O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Bẹẹ, awọn Boko Haram ko ni i gba Naijiria mọ wa lọwọ bayii

Ọsẹ to kọja yii la ba pe ni ọsẹ ẹkun oun oṣe ni Naijiria. Ojumọ kan, iṣẹlẹ aburu kan ni, bi wọn ti n jiiyan gbe, bẹẹ ni wọn n pa awọn mi-in. Ni ipinlẹ Borno, awọn Boko Haram si wọ inu oko irẹsi kan, nibi ti awọn araalu naa ti n ja irẹsi, wọn si pa eeyan mẹtalelogoji lẹẹkan. Wọn ka wọn mọbẹ, wọn si n bẹ wọn lori nikọọkan. Ko sẹni ti yoo gba wọn, ko si sẹni ti wọn le ke si ninu oko nibẹ, ko si ọlọpaa, ko si ṣọja, titi ti wọn fi pa awọn eeyan naa tan. Bi ọrọ yii ti jade lawọn ọmọ Buhari ti sare gbe iwe jade, wọn loun lo kọ ọ, o ni iku awọn eeyan naa ka oun lara, o dun oun gan-an ni, awọn maa ṣeto lati ri i pe iru iku bẹẹ ko tun waye mọ. Bo ba jẹ iru ọrọ yii lo jade lati ẹnu Buhari, eeyan kan ko le ka iye igba ti baba to wa ni Aso Rock yii ti sọ iru ọrọ bẹẹ jade. Ọrọ kan naa ti i maa i sọ jade lẹnu niyẹn: bi wọn ba pa oogun eeyan, yoo ni o dun oun, bi wọn pa ọgbọn eeyan, yoo ni o dun oun, bi wọn pa wọn ni Sokoto, ọrọ kan naa ni, bi wọn pa wọn ni Kafanṣa, ọrọ kan naa ni, bo si jẹ ilẹ Yoruba tabi ilẹ Ibo, ọrọ kan naa ni. Lati ọjọ ti Buhari ti waa n sọ pe oun yoo wa nnkan kan ṣe si i, ko ri kinni kan ṣe o. Ohun to n ṣẹlẹ ni pe, ki i ṣe Buhari lo n kọ awọn ọrọ yii, boya lo si mọ pe iru nnkan bẹẹ ṣẹlẹ. Idi ni pe bi Buhari ba mọ ni, itiju yẹ ko mu oun naa, pe irọ ojoojumọ ti oun n pa fawọn ọmọ Naijiria yii ko daa. Gbogbo igba to ba ti ni oun yoo ṣe kinni kan si ọrọ naa, ko si kinni kan to maa n ṣe, nibẹ ni ọrọ naa yoo si dakẹ si titi ti awọn Boko Haram yii yoo fi tun pa ẹlomi-in jẹ. Wọn ti pariwo titi pe ki Buhari le awọn olori ologun ẹ lọ, pe wọn ko kun oju oṣuwọn, tabi bawo ni awọn ọmọ ogun afẹmiṣofo ti wọn ko le to ẹgbẹrun marun-un (5000) ninu igbo wa yoo ṣe koju awọn ṣọja tiwa ti wọn le ni ẹgbẹrun lọna ọọọdunrun (300,000), ti wọn yoo si maa bori wọn ni gbogbo igba. O han pe apa awọn ṣọja wa ko ka awọn Boko Haram, bẹẹ ni ki i ṣe pe awọn ṣọja wa ko le jagun, awọn ti wọn fi ṣe olori wọn ni wọn n ṣe katikati. Sibẹ, bi gbogbo aye ti n pariwo to yii, Buhari ni awọn olori awọn ologun yii naa loun yoo maa lo lọ, nitori ko si kinni kan to ṣe wọn. Bẹẹ mẹwaa n ṣe awọn olori ologun yii, tabi bi nnkan kan ko ba ṣe wọn, bawo lawọn Boko Haram yoo ṣe maa ṣe bayii fun wa, ti wọn  yoo si maa fojoojumọ pa awọn alaiṣẹ, ti wọn yoo maa fi ẹmi wọn ṣofo bayii, ti ko si ni i si ẹni ti yoo gba wọn kalẹ. Afi ki ẹ ba wa bẹ Buhari ko ji giri, ki ẹ si fi ẹnu epe ba awọn ti wọn n purọ funfun lojoojumọ sọrọ, ki Ọlọrun gbe bukaata to ju agbara tiwọn naa lọ le wọn lọwọ, ki ẹ waa sọ fun Buhari pe ko wa nnkan ṣe si ọrọ eto aabo ilẹ yii, awọn to ba yẹ ko yọ niṣẹ, ko yọ wọn, ko si fi awọn ti yoo yanju iṣoro Boko Haram yii ṣe olori awọn jagunjagun wa. Ẹ tete sọrọ o, ki gbogbo ilu tete sọrọ. Nitori bi a ko ba sọrọ, ti ẹsẹ awọn Boko Haram yii ba rinlẹ daadaa tan nilẹ Hausa, gbogbo orilẹ-ede Naijiria ni wọn yoo kari. Ọlọrun ma jẹ ki Boko Haram gba Naijiria lọwọ gbogbo wa o.

 

Sultan, Lai Muhammed ni kẹ ẹ ranṣe si o

Sultan ilu Ṣokoto, Ọba Sa’ad Abubakar, sọrọ lọsẹ to kọja yii pẹlu itara. Bo ti n sọrọ naa lo n laagun, bẹẹ, agbalagba to n sọrọ, to n laagun, ẹkun gidi lo n sun. Sultan ni eto aabo ni gbogbo ilẹ Hausa ti dorikodo pata, ko ṣeni kan ti ẹmi ẹ de nibẹ mọ, ko si si ibi kan to lewu ju lati gbe ni gbogbo Naijiria lasiko yii ju ilẹ Hausa lọ. O ni awọn janduku ọmọ Boko Haram ti gba gbogbo ilẹ Hausa to jẹ lọsan-an gangan lo ku ti wọn n rin wọ inu ọja ati ile onile pẹlu ibọn lọwọ wọn, awọn agbofinro aa si maa wo wọn lai le ṣe ohunkohun fun wọn. O ni nnkan yoo buru fun Naijiria gan-an bi ọrọ ba n ṣe bayii lọ. Imọran tiwa ni pe ki Sultan wa aaye, ko lọọ ri Buhari funra ẹ. Ko ma ranṣẹ si i o! Bo ba ranṣẹ si i, irọ buruku lawọn olorikori to yi i ka yoo lọọ pa fun un, wọn yoo sọ pe ko si ogun mọ, ko si ọtẹ mọ nilẹ Hausa, koda, gbogbo Boko Haram lo ti sa lọ tan pata nigba ti wọn gbọ orukọ oun Buhari. Ko too lọọ ri Buhari paapaa, afi ko kọkọ ranṣẹ si Lai Muhammed pe ko waa ri oun o. O yẹ ko gbọrọ lẹnu ọkunrin aturọta-bii-elubọ yii nitori lati bii ọdun karun-un sẹyin ni Bọọda Lai ti n sọ pe ko si Boko Haram ni Naijiria mọ, apa ijọba Buhari ti ka wọn. O daju pe bi eeyan ba pe Lai bayii naa, ọrọ kan naa ti yoo sọ ni pe Buhari ti kapa awọn Boko Haram. Ki i ṣe pe o debẹ tabi o mọ ohun to n lọ nibẹ o, irọ-pipa kan rọ oun lọrun bii nnkan kan ni. Ohun to si ba aye ijọba Buhari jẹ niyi, nitori nibi yoowu ti wọn ba ha Buhari funra rẹ mọ, ko sẹnikan to n sọ ododo fun un. Irọ nla nla ni wọn maa n pa fun un, ti wọn yoo si ni ko si ohun kan to n ṣẹlẹ si awọn ọmọ  Naijiria, awọn ọmọ ẹgbẹ alatako kan n pariwo lasan ni. Buhari nilo ẹni ti yoo sọ ootọ fun un, ẹni ti yoo ba a sootọ ọrọ, iru awọn Sultan yii lo si le ṣe e. Nnkan n daru, nnkan si n bajẹ, bẹẹ ilẹ Hausa ni gbogbo atẹgun buruku yii ti n fẹ wa. Bi Sultan ba mọ pe ọrọ yii ka oun lara bo ti n wi yii, ko lọọ ri Buhari, ko si sọ fun un funra ẹ, boya ọkunrin naa yoo gbọ ọrọ si i lẹnu. Bi ko ba ṣe bẹẹ, bo ba jẹ bi nnkan ti n lọ yii naa lo n lọ, ọrọ ti Sultan sọ yoo ṣẹlẹ, awọn Boko Haram yoo gba ilẹ Hausa tan pata, koda, wọn yoo le awọn ọba wọn kuro lori oye, nigba naa ni kaluku yoo mọ pe aburu to wa ninu ijọba yii ju ti Boko Haram yii paapaa lọ. Sultan, tete! Ọjọ n lọ o.   

 

Ṣe ẹyin naa ti wọ reluwee awọn ọmọ Buhari

Lọdun to kọja, nigba ti minisita fun eto igbokegbodo ọkọ, Chibuike Rotimi Amaechi, n pariwo kiri pe Buhari ti ṣe ohun tẹni kan ko ṣe ri, o ti ra ọkọ oju-irin rẹpẹtẹ tuntun-n-tuntun lati maa rin, ko maa ko ero, ki awọn ọmọ Naijiria le maa jẹ anfaani ịjọba dẹmokiresi ti Buhari yii gbe de. Gbogbo alaye ti Amaechi n ṣe nigba naa, nitori pe ibo ti sun mọle ni. Ohun to si ṣe ni lati lo ọrọ reluwee naa lati fi tan awọn eeyan jẹ, ati lati tan Buhari funra ẹ, ki wọn le dibo fun ijọba wọn, ki Buhari paapaa si le ro pe minisita oun yii n ṣiṣẹ gan-an niyẹn. Amaechi lọ sọdọ awọn Ṣiana, awọn si ta awọn aloku ọkọ reluwee fun un, o si kun ọkọ naa lọda, o ko wọn wa si Naijiria, wọn waa ko awọn oloṣelu ati awọn araalu jọ, wọn ni ki wọn waa wo ara ti Buhari da, o ti ṣe bẹẹ, o ko reluwee de jigan. Ṣugbọn ko ju oṣu mẹta ti reluwee ti Amaechi ni oun ra ni tuntun fi bẹrẹ si i ku soju ọna, eefin buruku to dudu kirimu ati ikọ oorekoore leeyan yoo fi da ọkọ oju-irin Amaechi mọ, ko si tọjọ, ko toṣu, tawọn eeyan fi mọ pe aloku pata ni gbogbo reluwee ti ọkunrin yii ko wa, bẹẹ owo tuntun ni wọn gba lọ. Reluwee aloku ni wọn kun lọda, wọn kan waa fi ṣe arumọjẹ fawọn ọmọ Naijiria ni. Boya ni oṣu meji yoo kọja ki reluwee Amaechi yii too ku si oju ọna, eyi to si ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii buru debii pe Ọlọrun lo yọ awọn ero ti reluwee naa ko. Nitori laarin oru, ninu igbo ni reluwee naa da iṣẹ silẹ, bo ba si jẹ awọn Boko Haram gba agbegbe naa kọja ni, wọn yoo maa ko wọn bii adiẹ sinu ago ni. Bawo ni ijọba kan yoo ṣe maa fi ẹmi awọn araalu rẹ wewu bayii!  Bawo ni ijọba kan yoo ṣe kuku koriira awọn eeyan ti wọn n ṣejọba le lori bayii! Bawo ni minisita kan yoo ṣe ko aloku reluwee kalẹ pe ki awọn ọmọ Naijiria maa lo o pẹlu irọ buruku ti wọn n pa fun wọn. Bo ba jẹ loootọ ni Buhari mọ ohun to n lọ, ko si idi kan ti ko fi gbọdọ le ọkunrin Amaechi yii danu lẹsẹkẹsẹ. Ki i ṣe ki wọn le Rotimi Amaechi yii kuro lẹnu iṣẹ ijọba nikan ni o, ijọba Buhari gbọdọ ba a ṣẹjọ, ki wọn beere bo ṣe nawo ti wọn ko fun un, ki wọn beere idi to fi ko ẹmi awọn ọmọ Naijiria sinu ewu bayii! Ko si ohun to yẹ ko kangun ọrọ rẹ ju ko kuro nile ijọba, ko di ero itimọle lọ. Bi eleyii ba ṣẹlẹ si oun, awọn mi-in to ba fẹẹ ṣejọba ni Naijiria yoo bẹru lati purọ fun araalu, lati ko owo wọn jẹ, ati lati fi owo irinṣẹ ati ohun-eelo tuntun ra aloku fun wọn. O di dandan ki ijọba Buhari fiya to tọ jẹ Amaechi, lara ohun to le mu Naijiria daa niyẹn!

 

Ki lo n ṣe awọn eeyan yii bayii o

Ni ọsẹ to kọja, awọn agbofinro Hisbah ti wọn wa ni Kano kọ iwe kan si ileeṣẹ redio CoolFM ni Kano, iwe naa jẹ iyanu fun awọn eeyan ti ki i ṣe Naijiria paapaa, awọn ti wọn si jẹ ọmọ Naijiria n sọ laarin ara wọn pe ki waa ni orilẹ-ede yii da bayii o. Awọn Hisbah yii ki i ṣe ọlọpaa o, ọlọpaa Sharia ni wọn pe ara wọn, pe ko si ẹni to gbọdọ lodi si ofin Sharia lagbegbe awọn. Awọn ni wọn n fọ ṣọọbu awọn ọlọti, ti wọn si n gbogun ti awọn aṣẹwo ati awọn onitẹtẹ. Eleyii daa daadaa, ṣugbọn ohun to buru ninu iwa wọn ko ju ki wọn ma jẹ ki awọn ẹlẹsin mi-in ṣe ẹsin wọn lọ, tabi aṣeju baba aṣetẹ to mọ awọn eeyan wa lara lapa Oke-Ọya. Ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii ni wọn n pe ni Black Friday ni gbogbo aye. Ilu Amẹrika lo ti bẹrẹ, ko si si ohun ti wọn fi n ṣe ju ọjọ ti wọn n na ọja ni ọpọ lọ. Nitori pe ọjọ naa bọ si ọjọ keji ọjọ Idupẹ (Thanksgiving) lọdọ wọn lọhun-un, wọn maa n fi ọjọ naa ta ọja gbogbo ni owo pọọku. Ko si ọja ti eeyan ko ni i ra ni ọjọ naa lowo pọọku. Awọn ọlọja gbogbo aa si maa polowo ọja wọn, ki awọn eeyan le lọọ ra a. Awọn onileeṣẹ yii ni wọn n polowo ọja lori redio ni Kano, lawọn agbofinro Sharia yii ba kọwe si wọn ni redio yii, wọn ni ki wọn yee darukọ Black Friday lori redio wọn, pe ti wọn ko ba sinmi, ohun ti wọn yoo ri yoo le ju ohun ti wọn ro lọ. Ofin to da ileeṣẹ ibanisọrọ gbogbo silẹ ko fi aaye gba ẹnikẹni lati halẹ mọ wọn, tabi lati ṣe wọn nibi, ṣugbọn awọn Hisbah yii fẹẹ ṣe bẹẹ, wọn ni nitori Kuraani ti sọ pe ọjọ mimọ ni ọjọ Friday. Bẹẹ ni Saudi Arabia, ni ibi to jẹ ikorita ẹsin Islam, wọn n ṣe ipolowo ọja loriṣiiriṣii, ti wọn si n pariwo Black Friday lori redio ati tẹlifiṣan wọn. Bakan naa ni ọrọ naa si kun ori ẹrọ ayelujara, bi eeyan si tẹ “Black Friday in Saudi Arabia” sori Google, yoo ri oriṣiiriṣii nnkan ti wọn n ṣe. Ṣugbọn wahala tiwa pọ nibi yii gan-an, o pọ gan-an ni o. Ọrọ ti ko kan wa rara la oo maa tori ẹ ja, ti a oo maa tori ẹ yọ ara wa lẹnu. Bi wọn ba n ṣe Black Friday ni ilẹ awọn Larubawa gbogbo, kin ni ti awọn eeyan wa nilẹ Hausa nibi lati maa mura ija nitori eyi. Tabi awọn eeyan yii mọ ẹsin yii ju awọn ti wọn mu un wa fun wọn lọ ni. Ko si ohun meji ti awọn tọdọ wa yii n ṣe ju ki wọn fi jale, ki wọn fi rẹ awọn eeyan jẹ, ki wọn si fi fi ọgbọn gba nnkan wọn kuro lọwọ wọn lọ. Bakan naa ni wọn ko tun orukọ ẹsin Islam ṣe loju awọn eeyan, wọn ko fi ẹsin naa han bii ẹsin ifẹ, wọn n fi ẹsin naa han bii ẹsin to ni iwa ika ninu, ti ko si si aanu nibẹ. Ohun ti awọn Hisbah ati awọn ẹlẹgbẹ wọn mi-in n ṣe nilẹ Hausa niyi. Naijiria ki i ṣe orile-ede ẹlẹsin kan gẹgẹ bo ṣe wa ninu ofin wa, ẹsin to ba si wu kaluku lo le ṣe, ti ko sẹni kan to gbọdọ yọ ọ lo lẹnu. Ohun to maa n da wahala silẹ ni pe ijọba ki i da si iru ọrọ bayii nigba to ba yẹ, o digba to ba da rogbodiyan silẹ ki wọn too bẹrẹ si i soyinbo ẹgbẹ. Ijọba gidi gbọdọ ji giri si iru eyi, ki wọn pe awọn ti wọn kọ lẹta naa, ki wọn si kil̀ọ fun wọn, ki wọn ṣalaye fun wọn pe ofin wa lo faaye gba ki kaluku sin ẹsin to ba wu u, ki ẹnikẹni ma si ṣe fi ẹsin rẹ ko ẹlomi-in laya jẹ. O ba ni, ko bajẹ. Ẹ pe awọn Hisbah yii, ẹ ba wọn sọrọ, ẹ jẹ ki wọn mọ pe Naijiria ki i ṣe orilẹ-ede ẹlẹsin kan o!

Leave a Reply