O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Buhari ṣe rere, nitori oni kọ, nitori ọjọ ọla ni

Ọrọ awọn ọdọ ti wọn ṣe iwọde nijọsi, ohun ti awọn ti wọn ṣejọba Buhari yii n ṣe ko daa o. Ko daa, nitori kaka ki wọn mojuto ohun to yẹ ki wọn mojuto, wọn fi ẹtẹ silẹ, wọn n pa lapalapa ni. Ojumọ kan, irọ kan ni, ohun ti wọn si n wa ko ye ẹnikan. Bi wọn ṣe n fi ọwọ kan purọ pe awọn ko ṣe ẹjọ, awọn ko wa wọn, awọn ko fi ọlọpaa halẹ mọ ẹnikan ninu awọn ọdọ yii, bẹẹ ni wọn n fi ọwọ keji dẹ awọn DSS, awọn kọsitọọmu ati awọn agbofinro mi-in si wọn. Tabi nigba ti ileeṣẹ Aarẹ fọwọ si i ki wọn gbẹsẹ le owo ti awọn to ṣe atilẹyin fun eto iwọde yii ni ni banki, ti wọn ko si jẹ ki wọn ri owo naa gba jade lati igba naa. Nigba ti wọn bi awọn eeyan naa idi ti wọn fi n ṣe bẹẹ, wọn ni awọn fẹẹ yẹ owo ti wọn ni wo, awọn fura si wọn pe owo ti wọn n na yii, owo awọn afẹmiṣofo ti wọn n pe ni tẹrọriisi ni, eyi tumọ si pe awọn ti wọn ṣeto iwọde yii ati awọn ọdọ ilẹ wa, afẹmisofo ni wọn. Irọ buruku leleyii, ijọba Buhari n purọ mọ awọn eeyan yii ni. Ijọba Buhari mọ awọn afẹmiṣofo, wọn mọ awọn Boko Haram, wọn si mọ awọn ti wọn n ran Boko Haram lọwọ, ṣugbọn ijọba wa ko mu wọn, wọn ko si dẹ awọn agbofinro si wọn, koda, bi ọrọ ba le tan, awọn ṣọja ti wọn ko ti wọn yoo fẹsẹ fẹ ẹ ni. Ta n fẹẹ ku! Bẹẹ ojoojumọ lawọn Boko Haram yii n fẹmi awọn eeyan ṣofo, ti gbogbo aye si n sọ pe ki wọn yee pe wọn bẹẹ, ki wọn pe wọn lorukọ ti wọn n jẹ gan-an, pe afẹmiṣofo ni wọn. Ṣugbọn titi di asiko ti a wa yii, o le fun Buhari ati ijọba rẹ lati pe wọn bẹẹ. Bakan naa ni awọn Fulani ajinigbe, pẹlu gbogbo aburu ti wọn n ṣe lorilẹ-ede yii, ijọba Naijiria ko pe wọn ni afẹmiṣofo, wọn kan ni awọn Fulani ti inu n bi lasan ni wọn. Ṣugbọn awọn ọdọ ti wọn ṣewọde lati beere fun ẹtọ to yẹ kiijọba ṣe, awọn lawọn eeyan radarada kan jokoo sibi kan ti wọn ni tẹrọriisi, awọn afẹmiṣofo, awọn apanilai-nidii ni wọn. Ijọba Buhari yii ti kun fun awọn alaboosi eeyan ju, awọn ẹlẹtan ti wọn n tan Aarẹ funra rẹ, bi ko ba si yẹju wọn, wọn yoo ba ijọba rẹ jẹ kọja atunṣe. Ijọba rẹ nikan si kọ, wọn yoo ba aye oun naa jẹ loju gbogbo awọn ọmọ Naijiria debii pe iwọnba igba to ba ku ti yoo lo laye, ko ni i niyi nibi kan. Tabi nigba ti awọn eeyan ba ri ootọ ti wọn ko sọ, ti wọn n ri irẹjẹ, ti wọn ko sọrọ, to jẹ aburu ni wọn n ṣe. Awọn ti wọn n fi ibajẹ bo ododo mọlẹ, ti wọn n tan araalu jẹ, ti wọn ni awọn n ṣẹjọba. Nigba wo ni abuku Ọlọrun ko ni i kan wọn, awọn ti wọn ba ti ọmọ ẹlomiiran jẹ, nigba wo ni ti ọmọ wọn naa ko ni i bajẹ loju wọn. Ki ijọba yii yee daamu awọn ọdọ ti wọn ṣewọde ati awọn ti wọn ṣe atilẹyin fun wọn mọ, ki wọn jawọ ninu ẹjọ abosi ti wọn pe si kootu, ki wọn gbẹsẹ kuro lori owo awọn eeyan naa to wa ni banki, ki wọn ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe. Ohun to le mu alaafia wa siluu ree o. Gbogbo eyi ti wọn n ṣe ti wọn n lo ọlọpaa kiri, ti wọn n lo DSS yii, nigba ti ọrọ naa ba burẹkẹ lẹẹkeji, ijamba ti yoo ṣe ọmọ ẹlomi-in, paapaa awọn ti wọn n ṣejọba yii ni o, ati awọn oloṣelu ole, ati irandiran wọn ko ni i gbagbe laye. Buhari, ṣe rere o, nitori oni kọ, nitori ọjọ ọla ni.

 

Ẹ yee fọgbọn ko awọn ọmọ Hausa nikan wọnu iṣẹ ṣọja

Awọn wahala kan wa ti ijọba orilẹ-ede yii maa n da sọrun ara wọn, ti wọn si maa n fi ọrọ naa ko ba gbogbo Naijiria to ba ya. Ni Ọjoruu, ọsẹ to kọja yii, ileeṣẹ ologun ilẹ wa gba awọn ọmọ Hausa irinwo, iyẹn ọgọrun-un mẹrin (400) sinu iṣẹ aami-ṣọja, wọn ni nitori wọn jẹ ọdẹ ati awọn ti wọn ti n ran wọn lọwọ lori ọrọ Boko Haram laduugbo wọn. Bi kinni naa iba ti dara to, ọna ti ijọba gbe e gba yii ko daa. Lati ko ọmọ ipinlẹ kan naa, ọmọ ẹya kan naa, ọmọ adugbo kan naa, to pọ to bayii sinu iṣẹ ologun ilẹ wa lẹẹkan naa yoo mu rukerudo wa nigba to ba ya, atubọtan rẹ ko si le daa fun Naijiria, tabi ijọba to ba wa nibẹ nigba naa. Ofin wa lati gbaayan sinu iṣẹ ṣọja nilẹ wa, ohun ti ofin naa si wi ni pe ko ni i si ẹya kankan ti wọn yoo kan deede ko sinu iṣẹ ologun naa, wọn yoo pin in kari gbogbo ipinlẹ, lati ri i pe ẹya kan ko pọ ju ẹya kan lọ ninu iṣẹ naa, ki eleyii le mu iṣọkan apapọ wa si aarin wọn. Ṣugbọn nigba ti ipinlẹ kan ba ko ọgọrun-un mẹrin awọn eeyan sinu ṣọja lẹẹkan, ti ẹ ni tori Boko Haram, nigba ti ko ba si Boko Haram nkọ o. Bẹẹ ni ki i ṣe igba akọkọ niyi ti wọn yoo ṣe bẹẹ lapa Oke-Ọya yii, ti wọn yoo kan deede ji nijọ kan, ti wọn yoo ni awọn kan ran awọn lọwọ, ti wọn yoo si ko wọn sinu iṣẹ ṣọja Naijiria, ileeṣẹ ologun to jẹ ti gbogbo wa. Bawo ni ijọba yoo ṣe fọwọ si iru awọn nnkan bayii, nigba ti wọn ki i ṣe ohun to ba ofin mu. Ohun to han ni pe awọn ẹya Hausa n fi ọgbọ oriṣiiriṣii ko awọn eeyan wọn sinu iṣẹ ologun, bo ba si ya tan, apa awọn ẹya to ku ko ni i ka wọn, a ṣe pe ohun ti wọn ba fẹ ni wọn yoo maa ṣe, ileeṣẹ ologun aa si le kuro ni ti Naijiria, ko di ti awọn Hausa gan-an. Ko si ibi ti wọn ti n ṣe eleyii ti iru orilẹ-ede bẹẹ n toro, nigbẹyin, nnkan wọn yoo daru ni. Awọn ohun to si maa n da nnkan wọn ru naa ni iru iwa ti ijọba Buhari n hu yii, nibi ti irẹjẹ ati ẹlẹyamẹya ba ti fẹsẹ mulẹ, ti gbogbo aye si pariwo ti ijọba naa ko ba gbọ. Ẹ ma fọgbọn ko awọn ọmọ Hausa sinu iṣẹ ṣọja mọ, iwa to le fọ Naijiria patapata lẹyin ọla ni.

 

Ẹyin ọlọpaa, ẹ pada sẹnu iṣẹ yin o

Bi a ṣe n wi yii, bo tilẹ jẹ pe ọga awọn ọlọpaa patapata ti paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa pada si ẹnu iṣẹ wọn, pupọ ninu awọn eeyan naa ko ti i pada, wọn jokoo si teṣan wọn. Awọn mi-in ko tilẹ lọ si teṣan rara. Awọn kan ti ko mọ bi ọrọ yii ṣe jẹ n sọ pe ẹnu ọga ọlọpaa ko ka awọn ọmọ ẹ, ko lagbara kan, o paṣẹ fawọn ọmọ rẹ, wọn ko gbọ. Ọrọ naa ko ri bẹẹ, ko tiẹ ri bẹẹ rara. Ibi meloo ni ọga ọlọpaa yoo de, nibi meloo ni aṣẹ to ba pa yoo ti mulẹ. Bo ba mulẹ ni ilu nla, ṣe yoo mulẹ ni igberiko ni! Tabi ti awọn ọlọpaa ba yari mọ DPO kan lọwọ, ta ni yoo gba iru DPO bẹẹ lọwọ wọn. Ki wọn too gbe ẹjọ iru ọrọ bẹẹ de Abuja, nnkan yoo ti bajẹ pata. Eyi lawọn kan ṣe n lọgun lati ọjọ yii wa pe ki wọn fun ijọba ipinlẹ kọọkan lanfaani lati ni ọlọpaa tirẹ, ki gomina si laṣẹ lori awọn ọlọpaa to ba wa ni ipinlẹ rẹ. Ṣugbọn nitori ọrọ oṣelu, awọn ijọba apapọ ki i fẹẹ ya si i, bẹẹ ohun to yẹ ki wọn gbe yẹwo daadaa ni. Ni ti eyi to tilẹ ṣẹlẹ yii, ẹni ti Ṣango ba toju ẹ wọlẹ ni, lae, ko ni i ba wọn bu Ọbakoso. Ṣe nibi ti awọn janduku ti n dana sun ọlọpaa, ti wọn n dana sun teṣan, ti wọn n ja ọlọpaa mi-in sihooho, ta ni yoo waa ya lara lati ko aṣọ ọlọpaa kọrun, ti yoo ni oun n lọ sibi iṣẹ. Ati pe eto aabo wo ni ijọba Naijiria yii ṣe fawọn ọlọpaa yii funra wọn. Kin ni eto idiyelofo, iyẹn pe ti aburu ba ṣe wọn, eto wo ni wọn n ṣe fawọn araale wọn, awọn ọmọ wọn ati awọn ti wọn ba fi saye. Eelo lowo oṣu ọlọpaa ti yoo tori rẹ fẹmi laku, ṣe owo-oṣu ọlọpaa to ti kansẹlọ ni, tabi awọn oloṣelu kuẹkuẹ ti wọn ko mọ ọwọ ọtun wọn yatọ si tosi. Kin ni ijọba n ṣe lati mu inu awọn ọlọpaa dun, ti wọn yoo si ṣetan lati ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ, nigba ti owo-oṣu ati awọn ohun amayedẹrun to bojumu ba n tẹ wọn lọwọ. Gbogbo eleyii ko si nibẹ, ohun ti araalu ko si mọ ni pe iya to n jẹ ọlọpaa ju eyi to n jẹ ọpọlọpọ awọn eeyan ti wọn n rin kiri ilu lọ. Ijọba gbọdọ mojuto eleyii kiakia. Bakan naa, ki awọn ọlọpaa pada si ẹnu iṣẹ wọn, ohun to kọja ti kọja lọ, ko tun si ogun mọ, ko si ọtẹ, ki awọn naa si ba ara wọn sọrọ, ki wọn ri i pe wọn ko huwa aburu si araalu mọ. Bi wọn ba ri ninu wọn ti iwa ika ati ijẹkujẹ mọ lara, ki awọn naa maa ba ara wọn sọrọ, nitori gbogbo ohun to ba ṣẹlẹ ni kọrọ, o n bọ waa jade si gbangba. Gbogbo ohun to ba wọn yii, iwa buruku awọn ọlọpaa SARS lo ko o ba wọn. Iṣẹ wa lọwọ awọn naa lati ri i pe awọn paapaa ṣe iṣẹ ọlọpaa bo ti yẹ ki wọn ṣe e, ki wọn si sọ ara wọn di ọrẹ araalu bi wọn ti maa n pariwo. Bi wọn ba di ọrẹ araalu, awọn araalu gan-an funra wọn ni yoo gbe wọn bi aburu ba fẹẹ ba ọlọpaa kan. Ẹyin ọlọpaa, ẹ pada sẹnu iṣẹ yin o, Ọlọrun ko ni i fiya jẹ ẹnikẹni ninu gbogbo wa.    

 

Laye ijọba Buhari yii, afaimọ ki mẹkunnu gbogbo ma di atọrọjẹ

Owo-epo mọto tun lọ soke foo lẹẹkan naa. Ẹni ti yoo ba ra bẹntiroolu bayii, yoo ni aadọsan-an Naira (N170) fun lita epo kan. Naira mẹwaa ni wọn fi le kinni naa lojiji laarin oṣu kan pere. Nigba tọrọ yii kọkọ bẹrẹ, awọn ti wọn ti mu ọti oṣelu yo nilẹ wa, ati awọn mẹkunnu ti wọn ti fi tọrọ-kọbọ bo loju bẹrẹ si i kin ijọba yii lẹyin, wọn ni bi wọn ti n ṣe ni gbogbo agbaye niyẹn. Laakaye tiwọn ko jẹ ki wọn mọ pe ko si orilẹ-ede agbaye kan ti wọn n fi Naira mẹwaa si ori epo wọn lẹẹkan naa, bẹẹ ni ko si ibi kan ti wọn ti n fi owo kun owo-epo loṣooṣu bii ti ọdọ wa yii. Yatọ si eyi, ohun itiju lo jẹ, ṣugbọn awọn ko ri itiju naa, pe orilẹ-ede to n wa epo bẹntiroolu bii Naijiria yii, ki i ṣe ibẹ lo yẹ ki owo-epo wọn maa fi ojoojumọ gbowo lori. Buhari ṣeleri titi, awọn ọmọlẹyin rẹ leri titi, awọn amuṣua oloṣẹlu adugbo wa naa leri titi, wọn ni bi Buhari ba ti wọle bayii, owo-epo bẹntiroolu yoo di pọntọ ni. Koda funra wọn sọ ọ debii pe iṣẹ akọkọ ti wọn yoo ṣe ni lati tun awọn ileeṣẹ ifọpo wa ṣe, ki awọn si ṣee debii pe ki i ṣe owo-epo bẹntiroolu ni yoo ga soke ni Naijiria mọ. Ṣugbọn ọdun mẹfa lo ti n lọ yii, boya si ni Buhari ati awọn eeyan rẹ ranti pe awọn sọ bẹẹ ri, kaka bẹẹ, wọn ko gbogbo ilu siyọnu ni. Titi ko daa, ko si ọna reluwee, ko si si ọna irinajo mi-in ti a ni ju oju titi yii lọ. Nibẹ ni wọn n ko gbogbo ọja gba, nibẹ ni oṣiṣẹ n gba lọ sibi iṣẹ, ati awọn ọlọja gbogbo. Bi wọn ba fi kọbọ le owo-epo mọto, gbogbo ilu pata ni yoo kan lẹsẹkẹsẹ, nitori ko si ẹni kan ti ko ni ibi to n lọ. Nidii eyi, gbogbo owo ọja ni yoo lọ soke, ohun gbogbo yoo wọn gogo, inira mẹkunnu yoo si tubọ pọ si i. Ibeere ni pe ṣe ijọba yii ko ni eto kankan ti yoo dẹ mẹkunnu ilẹ yii lọrun ni! Tabi awọn naa ko ri i pe gbogbo eto ti awọn n ṣe ko ni idẹra kankan fun mẹkunnu ilẹ yii ni! Ṣe wọn yoo sọ pe awọn ko mọ pe inira nijọba wọn n mu ba araalu ni! Tabi ki lo n ṣẹlẹ gan-an paapaa! Bi ijọba yii ba n ba a lọ bayii, nigba ti wọn yoo ba fi kogba wọle, afaimọ ki gbogbo mẹkunnu ilẹ yii ma ti di ẹdun arinlẹ, ti wọn yoo si di atọrọjẹ nilẹ baba wọn. Eleyii ko daa, ko si le mu orukọ rere ba ijọba Buhari titi lae. Ohun ti yoo jẹ ki ijọba yii niyi ni ki wọn dẹ awọn mẹkunnu lara, ki wọn yee fowo kun owo-epo mọto mọ, eyi ti wọn ti ṣe yii, ki wọn pa a rẹ, ki wọn jẹ ki ẹrin pa mẹkunnu, ki gbogbo wa le fẹnu gbadura fun Buhari ati awọn ti wọn jọ n ṣejọba. Bi bẹẹ kọ, epe ni o, epe randu-randu!

 

Ṣebi ẹ ri olori ilẹ Ghana to ku nijọsi

Ọsẹ to k̀ọja yii ni olori ilẹ Ghana, Jerry Rawlings, ku. Bo si tilẹ jẹ pe ilẹ Ghana lo ti ṣejọba, to jẹ nibẹ naa lo ku si, kaakiri aye ni wọn ti ṣedaro rẹ, ti awọn eeyan si n pe ọkan ninu awọn olori ilẹ Afrika to ṣe rere fun ilu rẹ ni. Nigba ti nnkan buru ni Rawlings gbajọba gẹgẹ bii ologun. Nnkan bajẹ fun wọn debii pe ogunlọgọ awọn ọmọ Ghana lo sa wa si Naijiria, ati si awọn ilẹ Afrika mi-in, nitori ilu wọn ko fara rọ. Ṣugbọn Rawlings gbajọba ibẹ, o da sẹria fawọn ti wọn ba orilẹ-ede naa jẹ, o si mura lati ṣejọba daadaa. Ohun to dara ni pe ko too di pe o gbe ijọba naa silẹ, ilẹ Ghana ti yipada, o fi ẹsẹ eto ọrọ aje wọn mulẹ debii pe gbogbo awọn ti wọn ti sa lọ ni wọn pada sibẹ, ti awọn mi-in ko si tun sa lọ lati igba naa mọ. Bi ilẹ Ghana ba n da bii ẹdun, ti wọn n rọ bii owe loni-in yii, apẹẹrẹ ijọba rere ti Rawlings fi ẹsẹ rẹ mulẹ ni. Ohun ti gbogbo ọmọ Ghana ko ṣe le gbagbe rẹ ree, ti gbogbo aye si n daro rẹ pe aṣiwaju rere lo lọ. Ki Buhari ati awọn ti wọn jọ n ṣẹjọba yii fi ti Rawlings yii ṣe awokọṣe, nitori ohun ti kaluku ba ṣe ni araye yoo royin to ba lọ o. Jerry Rawlings, ọrun rere o!

Leave a Reply