O ṣẹlẹ, ọmọ Gomina Akeredolu fẹẹ wọ igbakeji baba ẹ lọ sile-ẹjọ

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ.

Ọmọ Gomina ipinlẹ Ondo, Babajide Akeredolu, ti fa ibinu yọ lori ẹsun ti Igbakeji baba rẹ, Agboọla Ajayi, fi kan an lasiko ti wọn n ṣe ifilọlẹ eto ipolongo ibo ẹgbẹ oṣelu ZLP niluu Ọrẹ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

Ninu ọrọ ti igbakeji gomina ọhun ba awọn alatilẹyin rẹ sọ lọjọ naa lo ti fẹsun kan ọmọ ọga rẹ pe owo to to bii ojilenirinwo o din meje miliọnu Naira (#433M) lo bọ sapo tirẹ nikan ninu biliọnu mẹrin o le diẹ (#4.3B) tijọba gbe pamọ si ọkan ninu awọn banki to wa l’Akurẹ.

Ohun ti ọmọ Akeredolu gbọ ree to fi fa ibinu yọ, to si ni dandan ni ki oun pe Ajayi lẹjọ fun ẹsun ibanilorukọ jẹ, o ni oun rọ oludije ẹgbẹ ZLP yii lati tete ko awọn ẹri to ba wa lọwọ rẹ jọ nitori pe awọn agbẹjọro oun ti n gbe igbesẹ lori ọna ti wọn fẹẹ fi ba a ṣẹjọ nigbakuugba to ba kuro lori aga ipo igbakeji gomina to wa.

Babajide ni ti Ajayi ba si da ara rẹ loju lori ẹsun to fi kan oun, o ni ko gbe ofin asẹmalu to n jẹ anfaani rẹ lọwọ si ẹgbẹ kan, ko si jẹ ki awọn pade nile-ẹjọ.

Leave a Reply