O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Arun wa lara awọn gomina ilẹ Hausa yii o

Ironu wa ko jọ ara wọn. Ironu ole, ironu ka ja ohun olohun  gba lo wa ninu awọn kan ni Naijiria, bẹẹ ni ironu konikaluku jẹ iṣẹ ọwọ ẹ wa ninu awọn kan. Nigba ti eeyan ba gbọ ọrọ lẹnu awọn ti wọn maa n pe ara wọn ni olori tabi aṣiwaju ni ilẹ Hausa, ko si ohun ti yoo wa si ọkan oluwa ẹ ju pe Naijiria ti wọn n pariwo yii, bo ba jẹ bo ṣe wa naa niyi, yoo ṣoro ki orilẹ-ede naa too bọ ninu hilahilo. Awọn aṣaaju awọn Hausa-Fulani ti wọn wa ni Naijiria yii jẹ kiki ole, opurọ, alonilọwọgba ati oloju-aye. Tabi bawo ni gbogbo awọn gomina adugbo naa yoo ṣe pade pọ, awọn gomina bii mejidinlogun, ti gbogbo wọn yoo si pade, ti wọn yoo si jokoo soju kan naa, ti wọn yoo si sọ pe awọn ti wọn ṣe iwọde SARS nijọsi, wọn ṣe e nitori ki wọn le le Aarẹ Muhammadu Buhari nipo ni. Iru ọrọ wo niyẹn! Bẹẹ iwa wọn niyẹn. Nigba ti awọn kan ba n gbiyanju, ti wọn n fi ẹmi la iku nitori ki Naijiria le dara, awọn eeyan yii yoo si wa gbogbo ọna lati ba ilakaka naa jẹ, nitori pe nibi ti nnkan ko ti dara yii, nibi ti ọrọ Naijiria ti n ṣe segesege yii, nibẹ ni awọn ti n jẹ. Ki wọn too ṣe ipade wọn ni Abuja yii, wọn ti kọkọ gbe ikede kan jade  pawọn fẹran awọn SARS ni tawọn. Wọn ko le ṣe ki wọn ma fẹran awọn SARS, nitori ko si ọdọ to n fọwọ ara ẹ ṣe iṣẹ aje lọdọ wọn, awọn SARS ko si rẹni mu nibẹ. Ati pe ọlọpaa mọ pe ti oun ba mu ọmọ Hausa-Fulani, iṣẹ yoo bọ lọwọ oun, were kan ko si ni i ṣe e debẹ, ọmo Yoruba ati Ibo nikan ni wọn yoo maa le kiri. Ohun ti awọn ti wọn ponu ninu awọn gomina yii ṣe n sọ isọkusọ niyi, ti laakaye awọn pupọ ninu wọn si dorikodo nitori  ohun tawọn n ri jẹ. Ṣe ka le sọ pe wọn n gbeja Buhari ni gbogbo eyi ti wọn n ṣe yii ni, tabi ki Buhari le sọ pe awọn ni wọn fẹran oun. Tabi ilẹ Hausa naa ni wọn kuku ṣe bayii fẹran. Irọ ni! Ijẹkujẹ ti wọn n jẹ, ole ti wọn n ja, owo ijọba ti wọn n ko jẹ, ti wọn ko si fẹ ki ẹnikẹni mọ, abi ko bi wọn lo fa gbogbo eyi ti wọn n ṣe yii, ki i ṣe pe wọn fẹran Buhari rara. Ifasẹyin to wa nilẹ Hausa tẹ wọn lọrun, wọn ko fẹ ki awọn ọmọ araalu kawe, ko ma di pe wọn yoo gbọn bii awọn ọmọ tiwọn. Ọmọ tiwọn n kawe niluu oyinbo o, wọn n kawe ni Amẹrika, wọn n kawe ni London, ṣugbọn wọn ko ni i jẹ ki awọn ọmọ araalu kawe yanju nile nibi, wọn yoo ni ko daa. Nigbẹyin, nigba ti awọn ba ṣe olori wọn tan, awọn ọmọ tiwọn naa yoo si bọ sibẹ lati maa ṣe olori awọn araalu lọ. Ọdalẹ ati alabosi ni wọn, awọn ti wọn n ba aye awọn araalu wọn jẹ lati fi tun aye tiwọn nikan ṣe. Iyẹn o ṣee ṣe nilẹ Yoruba nibi, tabi ilẹ Ibo paapaa, ohun ti iwa wa fi yatọ sira wọn niyẹn. Ero ẹyin lawọn, ero iwaju lawa; adanipada-sẹyin ni wọn, asunni-siwaju lawa. A o jọra, a ko si ni i jọra laye. Ṣugbọn bi Buhari ba ro pe wọn fẹran oun ni gbogbo eleyii ti wọn n ṣe yii, a jẹ pe oun paapaa ko mọ ohun to n ṣe e. Ki i ṣe awọn ti wọn ṣe iwọde SARS ni ọta ẹ, tabi pe awọn ni wọn fẹẹ yọ ọ loye, awọn gomina ilẹ Hausa yii gan-an lo fẹẹ yọ ọ loye, awọn ni wọn fẹẹ ba tiẹ jẹ, tori wọn mọ pe ti awọn ba ti le ti i titi to di ọta araalu pata, yoo ja bọ nipo giga to wa yii naa ni. Awọn gomina ilẹ Hausa yii lọta Buhari, nitori awọn ni a-ri-ododo-ma-sọ. Awọn lọta Naijiria, nitori ko-bajẹ ko-bajẹ ni wọn n ṣe. Ki Buhari tete sara fun wọn, bi bẹẹ kọ, wọn yoo ba tirẹ jẹ tọmọtọmọ.

 

Ẹ kan tun fẹẹ da kun wahala to ba yin ni, ẹ mura si i o

Ijọba Buhari yoo ko ara rẹ si wahala, yoo da kun iṣoro to ba wọn bayii, bi kinni naa ba si fẹju tan, apa wọn ko ni i ka a. Awọn DSS ti kungboro bayii, bẹẹ ni awọn imigireṣan n ṣe tiwọn, awọn ara banki ijọba apapọ naa n ṣe, wọn n wa awọn ti wọn ṣeto iwọde SARS yii kaakiri. Wọn fẹẹ mu wọn ni, wọn fẹẹ ti wọn mọle, ki wọn le fi irọ bo ootọ ohun to ṣẹlẹ mọlẹ ni. Wọn ko fẹ ki aye mọ pe wọn yinbọn ni Lẹkki, wọn fẹẹ wa gbogbo ọna lati ko awọn kan jade pe awọn ni wọn yinbọn, tabi ki awọn tọhun sọ pe awọn ko ri ibọn kankan nibẹ, oku kankan ko si ku rara. Ọkan ninu awọn lọọya to ṣẹranlọwọ fun awọn to ṣe iwọde naa fẹẹ rin irin-ajo, nigba to de papa-ọkọ ofurufu ti yoo ti wọ baaluu ni wọn sọ pe ko le lọ, wọn ni wọn ti fi orukọ ẹ sinu iwe awọn ti wọn n ṣẹwadii wọn lọwọ. Iwadii kin ni, iwadii ọrọ SARS yii naa ni. Ọlọpaa mu …, ọkan ninu awọn to ṣeto iwọde naa, wọn ko ri alaye kankan ṣe ju pe wọn ni o wa nibi iwọde ti wọn ṣe yii lọ. Ileeṣẹ banki apapọ ilẹ wa kọwe si gbogbo banki to ku, o si darukọ awọn ti wọn ṣeto iwọde yii pe ki wọn gbe ẹsẹ le owo ti wọn ni ni gbogbo banki, wọn ko gbọdọ jẹ ki wọn gba owo jade nibi kan. Lọrọ kan, ijọba Buhari n wa ọna lati mu awọn aṣaaju ọdọ yii, ki wọn le fi iya gidi jẹ wọn nitori ipa ti wọn ko lasiko iwọde SARS yii. Ṣugbọn ọrọ naa yoo lẹyin fun ijọba yii. Wọn n jẹ ekuru ko tan, awọn alakọri si n gbọn ọwọ rẹ sinu awo. Ijọba yii n purọ fun gbogbo aye pe awọn fẹ alaafia, awọn yoo tọju awọn ọdọ, awọn o yinbọn lu wọn, awọn fẹ irọrun fun wọn, ṣugbọn awọn yii kan naa ni wọn n gbẹyin lọọ fi ọlọpaa ati DSS mu wọn, ti wọn si n gbẹsẹ le owo wọn ni banki. Iru ijọba alagabagebe wo leleyii na. Gbogbo ẹni to ba mọ oju wọn ko ba wọn sọrọ, nitori nigba ti wọn ba sun awọn ọdọ yii kan ogiri, ohun ti oju wọn yoo pada ri yoo ju gbogbo eyi ti wọn ti ri sẹyin yii lọ o. Ẹ jẹ ki wọn mura si i, ojo ẹsin wọn ti ṣu dẹdẹ, nigba to ba bẹrẹ si i rọ le wọn lori, awọn ti ko ra nibẹ paapaa yoo san.

  

Bi iwa yin ba dara, ki le n ko ọlọpaa kiri si

O ti pẹ ti awọn ọga ọlọpaa loriṣiiriṣii ti maa n paṣẹ pe ki wọn ko awọn ọlọpaa ti wọn n ṣọ awọn eeyan kan kuro lẹyin wọn. Awọn eeyan yii ko ṣiṣẹ ijọba mọ, ẹlomi-in paapaa ko ṣiṣẹ ijọba ri, ṣugbọn tẹ ẹ ba de ile wọn, ọlọpaa bii marun-un le wa nibẹ pẹlu mọtọ wọn. Ẹlomi-in ninu wọn ti ṣe sẹnetọ, o ti ṣe gomina, tabi aṣofin ni bii ọdun mẹwaa sẹyin, sibẹ, ẹ o o ba ọlọpaa bii ẹgbẹlẹ ti yoo maa ṣọ oun nikan. Awọn ọlọpaa Naijiria ti di meji eepinni, ati olorin, ati onitiata, ati onibọọlu, ati oloṣelu jẹkurẹdi, titi de awọn ọba ti ilu ti wọn jọba le lori ko ju orule mẹwaa lọ, gbogbo wọn lo ku ti yoo maa ko ọlọpaa kiri, titi dori iyawo wọn. O buru debii pe bi iyawo awọn eeyan yii ba n lọ si pati, awọn ọlọpaa yoo si maa tẹle wọn lẹyin lọ si ode ariya, bi wọn ba fẹẹ nawo fun elere, ọlọpaa yoo si wa lẹyin wọn to n ṣọ wọn. Iru aye alabata ati aye buruku wo lo ju eyi lọ. Awọn ọlọpaa ki i to lati lọọ daabo bo araalu, nigba ti bii mẹwaa ba ti n ṣọ eeyan kan, ẹni ti ko si ni oore kan to n ṣe faraalu ju pe o n ṣe bisinẹẹsi tirẹ lọ. O dara ti ọga ọlọpaa tẹ orukọ awọn ti ọlọpaa n ṣọ yii jade, ṣugbọn orukọ to tẹ yii ko i ti i to rara, yoo ṣi le ni ẹgbẹrun diẹ awọn ti wọn ko jẹ kinni kan ti wọn n ko ọlọpaa kiri. Nigba ti aṣofin kọọkan ba ni ọlọpaa, ti adajọ kọọkan ni, ti ọba kọọkan ni ọlọpaa, ti oloṣelu ole kọọkan ni, meloo waa ni ọlọpaa ti yoo ku fun araalu! Ohun to n pa wa ku niyẹn o! Oga ọlọpaa ṣe eleyii daadaa, ṣugbọn ko tubọ mura si i. Ẹjọ aburu ti wọn n ro ni pe awọn n ko awọn ọlọpaa kiri ki awọn araalu ma kọ lu awọn. Bi iwọ ba ṣe rere, ara ki yoo ha ya ọ. Olowo, ọlọla, oloṣelu, to ba ṣe rere faraalu, kin ni yoo maa ko ọlọpaa kiri igboro si. Bo ba si di dandan fun olowo lati gba awọn ti yoo maa ṣọ ọ, awọn kan wa ti wọn ko ni iṣẹ meji ti wọn n ṣe ju iṣẹ ẹṣọ aladaani yii lọ, ki wọn fowo wọn gba ẹṣọ, abi ewo ni wahala! Awọn ole, ọlẹ, oniranu gbogbo!

 

Bawo ni gbese ṣe rọ ijọba Buhari yii lọrun to bayii

Ijọba yii ko tiẹ waa ni ojuti kankan mọ rara. Ijọba Buhari ni o! Bi a ti n wi yii, ijọba Naijiria ti gbe igba baara wọn, wọn ni awọn n lọọ yawo mi-in ni Brazil. Họwu, bawo ni Naijiria yoo ṣe lọọ yawo lọwọ Brazil, awọn orilẹ-ede ti idagbasoke tiwọn ko to tiwa. Awọn orilẹ-ede to yẹ ki wọn maa wo wa bii aṣaaju, ki wọn si maa fi wa yangan, awọn orilẹ-ede to yẹ ki wọn maa wo Naijiria gẹgẹ bii baba wọn ti wọn le fẹyin ti, nigba to jẹ Naijiria ti ṣaaju wọn ṣoriire. Nigba ti aja fi n ṣe inu ile, inu igbo lọbọ wa to n gbe. Nigba ti Naijiria n goke agba, awọn orilẹ-ede bii Brazil yii n rakoro ni. Ṣugbọn ni bayii, awa ti ba gbogbo ohun ti a gbe dani jẹ, a ti fa ara wa sẹyin debii pe a ko le da nnkan kan ṣe, o si kuku waa buru fun orilẹ-ede yii debii pe Brazil la ti tun n lọọ yawo, lẹyin ti a ti ya ni Amẹrika titi, ti a ya ni London ati Ṣaina, ati lawọn orilẹ-ede Yuroopu kaakiri. Eyi to tilẹ waa buru ni ti ijọba Buhari yii, gbese ṣaa ni! Ki lo kuku le to bẹẹ. Paripari rẹ si ni pe bi wọn ba ti yawo yii naa, wọn yoo ko o jẹ mọ ara wọn lọwọ ni, eyi idagbasoke ti wọn yoo sọ pawọn tori ẹ yawo, ẹnikan ko ni i ri i. Buhari, ẹ ma yawo kankan mọ o! Ẹ ma yawo ni Brazil, koda, ẹ ma ya nibi kankan. Iwọnba owo to ba wa lọwọ wa ni ka na, ohun to ba ṣee ṣe naa ni ka ṣe. Bi ijọba ba fi ootọ ba awọn araalu lo, ti wọn sọ ohun to n lọ gan-an fun wọn, araalu yoo gba ijọba gbọ, wọn yoo si duro ti wọn ninu ohun ti wọn ba n ṣe. Ṣugbọn ogun ka maa yawo kiri gbogbo aye yii, ohun ti yoo fa wa sẹyin fungba pipẹ ni o. Buhari, ma jẹ gbese mọ. Eleyii o daa o!

 

Ki lo kan yin ninu ọrọ awọn ara Amẹrika

Awọn eeyan kan ni wọn si wa nidii aburu yi! Awọn kan ni wọn fun awọn eeyan lowo ni ilẹ Ibo pe ki wọn maa ṣe iwọde pe awọn wa lẹyin Trump, olori ijọba ilẹ Amẹrika. Awọn oniluu ni awọn ko fẹ olori awọn mọ, ẹyin ko ilu ati fere jade, ẹ ni Trump lẹ fẹ. Bo ba ṣe ibi ti a ti ni ijọba to mọ ohun to n ṣe ni, iru awọn ti wọn ṣeto iwọde bayii yẹ ni mimu, ki wọn wadii ẹni to ko owo fun wọn ati idi ti wọn fi ṣeto naa, ki ijọba si mọ ohun ti wọn fẹẹ gba nibẹ gan-an. Iṣoro ati wahala to ba wa nibi wa nibẹ, ko ti i niyanju o, lojoojumọ si ni nnkan tiwa n le si i. Tiwa wa lara wa buruku. Awọn oponu yii ko waa ri nnkan kan ṣe si iṣoro tiwa, iṣoro Amẹrika ni wọn tori ẹ ko ilu jade. Bẹẹ ki i ṣe awọn ti wọn n jo kiri yii ni wọn wa nidii eto naa, awọn kan ni wọn wa ni kọrọ ti wọn n nawo ẹ. Ṣe onijibiti ni wọn ni abi awọn to fẹẹ ba orilẹ-ede yii jẹ, nitori ohun to kan wọn ninu ọrọ Donald Trump ko ye ẹnikan. O si yẹ ka mọ, nitori oni kọ, nitori ojọ mi-in ni. Ijọba gbọdọ wa awọn eeyan yii kan o, awọn ọmọ Naijiria gbọdọ mọ bi tiwọn ti jẹ gan-an!

Leave a Reply