O ṣee ṣe ki ẹgbẹ PDP padanu ibo aarẹ ọdun to n bọ – Bọde George

Monisọla Saka

Eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Oloye Bọde George, ti ni dugbẹdugbẹ to n fi loke ninu ẹgbẹ awọn yii le ṣokunfa iṣubu ẹgbẹ naa ninu ibo aarẹ to n bọ lọdun 2023.

Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nibi ipade apero to waye niluu Eko l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii lo sọ eyi.

Baba naa loun paapaa fọwọ si i pe ki alaga apapọ ẹgbẹ wọn, Iyorchia Ayu, fi ipo rẹ silẹ ki ipolongo eto idibo too bẹrẹ lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022, nitori pe ko yẹ ki Ayu to wa lati apa Ariwa orileede yii dipo naa mu mọ, niwọn igba to ti jẹ pe ọmọ apa ibẹ naa loludije dupo aarẹ ẹgbẹ awọn.

Bo ṣe kọ jalẹ lati mu ileri to ṣe nigba to fẹẹ dori ipo ṣẹ fihan pe awọn eeyan apa Guusu ko ja mọ nnkan kan loju wọn niyẹn, wọn ko si ni ipa kankan ti wọn le ko ninu ẹgbẹ naa.

O ni, “A o gbọdọ faaye gba irẹjẹ tabi magomago ẹlẹyamẹya tabi ẹsin lati pin wa yẹlẹyẹlẹ.

‘‘Ohun to waa ba ni lọkan jẹ ni pe pẹlu gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ wa yii, ta o ba tete wa nnkan ṣe si i tabi ka yanju ọrọ awọn eeyan apa Guusu ilẹ yii ti wọn n binu, ti wọn lo da bii pe awọn ki i ṣe ara ẹgbẹ naa mọ nitori gbogbo nnkan ti wọn n gbe gbẹyin awọn kọja, afaimọ ka ma padanu ipo aarẹ lọdun to n bọ.

“Ta a ba waa lọọ foju pa ọrọ yii rẹ, ta a ko o da si ẹgbẹ kan, a o gbọdọ sọ pe a n reti ibo kankan latọdọ wọn o.

Afi ki ẹgbẹ yii tẹle ofin iṣọkan, ori-o-ju-ori, ti wọn fi pilẹ ẹgbẹ naa. Ka faaye gba awọn ẹkun agbegbe kaakiri orilẹ-ede yii ki wọn ko ipa pataki, paapaa ju lọ awọn ipo to ṣe koko ninu ẹgbẹ wa, bi a o ba ṣe eyi, ewu nla ati ẹtẹ la n wawọ si ninu ibo ọdun 2023 to n bọ lọna”.

“A gbọdọ jẹ ki wọn mọ pe, ifẹ awọn eeyan ni wọn maa ṣe. A si gbọdọ pin awọn ipo mẹfa to ga ju lọ lọgbọọgba laarin awọn ẹkun mẹtẹẹta, tori PDP ki i ṣe ileeṣẹ aladaani.

A ni lati gbe ipo alaga gbogbogboo wa si ẹkun Guusu orilẹ-ede yii ki ipolongo ibo too bẹrẹ ta a ba fẹẹ jawe olubori ninu ibo apapọ ọdun to n bọ”.

Bọde George ni ibi tawọn ti ba ara awọn lonii niyi, nibi ti alaga apapọ ati oludije dupo aarẹ ti jọ wa lati apa ibi kan naa.

Leave a Reply