O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Sanwo-Olu, eleyii daa bẹẹ, ẹ jẹ konikalulu ke pe Ọlọrun ẹ

Awọn onileejọsin gbogbo yoo bẹrẹ ijọsin wọn pada lati ọjọ Jimọ ọsẹ yii. Awọn onimọṣalaaṣi yoo lọ si mọṣalaasi, awọn oniṣọọṣi naa yoo si lọ. Nigba iṣoro bayii, ko si ohun to dara ju bii ki eeyan ke pe Ọlorun. Iṣọro to ba de ti eeyan ko raaye ke pe Ọlọrun, tabi ṣe akojọpọ lati sin Ọlọrun, iṣoro nla gbaa ni o. Iru ẹ si ni ti Korona yii. Ni ọpọ igba ni awọn ẹlẹsin Kristẹni ati awọn ti Musulumi ti ba ijọba ja loriṣiiriṣii, awọn mi-in si sọ pe bi awọn ba lọ si ile ijọsin, ti Korona ba mu awọn nibẹ, ti awọn ku, o da awọn loju pe ọrun rere lawọn n lọ. Wọn ni ki ijọba fi awọn silẹ ki Korona pa awọn, ki wọn ṣaa ti jẹ ki awọn ṣejọsin fun Ọlọrun awọn. Ki i ṣe pe ijọba Naijiria nikan ni, ohun to n ṣẹlẹ kari aye nigba naa ni, ati oku to n ku, ti gbogbo eeyan n gbọroyin rẹ, ko si ijọba gidi kan ti yoo laju silẹ ti yoo fẹ ki awọn eeyan ku rẹpẹtẹ bi a ti gbọ ti wọn n ku ni Amẹrika, ku ni Brazil ati awọn orilẹ-ede mi-in bẹẹ yii, nitori bi kinni naa ba bẹrẹ, o le re kọja ibi ti awọn eeyan foju si patapata. Ṣugbọn nnkan naa n lọ silẹ diẹdiẹ bayii, o si da bii pe eyin ajakalẹ arun naa ti kan, paapaa ni awọn orilẹ-ede bii ti ọdọ wa nibi. Ajẹsara ati bi oju ọjọ ti ṣe maa n ri lọdọ tiwa yii ti jẹ ko han pe kinni naa ko ni i lagbara rẹpẹtẹ kan lọdọ tiwa yii, paapaa bi a ba le tẹle awọn ofin keekeeke tijọba ṣe. Aṣẹ ti ijọba Eko pa yii, pe ki awọn eeyan bẹrẹ ijọsin wọn dara gan-an ni, yoo jẹ ki ọkan onikaluku fuyẹ, nigba to jẹ pupọ ninu wa lo nigbagbọ ninu agbara adura ati ikepe-Ọlọrun ẹni. Kaluku yoo ribi gbadura bayii, yoo si le fi ẹnu ara rẹ tọrọ ohun to ba n fẹ. Nidii eyi, ijọba ti ṣe tiwọn o, wọn si ti ṣe bo ṣe yẹ ki wọn ṣe loootọ. Eyi to ku ku sọwọ araalu o. Ka ma ro pe ko si arun yii loootọ, Korona yii wa, o wa daadaa paapaa. Ṣugbọn awọn miiran ninu wa ti jẹ oriṣiiriṣii ewe ati egbo, bẹẹ la ni okun-ara to lagbara, to le pa arunkarun to ba wọ agọ ara wa. Ṣugbọn ki i ṣe gbogbo wa lo ri bẹẹ fun, awọn mi-in wa laarin wa to jẹ hẹgẹhẹgẹ lara wọn. Wọn ko ni ajẹsara to to, ara wọn ko si ni okun to le koju iru arun bẹẹ. Eyi lo ṣe jẹ to ba kọlu wọn, ọrun lẹrọ ni. Ṣugbọn a le dena ẹ, a le kapa ẹ, nigba ti a ba ti tẹle ofin ti wọn fun wa. Ka bo imu wa, ka si jinna si ara wa daadaa nibi ti a ba ti n ṣe ijọsin wa. Korona ko ni i mu wa, bẹẹ ni a ko ni i ba wọn ku iku ajọku, ṣugbọn ki awa naa ṣọra wa o.

 

Kin ni awọn aṣofin Kwara n ṣe bayii si

Ni Ọjọruu to kọja lọ, ile-ẹjo ko-tẹ-mi-lọrun to jokoo si ilu Ilọrin dajọ pe ẹgbẹ APC ko ni oludije fun ipo ile-igbimọ aṣofin lati agbegbe Ilọrin South, ninu ibo ti wọn di ninu oṣu kẹta, ọdun to kọja, nitori bẹẹ, ki wọn ṣebura fun ọmọ ẹgbẹ PDP to wọle ibo naa, iyẹn Rahem Agboọla, ki wọn si le Azeez Elewu ti ọmọ ẹgbẹ APC ti fi tipatipa gbe sori ijokoo naa kuro nile-igbimọ kia. Iyẹn nikan kọ, gbogbo owo-oṣu ti ọkunrin APC yii ti gba ni wọn ni ko da pada, ko da a pada, nitori owo ti ko tọ si i lo n gba lati ọjọ yii, ko si kinni kan to kan an lati jokoo sile-igbimọ aṣofin Kwara. Ọrọ yii ko ba ti da bayii, bo ba jẹ alaga ile-igbimọ aṣofin naa, Yakubu Danladi, tẹle ofin ile-ẹjọ, to si tẹle ofin Naijiria. Ṣugbọn ọkunrin naa nigbagbọ pe nigba to ti jẹ APC lo n ṣejọba, to si jẹ awọn ti awọn wa ninu APC lawọn n tẹ oju ofin mọle yii, ko si ohun ti ẹnikan le ṣe fawọn. Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ, eto ijọba awa-ara-wa ko si ri bẹẹ rara. Lori ofin ati ilana ẹtọ onikaluku ni ijọba alagbada da le, o yatọ si ijọba ologun, nibi ti olori ologun kan le maa ṣe ohun to ba fẹ. Ile-ejọ akọkọ ti da ẹjọ yii tipẹ, lati inu oṣu kọkanla, ni 2019, ṣugbọn awọn Danladi ko gba, wọn bẹrẹ si i pọn irọ lewe, wọn ni awọn ti gbe ẹjọ naa lọ sile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, wọn ni ki Azeez Elewu ti ki i ṣe oun lo wọle ibo jokoo sileegbimọ nibẹ, ko maa gbowo iṣẹ tẹnikan ko ran an. Awọn eeyan bii Danladi yii ko dara ni ipo nla, wọn ko dara ni ipo ti o ba jẹ tilu, nitori wọn yoo huwa ti yoo ba ibẹ jẹ ni. Gẹgẹ bi ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti waa wi yii, olori ile-igbimọ aṣofin kan ko lẹtọọ lati ma ṣe ibura fun ọmọ ile-igbimọ yoowu ti ile-ẹjọ ba ti fi aṣẹ si pe ki wọn ṣe ibura fun. Ohun to n dun Danladi ni pe Agboọla nikan ni yoo jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP nile-igbimọ naa. Ṣugbọn ki lo kan wọn ninu iyẹn, ile-igbimọ aṣofin ko yẹ ko jẹ fun ti ẹgbẹ oṣelu kan, fun ti gbogbo Kwara lo yẹ ko jẹ, ilọsiwaju ati idagbasoke ipinlẹ Kwara lo yẹ ki wọn maa wa, ki i ṣe ti ẹgbẹ oṣelu tiwọn. Ẹgbẹ oṣelu kan yoo de, yoo ṣejọba, yoo lọ, ẹgbẹ oṣelu mi-in yoo si tun de. Ṣugbọn ipinlẹ ati awọn eeyan Kwara yoo wa nibẹ titi lae ni. Ki waa ni alaga ile-igbimọ kan yoo tori oṣelu fẹẹ fa idagbasoke awọn eeyan ibẹ sẹyin, nitori kin ni! Ẹ wo o, ẹ bara yin sọhun-un wayi ṣaa, kẹ ẹ ṣebura fẹni to wọle ibo, ko le maa ṣe ojuṣe rẹ lọ. Abi ta lo sọ pe ọkunrin naa ko le pada waa dọmọ APC! Abi awọn oloṣelu asiko yii kọ! Ṣiọ!

 

Wọn ṣa fẹẹ yi Akeredolu lagbo da sina!

Ko pọ ninu awọn gomina ti wọn n gba ijọba ti awọn pẹlu awọn ti wọn fi ipo naa silẹ maa tun n ṣe ọrẹ ara wọn. Ṣugbọn ti Rotimi Akeredolu ati Oluṣẹgun Mimiko yatọ, nitori lati ọjọ ti Mimiko ti lọ, ko sẹni kan to gbọ ọrọ odi nipa rẹ, tabi nipa ijọba rẹ, lati ẹnu Akeredolu ati ijọba tuntun to n ṣe. Eleyii yatọ si awọn ohun kan to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ mi-in gan-an, nibi to ti jẹ bii ọdun kan akọkọ, ẹjọ ni wọn yoo maa fi ṣe, wa-loni-in, wa-lọla, ni kootu ko si ni i jẹ ki ẹni to wọle naa tete raaye ṣejọba. Ṣugbọn ohun gbogbo lọ wọọrọ l’Ondo ni ti pe Akeredolu ko tu idi ọrẹ rẹ wo.  Bo ba jẹ o tu idi rẹ wo ni, ko si oloṣelu ti wọn yoo yẹdi ẹ wo ti wọn ko ni i ba nnkan kan, kinni ọhun yoo si maa run ni. Wọn ti wa lẹnu iyẹn lati bii ọdun kẹrin sẹyin bayii, afi bi ibo ṣe de ti awọn kan ni Akeredolu loun yoo fi ẹjọ Mimiko sun EFCC. Dajudaju, irọ leleyii, nitori bi Akeredolu ba fẹẹ ṣe iyẹn ni, ki i ṣe lẹyin to ti lo ọdun mẹrin nile ijọba ni yoo maa wa ọna lati fi ẹjọ Mimiko sun, iba ti ṣe bẹẹ tipẹ, Mimiko iba si ti maa lọ maa bọ lọdọ awọn EFCC Abuja. Mimiko naa yoo mọ iyẹn ṣaa, yoo mọ pe eyi tawọn eeyan n sọ yii ko le ri bẹẹ, bi ọrọ kan ba si ru u loju, ko lọ sọdọ Akeredolu funra ẹ, ko si wadii ododo. Awọn kan ni wọn n lo orukọ rẹ, wọn si fẹẹ ko kọyin si Akeredolu lasiko ibo to n bo yii ni. Bawọn oloṣelu ṣe ri niyẹn, ko si ohun ti wọn ko le ṣe lati ba nnkan jẹ, to ba ti di ọrọ idibo bayii. Eyi fi han pe iṣẹ nla ṣi wa lọwọ Akeredolu funra ẹ, o ti lọ si Eko lọdọ Tinubu, ṣugbọn iṣẹ wa nilẹ l’Ondo, ti yoo ṣe, bi bẹẹ kọ, to ba pẹ diẹ bayii, wọn yoo yi i lagbo da sina ni. N lo ba tan!

 

Ṣugbọn nibo ni maanu yii tun n lọ

Ọrọ apara ni, ko jẹ jẹ bẹẹ. Ṣugbọn to ba waa lọọ jẹ bẹẹ, a jẹ pe Agboọla Ajayi, Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, ko mọ eyi to kan rara. Ariwo to gba gbogbo ipinlẹ naa kan lọsẹ to kọja ni pe Agboọla n lọ sinu ẹgbẹ oṣelu ZLP lọsẹ yii, wọn lo ni nibẹ loun yoo ti du ipo gomina oun. Ko too digba yii, nigba ti ọkunrin naa ba wọn du ipo yii ninu ẹgbẹ PDP ti ko wọle, ohun to sọ ni pe ko si ibi ti oun fẹẹ  lọ, oun yoo wa ninu ẹgbẹ naa lati le jọ gbajọba lọwọ Akeredolu ni. Ohun to ba fi waa mu Agboọla gbagbe ileri to ṣe yii, to waa gba ẹgbẹ oṣelu mi-in lọ, to ni oun fẹẹ du ipo gomina, a jẹ pe oun gan-an ko lojuti kan bayii, awọn ara ipinlẹ Ondo yoo si fi ọwọ ara wọn ṣe ara wọn lasan ni ti wọn ba dibo wọn fun un.To ba ṣe eleyii, yoo fi han pe ki i ṣe pe Akeredolu ni ko dara, oun gan-an ni ko daa, oun ni wọn fi jọba to tun n wẹ ọṣẹ awure, oun ni ipo to wa ko tẹ lọrun, to jẹ ipo ti ọga rẹ wa gan-an lo fẹ. Iwa bẹẹ ko daa, iwa ole ati ojukokoro ni. Ẹnikẹni to ba si ni iwa ole, ojukokoro ati iwọra bayii, bi iru wọn ba de ipo gomina, ilu naa yoo fọ mọ wọn lori ni. Nigba to jẹ ki i ṣe ifẹ awọn araalu lo gbe wọn debẹ, to jẹ nitori ole ti awọn fẹẹ ja ni. Tabi kin ni Agboọla yoo tun sọ pe oun n wa kiri. Ọran ni wọn fi n ṣe gomina ni. Bo ṣe rọrun to, oun naa lo sa lọ sinu PDP ti wọn ko le fa a kalẹ ko du ipo gomina lorukọ wọn, ti wọn ko tun le fi i ṣe igbakeji yẹn, bẹẹ lo n sọ pe oun ni baba oloṣelu ipinlẹ Ondo, oun naa yoo ti ri i bayii. Bẹ ẹ ba moju ẹ, ẹ jẹ yaa sọ fun un ko jokoo ẹ jẹẹ. Bi bẹẹ kọ, abuku oniyọrọ ni yoo kan nibi to n lọ yii, yẹyẹ ti wọn yoo si fi i ṣe, yoo ju ti baba to ba iyawo ọmọ rẹ sun lọ.

 

Ọlaniyan Ibadan, bẹẹ lọmọkunrin i ṣe o jare

Bi ọmọde ba ṣe bii ọmọde, agba a si maa ṣe iṣe agba. Igba mi-in, ki i ṣe ọjọ ori ni wọn fi maa n ni eeyan n ṣe bii ọmọde, ihuwasi a maa fa a nigba mi-in, koda, ki ọjọ ori eeyan pọ rẹpẹtẹ. Igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ, Alaaji Rauf Ọlaniyan, lo fi iwa agba yii han lọsẹ to kọja yii. Awọn oniroyin tọwọ bọ ọ lẹnu, wọn fẹ ko sọ kinni kan lori ohun to ṣẹlẹ si i nile awọn Ajimọbi lẹẹmejeeji to lọ sibẹ. Ṣugbọn kaka ki Ọlaniyan sọrọ ti yoo tun da nnkan ru, tabi ti yoo fọ ọrọ loju debi ti awọn oloṣelu ati awọn oniroyin to n wa ohun ti wọn yoo jẹ ni tiwọn yoo fi maa sọrọ sijọba wọn, o ni awọn ti mọ ohun to ṣẹlẹ ti iyawo Ajimọbi fi binu bẹẹ. Njẹ ki lo de to fi binu bẹẹ, o ni iku ọkọ rẹ lo ka a lara, eeyan ko le sọ iru nnkan to to bẹẹ yẹn nu ko ma bara jẹ, bi ọkọ ẹni ba ku, adanu nla ni. Pẹlu iru ọrọ yii, o daju pe ohun yoowu ti obinrin naa ibaa ṣe fun Ọlaniyan, o ti gbe oju fo o, o si ti mọ pe ko si ohun ti ẹni ti ọfọ ba ṣẹ ko le ṣe. O daju pe oju iyawo Ajimọbi naa yoo ti walẹ bayii, oun naa yoo si ti ri awọn aṣiṣe rẹ, yoo ti ri i pe ọrọ oṣelu nibi to de duro, ati awọn abanida a ti yoo maa tiiyan gbọn-ọn gbọn-ọn nitori ki awọn le ri ibi ba wọnu ọrọ fun imọtara wọn nikan ko ni i ba ni debẹ mọ bi ọrọ naa ba burẹkẹ. Ajimọbi ti lọ, iwa rere to ba hu silẹ lawọn ẹbi ati awọn ọmọ rẹ yoo jẹ. Ṣugbọn kekere niyẹn, iwa rere ti awọn to ba fi silẹ ba n hu bayii ni yoo jẹ ki ounjẹ naa pẹ lẹnu wọn. Ki iyawo Ajimọbi naa mọ eyi, ọwọ diẹdiẹ lara n fẹ o.

Leave a Reply