O ṣẹlẹ: Akpabio ti darukọ awọn aṣofin ti wọn jọ kowo jẹ o

Minisita to n ri si ọrọ agbegbe Niger Delta, Oloye Godswill Akpabio, ti darukọ awọn aṣofin to ni awọn naa lọwọ ninu awọn ikowojẹ nileeṣẹ NDDC ti wọn n pariwo yii o. Ileeṣẹ NNDC (Niger Delta Development Commission) ni ileeṣẹ to n ri si idagasoke agbegbe Niger Delta, nibi ti wọn ti n wa epo bẹntiroolu ilẹ wa. Ẹnu ọjọ mẹta yii ni aṣiri tu pe Minisita yii naa n ko owo jẹ nileeṣẹ yii, pe gbogbo bi owo ti n sọnu nibẹ ko ṣe ẹyin rẹ, oun lo si n ṣeto awọn iṣe awuruju fawọn eeyan, to jẹ bi wọn ba gba owo iṣẹ naa, wọn ko ni i ṣe e, wọn yoo kan ko owo naa jẹ lasan ni.

Nigba ti ọrọ naa ta seti awọn aṣofin, ni wọn ba ranṣẹ si Akpabio, wọn ni ko wa siwaju igbimọ kan ti awọn gbe dide lati wadii owo to n sọnu nileeṣẹ NDDC. Igba ti Akpabio debẹ, o ni ki wọn ṣe oun jẹjẹ o, ọrọ pe a-kowo-jẹ a-o-kowo-jẹ yii, ki i ṣe oun nikan ni kinni naa ta ba o, o ta ba awọn aṣofin paapaa. O naka si awọn aṣofin yii pe awọn naa maa n gba owo awọn iṣẹ kan ti wọn ko ṣe lọdọ awọn. N lawọn aṣofin kan ba ni ko darukọ awọn ti wọn gba iṣẹ lọdọ wọn. Bo ti fẹẹ maa sọrọ ni alaga igbimọ to n gbọ ẹjọ yii bẹrẹ si isọ pe ‘i so kee! i so kee!’, ki Akpabio ma wi nnkan kan mọ.

Ọro naa di ibinu nigbẹyin, nitori olori ile igbimọ aṣofin ọhun, Fẹmi Gbajabiamila, ni afi ki Akpabio darukọ awọn to n sọrọ ẹ lọdọ awọn yii, bi bẹe kọ, awọn yoo jẹ ko foju ba ile ẹjọ pe o ba awọn lorukọ jẹ. O jọ pe eyi lo jẹ ki Akpabio bẹrẹ si i darukọ awọn aṣofin ti ọwọ wọn ko mọ nidii ọrọ yii. Awọn to darukọ ni Nicholas Mutu, Senator Peter Nwaobosi, Senator Mathew Urghohide, James Manager, Samuel Anyanwu ati awọn mi-in lati ipinlẹ Edo ati Ondo. Dajudaju, ọrọ yii ti di ba a ba fa gburu, gburu yoo fa igbo, ibi ti yoo yọri si la o ti i mọ.

 

Leave a Reply