O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Ẹ jẹ ka ki Adeboye pẹlu Oyedepo

Nibi ti ilu ba ti daa, ki i ṣe awọn baba ọmọ ọgọrin ọdun, aadọrin ọdun, ni wọn yoo tun maa sare kiri lati ta ko ijọba kan. Ṣugbọn Naijiria wa yii ko daa, awọn ti wọn si n ṣejọba ni ko jẹ ko dara. Ṣugbọn ki i ṣe awọn ti wọn n ṣejọba wa nikan ni ika to wa nilẹ wa, awọn eeyan ti wọn n jẹ ijẹkujẹ ninu ijọba ti wọn n ṣe ni Naijiria naa buru pupọ ju iku ti n pa ni lọ. Bi wahala ba ba awọn eeyan, wọn ko ni i sọrọ, wọn si le sọrọ pe ohun ti ijọba n ṣe lo dara ju, bo tilẹ jẹ ninu ọkan wọn lọhun-un, wọn mọ pe ohun tawọn eeyan ti wọn n ṣejọba naa n ṣe ko dara. Nitori ẹ leeyan yoo ṣe ki awọn eeyan bii Pasitọ Adeboye, ati Biṣọọbu Oyedepo, ati awọn pasitọ mi-in loriṣiiriṣii, gbogbo awọn ti wọn ti jade sita pe ohun to n lọ ni Naijiria yii ko dara, ti wọn si n ṣe atilẹyin fun awọn ọdọ ti wọn n fi ẹhonu wọn han kaakiri. Ẹni ti ọrọ ko ba ye yoo ro pe awọn eeyan yii ko fẹran ijọba Buhari ni. Ṣugbọn ẹni to ba mọ idi ipilẹṣẹ ijọba yii, yoo mọ pe gbogbo awọn pasitọ wọnyi ni Buhari de ọdọ wọn, awọn ti ko ba si de ọdọ wọn, o ranṣẹ pataki si wọn lori idi ti oun ṣe fẹẹ gbajọba. Ijọba naa lo si gba ti ko ṣe daadaa to yii. O wa ninu ọrọ Ọlọrun, ninu Bibeli, paapaa lọdọ awọn Musulumi naa, pe nibi ti eeyan ba ti ri ibajẹ to n lọ lawujọ, ki tọhun yi i pada kia ni. Awọn Musulumi tilẹ ta ku pe tọhun ko gbọdọ dakẹ, bi ko ba le fi agbara rẹ yi i, ko fi ọrọ ẹnu rẹ yi i pada, ko ṣaa jẹ ki gbogbo aye mọ pe kinni naa ko dara. Ohun tawọn eeyan Ọlọrun wọnyi n ṣe ree. Ko yẹ ki iru Adeboye maa kanra mọ ijọba Buhari, tabi ko maa wa lẹyin awọn ti wọn fẹẹ doju ijọba naa de, ṣebi igbakeji Buhari, ọkan ninu awọn ọmọlẹyin Adeboye ni. Ṣugbọn Adeboye ri i pe ohun to n lọ ko dara, idi to fi n tẹle awọn ajafẹtọọ gbogbo niyi. Ọmọ rẹ. Leke Adeboye, lo ṣe isin fun awọn ọdọ ni Alausa, bẹẹ ni iyawo rẹ, Pasitọ Adeboye obinrin, ko ounjẹ rẹpẹtẹ fawọn ti wọn n fẹhonu han naa. Ohun to yẹ ki awọn aṣaaju wa ṣe niyi, bi nnkan ko ba dara, ‘Ẹ sọrọ soke,’ nitori ẹni to ba dakẹ, ti ara rẹ yoo ba a dakẹ, bi Naijiria ba si buru ju bayii lọ, awọn olowo, awọn oloṣelu ati awọn eeyan nla awujọ paapaa yoo fara gba a. Ẹ ṣeun o, Pasitọ Adeboye; ẹ ṣe e, Biṣọọbu Oyedepo, ati awọn pasitọ to ku gbogbo.

 

Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko

Bẹẹ naa lawọn gomina ilẹ Yoruba gbogbo

Nigba toro yii ba relẹ daadaa, to mu idẹra ati alaafia ti gbogbo ilu n fẹ wa, yoo ṣoro lati gbagbe awọn gomina nilẹ Yoruba, paapaa, Babajide Sanwo-Olu l’Ekoo, Ṣeyi Makinde ni Ọyo, ati Kayọde Fayẹmi paapaa l’Ekiti. Sawoolu ṣe e debii pe o ri awọn ọlọpaa ti wọn pa ninu awọn ọdọ yii ni Surulere mu jade, wọn si darukọ wọn faye gbọ, o si leri pe ijọba oun yoo tẹle ọrọ naa lati ri i pe iya jẹ awọn ọlọpaa yii dọba. Makinde lọ sile awọn ti wọn pa ni Ogbomọṣọ, bẹẹ lo fun wọn lowo, to si sọ pe ni gbogbo ọna ni ijọba oun fi fara mọ ọn pe ki wọn ko SARS kuro ninu awọn ọlọpaa Naijiria, ki wọn pa wọn rẹ pata, nitori iwa wọn ko dara. Awọn ko huwa bii awọn gomina ilẹ Hausa to jẹ gbogbo ohun ti ijọba Buhari ba ti ṣe lo dara, koda ko jẹ ohun ti yoo fi iya jẹ awọn eeyan wọn ni. Ojuṣe akọkọ ti gbogbo ijọba ni ni lati daabo bo awọn eeyan rẹ lọwọ ewu gbogbo: boya iku ojiji ni o, tabi iṣofo ẹmi ati dukia, tabi ifiyajẹni ati ihalẹ gbogbo. Ijọba ti ko ba ti le daabo bo awọn araalu rẹ, ijọba buruku ni, gbogbo eeyan lo gbọdọ kọyin si iru ijọba bẹẹ, koda ki wọn jọ wa ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa. Ohun to n mu orilẹ-ede agbaye dara si i lojoojumọ niyi. Ohun ti awọn ọdọ Naijiria wọnyi n beere fun, ohun daadaa ni, ijọba ko si gbọdọ da ọrọ naa si agidi, ki wọn ṣe ohun ti wọn n fẹ fun wọn ni. Ohun ti wọn fẹ yii ki i kuku ṣe pe awọn nikan ni wọn yoo jẹ anfaani ẹ, gbogbo ọmọ Naijiria ni ọrọ naa yoo mu itura ba bo ba ṣẹlẹ, nitori ẹ ni gbogbo ilu ṣe gbọdọ ti wọn lẹyin, titi ti ijọba yii yoo fi ṣe ohun ti wọn n pariwo ẹ yii. Afi ka ṣe e ko yanju, bi a o ba ṣe e ko yanju, awọn ti wọn n ṣejọba wa yoo ro pe awọn ni Ọlorun wa ni. Ẹ ṣeun, ẹyin gomina wọnyi, ẹ tubọ mura si i ko ṣee ṣe!

 

Lai Mohammed

Amọ bi ọrọ ba ti da bayii, ẹnu Lai Mohammed ni kẹ ẹ maa ṣọ

Nigba  tiẹ ba ti fẹẹ mọ bi ijọba Buhari yii ṣe n ronu, ẹnu Lai Mohammed, minista fun eto ikede, ni kẹ ẹ maa ṣọ. Yoo tun wa ṣoro ṣaa o, boya ironu naa jẹ ti Aarẹ Buhayhri ati Lai lasan, pẹlu awọn ti wọn jọ n ṣe wọle-wọde, tabi ironu awọn gbogbo ti wọn n ṣẹjọba. Nibẹrẹ osẹ to kọja yii, Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, jade, o ni ijọba Buhari tọrọ aforijin lọwọ gbogbo ọdọ, o ni ki wọn ma binu pe awọn ko tete da si ọrọ awọn SARS yii, awọn gba pe awọn jẹbi, ki gbogbo ọdọ pata fori ji awọn. Gbolohun to ti ẹnu Ọṣinbajo jade yii, gbolohun atunṣe ti awọn eeyan fọkan si pe o le jẹ ki ijọba yii ronupiwada, ki wọn si bẹrẹ si i ṣe ohun to dara ni. Ṣugbọn lojiji ni Lai Mohammded jade, oun ko si ni ọrọ alaafia kan lẹnu ti yoo sọ fawọn ọdọ yii ju pe ko sẹni to le da ijọba ru mọ awọn lori, ẹni to ba fẹẹ gbiyanju ẹ, awọn yoo dẹ awọn aja ijọba si i, ohun ti oju onitọhun ba si ri, ko fara mọ ọn. Ọrọ Lai Mohammed, bii ọrọ aja ti yoo sọnu ti ko ni i gbọ fere ọdẹ ni. Gbogbo ohun to n ṣe yii, ati gbogbo ipo to ro pe oun wa yii, ọdun meji ati diẹ naa lo ku fun un, ka tilẹ sọ pe ijọba Buhari yii lo gbogbo akoko rẹ pe. Lẹyin ti Buhari ba lọ, ti wọn gbajọba kuro lọwọ rẹ, ti wọn da Lai pada sibi to ti lọ, nibo lo ku ti yoo gba. Nibo lo fẹẹ gbe! Awọn nnkan wo lo fẹẹ maa ṣe, ta ni yoo pe e sibi iṣẹ gidi kan pe ko waa sọrọ tabi ko waa gba ẹnikẹni nimọran! Aye yoo pa ọkunrin naa ti bii aṣọ to gbo ni, nitori orukọ rẹ ko dara nigboro raa. Iwọnba awọn ti wọn n lọ si ọdọ rẹ bayii, nitori iṣẹ ati awọn ohun diẹ diẹ ti wọn le ri gba lọwọ rẹ nitori to wa nile ijọba ni, bi ko ba si nile ijọba mọ, aye yoo pada lẹyin rẹ debii pe yoo ro pe oun ko si ninu aye naa mọ ni. Ọrọ naa yoo kan awọn ọmọ rẹ paapaa, nitori wọn yoo maa bu wọn ni, wọn yoo si maa yinmu si wọn ni gbangba pe ọmọ Lai Mohammed, opurọ Naijiria nigba kan, ni wọn. Bi Lai Mohammed ko ba ro ti ara rẹ, ko ro tawọn ọmọ rẹ, ko ma fi asiko tirẹ yii ba aye awọn ọmọ naa jẹ lọjọ ọla. Ẹ sọ fun Lai ko yee purọ, ko si yee halẹ mọ awọn ọmọ Naijiria, ọrọ yii yoo lẹyin bo dọla o.

 

Gomina Gboyega Oyetọla tipinlẹ Ọṣun

Awọn ti wọn kọlu Oyetọla l’Ọsun

Iroyin to pada jade yii daa. Iroyin to sọ pe awọn ti wọn ko lu Gomina Adegboyega Oyetọla l’Oṣogbo ki i ṣe awọn ti wọn n fi ẹhonu han, awọn tọọgi oloṣelu ni. Bi iru ọrọ bayii ba ṣẹlẹ, iyẹn iru iwọde to n lọ lọwo yii, awọn meji ni wọn maa n fẹẹ fi kinni naa jẹ anfaani ti ko tọ si wọn. Akọkọ ni awọn oloṣelu, ẹẹkeji ni awọn ọdaran, awọn ọmọọta. Awọn oloṣelu yoo jade lati wa ọna ti wọn yoo fi sọ kinni naa di ti ara wọn, ki i ṣe nitori ohun meji si ni eyi bi ko ṣe ọna ti kinni naa yoo gba di owo fun wọn. Awọn ọmọọta yoo wa ọna ti wọn le fi ja owo ati dukia awọn eeyan gba nibi iru iwọde bayii, nitori iwa ọdaran to ti mọ wọn lara. Ṣugbọn gbogbo ẹni to ba n tẹle awọn ọdọ yii yoo ti ri i pe ko si erongba lati huwa ọdaran ninu ohun ti wọn n ṣe, koda, wọn ko ṣe jagidijagan, bẹẹ ni ko si ẹni to lo ohun ija oloro kankan nibi awọn iwọde wọnyi, ohun ti ko si jẹ ki ọlọpaa tabi ṣọja kankan ri wọn mu niyẹn. Awọn ọdọ wọnyi n ṣe iwọde wọn, nitori wọn mọ ohun ti wọn n wa, wọn si mọ ohun ti wọn fẹ ki ijọba ṣe. Wọn fẹẹ gba agbara lọwọ awọn oloṣelu ati awọn eeyan yẹpẹrẹ ti wọn ti joye arijẹnimadaru ti wọn kun ilẹ wa, ti ko mọ ju ki wọn maa rẹ araalu jẹ lọ. Awọn ọdọ naa ko fi ti pe Musulumi ni wọn tabi pe Kristiẹni ni wọn ṣe, wọn ko si fi ti pe boya Hausa ni wọn tabi Ibo ṣe, koda, wọn ko ni olori kan laarin ara wọn, awọn nikan ni wọn mọ bi wọn ti n ṣe e. Nitori rẹ ni Ọlọrun ṣe tete tu aṣiri awọn ti wọn kọ lu Oyetọla, awọn tọọgi oloṣelu ti wọn fẹẹ dara pọ mọ awọn ọdọ wọnyi, ki wọn le ri wọn sọ lẹnu. Ko si ohun meji ti yoo dara ju ki ijọba ati awọn ọlọpaa wa awọn tọọgi yii ri, ki wọn mu wọn, ki wọn si fi iya ti ko lẹgbẹ jẹ wọn. Bo ba ṣee ṣe lati ri awọn oloṣelu were ti wọn ran wọn niṣẹ yii mu, ki wọn mu awọn naa, ki wọn fi wọn han gbogbo aye, kaye le mọ pe ọbayejẹ ni wọn, lẹyin naa ni ki wọn jẹ ki iya to tọ si wọn jẹ wọn. Awọn ọmọọta ti wọn kọlu gomina naa ko ṣe daadaa rara, iya gidi si gbọdọ jẹ wọn, ki wọn le ti ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.

 

Tola Oyediran

Iku Ọmọ Awolọwọ n’Ibadan

Refurẹẹni Tọla Oyediran, akọbi Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ lobinrin, naa jade laye lọsẹ to kọja. Iku rẹ ṣe gbogbo aye ni kayeefi, ohun to si fa a ni pe awọn ti wọn ju u lọ ṣi wa laye daadaa. Ninu oṣu kejila, ọdun yii, ni Mama naa iba pe ẹni ọgọrin (80) ọdun, afi bi iku yii ṣe sare mu un lọ. Ko si ohun to mu iku rẹ dun awọn eeyan pupọ ju pe loootọ ni gbogbo aye n ranti, ti wọn si mọ ẹni ti Awolọwọ i ṣe, ọkan ninu awọn ti itan baba naa wa lọwọ rẹ lo ti tun lọ yii, nitori lẹyin oun, ọmọ baba yii kan naa lo tun ku laye. Ati pe iwa bii ti Awolọwọ ati awọn ilakaka lori bi awọn ohun ti baba naa ja fun nigba aye rẹ ko ṣe ni i parẹ lobinrin naa fi ọpọ aye rẹ ṣe, titi di igba to si ku yii naa lo jẹ ọrọ awọn ọdọ ti wọn fẹẹ fi ẹhonu wọn ṣe atunṣe si Naijiria lo n sọ lẹnu. Ẹkọ inu ọrọ yii ni pe ko si ẹni to wa laye yii ti ko ni i ku, ko si ẹni ti yoo lagbara loni-in ti ko ni i di ọlẹ bo ba dọla. Gbogbo ibi yoowu ti eeyan ba le wa laye yii, boya tọhun fẹ o, boya o kọ ni o, yoo fi ipo naa silẹ ni. Awọn oloṣelu ti wọn n ṣe gaugau kiri ilu bayii, meloo meloo ni iru wọn ti wọn ti wa ti wọn ti lọ, ṣugbọn ilu n ranti Awolọwọ ati awọn ọmọ rẹ nitori iṣẹ rere ti baba naa ṣe nidii oṣelu ni. Ẹni to ba wa ni ipo kan ko ṣe e daadaa, ko lo ipo naa lọna rere, ki gbogbo aye le maa ranti rẹ tọmọtọmọ. Ki Ọlọrun da ọmọ Awolọwo kan naa to ku si, ati awọn ọmọọmọ rẹ, ko si ṣe itunu fun Purofẹsọ Oyediran ti i ṣe ọkọ oloogbe, ati awọn ọmọ ti iya naa fi saye lọ. Iku ko loogun, ko si ohun tẹnikan kan le ṣe si i.

Leave a Reply