O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Ewo ni Tinubu tun n wi yii o!

Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin to lọọ ṣe abẹwo si Gomina Babajide Sanwoolu l’Ekoo, ohun to si sọ ni pe awọn ti wọn ṣe iwọde ni too-geeti Lẹkki ni ẹjo lati jẹ, itumọ eyi ni pe ọlọpaa gbọdọ mu wọn, ki wọn si kawọ pọnyin rojọ niwaju awọn adajọ. Tinubu ni awọn kan lo ko wọn debẹ, awọn kan lo si n fun wọn ni jijẹ mimu nibẹ, o yẹ ki wọn wadii gbogbo wọn, bo ba si ṣee ṣe, ki ọwọ ijọba tẹ wọn. Iru ọrọ wo lo n tẹnu ọkunrin oloṣelu yii jade bayii, awọn wo gan-an si ni Tinubu n tori ẹ ṣe gbogbo ohun to n ṣe.Tabi bawo ni eeyan yoo kuku  ṣe ya alailaaanu ati ọdaju bayii! Ṣe bi Tinubu ṣe ri niyi ni abi oṣelu to n ṣe yii naa lo kuku sọ ọ da bayii! Iyẹn ni pe ohun ti awọn ti wọn yinbọn pa awọn ọmọ ọlọmọ yii ṣe daa! Iyẹn ni pe inu Tinubu dun si ohun ti Buhari ati ijọba rẹ ṣe nilẹ Yoruba! Iyẹn ni pe to ba jẹ Tinubu naa lo wa nile ijọba ohun ti yoo ṣe fun Yoruba ree! Dajudaju, pẹlu **orukọ ti Tinubu ni yii, ko ṣe dandan mọ lati maa wadii awọn ti wọn lọọ yinbọn pa awọn ọmọ ọlọmọ yii kiri mọ, Tinubu paapaa le sọ si: bi ko ba mọ awọn ti wọn yinbọn yii, o yẹ ko mọ awọn ti wọn ran wọn, nigba toun naa ti wa ninu awọn ti ko fẹran ohun ti awọn ọmọ naa n ṣe ni too-geeti yii, ileeṣẹ to jẹ ileeṣẹ ọmọ tiẹ gangan. Bo ba jẹ ibi ti ijọba oloootọ wa ni, eyi ti Tinubu fi n wadii awọn ti wọn ran awọn ọmọ yii lọ sibẹ, niṣe ni ijọba iba mu oun funra ẹ, ti wọn o ba ni ko waa ṣalaye ohun to mọ nipa awọn ti wọn yinbọn pa awọn eeyan ni Lẹkki. Ootọ ti foju han bayii, inu Tinubu ko dun si awọn ọmọ to n ṣẹwọde, o si yẹ ko ṣalaye fun gbogbo aye bi wọn ṣe ṣeto ibọn lati fi le wọn lọ. Ọlọrun ṣe e ṣọja ti lawọn ko mọ, ijọba Buhari ko sọ pe awọn mọ, awọn ọlopaa lawọn ko mọ, ṣugbọn ninu gbogbo wọn, ko sẹni kan to beere pe ki lawọn ọmọ naa n wa nibi ti wọn wa, tabi pe kin ni wọn n ṣe, afi Tinubu tiwa nikan, ẹni to n pe ara rẹ ni Aṣiwaju. Ki i ṣe awọn ọmọ wọnyi ni ọlọpaa yoo mu o, Tinubu lo yẹ ki wọn mu, Tinubu yii gan-an lo yẹ ko rojọ ni kootu agbaye, nitori oun ni ẹni akọkọ ti yoo fi han pe inu oun ko dun si ohun ti awọn ọmọ naa n ṣe. Ẹ mu Tinubu yii o, ko waa ṣalaye ohun to mọ nipa awọn ti wọn yinbọn ni Lẹkki, bi bẹẹ kọ, ipadabọ ọrọ naa yoo le ju bayii lọ.

 

Sanwo-Olu, ma jẹ ki wọn fi tiwọn ko ba tiẹ o

Bi Gomina Babajide Sanwoolu yoo ba gbọn, ti yoo si fẹ ki orukọ oun wa ninu iwe rere awọn eeyan, yoo yẹra pupọ fun gomina Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ati ọmọ rẹ, ati gbogbo ohun to ba ni i ṣe pẹlu ẹ. Loootọ, Tinubu lo fi Sanwoolu ṣe gomina gẹgẹ bii iroyin to jade daadas nigba naa, ṣugbọn Sanwoolu ni gomina Eko bayii, ki i ṣe Tinubu, ohunkohun to ba si ṣẹlẹ lasiko yii, ko sẹni ti yoo sọ pe Tinubu ni gomina Eko lasiko yii, ohun ti wọn yoo maa sọ ni pe lasiko ijọba Sanwoolu ni. Nigba ti ọrọ naa ba tilẹ pẹ debi kan, wọn ko ni i ranti orukọ Tinubu nikan mọ, Sanwoolu ati ijọba rẹ ni wọn yoo maa pariwo. Ohun ti Sanwoolu ṣe gbọdọ ṣọra ree, ki awọn ẹbi rẹ ati ọrẹ ti wọn ba sun mọ ọn si ba a sọrọ. Ki i ṣe dandan ko ṣe saa meji gẹgẹ bii gomina Eko, to ba jẹ eyi ti awọn Tinubu fi i ṣe yii naa nikan lo le ṣe, ti wọn ko ba fa a kalẹ lẹẹkeji, ko ma tori iyẹn ṣiwa-hu, tabi ko ṣe ohun ti yoo fi ba orukọ ara rẹ jẹ titi aye. Nigba ti ọrọ yii ṣẹlẹ, oun funra ẹ ti sọrọ daadaa o, o ti ṣe alaye bi oun ko ṣe mọ awọn ti wọn ran awọn ṣọja to waa yinbọn pa awọn ọdọ ni Lẹkki, o si ti sọ pe awọn alagbara to ju toun lọ lo wa nidii ọrọ yii. Gbogbo aye lo ti gbọ, wọn si mọ ohun to n ṣẹlẹ, Ṣugbọn ko ma waa jẹ ki baba ẹ nidii oṣelu, iyẹn Aṣiwaju Tinubu ba toun jẹ o, ko ma jẹ ki baba ẹ yii fi oun rugbo, nitori ipo gomina tabi ohun mi-in, nitori wahala tirẹ ni yoo da lọla. Ni gbogbo igba ti wahala yii n ṣẹlẹ, Tinubu wa nibi kan ti ko sọrọ, igba ti yoo si sọrọ bayii, ohun to sọ ni pe ki wọn wa awọn ti wọn n ṣewọde, ki wọn mu wọn lati waa sọ tẹnu wọn. Tinubu ko sọ tawọn to ku, ko si sọ pe ibọn ti wọn yin fun wọn ko daa, bẹẹ oun lo n n pe ara ẹ ni onidẹmokiresi agbaye. Ṣe bi wọn ti n ṣe demokiresi ni Amẹrika ti oun sa lọ nijọsi, ati aọwn ibom-i-n to kọle si kiri aye niyẹn. Ko si ohun ti Tinubu ṣe ti ko ni i gbẹsan ẹ lọdọ awọn eeyan to ba ya, nitori eti araalu ko di, oju wọn ko si fọ, wọn n wo gbogbo ohun to n ṣe fun wọn, nigba to ba si ya, oun naa yoo gba ẹsan rẹ lẹkun-un-rẹrẹ. Bi ẹni kan ba wa nibi kan to ba ni ko si ẹsan ti yoo gba, tọhun n tan ara rẹ ni o. Nitori bẹẹ, ki Sanwoolu ṣọra ẹ, ko ma jẹ ki ẹnikẹni ko ba a. Ko ṣe ijọba Eko pẹlu ootọ inu ati iwa ọmọluabi, ko sọ ara rẹ di ọrẹ awọn araalu, ko ma tori baba isalẹ rẹ ko sọ ara rẹ di ọta wọn. Aabọ ọrọ ni eleyii fun Sanwoolu, ẹni to ba ri i ko ṣalaye ẹ fun un daadaa.

 

Ohun to ṣẹlẹ si Ọba Akiolu gan-an niyẹn

Ẹnu ya awọn eeyan, niigba ti awọn janduku kan wọ aafin Ọba ilu Eko, ti wọn si lọọ gbe ọpa aṣẹ kabiyesi naa, ti wọn si ko ọpọlọpọ ẹru rẹ lọ. Dajudaju, ki i ṣe awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde yii ni wọn lọọ ṣe eleyii, awọn tọọgi ati janduku eeyan ti wọn ja kinni naa mọ wọn lọwọ ni. Ṣugbọn ohun meji ṣe pataki ninu ohun to ṣẹlẹ si Ọba Akiolu. Akọkọ ni pe awọn ti wọn fẹẹ maa pariwo kiri pe awọn Ibo lo lọọ gbe ọpa aṣẹ ọba naa, kia ti fidio ti jade ni wọn ti ri i pe irọ lawọn n pa. Ninu Fidio naa lo ti han pe awọn ọmọ Yoruba, awọn ọmọ Eko, nibẹ ni wọn wọ aafin Akiolu, nitori ariwo ti wọn n n pa ni pe, ‘Ọpa aṣẹ ọba ree o! Ọpa aṣẹ Olowo Eko ree o!’ Nigba ti wọn si de ibi odo-iwẹ-adaṣe to wa nibẹ, niṣe ni wọn n sọ pe ‘Ẹyin bọisi, o ya ẹ jẹ ka wẹ!’ Eleyii fi han pe ki i ṣe Ibo kankan lo waa fọ aafin Akiolu, awọn Yoruba, awọn ọmo eeria-bọisi (Area Boys) adugbo naa ni. Ọna keji ni pe bi wọn ṣe n ko gbogbo ohun ti wọn n ko lọ sita, niṣe ni awọn araadugbo n wo wọn, ti wọn si n pariwo yẹyẹ, ariwo, ‘Ọlọrun lo mu un’ le Akiolu lori, eyi to tumọ si pe inu awọn eeyan yii n dun si ohun to ṣẹlẹ si Akiolu, wọn ko si ṣetan lati ran an lọwọ tabi gbeja ẹ, bi awọn ọmọọta naa ti n ko o lẹru lọ. Kin ni eleyii tumọ si loju awọn eeyan! Itumọ eyi ni pe ọba naa ki i ṣe ẹnikan ti awọn eeyan rẹ fẹran rara, ko si ẹni kan to fẹ tirẹ ni adugbo to n gbe, ko si sẹni kan to ṣetan lati ja nitori ẹ, tabi fi ori laku fun un, nitori ko dara si wọn. Bo ba jẹ Akiolu dara si awọn eeyan rẹ ni, ko si ẹni ti yoo lọ si aafin rẹ ti yoo maa ji i lẹru ko o, bi wọn ba tilẹ debẹ, awọn araadugbo yoo dide si wọn, wọn ko si ni i le ṣe aburu ti wọn ṣe nibẹ. Ṣugbọn Akiolu ro pe owo tiwọn ni gbogbo aye wa, ati pe awọn araadugbo tabi ẹnikẹni ko tun jẹ kinni kan mọ, oun naa si n ṣe gẹgẹ bii awọn oloṣelu wa ti n ṣe. Abọ ẹ niyi o, o si yẹ ki eleyii jẹ arikọgbọn fun gbogbo ọba. Gbogbo ọba to n jade to n pe ara rẹ ni oloṣelu, ẹ jẹ wo ohun to ṣẹlẹ si Akiolu yii kẹ ẹ fi kọgbọn, nitori bo ba ṣẹlẹ tan, tiyin le buru ju ti Ọba Akiolu yii lọ o. Ikilọ diẹ to fọlọgbọn.

 

Ṣe ẹ gbọ isọkusọ tawọn aṣofin wa n sọ

Awọn aṣofin wa jokoo si Abuja, wọn ko sọ nnkan kan ni gbogbo igba ti ilu n gbona. Bẹẹ ilẹ Yoruba ni wọn lọ sibẹ lati lọọ ṣoju o, aṣofin Yoruba ni wọn n pe ara wọn. Ṣugbọn ko si kinni kan ti wọn le sọ nigba ti iya n jẹ gbogbo eeyan nilẹ Yoruboa nibi, ti awọn ọmọ wa si n foju wina ibọn awọn ṣọja. Nigba tọrọ naa ti n lọ silẹ tan, ti Ọlọrun ti gba akoso, ọrọ ti wọn le wi, ọrọ to le ti ẹnu wọn jade ni pe ki awọn kan ma sọ ilẹ Yoruba di oju ogun o. Awọn ti wọn n powe ọrọ yii mọ, awọn Ibo ni o, isọkusọ ati igbekugbee ti wọn n gbe kiri laarin ara wọn ni pe awọn Ibo lo n da wahala silẹ nilẹ Yoruba, awọn ti wọn jẹ ọta wa gan-an, awọn Mọla, to ti yi wa ka, ẹnu wọn ti wuwo ju lati le sọ ọ loju Buhari tabi lẹyin ẹ pe awọn Mọla ni ọta wa, awọn Fulani ati Hausa to wa nilẹ Yoruba bayii ni. Awọn ni wọn fẹẹ dọgbọn da si ija to n lọ yii, ki wọn le ri jẹ ninu madaru naa to ba ṣẹlẹ, ki wọn si le fi pa awọn Yoruba nipakupa. Bo ba jẹ ohun ti wọn fẹẹ ṣe ni agbegbe Fagba, ni Iju, l’Ekoo, ṣee ṣe fun wọn ni, eyi ti a n sọ yii kọ la ba maa sọ, nitori ohun ti yoo ṣẹlẹ nilẹ Yoruba yii, apa ki ba ti ka a rara. Nibo ni wọn ti waa ri ọmọ Ibo ninu ija to kọja lọ yii o? Awọn janduku ti awọn oloṣelu n lo laarin ara wọn, awọn ti wọn mọ ile wọn, ti wọn mọ ibi ti awọn oloṣelu yii n ko ẹru ati owo ti wọn n ji lọwọ araalu si, awọn naa ni wọn n pada lọọ kọ lu wọn, ti wọn si n ko wọn lẹru lọ, ki i ṣe Ibo tabi ẹya mi-in. Awọn aṣofin wa ko riran ri gbogbo eleyii, oṣelu ti ko wọn ni laakaye lọ. Ohun ti wọn ṣe jokoo si Abuja ti wọn n sọ isọkusọ ree, nitori ti wọn ko fẹ ki ọna ounjẹ wọn di. Awọn eleyii ki i ṣe aṣofin wa, bẹẹ ni wọn ki i ṣe aṣoju awọn eeyan, awọn alaimọkan ni wọn pọ ninu awọn ti wọn ni ki wọn maa ṣoju wa. Ọlọrun yoo yọ wa lọwọ wọn. Amin.

 

Nigba ti ẹlẹṣẹ ba n jiya …

Ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii fihan pe loootọ lọrọ pe bi ẹlẹṣẹ ba n jiya, awọn olododo yoo pin nibẹ. Awọn janduku ti wọn fi ọrọ awọn ọdọ to lodi si awọn ọlọpaa SARS kẹwọ, ti wọn n ji awọn eeyan lẹru ko, ti wọn si n ba dukia wọn jẹ. Ile awọn oloṣelu ni wọn ro pe awọn n lọ, ṣugbọn awọn mi-in ki i ṣe oloṣẹlu, awọn oniṣowo ati eeyan ti wọn n ṣiṣẹ wọn jẹẹjẹ ni. Bẹẹ awọn oloṣẹlu yii lo ko ba awọn araalu wọnyi. Ẹ wo ohun ti wọn ko pamọ, ẹ wo ounjẹ araalu ti wọn tilẹkun mọ. Loootọ, ko dara lati fipa ko ẹru ati ohun-ini ẹlomi-in, ṣugbọn awọn oloṣelu yii ni wọn kọkọ fi biro ko owo ati ẹru awọn araalu wọnyi lọ. Wọn ko ounjẹ wọn pamọ, wọn ko ẹru ti i ba ṣe wọn lanfaani lọ. Wọn si ro pe awọn yoo ṣe iru eleyii gbe! Nigba wo ni Ọlọrun ko ni i mu gbogbo wọn. Ohun ti awọn oloṣelu yii n ṣe ni gbogbo araalu foju ri yii, o si han loootọ pe awọn ẹni ibi lo pọ ju laarin wọn. Ki awọn ti wọn ki i ṣe oloṣelu ti ẹru wọn sọnu ma binu, ki wọn mọ pe iya ilu lawọn jẹ, Ọlọrun yoo si fi ọpọ rọpo fun wọn. Ni ti awọn oloṣelu yii, iya wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, kekere ni wọn ri yii, eyi to ju bẹẹ lọ n bọ, ki wọn mura silẹ, apa wọn ko ni i ka a bo ba ṣẹlẹ, tiran-tiran ni wọn yoo jiya naa bọjọ ba pe. Bẹẹ ọjọ naa ti fẹrẹ pe tan, ẹ jẹ ki wọn mura si aburu ti wọn n ṣe fun araalu, ọjọ ẹsan wọn ko jinna rara.

3 thoughts on “O ṣoju mi koro (Apa Keji)

  1. Oro asiwaju yii ti koja afenuso, ohun gbogbo ye olorun, oro orile ede yii ti di ki olori di ori re mu, sugbon ifura loogun agba, bi ara Ile eni o baa gbabode,ara ita o ni ko ni leru.

  2. Enikan olefi ara re joye lori ilu kan laisepe ilu lowoye awokose rere lara onitoun nigbanaa wonle fije oye sugbon talo fi tinubu je asiwaju atipe kilonje jagaban oye iruwo niyen?

    *Asiwaju daada koni mase atako tabi inunibini eni,an
    *Asiwaju ki yan fun aralu adari ti wonfe ni ipinle won, paapa ni ipinle eko, mayan fun wa mo
    *asiwaju ki sawole tabi pinroro nigbati aralu nfi ehunu han
    *asiwaju kan koni lanu kosope kini aralu sewa bere ounti wonfe, lekki ki sha se ojude tinubu , oun ko loma sope a won wo lo ran aralu lati bere oun tootosi.
    *Akise malu fulani bi wonsebi ni wonsebi awanaa, aodeti oun rinwa omo bibi ilu eko joniwa, komala lewa lowo mo too O TO GE!

Leave a Reply