O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Ibo ipinl Edo yii, ẹkọ pataki lo y ko jẹ fawọn oloṣelu gbogbo

Ibo ti wọn di ni ipinlẹ Edo ni ọjọ Satide to kọja yii ti wa, o si ti lọ, ṣugbọn ẹkọ pataki lo yẹ ki ọrọ ibo naa jẹ fun awọn oloṣelu ti wọn ba ni laakaye. Idi ẹkọ to wa nibẹ ni pe awọn araalu lo lagbara ju lọ, ko si ẹni to lagbara to wọn, bi araalu ba sọ pe ibi yii ni awọn n lọ, tabi pe ẹni yii lawọn n fẹ, ti gbogbo wọn si fi imọ ṣọkan lori ẹ, yoo ṣoro pupọ ki oloṣelu kan too foju wọn gbolẹ, ati pe oloṣelu ti gbogbo aye ba n rọ lẹyin rẹ, nitori pe o n ṣe ohun ti aye n fẹ ni, to ba ti bẹrẹ si i ṣiwa-hu, to bẹrẹ si i ri ara rẹ bii pe oun ju gbogbo awọn eeyan naa lọ, bo ṣe gun oke naa ni yoo ṣe ja bọ. Ohun to ṣẹlẹ ni Edo yii ni eeyan yoo fi ṣe apẹẹrẹ, nitori bo tilẹ jẹ pe awọn alagbara gbogbo, lati ileeṣẹ Aarẹ, titi dori awọn agbaagba oloṣelu agbegbe naa, wa lẹyin Ize-Iyamu to n du ipo labẹ APC, sibẹ, ibo to mu ko to nnkan. O fẹrẹ jẹ ni gbogbo ipinlẹ naa lawọn araalu ti fohun ṣọkan pe Godwin Ọbaseki lawọn fẹ ko maa ba iṣẹ rẹ lọ. Gbogbo eeyan lo mọ pe irẹjẹ ni ọrọ Obaseki fẹẹ bọ si, wọn mọ pe bi adiẹ da mi loogun nu, ma fọ ọ lẹyin ni ọga rẹ tẹlẹ, Adams Oshiomhole, fẹẹ ṣe fun un, wọn si mọ pe kinni naa ko ni i mu ohun rere kan wa fun awọn ara ipinlẹ naa ju ipalara lọ. Ohun to dara ju nibẹ ni pe loootọ lawọn oloṣelu wọnyi ha owo ati awọn nnkan mi-in, awọn araalu si gba owo wọn daadaa, ṣugbọn ẹni ti wọn fẹ ni wọn dibo fun. Eyi fi han pe awọn ọmọ Naijiria naa ti n gbọn. Oloṣelu to ba fẹẹ ha owo ko mura si i, awọn eeyan yoo gba a lọwọ rẹ daadaa, wọn kuku ti mọ pe owo awọn ni. Ṣugbọn wọn gba owo lọwọ rẹ ko ni ki wọn dibo fun un, ohun ti wọn si ṣe fun Oshiomhole ati eeyan rẹ niyi. Ọbọ ati ẹranko lasan ni awọn oloṣelu ilẹ yii maa n pe awọn araalu, nitori rẹ ni wọn ṣe maa n gba wọn bii bọọlu sibi to ba wu wọn, wọn ti fọkan si i pe pẹlu owo awọn, ohun ti awọn ba sọ fawọn eeyan ni wọn gbọdọ ṣe. Bi gbogbo Naijiria ba gbọn bayii, ti oloṣelu ko owo wọn wa, ti wọn gba a lọwọ ẹ daadaa, ṣugbọn ti wọn dibo fun ẹni ti ọkan wọn mu lọjọ idibo, ko si ohun to buru nibẹ, nigba to jẹ ti wọn ba ni awọn ko gba owo tabi gba ohun ti oloṣelu ko wa, bii igba ti wọn n fi ẹmi ara wọn wewu ni. Ṣugbọn ti wọn ba gba owo lọwọ oloṣelu, ki wọn dibo fun ẹni ti ọkan wọn ba mu, ẹni ti ọkan wọn sọ fun wọn pe yoo ṣe ilu awọn tabi agbegbe awọn daadaa. Ki ibo Edo yii jẹ ẹkọ fun awọn oloṣelu, pe bi wọn nawo ju bẹẹ lọ, bi iwa wọn ko ba dara, ti araalu ko si fẹ wọn, ofo ni wọn yoo gba lọjọ idibo. Ko si jẹ ẹkọ ati ilaniloju fun gbogbo araalu, pe ọwọ wọn ni gbogbo agbara wa, wọn gbowo lọwọ oloṣelu ko ni ki wọn dibo fun un, ẹni ti ọkan wọn ba fẹ ni ki wọn dibo fun, ohun kan naa to le mu oriire ba gbogbo wa niyẹn.

 

Ironu ikooko ni yoo pa aja

Diẹ bayii ni ikooko ati aja fi ju ara wọn lọ, bi aja ba tobi daadaa, ti aaye si gba a, o maa n tobi ju ikooko lọ. Ṣugbọn kinni kan wa ti ikooko fi ju aja lọ, iyẹn naa ni eegun buruku to wa lara ikooko, ni gbogbo ọna lo fi lagbara ju aja lọ, ko si si igba to pade aja ti ki i ṣe ewu buruku ni aja naa wa, nitori bii ọmọde meji n ṣere ni yoo lu u pa. Nidii eyi, gbogbo igba ni aja maa n ronu ikooko, abi bawo ni nnkan to ri kekere yoo ṣe maa fiya jẹ ohun to tobi. Bi ọrọ Adams Oshiomhole ti ri loni-in yii ree, nitori igi to fi oju kere, igi naa ti fọ ọ loju bayii. Ibo ti wọn di kọja ni Ẹdo yii, wọn fi gba aṣọ iyi to wa lara Oshiomhole ni, ki Ọlọrun ma gba aṣọ iyi to wa lara kaluku wa. Bawo ni yoo ṣe ṣe e, ibo ni yoo gbe ọrọ ara rẹ gba, gbogbo ohun to fi n ṣakọ ninu ẹgbẹ APC ko ju pe o n mu ipinlẹ rẹ lọ, iyẹn ni pe ipinlẹ rẹ wa ninu awọn ipinlẹ to jẹ ti APC. Ni bayii, ipinlẹ naa ti bọ kuro lọwọ rẹ, o ti di ipinlẹ awọn PDP, eyi ni pe ko ni iranwọ tabi ipo kankan, tabi agbara kan to le lo ninu APC, bi wọn si n pin in, ko kan an paapaa, ko le ri kinni kan gba ninu ẹgbẹ wọn, nitori ẹgbẹ naa kọ lo n ṣe akoso ipinlẹ rẹ. Bẹẹ oun lo fi aṣeju ba gbogbo ohun to n ṣe jẹ, oun ni wọn fi jọba tan, to tun n wẹ awure. Oun lo fi agbo fun eegun, ti ko ju okun rẹ nu. Oun lo fi ọmọọṣẹ rẹ joye, ti ko fẹ ki tọhun ṣejọba. Ohun to si buru ni pe nigba ti Adams Oshiomhole yii n ṣe ijọba tirẹ ni ipinlẹ Edo yii kan naa, gbogbo awọn agbaagba oloṣelu ibẹ ti wọn n fẹẹ sọ pe bawọ ni yoo ti ṣe e, tabi ti wọn n fẹ ko foribalẹ fawọn, gbogbo wọn ni Oshiomhole ba ja, to si ri i pe oun da wọn jokoo sile, o ni ko saaye baba isalẹ ninu eto oṣelu ipinlẹ Edo. Gbogbo eeyan lo patẹwọ fun un nigba naa, afi bi oun naa ṣe waa kuro nipo gomina to fẹẹ maa ṣe baba isalẹ fun ẹni to wa nibẹ, to fẹ ki  tọhun maa waa foribalẹ foun. Nibi ti wahala ti bẹrẹ niyẹn o. Kaka ko si ṣe suuru, ko ṣe bii iya oniṣọọbu àwo tánńganran ti ewurẹ sa wọ, to rọra fi suuru le e jade ko ma baa fọ ọ ni gbogbo àwo to n ta, oun ko ṣe bẹẹ, o fi girigiri ati girimọkai le ewurẹ to sa wọ ṣọọbu tirẹ, niyẹn ba fọ ọ ni gbogbo awo. Ohun to buru ni pe nidii oṣelu, iru agbara ti Oshiomhole ti ni lati bii ọdun mẹwaa sẹyin, ko le ri iru agbara naa mo laye! Agbara naa ti bọ, o bọ niyẹn! Oun naa ti di agbelẹ he eeyan, wọn yoo kan maa wo o lasan taanu-taanu ni, agbara oṣelu ipinlẹ ti yọ bọ sọwọ awọn mi-in, tirẹ tan nibẹ niyẹn. Ohun ti yoo si maa fa ironu ojoojumọ fun un ree, paapaa to ba n ri Godwin Obaseki ati awọn alatilẹyin iyẹn tuntun. Ṣugbọn yoo maa wo o, yoo maa ronu ni, ko ni i si ohun ti yoo le ṣe, ironu ikoko lansan ni, bẹẹ ironu ikokoo ni yoo pa’ja!

 

Nibo ni Tinubu yoo gbe oju ẹ si bayii o!

Awọn ti wọn gba Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu nimọran pe ko lọọ ṣe odidi fidio, ko fi maa bu Godwin Obaseki, ko si maa pe e ni oriṣiiriṣii orukọ nitori ibo gomina ti wọn di kọja yii ko fun un nimọran to daa, nitori wọn kan fi orukọ rẹ ta tẹtẹ ni. Eyi-jẹ, eyi-o jẹ, ni wọn fi ọrọ naa ṣe fun un, bi o si ṣe maa n ri fun onitẹtẹ lẹyin ti esi tẹtẹ ba jade naa lo ri fun Aṣiwaju yii. Bi onitẹtẹ ba ta tẹtẹ to ba jẹ, ijo ati ayọ gidi ni ninu ile ati ibi to ba jẹ̀ si, nitori tẹtẹ naa yoo mu owo ati iyi wa fun un. Ṣugbọn bo ba ṣe pe ko jẹ ni, abuku ati ẹtẹ ni tẹtẹ to ta naa yoo mu wa, yoo si sọ ọ di talaka, bi ko ba jẹ pe o ni owo mi-in nipamọ. Awọn kan ni wọn ni ki Tinubu fi ọrọ ibo Edo yii ta tẹtẹ. Tẹtẹ to wa nibẹ naa si ni pe bo tilẹ jẹ pe ibo Edo yii ko kan an lọwọ tabi lẹsẹ, ṣugbọn nitori pe o n pe ara rẹ ni aṣiwaju APC lapapọ, ti awọn mi-in naa si n ba a du oye naa pe oun nikan kọ ni National Leader, bo ba ṣe pe bi wọn ṣe dibo yii, ti ẹni ti APC fa kalẹ ba wọle ni, nigba to jẹ oun nikan lo jade to ṣe fidio, to si fi ara rẹ han bii aṣaaju tootọ, ti ipinlẹ Edo ki i si i ṣe ipinlẹ tabi agbegbe rẹ, yoo ṣoro ki ẹnikẹni too jade pe oun ni aṣaaju APC, tabi pe oun n ba Tinubu du ipo naa, kaluku yoo ti gba pe aṣaaju awọn ni, ati pe ko si ibi ti ko ti le da si ibo wọn. Ṣugbọn nigba ti ibo yi waa ri bo ṣe ri yii, nnkan buruku gbaa ni. Tẹtẹ ti gbodi, owo ti jona, iyi ati apọnle si ti ba ibomi-i n lọ. Koda, awọn kan sọ ninu ẹgbẹ wọn bayii pe Tinubu to da si ọrọ naa lo tubọ jẹ ko buru fun APC nibẹ, nitori wọn ko fẹ orukọ Tinubu lọdọ wọn rara. Bẹẹ eleyii le ma jẹ ododo rara. Eyi ti yoo mu abuku inu tẹtẹ ti Tinubu ta yii wa ni awọn ti wọn ti n pọn ọn le ni apa Oke-Ọya lọhun-un, ti wọn n pọn ọn le  pe ohun gbogbo to ba ṣẹlẹ ninu APC ni ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo, Tinubu ni alaṣẹ. Iyẹn ko si mọ bayii, nitori Oshiomhole to pọn sẹyin lo ti ja bọ yii, ibo ti i ba fun un ni apọnle lo ti bọ mọ wọn lọwọ yii, ẹgbẹ APC ti sọ ipinlẹ pataki kan nu, awọn aṣaaju ẹgbẹ naa ni Abuja si n sọ pe Tinubu naa lọwọ si i. Ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn oloṣelu wa ki i mọ ibi ti agbara wọn mọ. Wọn maa n ro pe awọn ju bi wọn ti jẹ lọ, eyi ni wọn ṣe maa n tẹlẹ hobahoba, ti wọn yoo maa mi họọ họọ, ti wọn yoo si maa ro pe awọn ni igbakej Ọlọrun. Bi Tinubu ba jokoo rẹ jẹẹ ni, aṣọ iyi rẹ yoo wa lọrun rẹ, koda, awọn ara Abuja yoo ṣi maa bẹru rẹ kaakiri. Ṣugbọn ibo ipinlẹ kan ti da nnkan ru bayii, ọjọ ti Tinubu yoo ri iyi rẹ ra pada, ti yoo si di aṣaaju APC tootọ, ti gbogbo eeyan yoo si gba wi pe oun nikan ni aṣaaju awọn ninu ẹgbẹ wọn, ọjọ naa ti tun jinna si i bayii, nitori ohun to ṣẹlẹ ni Edo yii ti fa iwe ọrọ naa ya. Abi bawo ni yoo ṣe ṣe e ti wọn ba ni kinni kan an ṣe nipinlẹ Edo bayii, ṣe yoo pe Gomina Obaseki ni ọrẹ rẹ ni abi ọta rẹ ni, lẹyin to ti tori ọrọ oṣelu ṣe odidi fidio eebu fun un. Afi keeyan yaa maa woran, Tinubu nikan lo mọ ọna ti yoo gba yọ. Ẹkọ inu ọrọ yii ni ki oloṣelu mọ iwọn ara rẹ, ko mọ ibi ti agbara oun mọ, ati iru ọrọ to yẹ ko tẹnu agbalagba, ẹni apọnle jade. Idi ni pe agba ti o ba wẹwu aṣeju, ẹtẹ ni yoo fi ri, bi agbalagba kan ba so agbado mọdii, yoo kan di alawada adiẹ lasan ni.

 

Abi awọn ọmọ Buhari tun fẹẹ ba Wọle Ṣoyinka naa ja

Ki i ṣe gbogbo igba ni ọrọ Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ati ti Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ maa n ba ara wọn mu. Nibikibi ti Ọbasanjọ ba gba, Ṣoyinka ki i fẹẹ ba ibẹ kọja rara, nitori ọrọ oun ati Ọbasanjọ ki i ṣe oni, ki i ṣe ana, ọjọ pẹ ti wọn ti maa n ta ko ara wọn. Nitori rẹ lo ṣe jẹ nigbakigba ti awọn mejeeji ba sọrọ, ti ọrọ wọn ba si dọgba, ki kaluku yẹ ọrọ naa wo daadaa, ẹni ti wọn ba si sọ ọ fun, ko mọ pe ki i ṣe ọrọ ere rara. Ọsẹ to kọja lọhun-un ni Oloye Ọbasanjọ sọ pe Naijiria fẹẹ fọ si wẹwẹ, pe awọn ọmọ orilẹ-ede yii ti pin si yẹlẹyẹlẹ, wọn si ti dọta ara wọn, bẹẹ ijọba Buhari yii lo sọ wọn di ọta ara wọn. Ki lo sọ bẹẹ si ni awọn ọmọ Buhari gba ti wọn fi ya a, wọn ni ko dakẹ, ko ma sọ bẹẹ mọ jare. Ọrọ ti ko ni itumọ lo n ti ẹnu rẹ jade. Wọn ni ko si ohun to ṣe Naijiria, gbọn-in lo duro. Awọn ọlọgbọn mọ pe ọrọ omugọ lawọn eeyan naa n sọ, ọrọ ẹni to ri ina nilẹ, to si ni ki ọga awọn maa kori bọ ọ nitori ijẹkujẹ ti awọn n jẹ leti ina naa ni. Nibi ti wọn ti n fa eleyii ni Ṣoyinka ti da si i, o ni ọrọ gidi ni Ọbasanjọ sọ, ohun to n ṣẹlẹ lo si wi, orilẹ-ede Naijiria ti n pin si wẹwẹ, awọn eeyan to wa ni Naijiria si n fojoojumọ di ọta ara wọn, nitori bi awọn Fulani ṣe ya wọ awọn ilu oniluu, ti wọn si n huwa aburu loriṣiiriṣii, ti Buhari ko si le da wọn lẹkun. Nigba ti Ṣoyinka sọrọ yii, gbogbo awọn eeyan simi lọ, idi ni pe ọkan ninu awọn alatilẹyin Buhari to gbe e wọle ni, bo tilẹ jẹ pẹlu ọrọ ẹnu lasan. Ṣugbọn ko jọ pe awọn ọmọ Buhari fẹran ọrọ ti Ṣoyinka sọ, wọn bẹre si i gba iwaju, wọn n gbẹyin, wọn ni Ṣoyinka le ri Buhari to ba fẹẹ ri i, ọdọ rẹ lo si yẹ ko ti waa sọ iru ọrọ to n sọ nita yii. Ṣe ọrọ niyẹn lẹnu awọn digbolugi! Tabi kin ni ọrọ aṣiri ninu pe ilu ko dara, ki ẹni ti o ba si mọ ohun to n lọ ba olori ijọba sọrọ, ki wọn le ṣe atunṣe. Ewo ni ọrọ aṣiri ninu iyẹn! Gbogbo awọn ti wọn ti n wa ni kọrọ, ti wọn n pa kubẹkubẹ lalẹ, ti wọn n sọrọ fun Buhari, ewo lo mu lo ninu ọrọ ti wọn sọ fun un. Ododo ọrọ ko ni pe wọn n tẹ kọlọfin si ninu, nitori ododo ko ni kọlọfin, awọn alaboosi nikan ni wọn maa n wa ibi sa si kiri. Ki Buhari ma gboju le awọn ti wọn yi i ka yii o, ko ma si ṣe tẹle ọrọ wọn, nitori awọn gan-an lo da bii pe wọn fẹẹ ko ba a, wọn si fẹẹ ba orukọ rẹ jẹ titi aye, lati irandiran! Abi nigba ti wọn ba fọ Naijiria mọ ọn lori nkọ! Ki i ṣe gbogbo wa ni iya rẹ yoo jẹ ni! Awọn akoṣibero gbogbo, nigba wo ni Ọlọrun paapaa ko ni i mu wọn.

Leave a Reply