Ọsan gangan ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Adajọ Kootu Ṣaria kan kagbako awọn ajinigbe. Alaaji Hussaini Samaila ni adajọ naa ti awọn agbebọn-rin ti wọn tun jẹ ajinigbe, gbe sa lọ ninu kootu rẹ to wa nijọba ibilẹ Safana, nipinlẹ Katsina.
Abule kan ti wọn n pe ni Bauren Zakat ni kootu naa wa tẹlẹ gẹgẹ bawọn eeyan wọn ṣe wi, wọn ni ṣugbọn wọn ti gbe e lọ sibi kan to n jẹ Safana. Tibọn-tibọn ni wọn ni awọn ajinigbe ọhun ya wọ kootu yii, ni wọn ba ko Adajọ Samaila ni papamọra, wọn si gbe e lọ tefetefe.
Ohun ti iṣẹlẹ yii fi ru awọn eeyan loju ni pe, awọn oṣiṣẹ kootu wa lẹnu iyanṣẹlodi lọwọlọwọ, ko sẹni to n lọ si kootu latigba ti wọn ti bẹrẹ iyanṣẹlodi naa.
Ohun ti Adajọ Samaila lọọ ṣe ni kootu lọsan-an gangan to bọ sọwọ yii ṣokunkun si gbogbo awọn to gbọ pe wọn gbe e sa lọ ni.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Katsina, Gambo Isah, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
O ṣalaye pe nitori aabo ti ko to naa ni wọn ṣe gbe kootu yii kuro nibi to wa tẹlẹ, ti wọn gbe e lọ si Safana. Gambo sọ pe Adajọ Samaila ko beere fọlọpaa tabi ẹṣọ kankan to fi da lọ si kootu, ẹnikẹni ko mọ pe o wa nibẹ.
O fi kun un pe awọn oṣiṣẹ kootu ko ṣiṣẹ lasiko yii paapaa, ohun ti adajọ lọọ ṣe ni kootu ko ye ẹnikan. O ni iwadii ti bẹrẹ ṣa lati ri idi okodoro iṣẹlẹ naa.
Titi ta a fi pari iroyin yii, wọn ko ti i gburoo Adajọ Hussaini Samaila, bẹẹ lawọn to ji i gbe ko ti i kan si mọlẹbi rẹ fun owo itusilẹ.