si n sọ niyẹn. Bi Buhari ati ijọba rẹ ba fẹ ki wọn ranti awọn si rere, afi ki wọn gba awọn ọmọ Naijiria to ku lọwọ awọn Fulani yii, ki wọn ri i pe awọn pa iwa ẹlẹyamẹya ti ninu ijọba wọn. Ki wọn yẹ ọrọ ti Ọbasanjọ sọ yii wo, ki wọn si mu un lo, nitori ohun ti yoo ran Buhari atijọba rẹ lọwọ ni.

  

Ṣugbọn ara wọn kọ ootọ ọrọ

Nigbakigba ti Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ba sọrọ kan, paapaa ọrọ to ba jẹ bi orilẹ-ede wa yii ti le dara ni, awọn kan yoo ti dide kia, wọn yoo ni isọkusọ lo n sọ, pe ki lo de ti oun ko ṣe bẹẹ nigba to n ṣejọba, ati pe ohun ti oun naa ko jẹ gba lo maa n fi lọ wọn. Bi Ọbasanjọ ti sọrọ pe ijọba yii n sọ awọn ọmọ Naijiria di ọta ara wọn, kia ni awọn afẹnuwa mọto inu ijọba rẹ ti n ka boroboro, wọn ni ki Ọbasanjọ fi alaye silẹ, ko gbaju mọ iṣẹ oko to n ṣe. Aimọkan lo n ṣe wọn bẹẹ. Idi ni pe ko si ẹni to le royin oju ogun bii ẹni to lọ sọhun-un to de, boya o sa wale ni o, tabi o jagun naa to ṣẹgun. Ni awọn orilẹ-ede to daa lagbaaye, nigba ti eeyan kan ba ti ṣe ijọba fun ọpọlọpọ ọdun bii ti Ọbasanjọ yii, to si ni iru iriri ti baba yii ni, awọn ti wọn ba ṣẹṣẹ gbajọba lati ṣe olori orilẹ-ede bẹẹ yoo maa wa wọn lọ ni, wọn yoo si maa pe wọn si kọrọ fun imọran to dara, ati ọna ti wọn yo gba lati ṣe ohunkohun. Ko ṣẹni kan ti i bu wọn. Ṣugbọn ti Naijiria ko ri bẹẹ, ohun gbogbo lawa fi i ṣe oṣelu, nibi ti awọn ọmọ ẹni ti ko jẹ kinni kan, awọn ọmọ eeyan lasan yoo ti maa bu awọn ti wọn jiya, ti wọn jiṣẹ lati jẹ ka wa ni Naijiria, awọn t’Ọlọrun ti gbe ga laaaye ara tiwọn. Ọbasanjọ ni ẹbi tirẹ, ṣugbọn lara ẹbi rẹ yii ni ijọba ọlọgbọn yoo ti mu, ti wọn yoo ni in lọkan pe awọn ko ni i ṣe ohun ti Ọbasanjọ ṣe. Ṣugbọn ijọba eleyii ki i gbọran, tiwọn nikan lo ye wọn. Ẹ wo ọkunrin kan ti n jẹ Mailafia, ọkunrin to ni awọn ọmọ ogun Boko Haram ti ijọba ti fi silẹ lẹyin ti wọn ronupiwada sọ foun pe gomina ilẹ Hausa kan ni olori awọn, pe oun lo n fun awọn ni gbogbo ohun ti awọn n lo, oun lo n ro awọn lagbara. Kaka ki ijọba Naijiria wa Boko Haram to sọrọ yii ri, ki wọn ṣewadii ọrọ naa jinlẹ jinlẹ, boya wọn yoo jẹ ri ododo ibẹ di mu, Mailafia ni wọn n le kiri. Bi DSS ti n le e, bẹẹ lawọn ọlọpaa n le e. Nigba ti wọn ko si ri ẹsun ti wọn yoo ka si i lẹsẹ lori ọrọ to sọ yii, awọn ọlọpaa ni ko waa foju kan awọn, lori ẹsun pe igba kan wa to ti kowo jẹ ri. Orilẹ-ede wo ni wọn ti n ṣe iru eleyii ti ọrọ wọn yoo yanju! Nibo ni wọn ti n ṣe eleyii ti nnkan wọn yoo tete dara! Afi ki Ọlọrun mu awọn aṣebajẹ ilẹ yii kuro, ki ogo ati oriire to wa lara Naijiria le bu yọ.

 

Ẹ beere lọwọ wọn, ofin wo ni wọn tun n yẹ wo

Bi a ti n sọrọ yii, awọn aṣofin Naijiria wa nibi ti wọn ti n ṣeto bi wọn yoo ṣe yẹ ofin ilẹ wa wo lọwọlọwọ. Wọn ti gbe igbimọ kan dide, owo ti wọn si ti ya sọtọ lati fi ṣeto ofin yiyẹwo yii le ni biliọnu daadaa. Bawọn aṣofin kan ba ti ṣẹṣẹ wọle, wọn yoo sọ pe wọn yoo yẹ ofin wo. Bi awọn ba ti lọ ti awọn mi-in tun de, wọn yoo tun ni wọn yoo yẹ ofin wo. Bẹẹ lo jẹ pe lọdun mẹrin mẹrin lawọn eeyan yii n ya owo sọtọ fun atunyẹwo ofin ilẹ wa. Eyi to buru ni pe lati ọjọ ti wọn ti n ṣe e yii, ko si igba ti wọn ri kinni naa yanju, ko si ofin gidi kan to ṣe awọn eeyan lanfaani, tabi ofin kan to yi Naijiria pada, kaka bẹẹ iwa ibajẹ n pọ si i, janduku n pọ si i, ikowojẹ ati ole jija, paapaa lati ọdọ awọn oloṣelu yii wa ti le debii pe niṣe lo da bii pe ko si ofin niluu yii mọ. Bẹẹ, awọn naa ni wọn n ṣofin yii, lara wọn naa ni wọn n kowo jẹ, bẹẹ ni ko si ofin kan to mu wọn. Bi ofin ba pọ rẹpẹtẹ bayii ti iwa ọdaran ko si yee pọ, itumọ to wa nibẹ naa ni pe ofin yii ko ṣiṣẹ kankan. Bẹẹ ni ki i ṣe pe ofin ni ko ṣiṣẹ, awọn ti wọn n ṣe ofin yii naa ni ko jẹ ki ofin ṣiṣẹ. Bii apẹẹrẹ, Ṣe ọlọpaa yoo sọ pe oun ko mọ ole laarin awọn ọloṣelu yii ni! Ṣe ọga ọlọpaa yoo sọ pe oun ko mọ pe awọn ọmọ oun wa loju titi ti wọn n da awọn eeyan lọna, ti wọn n gba owo wọn ni! Ṣe olori ẹgbẹ oṣelu, boya APC tabi PDP, yoo ni oun ko mọ pe awọn oloṣelu n fi owo fa awọn eeyan ki wọn too dibo fun wọn ni. Tabi ta ni a n tan! Ṣe Aarẹ ilẹ wa yoo ni oun ko mọ pe ojooro wa ninu eto igbanisiṣẹ, eto bi a ṣe n pin owo ni Naijiria, nibi ti awọn to n ṣiṣẹ ko ti rowo gba, to jẹ awọn ipinlẹ ti wọn ko pawo wọle ni wọn n gba owo to pọ ju lọ lọwọ ijọba apapọ. Eyi ni pe ofin wa, awọn olori wa gan-an ni ko tẹle ofin. Ofin kan ṣoṣo ti awọn aṣofin ilẹ wa le ṣe naa ni ki wọn maa paṣẹ fun Buhari pe ipade apero lori ofin Naijiria ti wọn ṣe ni 2014 to gbe pamọ si yara ẹ, ko gbe e jade, ko si ṣe amulo rẹ, gbogbo ohun ti Naijiria n fẹ lo wa nibẹ, awọn ọmọ Naijiria funra wọn ni wọn si ṣe ofin naa, nitori awọn ti awọn eeyan yan lo ṣe e. Bi awọn aṣofin yii ko ba ti le ṣe iyẹn, ki wọn yee jokoo sibi kan ko wa lowo min jare, ki wọn yee pariwo awọn n ṣe ayẹwo ofin, ki wọn yee mu tii jẹ Ṣikin lọfẹẹ, ki wọn fi ofin silẹ, ki wọn tun iwa wọn ṣe. Ko ju bẹẹ lọ o jare.

 

Ojoojumọ la n gbọ bẹẹ; ẹ wo o, o ti su wa jare

Ọga awọn ṣọja patapata, Tukur Burutai, ti sọ pe nibi ti ọrọ de bayii, ileeṣẹ ologun ilẹ yii ko ni i fi ọwọ bọrọ mu ọrọ awọn janduku to n da ilu laamu yii mọ, o ni awọn yoo gbogun ti wọn gidigidi.  O ni gbogbo awọn ọdaran ti wọn n daamu ilu yii lawọn yoo ba fija pẹẹta, awọn yoo si foju wọn ri mabo laipẹ rara. Ọrọ naa kuku daa, o si dun-un gbọ leti. O daa gan-an ni paapaa, abi nigba ti olori awọn ṣọja funra ẹ ba fi ọkan awọn araalu balẹ pe awọn ọdaran ti rogo lọwọ awọn, ki awọn araalu maa jo, ki wọn maa yọ lo ku! Ṣugbọn awọn ọmọ Naijiria ko ni i ṣe bẹẹ, nitori o fẹrẹ jẹ lojojumọ ni wọn n gbọ iru ariwo bayii lati ọdọ ijọba wa, paapaa lati ọdọ awọn ṣọja yii, wọn si ti da kinni naa si idannu, tabi ẹnu didun lasan, iyẹn bi ki i baa ṣe ẹtan. Wọn ni lojoojumọ ni Buratai n sọ pe awọn yoo ba janduku ja, ojoojumọ naa si lawọn janduku n pa awọn ọmọ awọn. Ṣugbọn nibi ti iṣoro wa naa ni pe Buratai funra ẹ ko gba pe ki i ṣe awọn janduku lo n da Naijiria laamu, awọn afẹmiṣofo ni, awọn apaayan lai nidii, awọn ọmọ ogun Fulani loriṣiiriṣii. Ohun ti ijọba Buhari ko fẹẹ gbọ niyi, ohun ti Burantai funra rẹ ko si le sọ naa niyẹn. Lọjọ ti wọn ba gba pe awọn ọmọ ogun afẹmiṣofo lo n yọ wa lẹnu, pe ki i ṣe janduku to kan fẹẹ ji owo ko, to jẹ apaayan lai inidii ti gbogbo aye n pe ni tẹrọriisi (terrorist) lawọn Fulani yii, nnkan yoo yipada fun wa awọn jagunjagun wa yoo si le koju awọn eeyan buruku yii pẹlu irinṣẹ to dara. Iṣọro awọn eeyan yii ni pe wọn ko fẹẹ pe Fulani ni afẹmiṣofo, wọn fẹẹ maa fi oori pa wọn lori, ki wọn le ṣe ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe. Eyi lọrọ Buratai ko ṣe wọ ẹnikẹni leti, asiko si ti to koun naa wa nnkan mi-in sọ.

Leave a Reply