O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Kin ni Pasitọ Tunde Bakare n fẹ gan-an?

Kin ni Pasitọ Tunde Bakare n fẹ gan-an? Ki lo n wa kiri? KI lo fẹẹ gba? Nibo lo ti fẹẹ gba a? Ki lo si fẹẹ fi gba a? Loootọ ni ọkunrin ajihinrere yii ti kede lọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an, 2019, pe oun loun yoo gbajọba lẹyin Aarẹ Muhammadu Buhari. Ko fi ọrọ naa pamọ rara, o ni Buhari lo wa nipo kẹẹẹdogun gẹgẹ bii aarẹ orilẹ-ede Naijiria, oun Bakare loun si wa ni ipo kẹrindinlogun, o ni bi wọn ti ṣe kọ ọ lati ode ọrun wa niyẹn. Nigba ti a ko ti i dibo, eeyan ko le mọ boya Ọlọrun lo sọ eleyii fun Bakare tabi ko jẹ oun funra ẹ lo n sọ ohun to wu u lọkan jade. Ṣugbọn kinni kan ni, bi nnkan kan ba wa to wu Tunde Bakare ju lọ lasiko yii, bi yoo ṣe di aarẹ Naijiria ni. Amọ o, ko waa yẹ ki Bakare tori pe yoo di aarẹ Naijiria, ko sọ ijọba ọrun nu funra rẹ, tabi ko ko awọn ọmọ ijọ rẹ, ati awọn ogunlọgọ ọmọ Naijiria ti wọn n tẹle e ṣina, ko si sọ wọn di ẹni anu. Ko yẹ nibi kankan fun ojiṣẹ Ọlọrun nla bayii ko da iṣẹ Ọlọrun papọ mọ ọrọ oṣelu, ẹni yoowu to ba ṣe bẹẹ, yoo di alabuku rẹpẹtẹ loju aye, abuku naa yoo si pọ debii pe yoo pa iṣẹ iranṣẹ rẹ lara. Nigba ti eeyan ba gbọ ọrọ ti Pasitọ Bakare sọ lori pẹpẹ nipa Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lọsẹ to kọja, tọhun yoo mọ pe ọrọ naa ki i ṣe iwaasu, bẹẹ ni ko ba ori pẹpẹ mu, ọrọ oṣelu pọnnbele ni.  Bẹẹ ni ko yẹ ki Pasitọ Bakare maa sọrọ oṣelu lori aga iwaasu rẹ, nitori oloṣelu a maa purọ, oloṣelu a maa ṣeke, awọn oloṣelu Naijiria ko ni iwa bii Ọlorun. Ṣe Pasitọ Bakare fẹẹ da bii wọn ni. Tabi kin ni idi ti yoo fi lọ si ori aga iwaasu ti yoo maa ṣalaye ọrọ nipa Tinubu fun wa, ti yoo si tori pe o fẹẹ gbeja Tinubu, ti yoo ni awọn agbaagba kan wa nilẹ Yoruba to jẹ agbalagba Ṣakabula ni wọn. Boya Bakare ko mọ ohun to ṣe, ohun to n sọ n da kun ija ati ainiṣọkan to wa nilẹ Yoruba ni, ko si huwa bii ojiṣẹ Ọlọrun to n pe ara rẹ. Bakare n bu awọn agba ilẹ Yoruba, o ni wọn ko dariji Tinubu nitori awọn ohun to ti ṣe sẹyin laye rẹ. O ni wọn n pe Tinubu ni ọmọ Iragbiji, pe Tinubu ki i ṣe ọmọ Eko, o ni ewo lo kan awọn agba yii ninu iyẹn, ewo lo kan wọn ibi ti Tinubu ti wa, ṣe awọn mọ ohun ti oju rẹ ri ni kekere ni. Bakare ni awọn agba Yoruba n sọ pe Abibatu Mọgaji ki i ṣe iya Tinubu, pe kin ni wahala tiwọn ninu iyẹn, pe loootọ, alagbatọ Tinubu ni Mọgaji, o si lẹtọọ lati pe e ni iya rẹ nibikibi. Bakan naa ni Bakare sọ pe awọn agba yii n binu, wọn n ṣe ilara pe Tinubu ko owo jẹ, pe ki lo de ti awọn naa ko lọọ ko owo tiwọn jẹ, abi ta lo di wọn lọwọ mu. Gbogbo awọn ọrọ yii ko yẹ lẹnu pasitọ kekere rara, ka ma ti i sọ ojiṣẹ Ọlọrun nla bii ti Bakare. Gbogbo ohun to ka silẹ yii, gbogbo ohun ti Yoruba n pe ni iwa ọmọluabi ni. Bi Tinubu ba ṣẹ, to si mọ pe oun ṣẹ, ko tọrọ aforiji, ki awọn agba yii le dariji i, ohun ti iwa ọmọluabi wi niyẹn. Ati ninu ofin ọrọ Ọlọrun ti Bakare n ṣe ojiṣẹ fun, ẹni to ba fẹẹ tọrọ aforiji, o gbọdọ kọkọ jẹwọ ẹṣẹ rẹ ni gbangba, awọn eeyan yoo si dariji i. Ṣugbọn nibo ni Tinubu duro si to jẹwọ pe ọmọ Iragbiji loun, ki i ṣe gbogbo ẹni to ba sọ bẹẹ lo n ba ja, nitori ko le maa ri awọn ara Eko mu lọbọ! Nibo ni Tinubu duro si to jẹwọ pe Abibatu Mọgaji kọ ni iya oun, tabi ta ni Tinubu darukọ iya ati baba rẹ fun bi gbogbo aye ti n pariwo to pe ki i ṣe Iyalọja naa lo bi i. Bi Tinubu ba jẹwọ pe oun ki i ṣe ọmọ Iyalọja, bawo ni yoo ṣe le fi ọmọ bibi inu tirẹ jẹ Iyalọja le gbogbo Eko lori! Nigba ti Pasitọ Bakare si sọ pe kawọn agba ilẹ Yoruba lọọ ko owo ilu jẹ bii ti Tinubu, oun naa ṣaa gbọdọ mọ pe iwa bẹẹ ki i ṣe ti ọmọluabi laarin Yoruba, Yoruba ki i ṣe apọnle fun ẹni to ba fi janduku tabi ọna agabagebe ko ọrọ jọ. Bawo ni Bakare yoo ṣe waa sọ pe bi Tinubu ba kowo jẹ, kawọn agba yii na lọọ ko tiwọn jẹ. Ko daa o! Bẹẹ Bakare yii ti pe Tinubu lole nigba kan, to si ni gbogbo owo to ko mi ni yoo pọ silẹ lagbara Ọlọrun! Eyi ti Bakare waa sọ yii, ko fi tun ti Tinubu ṣe, o fi ba tiẹ jẹ ni. Bakare ti jẹ kaye ti mọ bayii pe ọmọ Iragbiji ni Tinubu, ki i ṣe ọmọ Eko, pe Abibatu Mọgaji kọ lo bi i, ati pe o n ko owo araalu jẹ. Ṣe ohun ti Bakare fẹẹ sọ fun wa ree, abi ọrọ naa kan ja bọ lẹnu rẹ ni! Ki lo de tọkunrin yii sọ iru ọrọ yii jade! Kin ni Pasitọ Tunde Bakare n fẹ gan-an o!

 

Ni ti Tony Adefuye, ebi lo n pa baba

Ki Ọlọrun ma fi ebi alẹ pa wa. Nigba ti ebi ba n pa agbalagba, tabi ti iṣẹ gidi ba mu agbalagba, tabi bi agbalagba ba jẹ onijẹkujẹ ti ko mọ ko tọ, isọkusọ ni yoo maa ti ẹnu rẹ jade, ọrọ rirun ni yoo maa ti ẹnu rẹ jade, ko si ọrọ ọgbọn kan ti yoo tẹnu iru eeyan bẹẹ jade. Oun ni ti baba kan ti wọn n pe ni Tony Adefuye. Fun ẹni ti ko ba ranti ọkunrin yii daadaa, awọn ohun meji pataki ni ẹ oo fi ranti rẹ. Nigba ti MKO Abiọla ku, lọjọ ti wọn n sinku rẹ, ọkunrin yii ko ẹwu kọrun, o gba ile Abiọla lọ. Ṣugbọn nitori ti wọn ti mọ ọn daadaa pe ọkan ninu awọn ti Sani Abacha lo lati da ilẹ Yoruba ru ati lati ṣe iku pa Abiọla nigba naa ni, awọn eeyan sare si i, wọn si n pariwo pe ‘Tony Adefuye ree o’, ki oloju too ṣẹ ẹ, wọn ti ja a sihooho, gbangba lawọn obinrin si n wo ‘Baba Aburo’ rẹ nisalẹ, koda, awọn ọmọde fẹrẹ le fi ṣere. Ihooho ni Tonu Adefuye fi fi ile Abiọla silẹ lọjọ naa, pẹlu itiju nla, awọn agbaagba to wa nitosi ni ko si jẹ ki wọn yanju ẹ sibẹ patapata. Nigba ti wọn tun n ṣe kampeeni fun Muhammadu Buhari lọdun 2015, Tony Adefuye yii lo sọ ọ nibi ipade awọn agbaagba Yoruba kan ti wọn ṣe ni ilu Ibadan lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹta, ọdun naa, pe ‘Omọ ale Yoruba nikan lo le dibo fun Jonathan, gbogbo Yoruba lo gbọdọ dibo fun Buhari!’ Buhari ti agba ti ko larojinlẹ naa ni ki wọn dibo fun lọjọ naa lo n ṣe aye Yoruba ṣikaṣika bayii o. Eyi ti Adefuye waa lanu to sọ bayii, ọrọ naa le debii pe awọn eeyan ti n pe ipe fun pe ki wọn lọọ yẹ ọpọlọ ọkunrin naa wo, ko ma jẹ nnkan kan n ṣe e ni ọpọlọ ti awọn araale rẹ ko si tete mọ. Nitori ọrọ oṣelu ati ijẹkujẹ, Adefuye ni Yoruba ko ti i ṣejọba Naijiria, nitori Ọbasanjọ to ṣejọba nijọsi, ọmọ Ibo ni, Ibo ni baba rẹ, ki i ṣe Yoruba rara. Ki la waa ba lọ, ki la ba bọ, ṣe nitori ki Tinubu le wọle sipo aarẹ yii naa, beeyan tilẹ jẹ aja Tinubu ju bẹẹ lọ, laakaye diẹdiẹ ṣaa yẹ ko wa lagbari onitọhun. Lati jade waa sọ pe Yoruba ko ti i ṣe olori ijọba Naijiria ri ki i ṣe ọrọ daadaa. Ọrọ opurọ, ọrọ ẹlẹtan, ọrọ ẹnikan to n pe awọn to ku ni ọbọ ni. Ko si ohun to buru bi Yoruba ba n lakaka lati di aarẹ Naijiria, paapaa, to ba jẹ iru adehun bẹẹ ti wa nilẹ tẹlẹ laarin awọn ti wọn jọ n ṣe APC, bẹẹ ni ko sohun to buru rara bi Tinubu ba ni oun yoo ṣe aarẹ. Ṣugbọn eyi ti ko dara ni eyi ti awọn eeyan ti wọn sun mọ Tinubu n ṣe yii, paapaa iru awọn Tony Adefuye. Nitori ki Tinubu le ṣejọba, ẹ jade, ẹ n pe Ọbasanjọ mi ọmọ ale, koda, bi Ọbasanjọ ba ni tirẹ lara, ki i ṣe iru isọkusọ bayii ni yoo tun nnkan ṣe. Ẹ wo o, ẹ jẹ ka yẹ ọpọlọ Tony Adefuye wo, nnkan ti le ta si i ninu ọpọlọ. Idi ni pe awọn iwa to n hu yii ki i ṣe oju lasan, ijẹkujẹ o gbọdọ ma ṣeeyan bayii, nnkan mi-in wa nibẹ fun un! Ẹyin famili, ẹ tete ṣepade nitori baba yin o!

 

Ẹ ma jẹ kawọn ọta gba ọdọ awọn Amọtẹkun Ibadan yii mu wa o

Iroyin to n jade lati igboro ilu Ibadan ati awọn agbegbe mi-in ni ipinlẹ Ọyọ nipa awọn ẹṣọ alaabo ti wọn n pe ni Amọtẹkun ki i ṣe iroyin to dara rara. Ọtọ ni iṣẹ ti wọn tori rẹ pe awọn Amọtẹkun, ṣugbọn o jọ pe iṣẹ naa ko ye awọn pupọ ninu wọn, ọtọ ni iṣẹ ti wọn n ṣe. Wahala awọn Fulani onimaalu lo ba ilẹ Yoruba, nitori ki awọn eeyan wa ti wọn ba si le doju kọ ija naa le ṣe bẹẹ ni wọn ṣe gbe Amọtẹkun dide. O waa ṣe ni laaanu pe awọn Amọtẹkun wọnyi ko gba inu igbo lọ lati lọọ ba awọn Fulani onimaaluu ja, awọn ọmọ Yoruba to n ringboro kiri, ti wọn n wa iṣẹ oojọ wọn lọ, ni wọn ku ti wọn n doju ija kọ. Ọmọ Yunifasiti Ibadan kan, Akọlade Gbadebo, ku, ti wọn si n fi iku ẹ kọ awọn Amọtẹkun lọrun pe awọn ni wọn yinbọn pa a, ọkunrin kan gbe iwe sori ẹrọ ayelujara nipa awọn Amọtẹkun pe diẹ lo ku ki awọn Amọtẹkun yii lu oun pa, ati oriṣiiriṣii awọn iwa ipanle ati idaluru mi-in ti wọn ni awọn Amọtẹkun yii n hu n’Ibadan, ati ipinlẹ Ọyọ yikayika. Dajudaju, ki i ṣe ohun ti wọn ni ki awọn eeyan yii waa ṣe ni wọn ṣe yii, itura ni wọn ni ki wọn waa mu ba awọn eeyan, ṣugbọn ipalara lo da bii pe wọn n mu waa ba wọn. Bi iru ikọ bayii ba wa, oriṣiiriṣii awọn eeyan ni yoo wa ninu rẹ, bi awọn kan yoo ṣe daa ni awọn kan yoo buru, ti iwa awọn mi-in ko si ni i yatọ si ti awọn ọdaran ti wọn ni ki wọn waa mu. Eyi ni ijọba Makinde ṣe gbọdọ ji giri, ki wọn mura lati yọ awọn panda, eeyan buruku, ti wọn wa ninu ikọ Amọtẹkun kuro kia, ki wọn too ba nnkan jẹ patapata fun wa. Awọn Fulani n paayan kiri Oke-Ogun, wọn n ṣe wọn lọṣẹ ni agbegbe Ibarapa, ibi yii si ni awọn eeyan ti n wa iṣẹ wọn, ki wọn waa dojukọ awọn afẹmiṣofo to wa nilẹ Yoruba gbogbo. Ṣugbọn bi awọn Amọtẹkun tiwa naa ba sọ ara wọn di ọlọpaa, ti wọn fi oju ija silẹ, ti wọn n wa ibi ti wọn yoo ti jẹun, ti wọn yoo ti fi ibọn halẹ mọ awọn araalu kiri, ohun to buru gbaa ni eyi, wọn yoo si fun ijọba apapọ lanfaani lati kan wọn lẹyin ni, nitori wọn yoo sọ pe ohun ti awọn n wi ree o! Ki Makinde tete yaa mura kiakia, ki olori awọn Amọtẹkun naa sun ṣokoto rẹ giri, ikọ Amọtẹkun to ba ṣe werewere, lẹsẹkẹṣẹ ni ki ẹ ti mu un, ọmọ ẹni yoowu to ba si jẹ, ko tete fa a le ọlọpaa tabi ijọba lọwọ, ki wọn gbe e dele ẹjọ, ko si jiya ẹṣẹ rẹ lodidi. Eleyii ṣe pataki o, bi a ko ba fẹ ki awọn ọta gba ibi werewere awọn Amọtẹkun yii mu wa.

 

Kinni Fayoṣe n ṣe bayii si?

Ija agba buruku to wa laarin Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe ati Gomina ipinlẹ Ọyọ bayii, Ṣeyi Makinde ko ni i mu daadaa kan ba PDP nilẹ Yoruba, yoo fọ ẹgbẹ naa si wẹwẹ kọja atunṣe. Ṣugbọn ti eeyan ba fẹẹ sọ ọrọ naa si ibi ti ọrọ wa, ohun ti eeyan yoo beere ni pe kin ni idi ti Fayoṣe fi n ṣe bo ti n ṣe yii, nitori iwa ti ọkunrin naa n hu yii, ipalara ni yoo pada jẹ fun ẹgbẹ wọn. Ohun to buru ni pe ohun ti Fayoṣe ko gba, ti ko si le gba, ni gbogbo igba to n ṣe gomina, loun wa n fi lọ awọn eeyan bayii, iru iwa bẹẹ ko si dara. Ninu ofin ẹgbẹ wọn lo ti wa pe awọn ti wọn ba wa nipo bii gomina tabi sẹnetọ ni yoo ṣe olori ẹgbẹ naa ni adugbo tabi ipinlẹ wọn. O ṣee ṣe ki eto naa ma dara, nitori ẹlomi-in le jẹ gomina tabi sẹnetọ ko ma mọ bi wọn ṣe n ko awọn eeyan jọ, tabi bi wọn ṣe n tun ẹgbẹ ṣe. Ṣugbọn bi wọn yoo ba yi iru ofin bẹẹ pada, asiko ti Fayoṣe n ṣe gomina lo yẹ ko ti gbe e jade pe ofin yii ko daa, ẹ jẹ ka yi i pada. Ṣugbọn ni gbogbo igba to jẹ oun nikan ni gomina PDP nilẹ Yoruba, ija to n ba awọn eeyan ti wọn jẹ aṣaaju rẹ ninu ẹgbẹ ja naa ni pe oun ni gomina, oun nikan ni gomina PDP, oun si lolori ẹgbẹ naa. Ṣebi lara ohun to sọ oun ati Bọde George di ọta ara wọn niyẹn. Ki lo waa de to jẹ ohun ti oun ko gba nigba naa lo fẹ  ki Ṣeyi Makinde gba bayii, ki Ṣeyi Makinde jẹ gomina, ṣugbọn ko jẹ oun Fayoṣe ni yoo maa paṣẹ fun un; ki Abiọdun Olujinmi jẹ aṣofin Ekiti, ko jẹ oun Fayoṣe ni yoo maa paṣẹ fun un. Bẹẹ Fayoṣe yii ko joye kankan ninu igbimọ apaṣẹ awọn PDP, ọmọ ẹgbẹ lasan ni. Bo ba jẹ ohun ti Fayoṣe n fẹ naa ree, ki i ṣe oun ni yoo ṣe kinni yii funra rẹ, yoo ri awọn agbaagba ẹgbẹ to ku, nigba ti wọn ba si n ṣe ipade gbogboo, wọn yoo yi ofin ẹgbẹ tiwọn pada yatọ si ti ofin ẹgbẹ to ku, wọn yoo gbe iru agbara to n wa yii fun un. Ṣugbọn igba ti ẹgbẹ ko ti i ṣofin, dandan ni ki Fayoṣe fara mọ ofin to wa nilẹ, ofin ti oun naa ti lo tẹlẹ. Bi Fayoṣe ba n ṣe bo ti n ṣe yii, yoo ba ẹgbẹ PDP yii jẹ nilẹ Yoruba, bo ba si ba ẹgbẹ naa jẹ, oun naa ko ni i jẹ kinni kan nidii oṣelu mọ, yoo wa lasan bii korofo ni. Bẹ ẹ ba ri ọkunrin naa, ẹ beere pe, ‘Fayoṣe, ki lo n ṣe bayii si o?’

 

 

Leave a Reply