O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Afigba ti Buhari atawọn eeyan ẹ fi gbese ṣe wa leṣe

Ni ọjo Ẹti to koja yii, ileeṣẹ to n ṣe iṣiro bi eto ọrọ aje orilẹ-ede wa ṣe n lọ fi han gbogbo aye pe Naijiria wa ti tun ko wọ inu rogbodiyan airowo-na, airitaje-ṣe, ainiṣẹ-lọwọ ati iyan ti yoo ba wa finra fun igba pipẹ. Bo ba jẹ araata kan lo sọ bẹẹ ni, kia lawọn oloṣelu inu APC yoo gbẹnu soke gan-n-gan, wọn yoo bẹrẹ eebu ta a wi yii, wọn yoo ni ọrọ oṣelu ni, wọn fẹẹ fi ba ti Buhari jẹ ni, tabi ki wọn ni wọn fẹẹ fi le Buhari loye nitori pe Fulani ni, tabi nitori pe ọmọ APC ni. Ṣugbọn funra ileeṣẹ ijọba APC funra wọn ni wọn kede ẹ pe eto ọrọ aje Naijiria ti dẹnukọlẹ, o si ti bajẹ debii pe nnkan yoo le gan-an fun gbogbo eeyan, afi ki Ọlọrun ṣọ wa. Loootọ ọrọ naa kan gbogbo aye, nitori arun korona to ba gbogbo wa finra, ṣugbọn ki i ṣe Naijiria nikan ni kinni naa ba ja, ọbun ri iku ọkọ tiran mọ ni tiwa. Ọbun to ni lati ọjọ ti ọkọ oun ti ku, oun ko wẹ, ki ọkọ rẹ too ku nkọ! O pẹ ti awọn ti wọn mọ nipa eto ọrọ-aje ti n pariwo pe gbese ti ijọba Buhari n fojoojumọ  jẹ yii n pọ ju, pe gbese naa yoo lẹyin. Owo ti ijọba yii ti ya laarin ọdun mẹfa ti wọn ti de yii ju eyi ti awọn ijọba bii marun-un to kọja sẹyin ti ya lọ. Ojoojumọ ni wọn n yawo, bi wọn ya ni Yuroopu, wọn yoo ya ni Asia, eyi ti wọn si ya l’Amẹrika ko ṣee fẹnu sọ. Ko si ohun to buru bi ijọba ba yawo, nigba ti wọn ba ni nnkan gidi ti wọn yoo fi owo naa ṣe. Ṣugbọn ọpọlọpọ owo ti ijọba Buhari n ya yii naa, awọn kan wa nibẹ ti wọn n ko o jẹ. Iwọnba owo to ba si ku nilẹ, awọn iṣẹ ti ko nilaari, iṣẹ to mu ti ẹlẹyamẹya dani, bii ka ni a fẹẹ ṣe ọna reluwee lati ilẹ Hausa lọ si orilẹ-ede Nijee, bii ka ni a fẹẹ sanwo kan fawọn ọmọ Boko Haram ti wọn ti ronupiwada, bii ki wọn ni wọn yoo fi owo kan tun ọsibitu ti ko ṣiṣẹ ṣe, ati awọn iṣẹ ti wọn yoo dawọ le ti ko ni i pari lae, awọn ohun ti wọn yoo fi owo naa ṣe ree. Owo ti wọn n ya naa yoo si tan, wọn ko si ni i ri kinni kan tọka si pe awọn fi owo ṣe, sibẹ, awọn ọmọ Naijiria yoo bẹrẹ si i san gbese owo ti wọn ko mọ bijọba wọn ṣe na an. Lojoojumọ lawọn ileeṣẹ n da awọn eeyan silẹ, awọn ọlọja patẹ, wọn ko rẹni beere ọja, awọn ọdọ jade ileewe, wọn ko riṣẹ ṣe, ohun to si ṣẹlẹ yii, o le ni ọdun mẹrindinlọgbọn ti iru rẹ ti ṣẹlẹ gbẹyin nilẹ wa. Ijọba yii ba eto ọrọ aje Naijiria jẹ pata. Lara ohun to si fa aburu yii ni pe ijọba wa ki i gbe awọn ti wọn ba mọ iṣẹ kan sidii iṣẹ naa, gbogbo iṣẹ ti wọn ba fẹẹ gba, awọn eeyan si, tabi ti wọn yoo ba gbe jade, ẹlẹyamẹya ni wọn yoo fi ṣe e, wọn yoo pa awọn ti wọn mọwe, ti wọn mọṣẹ ti, wọn yoo gbe iṣẹ naa fawọn eeyan wọn to jẹ olodo. Igbẹyin awọn iwa rakaraka naa lẹ ri yii o, Naijiria ti wọnu rogbodiyan eto-ọrọ aje, awọn ọjọgbọn aye si sọ pe nnkan yoo nira fọmọ Naijiria, afi ki Ọlọrun ma jẹ ko nira mọ wa ni tiwa. Ẹyin aṣaaju APC, ẹyin ti ẹ sun mọ Buhari ati ijọba rẹ, ẹ sọ fun Buhari yii ko tun nnkan ṣe, ko ji giri, ko dide, ki wọn yee na inakunaa, ina apa; ki wọn yee fi eto ati iṣẹ ọrọ aje ṣe ti ẹlẹyamẹya, ko mọ bi yoo ti pese iṣẹ fawọn ọdọ, ko si ṣeto bi nnkan Naijiria yoo ti ṣe dara. Ṣebi ileri ti oun ati awọn eeyan rẹ ṣe ki araalu too dibo fun wọn ree! KI lo waa de ti wọn ko ni i mu ileri wọn ṣẹ. Iya n jẹ mẹkunnu nilẹ yii! Ẹ sọ fun Buhari ko yi nnkan pada, bi bẹẹ kọ, nnkan yoo le mọ oun naa o! Nitori were sun, were sun, bi were ba sun kan ogiri, were yoo yiju pada. Kekere ni eyi ti wọn ri ti wọn n pariwo, rogbodiyan gidi n bọ lẹyin bi nnkan ba n lọ bayii; bo ba si ṣẹlẹ tan, ẹni ti ko ra paapaa yoo san.

 

Ẹyin ara Kwara, ẹ ẹ si ba Lai Muhammed sọrọ

Lọsẹ to kọja yii, Alaaji Lai Muhammmed, minisita fun eto iroyin ni Naijiria wa tun ṣe bo ti maa n ṣe, o gbiyanju lati pe gbogbo aye lọbọ, bẹẹ lo gbe irọ banta-banta kalẹ lati fi ṣe oju aye fun awọn to n ba ṣejọba. Ohun to buru ju lọ ninu ọrọ Lai Muhammed ni pe bi ọrọ kan ba ṣẹlẹ, ọkunrin naa mọ ododo o, o mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an, o si mọ bi ọrọ ti ri. Ṣugbọn kaka ko bọ sita ko sọ oootọ, Lai yoo yi ọrọ naa pada, yoo si gbe oje-marina nla kalẹ, irọ yoo si maa yi lu ara wọn lati ẹnu ọkunrin minisita naa, afi bii afiṣe. Ki lo tun fa eleyii? Lọsẹ to koja ni ileeṣẹ oniroyin agbaye ti wọn n pe ni CNN gbe iroyin wọn jade lori ohun to ṣẹlẹ ni too-geeti Lẹkki, lọjọ ti awọn ologun ṣina ibọn fun awọn ti wọn n ṣewọde wọn jẹẹjẹ, ti wọn dojukọ awọn eeyan ti wọn ko mu ohun ija kankan dani, tabi fa ijangbọn pẹlu ẹni kan. CNN ṣe atupalẹ iroyin naa, wọn si fi iwadii tiwọn kun un. Iroyin wọn naa ja irọ ti ọpọ awọn eeyan ijọba ti n pa pe ko sẹni to ku ni Lẹkki, o ja irọ awọn ṣọja ti wọn n sọ pe awọn ko yinbọn lu ẹni kan nitori oke lasan lawọn n yinbọn awọn si, bẹẹ lo ṣe afihan pe ọta ibọn ti wọn lo ni Lẹkki yii, awọn ṣọja Naijiria lo n lo iru ẹ lagbegbe yii. Ki i ṣe pe iroyin naa jẹ tuntun, ohun ti ọpọ eeyan ti mọ ni, iroyin ti awọn ileeṣẹ oniroyin ni ilẹ wa nibi naa si ti gbe jade ni. Ṣugbọn CNN fi kun un, nitori wọn fi awọn ṣọja ti wọn n yinbọn han, gbogbo aye si ri i pe awọn ṣọja naa ko doju ibọn wọn kọ oke, kaka bẹẹ, wọn doju ibọn naa kọ awọn ti wọn n ṣewọde taara ni. Bẹẹ ni wọn fi oku awọn eeyan han, bẹẹ ni wọn si tọpinpin ibi ti ọta ibọn ti wọn lo nibẹ ti n wa, wọn ni ọta ibọn ti Naijiria n ra lọdọọdun ni. Koda, afọju gbọ, aditi si ri i, pe ko si aṣanu ninu iroyin naa, bi ọrọ ti jẹ lawọn oniroyin agbaye yii sọ. Bi kinni naa ti jade ṣaa ni Lai Muhammed ko awọn oniroyin jọ, to si sọ pe irọ ni CNN pa, ko seeyan to ku, awọn ṣọja naa ko yinbọn luuyan, koda, ibọn wọn ko ni ọta gidi ninu. Bẹẹ ni Satide to tẹle e, ọga awọn ṣọja, Ahmed Taiwo, ni awọn ṣọja ko ọta ibọn lọ sibẹ, ibọn to ni ọta ninu ni wọn gbe lọ, ki wọn le fi mura silẹ bi kinni kan ba fẹẹ ṣẹlẹ ni, lati le daabo bo awọn ọmọ ogun to lọ sọhun-un. Eyi fi han pe ohun ti Lai Muhammed ko mọ nipa ẹ lo n sọ, nitori oun ko ṣaa si nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ko si ọmọ rẹ nibẹ, ko si araale tirẹ nibẹ, nitori awọn n jẹun, wọn n yo. Oun kọ lo ya fidio, ko si si nibi ti wọn ti n yinbọn. Bawo ni Lai waa ṣe mọ pe eeyan ko ku, ṣe ti ṣọja ba yinbọn, wọn n yin in lati fi ba ẹni ti wọn yin in lu ṣere ni! Ki ọrọ kan ṣẹlẹ, ki Lai Muhammed bẹrẹ si i purọ hẹrimọ hẹrimọ bayii ko tun orukọ  Buhari ati ijọba rẹ ṣe, o n ba wọn lorukọ jẹ si i ni. Naijiria wa la ti mọ pe opurọ ni minisita yii tẹlẹ, ṣugbọn oun naa ti sọ irọ rẹ di ti gbogbo agbaye bayii, o ti gbe e de ori CNN, gbogbo aye si ti mọ pe opurọ ni minisita wa. Ṣugbọn ki lo de ti Lai Muhammed n parọ fun gbogbo ọmọ Naijiria? Nitori kin ni! Ko sohun meji to fa a ju pe ko fẹ ki iṣẹ ti oun n ṣe yii bọ lọwọ oun lọ, ironu rẹ ni pe bi wọn ba gba iṣẹ minisita yii lọwọ oun, ki loun yoo tun maa ṣe laye oun yii! Bẹẹ orukọ rere san ju wura ati fadaka lọ. Bi Lai Muhammed ko ba ba awọn Buhari ṣiṣẹ, bi iwa ati iṣe rẹ ba dara, yoo ri iṣẹ to dara ju eyi lọ, yoo si niyi laarin igboro. Ṣugbọn pẹlu gbogbo eyi ti ọkunrin yii ti ṣe yii, nibo ni yoo rin si nigba ti ijọba ba kuro lọwọ Buhari, oju wo lawọn ọmọ Naijiria yoo maa fi wo o lẹyin ti wọn ba ṣẹjọba yii tan. Abi oun ro pe Buhari yii ni yoo maa ṣejọba titi aye ni, ti oun naa yoo si maa ṣe minisita lọ taye yoo fi parẹ! Ko ṣee ṣe bẹẹ, ile aye ko ri bẹẹ o. Ẹyin ara Kwara gbogbo, ẹ tete ba Lai Muhamed sọrọ, ẹ sọ fun un pe ohun ti i tan ni eegun ọdun, ọmọ alagbaa yoo ra akara fi jẹkọ. Awọn kan ti wa ni iru ipo bayii lanaa, wọn pada ja walẹ naa ni. Lai Muhammed yoo fi ipo minisita silẹ, yoo si jere gbogbo irọ to ba pa. Ẹyin ara Kwara, ẹ ba a sọrọ o, o ti kuro loko adeniyi o, oko adegbẹtẹ lo ku to n ro!

 

Awọn ọlọpaa ti wọn ji gbe nilẹ Hausa

Lati Borno ni wọn ti gbera, wọn n lọ si Gusau, ni ipinlẹ Zamfara, awọn ọga ọlọpaa mẹsan-an. Ọna Katsina si Zamfara ni wọn gba, nibi ti wọn ti n lọ ni awọn ajinigbe ti ji wọn gbe. Nigba ti awọn ọlọpaa ba n lọ, ti awọn janduku si da wọn lọna, ti wọn si ji wọn gbe, eleyii fi bi eto aabo orilẹ-ede yii ti bajẹ to han, o si yẹ ko ko ijaya ati idaamu ọkan ba awọn ti wọn n ṣejọba wa. Nibi ti wọn ti gbe wọn yii, ipinlẹ ti olori ijọba wa, Ọgagun Muhammadu Buhari, ti wa ni, ipinlẹ to si yẹ ko ni ojulowo eto aabo ni. Eyi to buru ni pe fun odidi ọjọ mẹwaa ti wọn ti ji awọn ọlọpaa naa gbe, ileeṣẹ ọlọpaa ko wi kinni kan, ati ileeṣẹ ọlọpaa Borno, ati ileeṣẹ ọlọpaa Zamfara, ko sẹni to da ọrọ naa sọ, wọn fi pamọ fun gbogbo araalu pata. Bi ko jẹ nigba ti awọn ajinigbe naa n beere owo, ti ọkan ninu wọn pe iyawo ẹ pe ko lọọ ta ilẹ oun, ki oun fi le ri ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin Naira (N800,000) ti wọn fẹẹ gba san, ko si ẹni ti iba mọ. Awọn oniroyin BBC lede Hausa ni wọn gbọ, ni wọn ba gbe iroyin naa jade lẹyin ọjọ kẹwaa ti wọn ti ji wọn gbe. Leyin ti ariwo naa gba gbogbo ilu, awọn ọlọpaa kede ni Satide to lọ yii pe awọn ti gba awọn mẹsẹẹsan-an ti wọn ji gbe naa, awọn to si fara pa ninu wọn ti n gba  itọju. Ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣe daadaa rara pẹẹ! Ani wọn tun n purọ pe wọn ko ji ẹnikankan gbe. Bawo ni wọn yoo ṣe ji ọlọpaa mẹsan-an gbe ti ijọba ati ileeṣẹ ọlọpaa yoo si sinmi bẹẹ, koda, ko jẹ wọn n ṣeto abẹle laarin wọn, ṣebi ikede lasan ni ijọba yoo ṣe, pe wọn ti ji awọn ọlọpaa kan gbe o, awọn wa lẹnu bi wọn yoo ti ṣe ri wọn. Ṣugbọn awọn ọga ọlọpaa wa ko sọrọ, ijọba naa ko si wi kinni kan. Ṣugbọn iyẹn kọ ni koko ọrọ yii, koko ọrọ yii ni pe nnkan buruku ni o, nigba ti awọn ajinigbe ba ti n le e ji ọlọpaa gbe, ti wọn si tọju wọn fun oṣẹ meji, ti ko sẹni to ri wọn gba jade. Bẹẹ ọlọpaa lawọn araalu gboju le pe wọn yoo gba awọn ti wọn ba ji awọn gbe. Ọdọ ta ni aralu waa fẹẹ sa lọ ti wọn ba ji eeyan wọn gbe bayii! Ohun ti ijọba yii ṣe gbọdọ mura gidi si eto aabo ilẹ wa yii niyi, nitori ko si ẹni kan ti ẹmi ẹ de ni Naijiria bayii mọ, ko si ohun ti ko le ṣẹlẹ ṣenikẹni. Ẹ ba wa tun eto aabo ilẹ yii ṣe o. Ẹ fọkan awọn araalu balẹ, ki awọn ọmọ Naijiria tiẹ le nisinmi diẹ laye wọn.

 

Fẹmi Gbajabiamila, ṣe ki i ṣe pe ko si nnkan kan o

Fẹmi Gbajabiamila, olori ile-igbimọ aṣoju-ṣofin jade ni ọọfiisi rẹ ni Abuja, o n lọ. Nigba to de ibi ti awọn fẹndọ ti wọn n ta oriṣiiriṣii iwe iroyin wa, o tẹsẹ duro lati ki wọn, nitori awọn yẹn ti mọ ọn, wọn maa n ki i bo ti n lọ. Oun naa fun wọn lowo, o si n ba tirẹ lọ, afi bi ọkan ninu awọn ọlọpaa to n ṣọ ọ kiri ṣe bẹrẹ si i yinbọn, nigba toju yoo si fi la, o ti yinbọn pa fẹndọ kan, Ifeanyi Okereke. Awọn fẹndọ to ku yari, wọn si ni afi ki ijọba da si ọrọ naa. Awọn DSS ti mu ọlọpaa yii ti mọle, wọn fẹẹ mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an. Gbajabiamila funra ẹ ti rojọ, ṣugbọn ẹjọ to ro ko daa rara, ẹjọ naa tubọ ba ọrọ yii jẹ ni. Ọkunrin naa ni nigba  toun fun awọn fẹndọ lowo tan, awọn kan ti bẹ siwaju awọn ti awọn ko mọ, ni awọn ọlọpaa oun ba bẹrẹ si i yinbọn soke, ibọn naa lo ta ba fẹndọ to ku. Ṣe ọrọ niyẹn! Ọrọ niyi ṣaa lẹnu olori ile-igbimọ aṣofin wa. Iyẹn ni pe nibikibi ti awọn eeyan ba ti sare jade, dandan ni ki awọn ọlọpaa yinbọn soke lati fi le wọn. Ki lo de ti ẹyin oloṣelu n sa fawọn araalu? Iwa yin ko daa ni! Ṣebi a ṣaa n ri awọn aṣofin ati oloselu ilu oyinbo ti wọn n lọ, ti wọn n bọ, laarin awọn eeyan tiwọn. Ki lo de ti oloṣelu Naijiria ko le jade ko ma ko ọlọpaa rin, ki lo de ti ẹ kuku mu aye le koko bayii! Fẹndọ ti iyawo ẹ ṣẹṣẹ bimọ, to n mura ikomọ, lo ri olori ile- igbimọ aṣofin orilẹ-ede rẹ, to ki i, ṣugbọn iku lo ba pade nibẹ. Ṣebi lara iwa ika ọwọ awọn ọlọpaa ti a n wi yii naa ree, ka kan maa yinbọn mọ araalu ṣaa, lai nidii gidi kan. Alaye ti Gbaja n ṣe yii ki i ṣe ọrọ. Ọrọ kọ rara! Ko wa nnkan mi-in sọ. Ati pe ki ijọba ri i pe wọn ba ọlọpaa apaayan yii ṣẹjọ, pipa ni ki wọn si pa oun naa nitori ẹni to ba pa alaiṣẹ, ko si ohun to tọ si ohun naa ju pipa lọ. Nigba ti wọn ba bẹrẹ si i dajọ iku fawọn ọlọpaa to ba paayan, ti ijọba si n yẹgi fun wọn, iwa ika awọn ọlọpaa yii yoo dinku, wọn yoo si sinmi a n yinbọn pa alaiṣẹ kiri! Ẹ ma jẹ ki eleyii bọ ninu ẹ o, ẹni to ba fibọn paayan, pipa ni ẹ pa a!

One thought on “O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

  1. E maa fi enikan sile ki e to lo nilu o , ati tinubu ati pastor emaparo stay in funwa oo ejeka yan eni to wunwa sipo nio……. eo ri oko nigeria tu etunwa baseje miran to ma bayeje raurau

Leave a Reply