Irọ wo lo ku ti Sanwo-Olu tun fẹẹ pa o
Ibeere pataki ni. Pe irọ wo lo ku ti Sanwo-Olu tun fẹẹ pa? Ọga awọn ṣọja to wa ni Bonny Camp, ti jade wa, Ahmed Taiwo lorukọ ẹ, o ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, lo pe awọn, ati pe inu awọn ko dun rara pe Sanwo-Olu jade lati maa sọ pe oun ko pe awọn. Ṣe ẹ ri i, bi ọrọ ba da bayii, ti ijangbọn tabi rogbodiyan ba de si aarin ilu, ojuṣe gomina ibẹ ni lati wa gbogbo ọna ti iru rogbodiyan bẹẹ yoo fi lọ. Nigba mi-in, o ṣee ṣe ko jẹ awọn ọlọpaa ni wọn yoo ranṣẹ si lati gba wọn, igba mi-in, o si ṣee ṣe pe awọn ṣọja ni wọn yoo bẹ lọwẹ. Ṣugbọn gomina ti yoo ṣe bẹẹ, ti yo pe ọlọpaa tabi ṣọja lati ba a pana rogbodiyan araalu, o gbọdọ jẹ gomina to mọ ohun to n ṣe, to mọ ohun to n lọ, to si mọ idi to fi pe awọn agbofinro yii pe ki wọn waa gba oun. Ṣugbọn Sanwo-Olu ṣe aṣiṣe nla, nitori bi ọrọ ba ri bo ti ri yii, ki i ṣe awọn ṣọja ni wọn n pe, wọn maa n lọọ ba awọn to n ṣewọde yii sọrọ ni, wọn yoo si wa ọna lati ri awọn to dari eto naa, ki wọn le pẹtu si wọn ninu, ki wọn si tu wọn ka. Bi eleyii ko ba ṣe, wọn yo lọọ ko awọn ọlọpaa wa, awọn ọlọpaa yii ko ni i yinbọn, tajutaju lasan ti to lati tu awọn ọdọ ti ko gbebọn, ti wọn ko mu ada tabi ohun ija kankan lọwọ yii. Ko si bi wọn ti le pọ to ti tajutaju ati ibọn onirọba ko ni i le wọn lọ. Ṣugbọn aṣilo agbara lo mu Gomina Sanwo-Olu, ohun to si jẹ ko ro pe ṣọja lo le yanju ọrọ to wa nile naa niyi. Ni oun ba fi ranṣẹ si wọn. Ṣugbọn ṣọja ki i lọ si ode alaafia, ohun to yẹ ki gomina yii ti mọ niyi, ode yoowu ti wọn ba lọ, ode ijangbọn ni. Ode iku! Iru ẹ naa lo si ṣẹlẹ yii. Eyi to waa buru ninu gbogbo ọrọ yii ni irọ ti Gomina yii n pa. O ti ṣe e, o ti ṣe e na, ọrọ si ti ja si ibi ti oun paapaa ko ro, ko si si ohun meji to le ṣe lẹyin ẹ mọ ju ko ba araalu sọrọ, ko si tuuba lọ, ko si jẹ ki wọn mọ pe oun ṣe aṣiṣe ni ọọkan ibẹ yẹn, ati pe iru aṣiṣe bẹẹ ko ni i waye mọ. Sanwo-Olu ko ṣe eleyii, kaka bẹẹ, o n puro mọ irọ ni. Irọ naa lo ja bayii o. Nitori ẹ naa la ṣe n beere: Irọ ewo lo waa ku ti Sanwo-Olu fẹẹ pa o. Ko sirọ kan ti yoo pa ti yoo niyi mọ. Ohun to yẹ bayii naa ni ko jade sita, ko sọ ohun to ṣẹlẹ gan-an fun gbogbo ilu, ko si tuuba, ki gbogbo ilu si fori ji gomina wọn. O ya, Sanwo-Olu, gbogbo aye n reti rẹ o!
Owo tawọn gomina to ti fẹyin ti n gba, ijẹkujẹ ni
Ohun kan ti Gomina Sanwo-Olu fẹẹ ṣe to dara gan-an, ti awọn aṣofin Eko naa si gbọdọ fọwọ si i, ni lati gbegi le owo-oṣu ati awọn ajẹmọnu ọran ti awọn gomina to ti fẹyinti n gba ni ipinlẹ wọn. Owo naa ko daa rara, awọn ohun tawọn si sọ pe ki wọn maa ṣe fun wọn ki i ṣe ohun to ṣee gbọ seti. Bi eeyan kan ba ti jẹ gomina tan, wọn ni wọn yoo maa ra mọto tuntun meji meji fun un lọdun mẹta mẹta, wọn yoo maa ran an lọ siluu oyinbo ko lọọ gba itọju lọdọọdun, wọn yoo kọle fun un l’Abuja ati l’Ekoo, wọn yoo ko awọn ọlọpaa fun un, wọn yoo maa sanwo gbogbo awọn oṣiṣẹ to ba wa nile ẹ, wọn yoo si jẹ ko maa ko awọn ọlọpaa to n lo lọ. Ijọba ni yoo si maa sanwo gbogbo eleyii o, bẹẹ lo jẹ owo-oṣu ti gomina to ba wa lori oye ba n gba lawọn naa yoo maa gba. Nitori pe wọn ṣe gomina fọdun mẹjo! Bẹẹ ni ko si iru anfaani bayii fun awọn oṣiṣẹ to fi ọdun marundinlogoji wa nibẹ, to jẹ ati gba owo ifẹyinti wọn gan-an, wahala ni. Ki waa ni gomina yoo maa gba iru owo buruku bayii lọwọ ipinlẹ kọọkan bayii. Bi Eko ti ṣe naa ni awọn ipinlẹ mi-in tẹle e, o kan jẹ Bọla Tinubu lo ṣaaju lasiko naa ni. Nitori naa lo ṣe yẹ ki eeyan ki Tinubu naa, nitori o ti sọ pe oun naa fara mọ ki ijọba Eko gbegi le owo ifẹyinti yii. Tinubu naa ti jade, o si ti ri i pe ohun tawọn ṣe ko dara, iwa irẹjẹ ati ika lo jẹ fun awọn araalu. Ṣugbọn bo ṣe ẹlomi-in naa ni, yoo tubọ maa ṣe agidi ni, yoo ni owo awọn ni, awọn aṣofin ọjọsi si kuku ti fọwọ si i. Nigba ti Tinubu waa sọ pe oun ti fara mọ ọn yii, ko si aṣofin kan to gbọdọ ni oun ko ni i fọwọ si i. Afi ki wọn fọwọ si i, ki irẹjẹ owo ti awọn gomina atijọ yii n gba lọwọ araalu si dopin kia. Ki gbogbo eto naa kari ilẹ Yoruba pata paapaa, nitori gbogbo wọn ni wọn ni owo ọran bayii ti wọn n gba lọwọ ijọba. Sanwoolu ṣe eleyii daadaa o, ki gbogbo gomina to ku yaa sare tẹle e.
Bẹẹ ki i ṣe Fayoṣe ni yoo ba tawọn PDP yii jẹ ṣaa
Awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu PDP ti ilẹ Yoruba nibi ṣepade wọn lọsẹ to kọja niluu Ibadan, labẹ Gomina Ṣeyi Makinde to yẹ ko jẹ olori pata fun ẹkun yii, gẹgẹ bi gomina ẹyo kan naa to wa nibẹ. Nibẹ ni wọn ti yan Ọlagunsoye Oyinnlọla bii alaga igbimọ ti wọn ni ko pari ija to wa laarin awọn aṣaaju ati awọn ọmọ ẹgbẹ naa kaakiri ilẹ Yoruba yii. Amọ bi awọn ti ṣepade tiwọn, ki wọn too kuro naa ni Ayọdele Fayoṣe ti i ṣe gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ naa gbe igbimọ tirẹ mi-in dide, o ni ipade awọn aṣaaju PDP niyi. Nibi ipade tiwọn yii, ko si gomina PDP kan, ko si awọn aṣofin, oun naa kan ko awọn kan jọ, o ni awọn ni aṣaaju ẹgbẹ naa. Awọn iwa ti Fayoṣe n hu ninu ẹgbẹ yii lati ọjọ yii ko fi i han bii aṣaaju daadaa fun ẹgbẹ wọn, iwa awọn eeyan ti wọn n pe ni pọn-tan-o-rudo ni, nitori oun ti pọn omi tirẹ tan, o si bẹrẹ si i da odo ru fun awon mi-in ti wọn fẹẹ pọnmi. Fayoṣe ti ṣejọba, nigba to si n ṣe gomina, oun ni olori ẹgbẹ wọn, tori oun nikan naa ni gomina PDP. Lati igba to ti waa kuro nijọba ni wahala ti bẹrẹ. Akọkọ ni pe ko fi ori fun ẹni to yẹ ko jẹ olori ẹgbẹ naa ni ipinlẹ tirẹ gan-an, iyẹn obinrin kan sṣoṣo to jẹ sẹneto lati ọdọ wọn, Abiọdun Olujimi. Ẹẹkeji ni pe ko gba fun awọn ti wọn jẹ olori ẹgbẹ naa ni agbegbe ilẹ Yoruba. Gbogbo ibo ti wọn di kọja lorukọ ẹgbẹ naa, ko yọju sibẹ, ko si ṣe atilẹyin kankan fun wọn. Lati waa gbe igbimọ mi-in kalẹ yatọ si eyi ti awọn ti wọn jẹ olori ẹgbẹ naa gbe dide, ọna lati ba ẹgbẹ naa jẹ pata ni. Idi ti Fayọṣe si ṣe n ṣe eleyii, oun nikan lo ye. Bi ohun yoowu ba wa laarin wọn to jẹ ede-aiyede, ko si ohun to buru ki Fayoṣe sun mọ awọn to ku ki wọn si yanju ẹ, nitori bi ẹgbẹ naa ba fọ, ko ṣe ẹnikẹni lanfaani ninu wọn. Ati pe ko ṣe apọnle foun naa, nitori wọn yoo ri i bii ọbayejẹ, adanikanjẹ, ati agufọn lasan. Bẹẹ, ẹgbẹ PDP ṣe pataki nilẹ Yoruba gẹgẹ bii ẹgbẹ alatako, nitori ko si ibi ti ẹgbẹ oloṣelu kan ṣoṣo ba ti n ṣejọba ki i dara. Bi APC ba wa nibẹ, ti wọn n ṣejọba lọ, ti ijọba wọn ko tẹ araalu lọrun mọ, o yẹ ki ẹgbẹ mi-in wa ti araalu yoo le dibo wọn fun. Ati pe bi APC naa ba mọ pe PDP wa nipo alatako awọn, wọn yoo ṣe ijọba daadaa. Ki waa ni Fayoṣe yoo da ẹgbe naa ru si! Kin ni Fayoṣe n fẹ gan-an! Eyi to n ṣe yii ko le fun un lorukọ rere, nitori bo ti n ṣe yii, afaimọ ko maa ba ti PDP jẹ nilẹ Yoruba patapata.
Ki Ọlọrun fun Dapọ Abiọdun ṣe
Ọkan ninu awọn ironu to daa gan-an, ti yoo ti ọdọ Ọmọọba Dapọ Abiọdun, Gomina ipinlẹ Ogun, ati awọn ti wọn jọ n ṣejọba rẹ jade ni pe ki wọn sọ aṣọ adirẹ di aṣọ ti awọn ọmọ ileewe yoo maa wọ ni ipinlẹ naa, jake-jado. Eyi ni pe aṣọ awọn ọmọleewe yoo kuro ni Kaki, yoo si di aṣọ adirẹ. Nigba ti ipinlẹ kan ba mọ ohun ti oun ni, ti oun le fi ṣe owo, ohun to dara ju ni ko lo ọna naa, nitori eyi ti gomina naa ṣe yii yoo mu owo nla wa fun ipinlẹ rẹ, owo naa yoo si ya oun paapaa lẹnu. Nigba ti adirẹ ba di ohun ti awọn ọmọleewe n wọ, awọn olowo ati ọlọla naa yoo wa oju adirẹ mi-in ti wọn yoo maa wọ. Awọn ti wọn si nile aṣọ adirẹ yii yoo pọ si i. Bi awọn ti wọn nile aṣọ adirẹ yii ba ti n pọ si i, bẹẹ ni awọn ti wọn n ṣe yoo si maa pọ si i, awọn mi-in yoo si da ileeṣẹ adirẹ silẹl lọpọ yanturu. Ọna owo nla kan ni funjọba, nitori ko ni i yaayan lẹnu bi awọn ara ilẹ okeere ba n wa lati waa ra aṣọ naa lọ sọdọ wọn. Ki Gomina Abiọdun ma duro sidii eyi nikan o, ko tubọ pa a laṣẹ ki awọn ti wọn n ṣejọba ati awọn oṣiṣẹ ijọba naa maa lo adirẹ, paapaa wa sibi iṣẹ wọn. Ki awọn ti wọn fẹẹ fi da ṣẹẹti fi da a, ki awọn ti wọn si fẹẹ fi da buba fi da a, ko ṣaa ti jẹ aṣọ to ba ibi iṣẹ mu. Lara ohun ti wọn n sọ fawọn gomina gbogbo ree, pe inu ile wọn ni ki wọn wo, ki wọn wo ohun to wa ni ipinlẹ wọn ti awọn naa le ṣe, eyi yoo mu owo irọrun wa fun wọn, yoo si mu nnkan rọrun fawọn eeyan wọn naa, gbogbo ilu yoo si maa gbadun labẹ ijọba wọn. Eyi ti Dapọ Abiọdun fẹẹ ṣe yii daa o, ki gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun dide ran an lọwọ, ki oriire to wa nibẹ le jẹ ti gbogbo wa.
Dangote lo ku ti yoo jogun Naijiria, abi?
Ni ọsẹ to kọja yii, ijọba orilẹ-ede wa, labẹ alaṣẹ Muhammadu Buhari, faaye gba ileeṣẹ Dangote pe ki wọn maa ko ọja wọn lọ si awọn ibi yoowu ti wọn ba ti fẹẹ ta a kaakiri orilẹ-ede Afrika, paapaa ni Nijee (Niger Republic) ati Togo. Ibeere to wa ninu igbesẹ yii ni pe ki lo de ti ijọba Buhari fẹẹ sọ gbogbo Naijiria di ti ileeṣẹ Dangote nikan. Ki lo de ti ijọba Naijiria n mu awọn onileeṣẹ ati awọn olokoowo to ku lọwọ dani ki ileeṣẹ Dangote le kọja, ko si jere ju awọn to ku lọ. Ki lo de ti ijọba Buhari n pa awọn ileeṣẹ to ku ni Naijiria nitori lati gbe Dangote ga. Nigba ti korona wa nita, ti ijọba ṣe ofin konilegbele, Dangote nikan lawọn Buhari fun laaye pe kawọn mọto ẹ maa rin lọ, ki wọn maa rin bọ, ki wọn maa ba iṣẹ tiwọn lọ. Awọn onileeṣẹ nla nla mi-in wa nibẹ, awọn bii Lever Brothers, UAC, Cadbury, Nestle, Guiness, Nigerian Breweries ati awọn ileeṣẹ bẹẹ bẹẹ lọ wa niluu, awọn naa n ṣowo, awọn mi-in si wa to jẹ ounjẹ jijẹ to wulo fun gbogbo ilu nikan ni iṣẹ tiwọn. Ṣugbọn awọn Buhari ko fun wọn laaye lati rin loju titi, afi Dangote nikan. O ti le lọdun kan sẹyin ti ijọba Naijiria ti ti gbogbo ẹnubode orilẹ-ede yii pa, ti wọn ko si jẹ ki ọja kankan wọle tabi jade, paapaa lati awọn ilu to ja si ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo. Titi di asiko yii, wọn ko ti i ṣi bọda naa. Ṣugbọn lọsẹ to kọja ni ijọba ṣe ofin yii pe ki Dangote maa lọ ko maa bọ lawọn bọda ti wọn ti ti pa yii, ko maa ko ọja wọle ko maa ko ọja jade. Ṣe iru eleyii daa ni. Nigba ti gbogbo aye pariwo, awọn Buhari tun fun ẹlomi-in laaye, ọmo Hausa kan to ni ileeṣe BUA, wọn ni koun naa maa ko ọja rẹ jade lẹnubode bii ti Dangote, ki gbogbo aye le mọ pe ki i ṣe Dangote nikan lawọn ṣe bẹẹ fun. Ati Dangote ati BUA, ọmọ Kano, nilẹ Hausa, lawọn mejeeji! Aṣe pe ko si oniṣowo ati awọn ti wọn ni ileeṣẹ nilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo bi? Ki lo de ti Buhari n ṣe bayii! Ki lo de ti awọn eeyan yii n fi ẹlẹyamẹya ṣejọba, tabi wọn ti ro pe ileejọba yii lawọn yoo ku si ni! Eleyii o daa! Irẹjẹ yii ṣẹ n pọ ju, ohun ti yoo ti ẹyin rẹ jade ko le daa o! Ẹni to ba leti ko yaa gbọ.