O ṣoju mi koro

Ki lawọn naa fi yatọ si Hushpuppi, onijibiti agbaye

Bi eeyan ba wo awọn ti wọn n ṣe ijọba yii daadaa, yoo ri i pe iyatọ diẹ lo wa laarin awọn ati Hushpuppi, iyẹn Ramọni Ọlọrunwa Abas, onjibiti agbaye ti wọn n pariwo. Jibiti ni Hushpuppi n lu, awọn ti wọn si n ṣejọba wa yii, onijibiti pọ ninu wọn. Ariwo ti awọn ti wọn n ṣejọba yii n pa bayii ni pe awọn fẹẹ fun awọn ọdọ ti ko niṣẹ ni iṣẹ gidi, awọn yoo si fun ẹgbẹrun kọọkan (1000) ọdọ niṣẹ ni ijọba ibilẹ kọọkan. Bi eeyan ba ranti pe ijọba ibilẹ ọrinlelẹẹẹdẹgbẹrin-din-mẹfa (774) nijọba ibilẹ to wa ni Naijiria, ohun to tumọ si ni pe, ẹgbẹrun lọna ọrinlelẹẹẹdẹgbẹrin-din-mẹfa yii ni ijọba fẹẹ fun niṣẹ. Ko si ẹni ti yoo gbọ iru eleyii ti ko ni i kan saara si ijọba to ba ṣe bẹẹ, nitori iye awọn eeyan ti wọn ni awọn fẹẹ fun niṣẹ yii pọ rẹpẹtẹ. Ṣugbọn ki i ṣe iṣẹ gidi nijọba yii n sọ, nibi ti jibiti wọn si ti foju han gedegbe niyi. Wọn ni awọn fẹẹ fun awọn ọdọ yii ni iṣẹ ki wọn la gọta, ki wọn mojuto oju popo nipa didari mọto loju ọna lati ri i pe ko si goosilo nibi kankan, ki wọn si palẹ awọn idọti mọ lati ri i pe gbogbo agbegbe lo mọ toni toni. Oṣu mẹta ni wọn yoo fi gba wọn siṣẹ naa, ogun ẹgbẹrun Naira ni wọn yoo san fun wọn loṣu kọọkan, bi oṣu mẹta ba si ti pe, kaluku yoo pada sile ẹ, iṣẹ tan naa niyẹn. Iṣẹ oṣu mẹta! Jibiti wo lo ju bẹẹ lọ. Bẹẹ wọn ko sọ sita pe oṣu mẹta lawọn fẹẹ fi fun awọn eeyan yii niṣẹ, wọn kan n pariwo pe awọn fẹẹ gba awọn ọdọ siṣẹ ni. Nigba ti eeyan ba fi oṣu mẹta ṣiṣẹ, to tun pada di ẹni ti ko niṣẹ lọwọ mọ, tawọn araalu ko si ni i tete mọ pe iṣẹ ti bọ lọwọ wọn. Paripari rẹ ni pe biliọnu mejilelaaadọta Naira ni wọn ni eto naa yoo na wọn. Itumọ iru iṣẹ ati ifowoṣofo bayii ko yeeyan, o si jọ pe awọn kan wa nibi kan ti wọn kan fẹẹ ko owo yii mi ni. Ijọba ibilẹ meloo lo wa ni ilẹ Hausa ti goosiloo wa nibẹ, tabi ti mọto to wa ni gbogbo ibẹ to aadọta, awọn wo ni wọn fẹẹ gba siṣẹ nibẹ yẹn. Tabi idọti wo ni wọn fẹẹ ko nibẹ, tabi oju ọgbara wo ni wọn fẹẹ tun ṣe nigba ti ko si gọta nibẹ, ti ko tilẹ si titi paapaa. Ijọba yii kan fẹẹ lu araalu ni jibiti ni, wọn yoo sọ pe awọn ti fawọn eeyan niṣẹ, bẹẹ, wọn kan fẹẹ da kun iṣoro wọn lasan ni. Ki lo de ti ijọba ko fowo yii da awọn ileeṣẹ keekeeke silẹ, ki wọn si gba awọn ọdọ yii si i. Ewo ni inakunaa bayii paapaa! Jibiti lasan ni, awọn Hushpuppi!

    

Ẹ fi iyawo Ajimọbi silẹ, yoo ye e nigba to ba ya

Wọn ni wọn tun dina mọ igbakeji  gomina Ọyọ ko ma debi ti wọn ti n ṣadura ọjọ mẹjọ Ajimọbi. Ko si ohun to buru ninu iyẹn naa, ohun daadaa ni. Eyi to si dara ju naa ni pe gbogbo aye yoo ri i pe ijọba ti ṣe ojuṣe ti wọn gbọdọ ṣe fun iku gomina tẹlẹ fun ipinlẹ wọn. Ohun to fa gbogbo eleyii ko yeeyan. Ọrọ oṣelu Najiiria, obinrin to ba n gbeja ọkọ rẹ nidii ẹ ko nikan i ṣe. Loju iyawo Ajimọbi, oun n gbeja ọkọ rẹ niyi o. Awọn ti wọn n ba ara wọn ja, ti wọn mọ ohun to n fa ija laarin ara wọn. Bi ko ba jẹ iku Ajimọbi, bawo ni ilu yoo ṣe mọ pe ọrọ ija ilẹ to tobi to bẹe yẹn wa laarin oun ati ijọba tuntun. Awọn araalu ti wọn ki i ro arojinlẹ, nigba ti wọn ba ri awọn oloṣelu yii ti wọn n fapaa janu pe ẹni kan lawọn fẹẹ gbejọba fun, wọn yoo ro pe nitori tiwọn ni. Ajimọbi n ja pe ki Adelabu wọle, ṣe nitori awọn ara ipinlẹ Ọyọ ni abi nitori lati bo gbogbo ohun ti wọn ṣe yii mọlẹ. Ṣe iyawo Ajimọbi mọ gbogbo eyi, to ba si mọ ọn, ṣe ohun to dara lawọn ọkọ rẹ n ṣe yẹn. Eeyan to ti ṣe gomina ipinlẹ kan ri waa n ṣe aisan to le to bẹẹ, ko jẹ ki gomina to wa lori oye mọ, wọn pe sọtun-un, wọn pe sosi, ẹ ko da wọn lohun, ṣe ija oṣelu yii naa ni. Ki obinrin yii too mọ pe oun nilo ijọba yii ju gbogbo awọn ti wọn n pariwo lẹyin oun yii lọ, Ọlọrun ko ni i jẹ ki ọrọ naa ti bọ sori fun un. Ko le pẹ, ko le jinna, ti gbogbo awọn ti o n ri lẹyin rẹ yii yoo fi yẹra, boya obinrin naa ko si ranti pe gbogbo dukia wọn n’Ibadan yii, ọwọ ijọba lo wa. Ati pe obinrin Yoruba kan ki i ṣe bẹẹ yẹn sọrọ si agbalagba ọkunrin gẹgẹ bi iyawo Ajimọbi ti ṣe si igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ lọjọ ti wọn lọọ ki i. Ọrọ naa yoo lẹyin to ba ya, o si daju pe awọn abani-da-a to n ti i yii ko ni i ba a debẹ to ba ya.


Akederodu pẹlu iyawo rẹ

Iroyin jade pe gomina Akeredolu ko Korona, oun ati iyawo rẹ, ati awọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ. Aworan fidio to jade fi han pe Akeredolu ko mojuto kinni naa to bo ṣe yẹ, gbogbo ofin ti wọn ni ki awọn eeyan maa tẹle ki wọn ma baa ko Korona yii, gbogbo ẹ ni Akeredolu n ru, o si daju pe ko le ru ofin bayii ki ọrọ ma kan iyawo rẹ atawọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ. Bi Akeredolu ba si ti n da gbele, iyawo rẹ naa gbọdọ tẹle e. Iyẹn lo ṣe yaayan lẹnu nigba ti iyawo rẹ waa fa ibinu yọ pe oun yoo gbe awọn iwe iroyin to kọ ọ jade pe oun ni Korona lọ sile-ẹjọ. O ni bi oun tilẹ ni arun naa, oun ki i ṣe oṣiṣẹ ijọba, nipa bẹẹ, ko si ẹni to lẹtọọ lati maa tu aṣiri ilera oun faye gbọ. Ẹ ti gbọ ọ ri! Ki iyawo Akeredolu loun ki i ṣe oṣiṣẹ ijọba!  Ṣugbọn inu rẹ n dun ti wọn ba pe e ni First Lady, inu ẹ n dun ti wọn ba ko awọn ọlọpaa fun un, ti wọn ni ki wọn maa rin lẹyin ẹ kaakiri ibi to ba n lọ; inu rẹ dun pe wọn ko awọn oṣiṣẹ ijọba rẹpẹtẹ si abẹ rẹ, wọn si fun un ni ọọfiisi ti yoo maa lo gẹgẹ bii obinrin akọkọ ni ipinlẹ Ondo, bẹẹ ni wọn si n ya oriṣiiriṣii owo sọtọ fun un. Gbogbo ẹni to ba ti n gba iru awọn owo bayii ko ni aṣiri kankan mọ, oṣiṣẹ ijọba taara ni. Ki lo de ti Iyawo Akeredolu ko kọ owo ti wọn n fun un, ki lo de ti ko le awọn ọlọpaa ijọba ti wọn n ṣọ ọ kuro lọdọ rẹ, ki lo de to n lọọ jokoo si ọọfiisi ijọba, tabi ko mọ pe owo awọn ara Ondo ni gbogbo owo ti oun n na yii ni. Ki waa ni aṣiri ti yoo sọ pe o wa ninu eto ilera oun, tabi ki awọn eeyan laju silẹ ko ko kinni naa ran awọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ ni. Ko niṣo nile-ẹjọ, ṣebi awọn lọọya yoo kan fi i jẹun lasan ni. Yẹyẹ!

 

Ṣugbọn Josẹẹfu Alalaa ni Igbakeji gomina Ondo

Ọgbẹni Agbọọla Ajayi ko yatọ si Josẹẹfu alalaa inu bibeli ati kuraani, iyatọ to kan wa nibẹ ni pe ala ti oun n la ni pe yoo di gomina Ondo. Bẹẹ ni ki i ṣe ibo ti wọn fẹẹ di lo n duro de, ala to la, ala ti yoo sọ ọ di gomina nitori Korona to mu Akeredolu to n ṣe gomina lọwọ lọwọ bayii ni. Bi ọrọ awọn oloṣelu ti ri lẹ ri yii, ko si ohun ti wọn ko le fi ṣe oṣelu, bẹẹ ni wọn ki i ro tẹlomi-in mọ tiwọn bi ọrọ ba ti di ọrọ oṣelu bayii. Agboọla gbọdọ kun fun adura gidigidi, nitori bi Koro to mu Akeredolu ba fi le ju bayii lọ, to fi waa di pe wọn n pe oun Agboọla ko waa ṣe gomina, wahala ti awọn APC, ati awọn araalu ti wọn fẹran Akeredolu yoo ko balẹ fun un, yoo ṣoro ki apa rẹ too ka a. Eeyan ki i ro iku ro ẹni keji ẹni, tabi pe ki aiyaara rẹ le debi ti a o fi gba ipo to wa, ohun ti ko dara gbaa ni. Agboọla mọ pe yoo ṣoro ki Akeredolu too gbejọba foun. Ti Akeredolu ba gbejọba fun un bayii, eto ẹgbẹ oṣelu wo ni yoo maa ṣe ninu ijọba rẹ, ṣe ti PDP to wa bayii ni yoo maa ṣe ni abi ti APC to ti kuro. Iyawo to kọọyan silẹ, to lọ sile ọkọ mi-in, to waa gbọ pe ara ẹni ko ya, to ni oun n bọ waa ṣetọju, ta ni ko mọ pe yoo pa alaaarẹ ọkọ rẹ atijọ yii ni. Bi nnkan ṣe wa bayii, bi ijọba ipinlẹ Ondo ba bọ sọwọ Agboọla ọmọ PDP, yoo ba ijọba naa jẹ kọja atunṣe, debii pe nigba ti Akeredolu ba gbadun to ba pada sile ijọba, ko si kinni kan ti yoo ye e mọ. Ewo lo n kan ọkunrin Agboọla yii loju to n soyinbo, ṣebi ibo ti n bọ, oun naa si ti wa ninu PDP, bi wọn ba fa a kalẹ, ko lo gbogbo agbara rẹ lati wọle di gomina, gbogbo araalu ni yoo pọn ọn le bi iyẹn ba ti ṣẹlẹ. Ṣugbọn to ba jẹ o n reti lati gba ọna ẹburu di gomina lẹyin ti aiyaara ba da Akeredolu jokoo ni, ọrọ rẹ yoo da bii ti ẹni to n wo iṣẹju akan ni o, yoo pẹ leti omi gan-an ni.

Awọn oloṣelu Ekiti yii, nnkan lọrọ wọn o

Fayẹmi, Ojudu, Adeyẹye, ọmọọya kan naa lawọn mẹtẹẹta, ija lo de lorin dowe ni. Fayọṣe nikan ni ki i ṣe ọmọoya wọn, nitori ẹgbẹ oṣelu ọtọ loun wa. Eyi to waa fẹẹ faja bayii ni pe awọn kan fẹẹ fi ile iya ati baba wọn silẹ, wọn fẹẹ lọọ ba Fayoṣe ninu ile baba tirẹ, n loun ba ti ibinu bọlẹ, o loun ko fẹ alejo ninu ile baba oun. Ojudu lo sọ pe Fayẹmi to n ṣe gomina n lọ si PDP. N lawọn ọmọ ti Fayẹmi naa ba ni Ojudu lo n lọ sibẹ. Loootọ ni Ojudu ni bi oun ba ti ku, ti wọn ba gbe asia PDP wa si ibi saare oun, oun yoo ji dide. Ṣugbọn awọn eeyan ni o n janbula ẹnu lasan ni, wọn ni  Dayọ Adeyẹye to ri yẹn ti sọ ju bẹẹ lọ. PDP ni Adeyẹye tọkan-tara tẹlẹ, oun naa si maa n leri kiri pe ko si ohun ti yoo gbe oun de isọ awọn APC, afi bi ọrọ ibo ṣe sun mọle ti wọn fa a kalẹ ninu APC, kinni ọhun si tobi loju rẹ ti ko fi le sọ pe oun ko ṣe. Fayoṣe to si n halẹ naa, ki i kuku ṣe pe PDP yii naa toro l’Ekiti, ojoojumọ ija ni, ija to si wa laarin awọn paapaa ju ija orogun lọ. Omọ APC to ba waa lọọ ru ara rẹ ba wọn ni PDP, yatọ si pe ko ni i ri ohun to ro pe oun yoo ri gba gba, ẹtẹ lasan ni yoo kangun ọrọ rẹ. O digba ti a ba fi kọra ni Naijiria yii, pe inu ẹgbẹ oṣelu kan leeyan n duro si to ba jẹ tootọ lo fẹran awọn eeyan rẹ, ti ki i ṣe pe yoo maa fo kiri nitori ijẹkujẹ: ko le di minisita, ko le di sẹnetọ, tabi ko di gomina, to si jẹ gbogbo ẹ naa, aajo aje ni, nitori atijẹ lasan ni. Bawọn aṣaaju APC yii ba n ba rakatia bayii kiri, ti awọn PDP fi gbajọba lọwọ wọn, epe lawọn ọmọlẹyin wọn yoo maa gbe wọn ṣẹ, wọn ko si ni i lẹnu lati pe ara wọn ni oloṣelu gidi nibi kan. Ki kaluku so ewe agbejẹ mọwọ o. 

Leave a Reply