O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Lori ọrọ SARS yii, ẹ sọ fun Buhari ko rọra, ilẹ n yọ

Bii ere ni kinni naa bẹrẹ, ṣugbọn nibi ti ọrọ yii n lọ yii, afi ki Aarẹ Muhammadu ̃Buhari ati awọn ti wọn jọ n ṣejọba rẹ yii rọra, ki wọn ṣọra gidigidi, bi bẹẹ kọ, nnkan le bajẹ mọ wọn lọwọ kọja ohun ti wọn n ro lọkan yii o. Awọn ọdọ ti wọn n ṣe iwọde lori ọrọ SARS ti gbe ọrọ naa kọja ibi ti ẹnikẹni ro, bi ijọba ba si n ṣe agidi tabi mẹbẹmẹyẹ, ti wọn jokoo sidii ẹtan ti wọn ti maa n fi tan araalu jẹ lati ọjọ yii wa, loju wọn bayii ni nnkan naa yoo ṣe daru mọ wọn loju patapata. Awọn ọmọ yii sọ pe awọn ko fẹ SARS mọ, wọn ni awọn ọlọpaa naa n pa wọn kaakiri ni, ati pe iwa ibajẹ ati iwa ika wọn gbilẹ ju ohun ti eeyan le fẹnu sọ lọ. Gbogbo eeyan lo mọ pe ododo ni awọn ọmọ wọnyi n sọ, ohun to si jẹ ki wọn maa ṣe atilẹyin fun wọn ree. Ṣugbọn kaka ki ijọba yii gbọ, ki wọn si tete wa nnkan ṣe si i, ọgbọn ẹwẹ, etekete, ni wọn gun le, ti wọn n wa ọna lati fi tan awọn ọmọ yii ati awọn araalu, wọn fẹ ki ohun gbogbo sare pada si bo ti wa tẹlẹ, ki wọn si maa ṣe wa bi wọn ti n ṣe wa lọ. Wọn kọkọ ni awọn fagi le SARS, o tun ya, wọn ni awọn ko fagi le e; wọn tun ni awọn fagi le e lẹẹkeji, o tun ya, wọn ni awọn fi nnkan mi-in rọpo ẹ, iyẹn SWAT, ni. Kin ni gbogbo eleyii. Awọn ohun to n ṣẹlẹ yii fi han pe ijọba yii ko mọ ohun ti wọn n ṣe rara ni. Tabi ki lo wa ninu pe ti nnkan ko ba dara, tabi ti araalu ko ba fẹ kinni kan, ki ijọba pa kinni ọhun ti. Bi SARS ba dara, ko si ẹni ti yoo jade lati ta ko wọn, tabi lati pariwo pe wọn ko dara. Ṣugbọn awọn ti iya ti jẹ, awọn ti eeyan wọn ti ku, awọn ti aburu ti ṣẹlẹ si, awọn ti wọn ti di alaabọ ara lati ọwọ awọn SARS yii, gbogbo wọn lo n jade wa, ohun ti wọn si n sọ ni pe wọn ko dara rara. Eyi to si buru ju ninu ọrọ yii ni ọrọ ti ọlọpaa Sajẹnti kan sọ pe awọn maa n san owo abẹtẹlẹ, iyẹn awọn ọlọpaa, pe ki wọn jọwọ, gbe awọn lọ sinu SARS ni, nitori ko si ẹni to wa nibẹ ti ko ni i ri ṣe gidigidi laarin ọdun kan pere. Iṣẹ ijọba yoowu ti eeyan kan ba ṣe, to si ri ṣe gidigidi laarin ọdun kan, jibiti lo n lu, ole lo n ja, nitori iṣẹ ijọba yatọ si iṣẹ adani: o ni iye owo-oṣu ti oṣiṣẹ kọọkan n gba, iru owo bẹẹ ko si ni i sọ ẹnikẹni di olowo ojiji kiakia. Amọ gbogbo eeyan lo mọ pe awọn SARS tiwa yii, awọn ọmọ ọlọmọ to n rin kiri jẹẹjẹ wọn ni wọn n ji gbe, awọn ni wọn n pe ni awọn ọmọ Yahoo, gbogbo ẹni ti wọn ba ti ri ni ọmọYahoo loju wọn; bẹẹ ni ki i ṣe pe wọn fẹẹ mu ọmọ Yahoo ti wọn ba ri mu lọ sibi kan, tabi ki wọn ba a ṣẹjọ, wọn kan fẹẹ gbowo lọwọ ẹ ki wọn si fi i silẹ ko maa lọ ni. Owo ti wọn n ri yii lo n sin wọn niwin, ohun lo n jẹ ki wọn ṣiwa-hu, ohun lo n jẹ ki wọn ṣe gbogbo aṣẹmaṣe ti wọn n ṣe. Eyi ni pe ọlọpaa SARS ko si fun awọn adigunjale ti wọn tori ẹ gbe wọn dide mọ, awọn ọmọ Yahoo, ati onijibiti gbogbo lo ku ti wọn n wa kiri, ki wọn le gba owo lọwọ wọn. Ohun to n bi awọn ọdọ yii ninu ree, nitori ọpọlọpọ awọn ọdọ yii lawọn SARS n mu to jẹ iṣẹ aje ati iṣẹ oojọ wọn ni wọn n ṣe, lai ki i ṣe ọmọ Yahoo tabi 419, ṣugbọn ti awọn SARS yoo fiya jẹ wọn lai nidii nitori ki wọn le ri owo biribiri ti wọn n gba kiri yii gba lọwọ wọn. Ko si ohun ti yoo tẹ araalu, tabi awọn ọdọ yii lọrun ju ki wọn kọkọ pa SARS rẹ lọ, ki ijọba tu wọn ka patapta, lẹyin naa, ki wọn ṣe atunṣe to ba yẹ. Ṣugbọn ọrọ naa tun le le ju bayii lọ o, nitiori awọn ọdọ wọnyi ti ri i pe awọn lagbara lati da ohunkohun duro, ati lati ta ko ijọba ti kinni kan ko ni i ṣe. Nidii eyi, bi ijọba Buhari yii ko ba tete ṣọra wọn, ti wọn ba n gbọ ọrọ lẹnu awọn asọrọmagbesi oniranu to yi wọn ka, iwọde yii yoo di nnkan mi-in, awọn ọmọde yii yoo si gbajọba kuro lọwọ wọn. O ti ṣẹlẹ lawọn ibi kan ri bẹẹ, o si le ṣẹlẹ ni Naijiria yii naa, ẹni ba mọ oju Buhari ko tete sọ fun un o.

 

Sheik Yusuf Assadussunnah

Ṣugbọn ṣe ẹ gbọ ohun tawọn oniranu kan n sọ nilẹ Hausa

Ẹni kan loun aafaa, oun ojiṣe Ọlọrun, ṣugbọn ọrọ to n ti ẹnu rẹ jade lori ọrọ awọn ọdọ to n fi ẹhonu han yii, ọrọ aṣiwere lasan ni. Sheik Yusuf Assadussunnah ni ijọba Buhari lo n faaye gba rẹdẹrẹdẹ, o ni bi wọn ṣe ko awọn ṣọja jade, ti wọn yinbọn pa awọn ọmọ ẹgbẹ Shitte ni Zaria ati Kaduna nijọsi, ki wọn ko iru awọn ṣọja bẹẹ naa jade, ki wọn yinbọn pa ẹnikẹni to ba n fẹhonu han lori ọrọ SARS, o ni bi wọn ba ti ṣe wọn bi wọn ti ṣe awọn ara Kaduna nijọsi, kaluku yoo gba ile baba ẹ lọ. Nibi ti ọkunrin naa ya akuri de lẹ ri yii. Ṣugbọn ki i ṣe oun nikan lo n sọ isọkusọ bayii, awọn mi-in naa n sọ bẹẹ. Koda, awọn mi-in n leri pe awọn ko kọ ki awọn tori ọrọ yii jagun. Awọn Hausa kan ni wọn n sọ kantan kantan bẹẹ o. Ohun to si n fi han gbogbo aye pe orilẹ-ede yii ki i se ọkan naa ree, ko si igba ti a ko si ni i pin si meji. Nibi ti awọn omugọ ba ti gbara jọ si ẹgbẹ kan, ti awọn ọlọgbọn gbara jọ si ẹgbẹ keji, ajọṣe iru awọn mejeeji yii ko le gunrege. Wọn ni ki wọn fopin si SARS nitori iwa ibajẹ ti wọn n hu, awọn gomina ilẹ Hausa kan jade pe SARS daa lọdọ tawọn. Bẹẹ awọn SARS yin n pa wọn rẹpẹtẹ nilẹ Hausa yii naa o, ṣugbọn nitori pe awọn eeyan wọn ki i sọrọ labẹ aburu, ibajẹ ati iwa ika ba wọn lara mu, ohun ni aaye isọkusọ bẹẹ ṣe gba wọn, nitori bi wọn ba dan iru rẹ wo ni ilẹ Yoruba tabi ilẹ Ibo, ọrọ naa yoo le gan-an. Ko tilẹ si gomina to jẹ ṣe bẹẹ, nitori ohun to n lọ yii ye wọn. Iwọde ti awọn ọdọ Naijiria n ṣe ni orilẹ-ede yii, ṣugbọn to ti kari aye, ti wọn n ṣe e ni London, l’Amẹrika ati awọn ilu nla aye mi-in, bi ẹni kan ba waa ni oun yoo tori ẹ lọ sogun, gbogbo aye ko wa ni i sọ pe were lo n ṣe onitọhun bayii bi!  Ko sẹni ti yoo da si iru ọrọ awọn aṣiwere bayii ju Buhari ati awọn ti wọn jo n ṣejọba rẹ lọ. Ohun ti wọn ṣe fẹẹ maa fi ṣọja halẹ mọ awọn ọdọ to n ṣewọde niyi, ti wọn ni awọn fẹẹ bẹrẹ  opureṣan kan kaakiri, iyẹn awọn ṣọja ti wọn n sa fun Boko Haramu yii ni o. Wọn fẹẹ fi halẹ, tabi ki wọn fi pa awọn ti wọn n ṣewọde ni lẹnu mọ. Ṣugbọn wọn ko gbọdọ ṣe bẹẹ, bi wọn ba gbiyanju ẹ wo, kinni naa yoo mu wọn lomi. Lẹẹkan si i, ẹ kilọ fun wọn, gbogbo aye lo n wo wọn o. Bi wọn ba fi ṣọja paayan ni ilu yii lasiko yii, ọrọ naa yoo di ohun ti gbogbo aye n ba wa da si, yoo si yọ Buhari yii kuro nipo olori wa.

 

Lauretta Onochie

Bi wọn ṣe n bẹrẹ naa ree o

Kinni kan ba ijọ ba yii jẹ, iyẹn naa ni pe bi wọn ba n huwa aburu kan lọwọ, ti gbogbo ilu n pariwo, ti wọn si n mura ija, kaka ki ijọba Buhari yanju ọrọ to ba wa nilẹ, nnkan aburu mi-in ni wọn yoo tun ṣe. Lọsẹ to kọja ni ijọba Buhari yan obinrin kan pe ki wọn fi i ṣe ọkan ninu awọn kọmiṣanna fun ajọ to n ṣeto idibo ni Naijiria wa yii, iyẹn INEC, orukọ obinrin yii ni Loretta Onechi. Gẹgẹ bii ofin ilẹ wa, ko si ẹni ti ko le ṣe adari INEC, nigba ti tọhun ba ti jẹ ọmọ Naijiria, to si kawe de ibi to yẹ. Ṣugbọn ofin yii fi lelẹ pe ko si ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan, tabi oloṣelu kan, to ba fi oju han to gbọdọ jẹ oṣiṣẹ tabi adari INEC. Idi ni pe INEC lo n ṣeto idibo, bi oṣiṣẹ wọn ba si ti jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan, iru oṣiṣẹ bẹẹ yoo ṣegbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu rẹ, yoo si da nnkan ru fawọn ẹgbẹ to ku, bẹẹ ni yoo ba gbogbo erongba ijọba ati ti araalu jẹ. Ohun ti ofin ṣe sọ pe ko ni i si ọga INEC kan ti yoo jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu INEC ree. Loretta Onochie ti a wa n wi yii, ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni. Ki i ṣe pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ naa lasan, aṣaaju ẹgbẹ naa ni, nitori rẹ ni Buhari si ṣe fi i ṣe ọkan ninu awọn amugbalẹgbẹẹ rẹ nidii eto iroyin. Ipo ti Loretta wa yii, ipo to fun un lagbara lati sọrọ si ẹnikẹni to ba wu u ni, ko si si ọjọ kan ti ko ni i bu awọn ẹgbẹ PDP, tabi ẹnikẹni yoowu to ba duro nibi kan to sọ pe ohun ti Buhari tabi ijọba rẹ n ṣe ko dara. Igba kan wa to da agbada nla, to si n fi agbada naa ya fọto kaakiri, agbada naa si jẹ eyi ti wọn ya fọto Buhari nla kan bayii si, ohun to si ṣe n wọ agbada naa kiri ni lati fi han bi oun ti fẹran Buhari ati APC to. Bawo ni ijọba yii yoo ṣe waa yan iru eeyan bayii gẹgẹ bii oṣiṣẹ INEC, a waa ṣe pe eeyan gidi ti tan ni Naijiria ni. Nigba ti  awọn ti wọn n ṣejọba ba n ru ofin Naijiria bayii, ki lo de ti araalu ko ni i ru ofin naa ju bayii lọ. Awọn aṣofin ti lawọn ko ni i fọwọ si i, ki Buhari fa orukọ Loretta yọ kuro ninu awọn to fẹẹ yan si INEC, ko forukọ ẹlomi-in ti ki i ṣe oloṣelu si i. Ohun ti gbogbo awọn ijọba daadaa laagbaaye n ṣe niyi, ki awọn ti wọn n ṣejọba tiwa naa ṣe bẹẹ o.

 

Timipre Sylva

Owo ina, owo epo mọto, ẹ fẹẹ paayan ni

Lẹyin ti arun Korona to wa niluu yii n kasẹ nilẹ, ohun tawọn ijọba to wa lorilẹ-ede aye n ṣe ni lati wa gbogbo ọna ti ara yoo fi dẹ awọn araalu wọn. Awọn ijọba yii mọ pe nnkan ti bajẹ jinna fun ọpọlọpọ eeyan lagbaaye, nigba tawọn onileeṣẹ ko raaye ṣiṣẹ wọn, ti awọn ọlọja ko raaye ta, ti ọpọ awọn ti wọn si ti ni iṣẹ lọwọ tẹlẹ di alaini mọ, nitori pe wọn le wọn kuro lẹnu iṣẹ wọn. Nitori rẹ ni wọn ṣe n wa ọna ti wọn yoo fi dẹ awọn araalu lara. Nibomi-in, wọn fun wọn lowo, nibomi-in, wọn din owo-ori wọn ku, nibomi-in, wọn ni ki wọn ma sanwo ina tabi owo omi, ni awọn ibomiiran, wọn ko jẹ ki awọn ọmọ san owo ileewe rara. Eyi ti wọn ṣe to dara ju ni yiya awọn onileeṣẹ lowo, ati fifi owo diẹdiẹ si apo awọn araalu wọn, ki nnkan le tubọ tu wọn lara. Ninu gbogbo eleyii, ko si eyi ti ijọba Naijiria ri ṣe. Eto pe ki wọn fun araalu lounjẹ ti wọn ni awọn ṣe, pabo lo ja si, awọn kan fi kinni naa ko owo jẹ lasan ni. Eleyii jẹ ki inira tubọ pọ fun awọn eeyan wa. Kaka ki ijọba wa ṣe ọna idẹra fun wọn, inira mi-in ni wọn gbe wa. Lojiji ni wọn fi owo kun owo epo mọto, wọn ko si ti i kuro lori iyẹn nigba ti wọn tun fi owo kun owo ina mọnamọna, eleyii si buru ju. Tabi nigba ti eeyan ba n san ẹgbẹrun meji naira fun owo ina NEPA tẹlẹ, ti wọn waa gbe kinni naa de lojiji pe ẹgbẹrun mẹwaa ni ẹni to n san ẹgbẹrun meji tẹlẹ yii yoo san. Ọna idẹra da, bawo ni eleyii ko ṣe ni i di inira ti ko lẹgbẹ fawọn eeyan, nigba ti wọn ni ki ile ti wọn ti n san ogun ẹgbẹrun tẹlẹ maa mu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un wa. Bẹẹ ni ki i ṣe pe ina ti wọn n lo pọ si i, ohun ti wọn n lo tẹlẹ naa ni. Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ to yẹ ki wọn gba araalu, iranu ni wọn n ṣe. NEPA ni awọn yoo sun kinni naa siwaju di ọsẹ meji, bẹẹ iyẹn ki i ṣe pe wọn ko ni i fi owo kun un. Ọsẹ meji ti kọja bayii, owo ina si ti di gọboi fun araalu gbogbo. Ta waa la fẹẹ ke pe bayii, tabi ijọba yii ko fẹ idẹra kankan fawọn araalu yii ni. Ọrọ yii yoo di wahala gidi o, bi wahala ọrọ naa ba si de, apa ijọba yii ko ni i ka a. Ki wọn tete da kinni yii pada kia, bi wọn ba si ri i pe ko ṣee ṣe, ki wọn gbe ileeṣẹ NEPA fawọn aladaani to pọ, ki wọn ṣe e bi wọn ti ṣe awọn onitẹlifoonu, onikaluku yoo le ba awọn ti wọn ba fẹ ṣe. Eyi ti ijọba ati awọn ole ti wọn n pese ina mọnamọna lasiko yii n ṣe ko daa, ohun ti yoo fa biliisi si wọn lọrun ni.

Leave a Reply