Stephen Ajagbe, Ilorin
Lẹyin ọsẹ kan ti oludamọran pataki feto ilera, Ọjọgbọn Wale Suleiman, kọwe fipo rẹ silẹ, ọkan lara awọn kọmiṣanna Gomina Abdulrahman Abdulrazaq, Aisha Pategi, naa ti tun kọwe fipo silẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
Aisha Pategi ni kọmiṣanna fun akanṣe iṣẹ, (Special Duties). Ileeṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ ijọba ibilẹ lo wa tẹlẹ ko too di pe gomina paarọ ipo rẹ lasiko ti awuyewuye kan waye lori owo kan ti awọn kan lẹka eto isuna n yọ loṣooṣu lapo ijọba ibilẹ.
Ninu atẹjade kan to fi kede ifiposilẹ rẹ, Aisha ni oun ti kọwe fipo silẹ bẹrẹ lati oni, ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 2020.
“Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun to fun mi ni oore-ọfẹ lati ṣiṣẹ labẹ ijọba Gomina Abdulrahman Abdulrazaq, gẹgẹ bii aṣoju ẹkun Pategi ati lati sin araalu.
“Igba ni ile-aye, mo si fi igboya sọ ọ wi pe asiko ti to fun mi lati kuro ninu iṣejọba yii, ki n si tun wa ilana ọtun mi-in lọ.”
Ọsẹ to kọja ni oludamọran pataki feto ilera, Wasiu Suleiman, kọwe fipo silẹ lai sọ idi to fi gbe igbesẹ naa. Bakan naa ni ọrọ kọmiṣanna yii ri, oun naa ko sọ pato ohun to fa a to fi ṣẹ bẹẹ.