O Ṣoju Mi Koro

Fayoṣe ati Magu ọrẹ rẹ, ṣaago n bu’go

Bo ba jẹ aaye gba Ayọdele Fayoṣe ni, yoo ti ko ilu jade sita bayii, ti yoo maa jo. Yoo maa jo nitori pe wọn ti mu Magu ni, olori ajọ EFCC to foju rẹ ri mabo. Lati igba ti wọn ti mu ọkunrin yii, ojumọ kan, ọrọ kan, ni Fayoṣe n sọ. Igba kan lo ti kọkọ sọ pe Ọlọrun lo mu un, nigba to si tun ya, o ni ki wọn fi ofin de Magu pe ko gbọdọ lọ sibi kan, ki wọn gba pasipọọtu rẹ, nitori bẹẹ lo ṣe foun naa. Ko tun pẹ lo sọ pe o yẹ ki ọkunrin naa pẹ nitimọle daadaa, eyi to si sọ gbẹyin ni pe Magun ta awọn ile ati ohun-ini mi-in to ba gba lorukọ EFCC fun awọn ọrẹ rẹ ni. Loju Fayoṣe, Ọlọrun ti mu Magu, o si yẹ ki iya gidi jẹ ẹ. Gẹgẹ bii ẹlẹran ara, Fayoṣe gbọdọ ṣe bẹẹ, paapaa nitori ohun ti oju oun naa ri lọdọ awọn EFCC yii ni gẹrẹ to gbejọba silẹ. Eyi ti ko mọgbọn dani ni ti awọn ọrẹ rẹ ti wọn bẹrẹ si i ba a jo, ti wọn n ba a yọ, ti wọn n ki i loriki oriṣiiriṣii pe o rẹyin Magu, ẹni to n le e kaakiri. Eyi ti ko mọgbọn dani ninu ọrọ tiwọn ni pe, loootọ, Magu le ni tirẹ lọwọ, ṣugbọn ṣe wọn purọ mọ Fayoṣe ni. Ṣe wọn ko fi ẹronpileeni ko owo lati Abuja wa fun un ni. Awọn ti wọn gbe owo fun un ti jẹwọ, Musiliu Ọbanikoro ti wọn fowo ran ti sọ bẹẹ, wọn ti ṣewadii ẹ, Fayọṣe ko lo owo ti wọn ko fun un tan, o fi pupọ gbọ bukaata ara tirẹ ni, to n ra ile, to n ra ilẹ kiri. Koda, ko jẹ angẹli ni wọn gbe wa lati ọrun ko waa ṣewadii ọrọ yii, ko si ki tọhun ma ri kinni kan sọ nipa Fayọṣe. Ẹsin alatọsi ko si lọwọ okobo, ole ko gbọdọ maa pe ole lole, ki akowo-ẹgbẹ-jẹ maa bu ọlọpaa pe o n le ọmọ onimọto kaakiri. Magu ni tiẹ lọwọ o, ṣugbọn kẹnikẹni yee ki Fayoṣe naa loriki ti ko tọ si i. Nnkan buruku wa lara oun naa o jare!

 

Ẹyin DSS, ẹ ma jẹ ki wọn sinmi o, ẹ tete yaa mu wọn

O le ṣoro gan-an ki wọn too ni ki ọlọpaa mu olori ijọba kan, ṣugbọn ko si ohun to buru bi wọn ba mu awọn ọmọ iṣẹ rẹ. Nitori ọrọ ọkunrin ti wọn n pe ni Magu yii ni o. Aṣiri ti tu bayii pe Magu n jale, Magu to n mu awọn ole, oun naa, ogboju ọlọṣa ni. Ṣe ti ile rẹpẹtẹ ti wọn ka mọ oun nikan lọwọ leeyan yoo sọ ni, tabi ti owo buruku ti wọn lo mọ nipa ẹ, tabi ti awọn ile rẹpẹtẹ ti wọn n ṣẹ si i lọrun. Ṣugbọn bi Magu ba gbe gbogbo Naijiria lọ, eeyan ko le ba a wi, awọn ti wọn yan an sipo ni wọn lẹbi. Ohun to ṣẹlẹ yii ta abuku ijọba Buhari pupọ, o si fi ijọba naa han bii ijọba ti ko mọ ohun to n ṣe rara. Ki wọn too yan eeyan sipo, iwadii gidigidi ni wọn yoo ṣe lori onitọhun, ti wọn yoo mọ boya ẹni to yẹ ki wọn fi siru ipo bẹẹ ni, tabi ẹni ti ko yẹ. Ijọba Buhari naa ṣewadii, awọn ti wọn si ni ki wọn ṣiṣẹ naa ni Magu ki i ṣe ọdẹ to ṣee fi ile ṣọ, yoo ko gbogbo ẹru ile lọ ni. Bakan naa ni awọn aṣofin ilẹ yii labẹ Bukọla Saraki sọ pe Magu ko le ṣe iṣẹ amunifọba yii, nitori ọwọ oun naa ko mọ rara, wọn si yọ orukọ rẹ sẹyin, wọn ni ki Buhari mu orukọ mi-in wa ki awọn fi ọwọ si i. Ṣugbọn olori ijọba wa ati awọn ọmọọṣẹ rẹ ko gba, wọn ni dandan, Magu lawọn fẹ, bo si tilẹ jẹ pe ohun ti wọn n ṣe naa ko ba ofin mu, wọn gbe Magu sori gbogbo ọmọ Naijiria, wọn fi i ṣe olori awọn EFCC. Nigba ti Magu ti ri awọn ti wọn n ṣejọba apapọ lẹyin rẹ, to si ti mọ pe gbogbo ohun ti oun ba ṣe, aṣegbe ni, nitori awọn ti wọn lagbara ju lọ ninu ijọba lo wa lẹyin oun, oun naa bẹrẹ si i fiya jẹ gbogbo ẹni tọwọ rẹ ba tẹ, o fi awọn ole to n ji owo ko silẹ, awọn alatako ijọba Buhari lo n le kiri, bẹẹ lo si n halẹ mọ awọn ti ko ba le mu, titi dori awọn bii Ọbasanjọ, Abdusalami Abubakar, Danjuma, ati awọn mi-in bẹẹ bẹẹ lọ. Awọn eeyan sọ pe nitori Saraki jẹ ole ni ko ṣe fọwọ si orukọ Magu, bẹẹ ileeṣẹ DSS to jẹ ti ijọba lo ni ki wọn ma gba orukọ Magu wọle. Ṣe ole kuku gbe ori adunrunmọ waye, iyẹn ni ti Saraki, nitori oun naa ti figba kan wa lara awọn akowo-ilu-jẹ, eyi lẹnikẹni ko si ṣe gba oun naa gbọ rara. Ṣugbọn lasiko yii, oun lo jare, awọn ọmọọṣẹ Buhari ti wọn ti Magu lẹyin ni wọn si jẹbi. Bo ba ti waa ri bẹẹ, ohun ti ko ni i boju mu to ni ki Magu maa da jiya rẹ, nitori agbepolaja ko jale, ẹni to ba a gba a silẹ, ole loun naa. O yẹ ki wọn mu awọn ọmọọṣe Buhari naa, nitori yoo ṣoro ki wọn too sọ pe awọn ko mọ nipa gbogbo aburu ti wọn n sọ pe Magu ṣe yii. Bi awọn DSS ba mu awọn naa, ti wọn si ti wọn mọle, ti wọn ba wọn ṣẹjọ, yoo jẹ ikilọ fawọn ọga nile iṣẹ ijọba to ku, ati awọn ti wọn n bọ lẹyin, pe eeyan ki i tori ijẹkujẹ, tabi ojuṣaaju, tẹ oju ofin ilu mọlẹ, bẹẹ leeyan ko gbọdọ gbe sẹyin aṣebajẹ nibi yoowu, koda ko jẹ ọmọọya ẹni ni. Ẹ ma jẹ ki wọn sinmi o, ẹ tete yaa mu wọn.

 

Kin ni maanu pasitọ yii ra nigba wọn na

Nigba ti wọn ti mu Magu lawọn eeyan ti wọn mọ ohun to n lọ nile ijọba ti n sọ laarin ara wọn pe ko si ki ọrọ naa ma kan Igbakeji Aarẹ, Pasitọ Yẹmi Oṣinbajo. Ko si pẹ loootọ ti ariwo fi gbode pe Magu ti jẹwọ lọdọ awọn ti wọn n wadii ẹ, o ti sọ niwaju igbimọ pe oun fun Ọsinbajo ni biliọnu mẹrin Naira pe ko fi ṣararindin. Ariwo ọrọ naa di ohun to mu wahala dani, nitori gbogbo ilu lo ti fẹrẹ gba ọrọ naa gbọ tan, ko too di pe Igbakeji-Aarẹ naa gba lọọya, to ni ki wọn ba oun kọwe si ọga ọlọpaa pata, ko mu ẹni to n kọ ikọkukọ kiri nipa oun. Igba naa ni Magu paapaa ṣẹṣẹ kọwe jade pe ko sẹni to darukọ Ọṣinbajo niwaju igbimọ ti oun wa, nitori ko si ohun to pa oun ati ẹ pọ, bẹẹ ni awọn ti wọn n wadii ọrọ lọwọ oun ko darukọ Ọṣinbajo. Bi wọn ti n sọ iyẹn naa ni awọn mi-in tun gbe e jade, pe ọmo rẹ kan, …., ra ile olowo nla kan si Abuja, pe nigba to ra a, ẹgbẹrin miliọnu (800m) lo ra ile ọhun, wọn ni owo ijọba ni. Ko sẹni ti yoo gbọ pe iru ọmọbinrin yii ra ile olowo nla bẹẹ ti ko ni i beere iṣẹ to ṣe ati ibi to ti rowo to to bẹẹ, nigba ti ọmọ naa ko ti i ju ọmọ ọgbọn ọdun lọ. Bi araalu ba ri iru ile bẹẹ pe ọmọ Ọṣinbajo yii lo ra a loootọ, ko si ki wọn ma ni owo ijọba ni, pe ipo ti baba rẹ wa ni wọn lo to fi le ri iru owo bẹẹ. Ṣugbọn ọmọ yii naa ti jade, o ni oun kọ loun nile, oun rẹnti ẹ ni, bẹẹ naa si ni lanlọọdu ẹ ti jade, to ni oun loun fi ile ọhun rẹnti fun un. Ẹkọ leleyii fun awọn ti wọn n ṣejọba, pe iba ni ki awọn ọmọ wọn jaye alabata mọ, nitori ọtọ ni ohun ti wọn yoo ṣe, ọtọ ni oju ti araalu ti iya n jẹ yoo fi wo o. Ni ti Ọṣinbajo funra rẹ, oun naa yoo ti ri i pe iṣẹ pasitọ yatọ si ti oloṣelu, ati pe bi eeyan ba ba ara rẹ niru aaye bayii, yoo ṣọra pupọ lati jẹ awọn iṣẹ kan, ati lati ma ṣe sọ awọn ohun ti ko ba mọdi, ti ko si ri okodoro rẹ. Ọpọlọpọ awọn iṣẹ buruku ni wọn ti ran Ọṣinbajo ti oun naa ti lari mọ, ọpọ awọn ọrọ lo ti sọ ti ko yẹ ko tẹnu ẹ jade, nitori ko ri idi okodoro wọn. Ni bayii, wọn ti gbe e le aye lọwọ, wọn lo o, wọn si pa a ti, o wa nibẹ bii ẹni ti ko si nibẹ, wọn n ti oju ara rẹ yan an mẹbọ. Afi bii ẹni pe ọkunrin pasitọ naa ti ṣe nnkan kan fawọn alatako ẹ yii tẹlẹ, tabi o ra nnkan lọwọ wọn ti ko sanwo. Bi ọwọ ko ba ṣee ṣan, eeyan n ka a ru ni o, ki oun naa jade sita ko sọ ootọ ọrọ, ko sọ ohun to n lọ nile ijọba. Bo ba sọ ootọ, ara rẹ yoo mọ, awọn araalu si le dari ohun to ti ṣe sẹyin ji i. Ṣugbọn to ba jokoo sibẹ ti wọn jọ n ṣu irọ ta bii akara, ti wọn ro pe awọn ọmọ Naijiria ko mọ, tabi pe wọn ko gbọn, oun ni yoo fori fa eyi to ju nibẹ, nigba ti awọn Mọla ba le e jade nigbẹyin.

 

Ẹ yẹra fawọn sẹnetọ yii, Korona wa lara wọn

Agbọ-sọgba-nu ni iku ọkunrin aṣofin Eko ti wọn n pe ni Tunde Burahimọ jẹ fun gbogbo ẹni to mọ ọn pata, bẹẹ ọpọlọpọ eeyan lo mọ ọkunrin oloṣelu naa. Ọjọ rẹ ti pẹ, eeyan kan to si lawọ, to ko awọn eeyan mọra ni, gbajumọ gbaa ni. Ṣugbọn lojiji lo ku, ko si si ohun to pa  a ju Korona yii lọ. Ohun ti ọpọ eeyan ko mọ ni pe ọrẹ timọ ni oun ati aṣofin ile-igbimọ aṣofin apapọ to ku nijọsi, iyẹn Adebayọ Ọṣinọwọ, ọrẹ ti wọn ti n ṣe lati bii ọgbọn ọdun sẹyin ni. Ni gbara ti Ọṣinọwọ ku ni ọṣibitu, Tunde Burahimọ wa ninu awọn ti wọn kọkọ mọ, nitori o ti mọ lati igba ti ara rẹ ko ti ya, o si wa lara awọn ti wọn ṣe kokaari ẹ lori bi wọn ti gbe e, ati bi wọn ti sinku ẹ. Igbẹyin ni pe Korona mu Tunde Burahimọ, oun naa si ba kinni naa lọ. Nidii eyi, ko yaayan lẹnu nigba ti iroyin gbe e jade pe o le ni aadọta awọn aṣofin ti wọn ti ni arun Korona yii lara, wọn ko kan ni i jẹwọ ni. Arun naa wa lara wọn, ṣugbọn wọn o ni i jẹ sọ fẹnikan, wọn yoo maa yọ lọ si ọsibitu, tabi ki wọn ni ki wọn waa tọju awọn nile, nigbẹyin, wọn yoo ko kinni naa ran gbogbo ẹni to ba yi wọn ka. Pataki ọrọ to wa nibẹ ni pe bi eeyan ba ri sẹnetọ kan bayii, bo si jẹ ọmọ ile-igbimọ aṣofin ni, keeyan yẹra fun wọn o, ko si yee ṣe yọnda yọnda kiri lẹgbẹẹ wọn. Bi bẹẹ kọ, tọhun yoo ko arun yii, oun ko si ni i mọ ibi ti oun ti ko o. Ọpọ eeyan larun Korona wa lara wọn, nitori lojoojumọ ni iroyin n sọ pe kinni naa n ran kiri ni Naijiria, bi a si ti n sọrọ yii, o ti le ni ẹgbẹrun mọkanlelọgbọn ti kinni naa ti mu ni Naijiria tiwa. Bẹẹ ni Korona naa ko ba ẹnikan ṣọrẹ, ki ọlọmọ kilọ fọmọ rẹ ni. Ẹ yẹra fun sẹnetọ, ẹ tiẹ yẹra fawọn oloṣelu yii, ohun to wa lara wọn o daa!

 

Ṣe ijọba yii mọ ohun ti wọn n ṣe bayii ṣa?

Eto tijọba Buhari yii maa n ṣe, eto naa ki i ba ara wọn mu, ọpọ igba lo si maa n da bii pe ijọba naa ko mọ ohun ti wọn n ṣe. Minisita fun eto ẹkọ, ati awọn ti wọn n ṣeto ki Korona ma muuyan kiri ni wọn jọ kede, ti wọn ni awọn ọmọleewe kan yoo wọle lati lọọ ṣedanwo aṣekagba wọn. Iyẹn ni pe awọn ti wọn fẹẹ jade iwe mẹwaa yoo lọọ ṣedanwo wọn pari, wọn yoo ṣe Wayẹẹki (WAEC), ti wọn yoo fi wọ ileewe giga, bẹẹ ni awọn ti wọn fẹẹ jade iwe mẹfa naa yoo ṣedanwo ipari, ati awọn ti wọn fẹẹ bọ sileewe girama kekere lọ sileewe girama agba. Eeyan yoo ro pe ijọba to kede iru eto bayii ti ṣe ohun gbogbo ni ṣẹpẹ ni, pe wọn ti mọ ọna ti wọn yoo gba ti ko fi ni i si ewu fun awọn ọmọ ti wọn fẹẹ ṣedanwo yii. Ṣugbọn lojiji ni ijọba yii kan naa tun pada wa pe awọn ko ṣi ileewe mọ, ki gbogbo ọmọọleewe jokoo sile wọn, bẹẹ ni ko ni i si idanwo oniwee mẹwaa lọdun yii rara. Ko si Wayẹẹki, kawọn ọmọ maa ṣere nile wọn. Ọrọ naa ka awọn aṣofin Naijiria lara, wọn ni bawo ni ijọba yii ṣe n ṣe ṣegeṣege bayii. O dun Atiku Abubakar paapaa, o loun ko mọ ohun to rọ lu ijọba yii rara. Bẹẹ lawọn Ẹgbẹ Afẹnifẹre sọrọ, ati awọn eeyan gidi mi-in lawujọ. Ohun ti gbogbo wọn n sọ naa ni pe ijọba yii ko leto rara, wọn ko mọ ohun ti wọn n ṣe ati ohun to n ṣe wọn. Ki wọn too jade bayii waa kede pe awọn fẹẹ ṣi ileewe, ṣebi o yẹ ki wọn ti ṣe awọn ayẹwo gidi, ki wọn si ti gbe eto kan kalẹ laaye ara wọn. Ikede ti wọn ṣe gbẹyin yii fi han pe wọn ko leto, wọn kan n figba kan bọkan ninu ni. Ki i ṣe Naijiria nikan ni iṣoro kofiidi yii wa, ṣugbọn kaluku aṣaaju ni wọn n wa ọna abayọ fawọn eeyan tiwọn. Awọn ọmọ Amẹrika n kawe nile, idanwo wọn ko yingin, bẹẹ ni awọn ọmọ ọpọ orilẹ-ede, lori ẹrọ ayelujara ni wọn ti n ṣe e. Awọn ti ko ni ẹrọ ayelujara ti ṣeto lati ri i pe awọn ọmọleewe ko sun mọ ara wọn. Awọn ọmọ ti wọn fẹẹ ṣedanwo ko to ida mẹwaa awọn ti wọn wa nileewe, ki lo waa de ti apa ijọba wa ko ka a. Nnkan ti n daru mọ ijọba yii lọwọ pupọ ju, afi bii pe awọn ti wọn wa nibẹ ko mọ nnkan kan loootọ ni. Eleyii ga o jare.

Leave a Reply