O ṣẹlẹ: Aara san pa maaluu mẹẹẹdogun n’Ikọgosi-Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Iṣẹlẹ manigbagbe lo ṣelẹ niluu Ikọgosi-Ekiti, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti, nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja pẹlu bi aara ṣe san pa maaluu mẹẹẹdogun.

Iṣẹlẹ ọhun la gbọ pe o waye loju ọna ilu naa si Ipole-Ekiti laarin aago mẹrin si mẹfa ti ojo kan rọ, iyẹn lagbegbe ti omi gbigbona ati tutu ti pade niluu Ikọgosi.

Nigba to n sọrọ nipa iṣẹlẹ naa lọsan-an yii, Asaoye tilu Ikọgosi-Ekiti, Oloye Ayọ Ademilua, ṣalaye pe ṣe ni agbegbe naa mi titi nigba ti aara ọhun san, ṣugbọn ko sẹni to mọ nnkan to ṣẹlẹ.

O ni nigba tawọn arinrin-ajo kan n kọja lagbegbe naa lawọn darandaran sọ iṣẹlẹ naa fun wọn.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ agbayanu ọhun, Onikọgosi, Ọba Abiọdun Ọlọrunniṣọla, fẹsun kan awọn darandaran naa pe wọn fẹẹ maa ta awọn ẹran ọhun fun araalu, eyi to le ṣakoba fun ilera eeyan.

Kabiyesi ni oun ti sọ fun Ọba Ọladele Babatọla to jẹ Onipole lati kilọ fawọn eeyan ẹ ki wọn ma ra iru ẹran bẹẹ.

O waa ke sijọba lati waa ko awọn maaluu naa ko ma baa da ajakalẹ arun silẹ lagbegbe naa.  

Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, ni ko sẹni to waa sọrọ naa fawọn agbofinro rara. O ni tawọn darandaran naa ba fura pe awọn eeyan lo da wọn loro ti wọn si sọ fawọn, iwadii yoo waye.

Leave a Reply