O doju ẹ, Ṣoworẹ mu babalawo lẹyin wọ kootu l’Abuja

Faith Adebọla

 

 

 

Awo-lanu lawọn eeyan n wo iran to ṣẹlẹ nile-ẹjọ Majisreeti agba kan to wa ni Wuse, l’Abuja, laaarọ ọjọ Iṣẹgun yii, nigba ti ajafẹtọọ ọmọniyan ati alaṣẹ atẹ iweeroyin SaharaReporters nni, Ọmọyẹle Ṣoworẹ, gbe babalawo to wọṣọ oogun abẹnugọngọ kan lẹyin lati lọọ jẹjọ ni kootu ọhun.

Bo ṣe wa ninu fidio kan nipa iṣẹlẹ ọhun to n ja ranyin lori atẹ ayelujara, iyalẹnu lo jẹ bawọn eeyan ṣe ri Ṣoworẹ to yọ ganboro si kootu naa pẹlu babalawọ kan to wọ aṣọ oogun abẹnu gọngọ pẹlu apo kan to gba mẹgbẹ, bẹẹ ni baba naa tẹle Ṣoworẹ ni ṣiṣẹ-n-tẹle wọ kootu naa.

Ọj Iṣẹ́gun, Tusidee, ọsẹ yii, ni igbẹjọ n tẹsiwaju lori ẹjọ ti Ṣoworẹ n jẹ lọwọ, ijọba apapọ lo fẹsun adaluru kan an, ti wọn si lo fẹẹ soju ijọba de.

Latinu oṣu ki-in-ni, ọdun yii, ni ajafẹtọọ yii ti n jẹjọ ọhun, bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ ti faaye beeli silẹ fun un.

Leave a Reply