O ṣẹlẹ, awọn ọlọpaa fẹẹ bẹrẹ iyanṣẹlodi lọjọ ipade gbogbogboo ẹgbẹ APC

Adewumi Adegoke

Bi awọn ọjẹ wẹwẹ lẹnu iṣẹ ọlọpaa ko ba yi ipinnu wọn lati bẹrẹ iyanṣẹlodi pada, afaimọ ki akude ma ba eto ipade gbogbogboo ti ẹgbẹ oṣelu APC n gbero lati ṣe lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, nitori ọjọ naa ni wọn ti ni Yẹkinni kan ko ni i yẹ ẹ, awọn maa gun le iyanṣẹlodi bi ijọba ko ba san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un owo-oṣu to kere ju lọ tawọn n beere fun. Wọn ni igbesẹ yii ti di dandan pẹlu bi awọn aladari ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣe gbe ọrọ awọn siwaju ijọba apapọ latọjọ yii tawọn ti n pariwo pe ki wọn wa nnkan ṣe si i.

Ninu iwe kan ti awọn agbofinro naa kọ si ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, Usman Alkali Baba, ni wọn ti sọ pe awọn ko ni i gba ohunkohun to ba din ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira tawọn n beere fun naa bii owo-oṣu ọlọpaa to kere ju lọ.

Wọn fi ku un pe oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku ati iwa ajẹbanu (EFCC) to ba wa ni ipele kẹta n gba owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun (280, 000) loṣu, nigba ti Kọnsitebu ninu iṣẹ ọlọpaa n gba ẹgbẹrun marundinlaaadọta (45, 000) loṣu.

Wọn fi kun un pe oṣiṣẹ EFCC to ba wa ni ipele keje n gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta o din mẹwaa (490, 000) loṣu, nigba ti ọga ọlopaa to wa ni ipele yii pẹlu iriri loriṣiiriṣii n gba ẹgbẹrun mọkandinlaaadọfa (109,000). Awọn eeyan naa ni ohun ijọloju lo jẹ pẹlu bi wọn ṣe n ṣe awọn bii ẹru nigba to jẹ pe awọn n daabo bo awọn araalu lai naani ẹmi awọn.

Wọn ni, ‘‘Iya n jẹ wa gidigidi, ọpọlọpọ wa ni ko le jẹun ẹẹmẹta lojumọ, bẹẹ ni a ko le ran ọmọ wa lọ si ileewe lai gba riba. Ẹ lọọ wo awọn baraaki ti awọn ọlọpaa n gbe bo ṣe ri radarada ti ko ṣee wo. Kọnsitebu to n gba ẹgbẹrun mẹtadinlaaadọta Naira loṣu yoo sanwo ile, yoo sanwo ina, yoo pese ounjẹ fun mọlẹbi rẹ ninu owo ti ko to nnkan.

‘ ‘A mọ iye ti awọn sẹnetọ, awọn goimna atawọn ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin ti a n ṣọ n gba. A ko si tori eleyii ṣiwa-hu, nitori naa, ki atunṣe ba ọrọ owo-oṣu wa lọna abayọ, bi bẹẹ kọ, ko sohun to le da iyanṣẹlodi naa duro.

Ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii niroyin naa n lọ labẹle pe awọn ọlọpaa ilẹ wa n gbero lati da iṣẹ silẹ nitori pe wọn ko san owo to daa fun wọn. Ṣugbọn kia ni ileeṣẹ ọlọpaa ti jade, ti wọn si ni ko si ohun to jọ bẹẹ. Ṣugbọn pẹlu bi awọn eeyan naa ṣe jade sita bayii pe awọn ko ni i ṣiṣẹ mọ lati ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta yii, o ṣee ṣe ki eleyii ṣakoba fun eto aabo nilẹ wa.

Leave a Reply