O ṣẹlẹ, adajọ poora lakooko to n gbẹjọ lọwọ n’llọrin 

 Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ṣe ni ọrọ naa da bii ere oritage nile-ẹjọ Magistreeti kan to wa niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, nigba ti Magistreeti Ibrahim Muhammed, poora lakooko to n gbẹjọ lọwọ ni ile-ẹjọ ọhun, ti ko si pada si ijokoo mọ titi ilẹ ọjọ naa fi su.

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, ati Anti rẹ, Sẹnatọ Khairat Abdulrazaq-Gwadabe, ni wọn fẹsun kan Kayọde Ogunlowo, Babatunde Saka ati Oluṣẹgun Oluṣọla Sholyment, fun iwa ibanilorukọjẹ, ati ẹsun mi-in to fara pẹ ẹ, ti wọn si ni ki ileeṣẹ ọlọpaa fi ofin gbe awọn afurasi ọhun.

Ileeṣẹ ẹka eto idajọ nipinlẹ Kwara, lo kọwe si ileeṣẹ ọlọpaa ni ọjọ kejilelogun, oṣu keje, ọdun yii, pe ki wọn mu awọn afurasi ọhun, ti iwe naa sọ pe “ẹ mu wọn ki ẹ si ṣewadii Oluṣẹgun Oluṣọla Shollyment, Kayọde Ogunlọwọ ati Babatunde Oluṣọla Saka, fun iwa dida omi alaafia ilu ru, irọ pipa ati ibani lorukọ jẹ, to ta ko iwe ofin orilẹ-ede yii, eyi lo mu ki wọn fi awọn olujẹjọ naa si ahamọ.

Nigba ti igbẹjọ naa fẹẹ bẹrẹ ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, Onidaajọ Magistreeti Ibrahim Muhammed, kede pe oun ni ibi kan ti oun fẹẹ lọ, sugbọn ti igbẹjọ naa ba pari ni oun yoo too lọ.

Lẹyin iṣẹju mẹwaa ti igbẹjọ naa bẹrẹ ti ọkan lara igbimọ ile-ẹjọ, Ibrahim Sharaf, ka ọrọ nipa gbigba beeli awọn olujẹjọ ọhun ni adajọ dide lai sọrọ kankan fun awọn agbẹjọro, o si jade lọ, ni ko ba wọle mọ, ireti awọn to wa nile-ẹjọ ni pe adajọ naa yoo wọle pada laipẹ, sugbọn ọrọ ko ri bẹẹ, ni awuyewuye ba bẹ silẹ ni ile-ẹjọ naa.

Leave a Reply