O ṣẹlẹ, adajọ ni ki wọn lọọ pa adiẹ to n fariwo daamu awọn araadugbo

Monisọla Saka

Ọrọ buruku toun tẹrin lọrọ idajọ kan to waye ni kootu Majisireeti kan niluu Kano, nibi ti Onidaajọ Halimah Wali, ti paṣẹ fọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Malam Yusuf, lati pa akukọ adiẹ rẹ ko too di ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun yii. Ẹsun ti wọn fi kan adiẹ yii ni pe ariwo to maa n pa laduugbo ti pọ ju. Ariwo rẹ si pọ to bẹẹ to fi jẹ pe o maa n di gbogbo awọn araadugbo lọwọ, ki i jẹ ki wọn sun lasiko ti wọn ba fẹẹ ṣe bẹẹ, eyi to ti ko idaamu ba wọn.

Ẹni kan ti oun ati Yusuf jọ n gbele lo pe e lẹjọ si kootu, to ni kikọ ti adiẹ naa maa n kọ lakọju ni gbogbo igba ko jẹ koun loju oorun, niṣe lo maa n fi ariwo kikọ to n kọ di oun lọwọ lati sun.

Adajọ Wali, ẹni to gbe idajọ yii kalẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni idaamu ni nnkan ọsin ọhun jẹ fun gbogbo adugbo, ariwo rẹ si n ni wọn lara, nitori bẹẹ ni oun ṣe sọ fun Yusuf, ti i ṣe olowo adiẹ naa, lati wọna bi yoo ba ṣe pa adiẹ rẹ ọhun ni kiakia.

Ṣugbọn ẹbẹ ni ọkunrin naa n bẹ adajọ yii pe ko jọwọ, jare, ko ma jẹ ki oun pa adiyẹ naa bayii, o ni ko fun oun di ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu yii, ki oun too pa a.

Yusuf ni nitori ọdun Ajinde loun fi ra adiẹ naa, ki oun le baa ri i pa lati fi ṣajọyọ ọdun yii. Eyi lo mu ki adajọ ṣaanu rẹ, to si paṣẹ fun un pe kilẹ ọjọ Ẹti too ṣu, o gbọdọ ran adiẹ naa sọrun, ai jẹ beẹ, o n kọ lẹta si ijiya nla latọdọ ile-ẹjọ ọhun niyẹn.

Bo tilẹ jẹ pe sinsin oriṣiriṣii ẹran atawọn nnkan ọsin mi-in ninu ile ẹni, yala fun jijẹ tabi tita, ko tako ofin ilẹ Naijiria, ọrọ ko ri bẹẹ to ba di ibi tawọn ẹranko igbo ti wọn ba le paayan lara, iru ẹni to ba maa sin wọn gbọdọ gba iwe aṣẹ lọdọ ijọba lati ṣe bẹẹ ni. Ṣugbọn pẹlu nnkan to wa nilẹ yii, iru adiẹ tawọn eeyan n sin nile ni wọn wọ lọ si kootu yii, Ọlọrun nikan lo si mọ bi ariwo adiẹ naa ṣe lagbara to.

Sa, adajọ ti ni adiẹ ti ko mọ ohun to n lọ yii ko gbọdọ kọja ọjọ Ẹti, Fraidee, lorilẹ aye.

 

Leave a Reply