O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Awọn wo ni wọn n fun Buhari yii nimọran gan-an

Olori ilẹ wa, Ọgagun agba Muhammadu Buhari, lọ si orilẹ-ede Mali, lọsẹ to kọja. Ohun pataki kan naa lo tori ẹ lọ, o lọọ ba wọn pari ija lọhun-un ni. Ko pada yaayan lẹnu pe wọn ko rija naa pari, koda, abuku ni wọn sọ pe o kan Buhari nibẹ, nitori ko si ẹni to ka ọrọ rẹ si kinni kan laarin awọn olori ijọba to ku. Ọrọ yii ko le ṣe ko ma ri bẹẹ, ẹni ti yoo ba niyi nita, ile ni yoo ti niyi lọ. Ṣugbọn Aarẹ tiwa nigbagbọ pe ita loun yoo ti maa niyi wa sile nitori bẹẹ, awọn ohun to ba jẹ ti araata ni yoo mura lati ba wọn da si, ti yoo si fi ina buruku to n jo loriṣiiriṣii ni ile tirẹ silẹ. Nigba ti Buhari n lọ si Mali yii, o lo ibomu-bẹnu lati bo imu ati ẹnu rẹ, Naijiria nibi lo si ti gbe kinni naa lọ. Lara ohun ti awọn ti wọn n gbogun ti arun Korona yii kari aye sọ naa ni pe lati ma jẹ ki arun yii gbilẹ, afi ki gbogbo ẹni to ba fẹẹ jade sita, tabi to ba fẹẹ gbalejo, tabi ti yoo ba wa laarin eeyan meji mẹta, lo ibomu-bẹnu. Ṣugbọn lati ọjọ ti Buhari ti n jade ni Naijiria, tabi to n ba awọn eeyan sọrọ, ko lo kinnni naa ri. Boya lo si mọ pe ohun to n ṣe yii ni ọpọ awọn alaṣẹ ilu n ṣe, ti ọgọọrọ eeyan nilẹ Hausa n ṣe, oun ni wọn n fara we, nigba ti oun to jẹ olori ilu ko ṣe bẹẹ, kin ni araalu yoo maa ṣe bẹẹ si. Iye oku to nikan sun ni ilẹ Hausa, agaga ni Kano ati Katsina, wọn ko ṣee ka niye tan bayii o. Lojoojumọ, iku ni. Kin ni Buhari ri ṣe si iru nnkan bayii. Tabi eleyii ko to ohun to n dẹru ba olori ijọba ni. Awọn olori ologun to yẹ ko ri si iru nnkan bayii, gbogbo wọn lo ti rẹ, gbogbo aye lo si n pariwo pe ki Buhari paarọ wọn, ṣugbọn Buhari ko ṣe bii ẹni pe oun gbọ, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan naa ko wulo fun Naijiria mọ. Ninu awọn minisita ati awọn ti wọn n ba a ṣejọba, ija buruku to n lọ laarin wọn ko ṣee gbọ, wọn aa ma ṣe tanadi ara wọn debii pe iṣẹ ijọba to yẹ ko lọ deede ko ni i lọ deede, ipalara oriṣiiriṣii lo si n lọ. Buhari to ni oun yoo gbogun ti iwa ibajẹ, iwa ibajẹ to wa ninu ijọba tirẹ funra rẹ ju eyi ti a ti n ba bọ latẹyin lọ. Awọn ohun to yẹ ki Buhari moju to gbogbo ree nile, awọn ohun to yẹ ki awọn oludamọran ẹ ba a sọ niyi! Tabi kin ni iṣẹ awọn to n gba Buhari nimọran! Bo ba si jẹ oun ni ko gbọ amọran wọn, ki wọn fi iṣẹ rẹ silẹ, ki aye le mọ ibi ti wọn yoo doju ọrọ wọn kọ. Ẹ gba a nimọran tootọ, ẹ jẹ ko mọ pe ẹni ti ko ba niyi ninu ile ẹ, ko ni i niyi nita o!

 

Abi kin ni baba yii yoo ṣe si tawọn ti wọn ko owo NNDC jẹ

Iwa ibajẹ inu ijọba yii le debii pe awọn ẹgbe oṣelu PDP pe lọsẹ to kọja pe ki Buhari kọwe fi ipo rẹ silẹ, nitori apa rẹ ko ka igbogun ti iwa ibajẹ yii mọ rara, ati ki awọn ti wọn n kowo jẹ ma wo Naijiria yii mọ gbogbo wa lori. Loootọ ẹgbẹ PDP naa ki i ṣe ẹni ti eeyan n ka ọrọ wọn si, nitori awọn naa ko kuku san to ba di ibi owo-kikojẹ, ṣugbọn awọn ohun to ṣẹlẹ lasiko yii ko le jẹ ki eeyan ko ọrọ wọn danu patapata. Ẹ jẹ ka fi ọrọ Magu ati Malami silẹ sẹgbẹẹ kan, ẹ jẹ ka wo ohun to n ṣẹlẹ nileeṣẹ ijọba ti wọn da silẹ fun idagbasoke agbegbe Naija-Delta, iyẹn NNDC (Niger Delta Development Commission). Awọn owo ti wọn ni wọn ko jẹ to foju han, ati awọn ọrọ aṣiwere ti wọn kọ siwee nipa bi wọn ṣe nawo naa jẹ ohun ti ko le mu orukọ orilẹ-ede yii ni iyi kan lẹyin odi rara. Lasiko ti Korona mu gbogbo eeyan yii, ti ijọba ṣofin pe ki ẹnikẹni ma jade, ileeṣẹ yii si kọ ọ sinu iwe wọn pe awọn fi milọnu ọtalelẹgbẹta o din mẹrin naira (N656m) ṣe idanilẹkọọ fawọn oṣiṣẹ awọn. Lasiko Korona! Awọn oṣiṣẹ wọn ko lọ sibi iṣẹ o, awọn kan kan jokoo sibi kan, wọn si ko owo naa jẹ, wọn si gbe e sinu iwe bẹẹ, pẹlu igbagbọ pe ko sẹni ti yoo yẹ awọn lọwọ wo. Awọn owo ti wọn ṣẹ si minisita wọn, Godswill Akpabio, lọrun ki i ṣe kekere, o si daju pe ọkunrin naa ti inu PDP waa kowo jẹ ninu ijọba APC yii ni. Ẹni ti wọn fi ṣe olori ileeṣẹ yii, nigba ti ọrọ da bayii, ti awọn aṣofin ni ko waa rojọ ohun to mọ, o kuku wa sibẹ o. Ṣugbọn ibeere ẹyọ kan ni wọn bi i, n lo ba daku pata. Ko si ji saye ti wọn fi gbe e jade, igba to jade lo ji saye pada. Akpabio ti wọn pe ko waa rojọ naa dewaju awọn aṣofin, o si sọ ọ loju wọn nibẹ pe gbogbo owo ti wọn n sọrọ ẹ pe o sọnu yii, pupọ wa lọwọ awọn aṣofin gan-an funra wọn, nitori awọn ọmọ ile-igbimọ naa gba iṣẹ lọwọ NNDC ti wọn ko si ṣe e, wọn si ti gbowo ẹ. N lawọn aṣofin ba binu, wọn ni ko maa lọ. Meloo leeyan waa fẹẹ ka ninu iwa ibajẹ to n lọ nileeṣẹ kan ṣoṣo. Gbogbo wa la n pariwo pe ijọba ko ran awọn ara Naija Delta, nibi ti wọn ti n wa epo bẹntiroolu ni Naijiria lọwọ, ṣugbọn awọn aṣiri to jade yii n fi han pe awọn oloṣelu Naija Delta gan-an lọta awọn eeyan wọn. Ṣugbọn Buhari lo yan awọn araabi yii sipo, ṣe bi yoo ṣe waa maa wo wọn niran ti wọn yoo ba aye jẹ, ti wọn yoo tun ba ọrun jẹ ree, ti wọn yoo si sọ Naijiria di ilu oniyẹyẹ laarin awọn orilẹ-ede aye gbogbo. Ko si ohun to n jẹ ki awọn eeyan yii mura si ole jija ju pe ijọba wa ki i ṣe nnkan kan fun wọn, paapaa ti wọn ba ti jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu wọn tabi ti wọn ba sun mọ Aarẹ funra rẹ. Ohun to n ba gbogbo ẹ jẹ ree o. Ẹ bẹ Buahri ko ma ṣe bii ẹni pe oun ko gbọ ọrọ awọn akowojẹ wọnyi, ko jẹ ki wọn ju wọn sẹwọn, ki Naijiria le sinmi.        

 

Bẹẹ o yẹ ki wọn fi iku Issa Funtua yii ṣe arikọgbọn

Ismail Issa Funtua, ọkan ninu awọn ti wọn sun mọ Buhari ju lọ ku lọsẹ to kọja yii. Bo ti ku laaarọ ni wọn ti palẹ oku ẹ mọ, koda, wọn ko rẹ ibi ti wọn sin in si, wọn kan ko yeepẹ le e lori lasan ni. Bẹẹ ni baba naa lọ. Ṣugbọn ninu awọn ti wọn lu ọmọ Naijiria ni jibiti to pọ ju lọ laye yii, ọkan ni Issa Funtua, awọn ekute ile to n jẹun nile ijọba gbogbo to ba ti jẹ ni Naijiria yii ni. Ṣugbọn laye ijọba Buhari yii ni Funtua di ikooko, ẹran nla lo ku to n gbe; o di kalokalo miwo miwo, o si n ko owo ọmọ Naijiria mi. Ọkunrin naa ko ni iṣẹ gidi kan, loootọ oniroyin ni, ṣugbọn lati ọdun 1980 to ti da iwe iroyin Democrat silẹ, ti iwe naa si ti ku ni bii ọdun marun-un lẹyin ẹ, ọkunrin yii ko ṣiṣẹ mi-in mọ, ka maa jẹ nidii ijọba to ba jẹ nikan lo n ṣe. Ohun to waa mu ti asiko Buhari yii le ni pe oun nikan ni ọrẹ ati ana Buhari ninu awọn mẹta ti wọn sun mọ ọn ju lọ. Awọn ti wọn n ba Buhari ṣejọba rẹ ree, oun, Maman Daura ati Abba Kyari. Nitori eyi lo ṣe n fi orukọ Buhari gba oriṣiiriṣii iṣẹ ijọba. Oun lo sun ọkunrin kan, Emefiele, kẹrẹkẹrẹ titi ti Buhari fi fi iyẹn ṣe olori banki apapọ ilẹ wa. Lati igba naa ni Funtua ti n gba owo dọla ni Central Bank, ti yoo ni oun fẹẹ fi raja kan lati oke-okun, ṣugbọn to jẹ awọn Mọla to n ṣẹwo ni yoo ta a fun, ti yoo si tibẹ ri ere rẹpẹtẹ ti awọn ti wọn nileeṣẹ nla ko le jẹ. Funtua gba iṣẹ ọgbọn biliọnu lọwọ Central Bank, o loun yoo ba wọn fi kọ aaye igbọkọ si (Car Park), si ileeṣẹ wọn l’Abuja. Bi eeyan ba tilẹ fẹẹ kọ aaye mọto fun gbogbo aye, owo rẹ wa gbọdọ to bẹẹ! Funtua ati ọkọ ọmọ rẹ fi jibiti ra banki Keynote. Bi wọn ṣe ṣe e ni pe ọkọ ọmọ rẹ lo wa nileeṣẹ ijọba to maa n gba awọn ileeṣẹ to ba jẹ gbese, tabi ti wọn fẹẹ kogba wọle (AMCON). Ọkọ ọmọ rẹ yii lo gba banki Keynote lorukọ ileeṣẹ yii, ti wọn ni ki awọn eeyan waa ra a. Funtua lawọn yoo ra a, bẹẹ ni Funtua ko lowo lọwọ. Ni ọkọ ọmọ rẹ ba gbowo lati ileeṣẹ AMCON, o gbe e si banki kan, banki naa ni awọn ya Funta lowo, ni wọn ba fi ra banki naa, wọn waa ni ki banki yii maa san gbese naa pada diẹ diẹ. Bi ileeṣẹ naa ṣe di tiwọn niyẹn. Nitori pe o sun mọ Buhari yii, ko sohun to nawọ si ti ko to o lọwọ. Ni awọn gomina, awọn minisita, awọn oloṣelu Naijiria gbogbo ba n wọ lọ sile ẹ bii pe oun gan-an ni olori ijọba. Ṣugbọn o ku lọṣẹ to kọja, o fi aye silẹ lai dagbere. Gbogb ohun to fi ọna buruku ko jọ yii, ko duro lati jẹ ere ọkankan nibẹ, nitori Ọlọrun fi han an pe oun ju gbogbo ẹda aye lọ. Ko si ọna mi-in ti awọn oloṣelu Naijiria fi le kọgbọn ju iru eyi lọ. Oloṣelu to ba fẹẹ ṣoriire, ko fi ti Funtua kọgbọn, ko ma wa ile aye mọya, ko mọ  pe ile aye ki i ṣe awaa lọ.

 

Ṣebi ẹ ri Dogara to n sare aye kiri

Nijọ kan, awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria yoo gbọn daadaa lati mọ pe awọn eeyan ti wọn n rin kaakiri ti wọn n pe ara wọn ni oloṣelu yii, oniṣowo to n wa owo kiri nidii okoowo wọn ni gbogbo wọn. Bẹẹ ni ko si okoowo meji ti wọn n ṣe ju oṣelu lọ, owo araalu ni wọn fẹẹ gba, ki wọn maa jẹ ohun to jẹ ti gbogbo ilu nikan lo wa lọkan wọn. Ifẹ araalu, tabi ti idagbasoke ilu kan bayii ko si lọkan wọn, ibi ti awọn yoo ti ri jijẹ-mimu tiwọn nikan ni wọn n wa, ki wọn si ri owo ti wọn yoo fi ṣeranu gidi kiri. Ohun to ṣe rọrun fun wọn lati kuro ninu ẹgbẹ oṣelu kan bọ sinu omi-in ree, ti wọn yoo maa paarọ ẹgbẹ oṣelu bii ẹni to n paarọ aṣọ. Tabi ẹ ko ri olori ile-igbimọ aṣofin wa tẹlẹ, Yakubu Dogara. Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni, inu ẹgbẹ naa lo si wa to fi di ara ile-igbimọ aṣofin ni 2007. Lẹyin to ti lo saa meji nile-igbimọ yii, o kuro ninu ẹgbẹ naa ni 2014, o dọmọ APC. Ni 2018, Dogara kuro ni APC, o tun pada sinu PDP. Lọsẹ to kọja yii, Dogara tun fi PDP silẹ, o si pada sinu APC. Ẹ jẹ ka bi ara wa, iru anfaani wo ni iru eeyan jakujaku bayii yoo ṣe fun ilu. Wọn yoo kan maa kowo ilu jẹ naa ni. Wọn ko ranti ọjọ iku tabi ọjọ ọla, owo ati ipo nikan ni wọn n le kiri. Ole ni wọn o, awọn alaparutu eeyan, awọn oniranu gbogbo!

 

Bẹẹ naa l’Oshiomhole, a-turọ-ta-bii elubọ

Ọkunrin Adams Oshiomhole yii ni yoo jẹ ki wọn maa bu awọn eeyan kukuru. Bi wọn ba n sọ pe eeyan kukuru biliisi, iru awọn Adams yii lo jẹ ki wọn maa wi bẹẹ. Biliisi gan-an lọkunrin naa, ki i ṣe ẹni to ṣee duro ti rara. Oshiomhole lo ba aye Ize-Iyamu jẹ ni 2016, to sọ pe ole ni, o kowo jẹ, ọmọ ẹgbẹ okunkun si ni, to n sọ pe ko si meji iru Godwin Obaseki, to ni oun fi Ọlọrun bura lori saare baba oun, Godwin lo dara ju ni ẹni to le ṣe gomina Edo. Oshiomhole naa lo n fo soke bayii pe Godwin yii ko daa, Ize-Iyamu ti oun pe ni ole lọjọsi lo daa ju lọ. Nigba  ti yoo ba ọrọ jẹ, o ni nitori Ọbaseki ko ri gomina ṣe lo ṣe kuro ninu APC, pe eeyan gidi kan ki i fi ẹgbẹ oṣelu to wa silẹ, ohun ti oun fi jẹ ọga niyẹn, nitori oun ko jẹ fi ẹgbẹ oṣelu oun silẹ. Ọkunrin yii ti gbagbe pe inu ẹgbẹ Labour loun wa tẹlẹ ki oun too sa lọ sinu ẹgbẹ AC, ki wọn too jọ waa di ọmọ ẹgbẹ APC. Nigba ti eeyan ba ti le parọ ju, iwa ọmọluabi yoo jinna si i. Bẹ ẹ ba ri Oshiomhole, ẹ jinna si i o, eeyan kukuru biliisi ni.

Leave a Reply